Orin Kan: Nitori Ko Si Ohun Ti Ọlọrun Ko Le Se
(“Nitori ko si ohun ti Ọlọrun ko le se” (Luku 1:37))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Fi Ibukun rẹ tu wa ka
Fi ayọ
kun ọkan wa
K’olukuluku mọ ‘fẹ rẹ
K’a layọ n’nu ore rẹ
Tu wa lara, tu wa lara
La aginju aiye ja
Ẹniti o Kọrin Yi: John Fawcett (1786)
Orin Titun na Nìyí
1. Ọlọrun ti se ‘leru ‘pe
Wundia kan yio loyun
Yio si bi ọmọkunrin kan
Oun yio pe ni ‘Manueli
To tumọ si, to tumọ si
Ọlọrun wa pẹlu wa
2. ‘Gbat’ akoko kikun na de
Ọlọrun mu ‘leri na sẹ
‘Gbato ran angẹli rẹ si
Wundia kan ni Nas’rẹti
Pe yo loyun, Pe yo loyun
Maria si ni wundia na
3. ‘Gbati Maria si gbọ ‘rọ na
O bere b’eyi o ti ri bẹ
‘Tori oun ko mọ ‘kunrin ri
‘Gbọn angẹli Gabriẹli wi fun
Ẹmi mimọ, Ẹmi mimọ
Ni yio seleyi ‘nu rẹ
4. Maria si gba ọrọ na gbọ
O d’angeli na lohun pe
Wo emi ọmọ-ọdọ Oluwa
Kori fun mi b’ ọrọ rẹ
Nitori pe, Nitori pe
Ko s’ohun t’Ọlọrun ko le se
5. Ẹmi Mimọ si siji bo
Wundia na t’ se Maria
Oun si fi inu rẹ soyun
Oyun Ọmọ Ọga ogo
Ọmọ kansoso, Ọmọ kansoso
Ti se Jesu Oluwa
6. Josefu pẹlu aya rẹ si lọ
Silu kan ti se Betlehemu
Lati lọ forukọ silẹ
Gẹgẹ b’asẹ Kesari
Pe ki gbogbo, Pe ki gbogbo
Enia lọ forukọ silẹ
7. ‘Gbati wọ wa ni Betlehemu
Ọjọ Maria pe ti yo bi
Oun si b’akọbi rẹ ‘mọkunrin
Sinu ibujẹ ẹran
Nitor’ ko si, Nitor’ ko si
Aye fun wọn nile ero
8. Lọjọkẹjọ wọn kọmọ nila
Wọn p’orukọ rẹ ni Jesu
T’or’oun ni yo gba wọn enia rẹ
La kuro nin’ ẹsẹ wọn
Ti yo si so, Ti yo si so
Wọn papọ mọ Ọlọrun wọn
9. Ọlọrun fẹ araiye gidi
O si ti fun wa lọmọ rẹ
Pe b’ẹnikẹni ba gbagbọ
Ki oun ko ma ba segbe
Sugbọn ko le, Sugbọn ko le
Ba jọba titi laelae
Comments
Post a Comment