Orin Kan: Ọkan Ọba Wa lọwọ Oluwa
(“Aiya Ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odo omi: on a si dari rẹ si ibikibi ti o wu u” (Owe 21:1))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọna ara l’Ọlọrun wa
Ngba sisẹ rẹ l’aiye
A nri ‘pasẹ rẹ lor’ okun
O ngun igbi l’ẹsin
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ọkan Ọba wa ni ọwọ
Oluwa b’od’ omi
Oluwa lo si ndari rẹ
Sibikibi to fẹ
2. Gẹgẹ b’ọkan ọba ti mbẹ
Ni ọwọ Oluwa
Bẹna l’ọkan enia gbogbo
To ngbe ninu aiye
3. Ọga ogo nis’ olori
Ni ‘jọba enia
Oun a si fi ijọba fun
Ẹnikẹni to wu
4. Gbogb’ ẹnyin to nse akoso
Awọn enia ‘nu aiye
Ẹ m’aisedede jinna si
Ibugbe yin laiye
5. Ẹ f’ododo j’ẹsẹ kuro
Leto isejọba yin
Ẹ fi anu han fun awọn
Talaka abẹ yin
6. ‘Gbati ẹ ba se eleyi
‘Gbana ni Oluwa
Yo fidi ‘jọba yin mulẹ
Lor’ awọn eniyan

Comments
Post a Comment