Orin Kan: Lasiko Ìyàn O Wà Pẹlu Rẹ
(“Iwọ ma bẹru: nitori mo wa pẹlu rẹ; ma foya; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: Emi o fun Ọ ni okun: nitotọ, emi o ran ọ lọwọ: nitotọ emi o fi ọwọ ọtun ododo mi gbe ọ soke” (Isaiah 41:10))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mase foya ohunkohun
Ọlọrun y’O tọ ọ
Ma gbe ibi ikọkọ Rẹ
Ọlọrun y’O tọ ọ
Ègbè
Ọlọrun y’O tọ ọ
Lojojumọ l’ọna gbogbo
On y’O ma tọju rẹ
Ọlọrun y’O tọ ọ
Ẹniti o Kọrin Yi: Civilla D. Martin (1904)
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gbati o wa ninu ‘soro
Jesu wa pẹlu rẹ
Tiwọ ko le s’ohun to fẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
Jesu wa pẹlu rẹ
Nikorita y’owu ko jẹ
Iwọ mase bẹru
Jesu wa pẹlu rẹ
2. ‘Gbati ‘wọ wa ninu ide
Jesu wa pẹlu rẹ
Tile aiye yi si su ẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
3. ‘Gbati ọta npọn ẹ loju
Jesu wa pẹlu rẹ
Tasi gbẹsẹ l’ohun ini rẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
4. Koda ni asiko iyan
Jesu wa pẹlu rẹ
Tohun gbogbo si wọn gogo
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
5. ‘Gbati ‘wọ nse ‘sẹ rẹ lasan
Jesu wa pẹlu rẹ
Ti isẹ rẹ ko ni ere
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
6. ‘Gb’ọmọ rẹ wa n’nu wahala
Jesu wa pẹlu rẹ
To si ndamu lo r’ọmọ rẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
7. ‘Gbat’ ara at’ọrẹ kọ ẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
‘Gbat’aya tab’ọkọ kọ ẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
8. Nipokipo tiwọ ba wa
Jesu wa pẹlu rẹ
Mase sọ reti nu ara
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
9. Nitotọ yo ran ẹ lọwọ
Jesu wa pẹlu rẹ
Yo fọw’ ọtun rẹ gbe ọ ga
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
10. D’ohun rẹ duro nin’ ẹkun
Jesu wa pẹlu rẹ
M’omije kuro loju rẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
11. Isẹ ọwọ rẹ ni ere
Jesu wa pẹlu rẹ
Nwọn o pada wa lat’ilẹ ọta
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
12. ‘Wọ yo jifa ‘sẹ ọwọ rẹ
Jesu wa pẹlu rẹ
Kiwọ to pe Oun yo dahun
Jesu wa pẹlu rẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment