Orin Kan: Ohun To Sowọn Lati Se
(“Nitori o sọwọn ki ẹnikan ki o to ku fun Olododo: sugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le daba ati ku” (Romu 5:7))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mura ẹbẹ ọkan
mi
Jesu nfẹ gb’ adura rẹ
O ti pe k’o gbadura
Nitorina yio gbọ
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ọlọrun fifẹ rẹ han
‘Fẹ to ga ju lo fihan
‘Gbato ran ‘mọ re waiye
Lati wa ku f’ẹsẹ wa
2. O sọwọn ki a to ri
Ẹnit’ yo gba lati ku
Fun olododo enia
Ti o mbẹ ni awujọ
3. Sugbọn fun ẹni rere
Boya a le r’ẹnikan
Ti yo daba lati fi
Ẹmi rẹ lele f’oun
4. ‘Gbata ko le rẹnikan
Lati ku f’olododo
Tab’ ẹni rere aiye
Melomelo awa ẹlẹsẹ
5. Nin’eyi ni ati ri
Ifẹ ailẹgbẹ t’ Ọlọrun
Ni si iran eniyan
‘Tori gbogbo wa ti sẹ
6. Gbogb’ enia ‘nu aiye
Lo ti sẹ to si kuna
Ogo Oluwa Ọlọrun
Ẹsẹ sọ wa d’ẹgbin si
7. ‘Gbọn Ọlọrun fi fẹ nla
Rẹ han sawa ẹlẹsẹ
Ninu eyi papa pe
Kristi wa ku f’ẹsẹ wa
8. Ìfẹ ailẹgbẹ leyi
Laiye ati ni ọrun
Pe ẹnikan f’ẹmi rẹ
Lelẹ f’awa ẹlẹsẹ
9. Or’-ọfẹ to ga ju yi
Ti farahan f’enia
jọwv gb’ore ọfẹ yi
Comments
Post a Comment