Orin Kan: Ìfẹ To Gaju
(“Ni ijọ keji Johannu ri Jesu mbọ wa sọdọ rẹ; o si wipe, wo o ọdọ agutan Ọlọrun, ẹniti o ko ẹsẹ aiye lọ!” (Jhn 1:29))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Borukọ
Jesu ti dun to
Ogo ni fun orukọ rẹ
O tan banujẹ at’ọgbẹ
Ogo ni fun orukọ rẹ
Ègbè
Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ
Ogo f’orukọ Oluwa
Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ
Ogo f’orukọ Oluwa
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ìfẹ to ga julọ laiye lọrun
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ọmọ bibi kansoso t’Ọlọrun
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ègbè
Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun
Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun
Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun
Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun
2. Ẹbun ọfẹ to ga ju laiye lọrun
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ọmọ kan soso lokan aiya rẹ
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ègbè
3. Ore ọfẹ alailẹgbẹ ni
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
To farahan fun gbogbo araiye
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ègbè
4. ‘Dọ agutan to k’ẹsẹ araiye lọ
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Ẹnito w agba ‘ran enia la
Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia
Comments
Post a Comment