Orin Kan: Ẹ Ma Gba Nkan Wọnyi Ro
(“Li akotan, ara, ohunkohun ti ise otọ, ohunkohun ti ise ọwọ, ohunkohun ti ise titọ, ohunkohun ti ise mimọ, ohunkohun ti ise fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi iwa titọ kan ba wa, bi iyin kan ba si wa, ẹ ma gba nkan wọnyi ro” (Fil. 4:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ìgbagbọ mi duro l’ori
Ẹ jẹ at’ododo Jesu,
Nko jẹ gbẹkẹle ohun kan
Lẹhin orukọ nla Jesu
Ègbè
Mo duro le Kristi Apata
Ilẹ miran, iyanrin ni”
Ẹniti o Kọrin Yi: Edward Mote (1834)
Orin Titun na Nìyí
1. Ohunkohun ti ‘se otọ
Ohunkohun ti ‘se ọwọ
Ohunkohun ti ‘se titọ
At’ohungbogbo ti ‘se mimọ
Ègbè
Ẹ ma gba ‘wọn nkan wọnyi ro
Ẹnyin ara mi n’nu Oluwa
2. B’ohunkohun ba jẹ fifẹ
At’ohun to nirohin rere
Biwa titọ kan ba si wa
Ani biyin kan ba si wa
Ègbè
3. Ẹ ma kiyesi ara nyin
Ẹ mase jẹ kiro ibi
Ki o wa s’okan aiya nyin
‘Tori awọn ‘rakọnrin nyin
Ègbè
4. B’ati nporisun omi mọ
Bẹni kẹ ma p’ọkan nyin mọ
Ani j’ohun ‘yebiye gbogbo
Ẹ ma tọj’ ero inu nyin
Ègbè
Comments
Post a Comment