Orin Kan: Ìwọ Fi Ore Rẹ De Ọdun Li Ade
(“Ìwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọra nkan ni ipa-ọna rẹ” (Orin Daf. 65:11))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle l’arin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ọlọrun ‘yin duro de Ọ
Ni orilẹ ede aiye
Lẹnu awa ọmọ rẹ
F’ore at’ ọdun d’ọdun
Ègbè
Iwọ lo mbẹ aiye wo
Lati ọdun de ọdun
Iwọ si fi ore rẹ
De ọdun kọkan l’ade
2. ‘Wọ lo mbomi rin aiye
Ti ewebẹ fi njade
‘Tori ódò rẹ Ọlọrun
Kun fun ọpọlọpọ omi
Ègbè
3. ‘Wọ lo nfọrọ sin’ aiye
‘Wọ lo npese ọka rẹ
Lati aiyeraiye wa
Niwọ ti nbukun aiye
Ègbè
4. ‘Wọ lo nrọjo sorilẹ
‘Wọ si mbusi hihu rẹ
Papa tutu ‘ginju nkan
Awọn oke nfo fayọ
Ègbè
5. Papa tutu na nkọrin
Afonifoj’ ko dakẹ,
‘Tori wọ se wọn lọsọ
Gbogbo wọn lo nho f’ayọ
Ègbè
6. Alabukunfun l’ẹni
Ti wọ yan lat’ sunmọ Ọ
Ki o le ma gbele rẹ
Kole ma jẹ ore rẹ
Ègbè
7. Iwọ ti ngbọ adura
Gbogbo wa mbọ lọdọ rẹ
Masai gbọ adura wa
Fi ‘re rẹ d’aiye wa lade
Ègbè
Comments
Post a Comment