Orin Kan: Oluwa, Ọlọrun Alanu

 (“Oluwa si rekọja niwaju rẹ, o si nkepe, Oluwa, Oluwa, Ọlọrun alanu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ li ore ati otitọ” (Exo 34:6))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olodumare

Ni kutukutu n’Iwọ o gbọ orin wa

Mimọ, Mimọ, Mimọ oniyọnu julọ

Ologo mẹta lai olubukun”

Ẹniti o Kọrin Yi: Reginald Heber (1826)


 


Orin Titun na Nìyí

1. Oluwa Ọlọrun oni ipamọra

Alanu ati olore-ọfẹ ni Ọ

‘Wọ nikan ni o pọ l’ore at’otitọ

‘Wọ to np’anu mọ fun ẹgbẹgbẹrun

 

2. Oluwa Ọlọrun aniwọ nikan ni

O le dari gbogbo ẹsẹ taba sẹ ji

Ati irekọja, at’ aisedede gbogbo

Niwọ ti f’ ẹjẹ rẹ parẹ pata

 

3. Oluwa Ọlọrun lotọ lo ndar’ ẹsẹ ji

Sugbọn ki yo jẹ k’ẹlẹbi lọ laijiya

A ma b’ẹsẹ obi wo ni ara ọmọ wọn

Ati lara ‘wọn ‘mọ-‘mọ deran kẹrin

 

4. Oluwa Ọlọrun mo wolẹ nwaju Rẹ

Mo foribalẹ fun ‘wọ ‘ba ayeraiye

Ami rẹ t’ tobi to at’agbara ‘sẹ ‘yanu rẹ

‘Jọba ainipẹkun na nijọba rẹ

 

5. Oluwa Ọlọrun ‘wọ ba jẹ k’emi ri

Ore ọfẹ to g agba ni oju rẹ

Gẹgẹ b’awọn baba gbagbọ to t’ kọja lọ

Ti se ri Ore ‘fẹ nla gba l’ọdọ rẹ

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan