Orin Kan: Ẹbùn Ọlọrun To Ga Julọ
(“Yio si bi ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pe orukọ rẹ: nitori on ni yio gba awọn enia rẹ la kuro ninu ẹsẹ wọn” (Matteu 1:21))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹ jẹ ka finu didun
Yin Oluwa Olore
Anu rẹ o wa titi
Lododo dajudaju
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹbun Ọlọrun faraiye
Jẹ ‘fẹ rẹ to ga julọ
To fi ‘han npa fifun wa
Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso
2. Ọlọrun nifẹ araiye
O si fun wa lẹbun nla
To fi ‘han npa fifun wa
Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso
3. Ohunt’eniyan ko le fun ni
L’Ọlọrun fi f’eniyan ni
To fi ‘han npa fifun wa
Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso
4. Ọfẹ lo fun wa lẹbun yi
Ẹbun aiyeraiye ni
To fi ‘han npa fifun wa
Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso
5. Ifẹ to ga julọ yi
Nigbala nip’ ore-ọfẹ
To fi ‘han npa fifun wa
Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso
6. ‘Wọ ọrẹ wa gb’ ẹbun yi
‘Fẹ Ọlọrun alailẹgbẹ
To wa ninu Ọmọ rẹ
Jesu Kristi Oluwa
Comments
Post a Comment