Orin Kan: Oluwa, Tirẹ Li Anu
(“Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li anu: nitoriti iwọ san a fun olukuluku enia gẹgẹ bi isẹ rẹ” (Orin Daf. 62:12))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle l’arin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹ fi ọpẹ f’Oluwa
‘Tori ti Oluwa seun
Nitori ti anu rẹ
O duro titi lailai
Ègbè
Oluwa tirẹ lanu
‘Wọ yo san f’olukuluku
Gẹgẹbi ‘sẹ ọwọ wọn
‘Tori tirẹ lagbara
2. Ẹ f’ọpẹ fun Ọlọrun
Ọlọrun awọn Ọlọrun
Niwaju rẹ okun sa
Jordani pada sẹhin
Ègbè
3. Nin’anu rẹ Oluwa
‘Wọ pariwo okun mọ rọrọ
Ariwo rir’ omi wọn
Ati gidigid’ awọn enia
Ègbè
4. Anu rẹ Oluwa Ọlọrun
Lofami yọ n’nu ‘ra ẹsẹ
‘Tori anu niwọ fẹ
Ki I si ise ẹbọ
Ègbè
5. ‘Wọ ran ọmọ rẹ waiye
Ninu ọpọ anu rẹ
Lati w agba ‘wọn enia
Kuro ninu ẹsẹ wọn
Ègbè
6. Iwọ Oluwa lo nse
Awari ọkan gbogbo
‘Wọ na lo ndan inu wo
‘Wọ mọ gbogb’ ero ọkan
Ègbè
7. Oju rẹ Oluwa si
Si gbogb’ọna ọmọ enia
Gbogb’ ohun to wa lokunkun
Kedere lo han si Ọ
Ègbè
8. ‘Wọ Oluwa lo nsanu
F’ẹnikẹni ti ‘wọ fẹ
Mo bẹ Ọ sanu f’emi
ọmọ ‘ransẹ ‘binrin rẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment