Orin Kan: Ẹniti a Bukunfun
(“Ìbukun ni fun ọkọnrin na ti ko rin ni imọ awọn eniyan buburu, ti ko duro li ọna awọn ẹlẹsẹ, ati ti ko si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgan” (Orin Daf. 1:1))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ko
tọ kawọn mimọ bẹru
Ki nwọn sọ ‘reti nu
‘Gba wọn ko ‘reti ‘ranwọ rẹ
Olugbala yio de”
Ẹniti o Kọrin Yi: William Cowper
Orin Titun na Nìyí
1. Oluwa fun wa lọrọ rẹ
Ki awa le ma pa mọ
Ki awa ba le mọ fẹ rẹ
Ki awa ma ba segbe
2. Bi a se le d’ẹni ‘bukun
Wa ninu ọrọ rẹ
Ohun to yẹ kawa ko se ni
Ka ma fiye sọrọ rẹ
3. B’aba fẹ di ẹni ‘bukun
Nipasẹ ọrọ rẹ
A ko ni lati ma rin papọ
Ninu imọ ‘wọn ẹni ‘bi
4. Lati le di ẹni ‘bukun
A o gbọdọ duro lọna
Awọn ẹlẹsẹ, o tun yẹ ki a jinna
Jinna sijok’ awọn ẹlẹgan
5. Eyi to yẹ ki a se niyi
Lati ri ‘bukun Oluwa
Ẹ jẹ ka ma se inu didun
Si ofin oluwa
6. Gbata ba nsasaro ninu
Ofin Oluwa wa
Ni ọsan ati ni our
Gbana ‘bukun wa o de
7. Gbana aw yio dabi
Igi ta gbin seti ‘do
Igi eyit’o nso eso
rẹ
Jade lakoko rẹ
8. Ewe igi yi ki yo rẹ
At’ohunkohun yio wu
T’oun si le dawọ rẹ le
Dede ni gbogbo rẹ a se
Comments
Post a Comment