Orin Kan: Ma Yọ Mi, Iwọ Ọta Mi: Nigbati Mo Ba Subu, Emi O Dide
(“Ma yọ mi, iwọ ọta mi: nigbati mo ba subu, emi o dide; nigbati mob a joko li okunkun, Oluwa yuio jẹ imọlẹ fun mi.” (Mika. 7:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Wa nigbati Kristi npe ọ
Wa, ma rin ‘na ẹsẹ mọ
Wa tu gbogb’ ohun t’o de ọ
Wa bẹrẹ ‘re ‘je tọrun
Ègbè
O npe ọ, nisiyi
Gbọ b’olugbala tin pe
O npe ọ, nisiyi
Gbọ b’olugbala ti npe”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gba temi nrin lọ lokunkun
An’ afonifoji iku
To dab’ ẹnipe imọlẹ
K’yo tan mọ fun mi
Ègbè
Ma yọ mi ‘wọ ọta mi
‘Gba mob a subu ngo dide
‘Gba mo joko lokunkun
Oluwa o jẹ ‘mọlẹ mi
2. ‘Gba ti mow a ni aginju
Ti ko s’ounjẹ mo le jẹ
Ti ko tun somi lati mu
Tile aiye su mi
Ègbè
3. ‘Gba t’okun pupa wa nwaju
T’ogun Farao mbọ lẹhin
Oke lọtun ọgbun losi
Ti ngo r’ọna abayọ
Ègbè
4. ‘Gba mo padan’ ohun gbogbo
Ti mo ti sisẹ fun laye
Tobi, aya tabi ọkọ
Ti wọn kọ mi silẹ
Ègbè
5. ‘Gba mo padanu ọmọ mi
T’aya tab’ ọkọ mi ku
Ti ko si ‘reti mọ fun mi
Tab’oluranlọwọ
Ègbè
6. Bi mo subu nigba meje
Sibẹ em’o tun dide
‘Tor’Oluwa lo di mi mu
Oun k’yo si fi mi silẹ
Ègbè
7. Ma yọ mi iwọ ọta mi
Lasiko idamu mi
‘Tor’Oluwa mọ sohun gbogbo
Ti emi nla kọja
Ègbè
Comments
Post a Comment