Orin Kan: Ma Gba Ọrẹ Kan Gbọ
(“Ẹ ma gba ọrẹ kan gbọ, ẹma si gbẹkẹle amọna kna: pa ilẹkun ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sun ni okan-aiya rẹ.” (Mika. 7:5))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“’Yo dahun gbogb’ adura
Ileri ati ‘fẹ rẹ
Ko sa ti yi pada ri
Ogo f’okọ rẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ma se gbẹkẹl’ ẹnikan
Ninu aiye ta wa yi
T’or’ ọkan enia le
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
2. Ẹ ma gba ọrẹ kan gbọ
Ẹ ma gbẹkẹl’ amọna kan
T’or’ ọkan enia jin
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
3. Pa ‘lẹkun ẹnu rẹ mọ
Ko da f’ẹnit’o gbori
Rẹ le okan aiya rẹ
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
4. Mase gb’ ẹnikẹni gbọ
‘Tor’ awọn ọmọkunrin
Le sai nani baba wọn
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
5. Lasan ni gbẹkẹle enia
‘Tor’ awọn ọmọbinrin
Le did’ ogun si ‘ya wọn
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
6. Ani awọn aya-ọmọ
Le did’ ogun siyakọ wọn
Ninu aiye leyi wa
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
7. Jesu at’ awọn woli ‘pe
Ọta ‘kaluk’ eniyan
Sa lawọn ara ile rẹ
Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ
Comments
Post a Comment