Orin Kan: Sọtẹlẹ Ni Ìgbàgbọ
(“O tun wi fun mi pe, sọtẹlẹsori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ ọrọ Oluwa” (Esek. 37:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọrẹ
bi Jesu ko si laye yi
Oun nikan l’ọrẹ otitọ
Ọrẹ aye yi y’o fiwa silẹ
Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa
Ègbè
Ah! Ko jẹ gbagbe wa/2x
Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa”
Orin Titun na Nìyí
1. Ọwọ Oluwa wa lara Esekiel’
O mu jade ninu ẹmi Rẹ
Lọ s’arin afonifoji to kun
Fun orisirisi egungung
Ègbè
‘Gungun wọnyi yo ye/2x
Bo ba s’ọtẹlẹ s’ wọn ni ‘gbagbọ
2. Oluwa mu ko sir in yi wọn ka
Oun si ri pe wọn gbẹ pupọ
Oluwa bi lere bi wọn le ye
O dahun p’Oluwa lo le mọ
Ègbè
3. Oluwa wi pe ki o sọtẹlẹ
Sori gbogbo Egungun wọnyi
Oun si wipe ẹnyin egun gbigbẹ
Ẹ tẹti kẹ gbọrọ
Oluwa
Ègbè
4. Lẹhin ‘gba ti oun si sọtẹlẹ
Ariwo nla ta larin Egungun
Gba t’oun tun wo ‘wọn egungun na
O ri mimi nla larin wọn
Ègbè
5. Egungun si wa s’ọdọ Egungun rẹ
Bẹni
isan at’ ẹran ara
Bẹ pẹlu ni awọ bo wọn loke
‘Gbọn emi kan ko si ninu wọn
Ègbè
6. Gba t’oun gboju soke s’Oluwa
O sọ fun pe s’ọtẹlẹ n gbagbọ
Gba t’oun sọtẹlẹ Ẹmi wọ nu wọn
Gbogbo wọn dide lor’ ẹsẹ wọn
Ègbè
7. Egungun yin i gbogbo ‘le Israeli
Ti nwọn wipe Egungun wọn ti gbẹ
Ati pe ko si ‘reti fun wọn mọ
Iran wọn lasi ti ke kuro
Ègbè
8. Oluwa wipe Em’o sohun titun
Emi o s’iboj’ awọn enia mi
Ngo mu wọn joko ni ilẹ ti wọn
Wọn yo nireti ayeraiye
Ègbè
9. Awa Israeli t’Oluwa Ọlọrun
Ti gbogbo ireti ti pin fun
Awa ko ni lati sọreti nu
‘Toripe Ọlọrun wa fun wa
Comments
Post a Comment