Orin Kan: Nwọn Nsun Fun Ibanujẹ
(“Nigbati o si dide kuro ni ibi
adura, ti o si tọ awọn ọmọ ẹhin rẹ wa, o
ba wọn, nwọn nsun fun ibanujẹ” (Luku 22:45))Rotimi and Ronke Ogundare
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mo fẹran iwe ọrọ
rẹ
O f’imọlẹ at’ayọ fun
Ọkan okun on ‘banujẹ!
Ọrọ rẹ t’ọna mi wiwọ
Ẹru rẹ ko jẹki nsirin
‘Leri rẹ m’ọkan mi sinmi”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gbati ‘banujẹ b’ọkan mi
Temi kosi nireti mọ
Temi ko si le gbadura
Ti emi nsun fun ‘banujẹ
Ọrọ rẹ lo jẹ ‘reti mi
‘Gbati gbogbo ‘reti mi pin
2. ‘Gbati nko jamọ ohun kan
Nigbati a kọ mi silẹ
Ti mo di ‘tanu lawujọ
Tamu ‘le aiye yi sumi
Iwọ Jesu ninu ifẹ
Fi ọwọ rẹ fami mọra
3. ‘Gbat’ ẹni ti mo fẹ dami
‘Gba mo wa lor’ aket’ aisan
S’Gbati ololufẹ mi ku
‘Gba ‘dam’ lẹbi dipo are
Ninu Jesu moni ayọ
‘Tori ‘wọ ni itunu mi
4. ‘Gbati a rẹmi silẹ tan,
To mije si jẹ ounjẹ mi
Ti mo nrin lọ ni igbawẹ
Ti soro bori ọkan mi
Iwọ nu omije mi nu
Comments
Post a Comment