Orin Kan: Ti Ọlọrun Ni Agbara
(“Ọlọrun ti sọrọ lẹkan; lẹrinkeji ni mo ti gbọ eyi pe ti Ọlọrun ni agbara” (Orin Daf. 62:11))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹjẹ ka finu didun
Yin Oluwa olore
Anu rẹ o wa titi
Lododo dajudaju
Orin Titun na Nìyí
1. Ọlọrun ‘wọ nikan ni
Ọkan mi nduro jẹ de
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
2. ‘Wọ nikan lapata mi
‘Wọ na ni igbala mi
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
3. ‘Wọ Ọlọrun ni abo mi
Lai a k’yo simi nipo
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
4. Bawọn ọta tilẹ ngegun
Sibẹ ki yo duro lai
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
5. Lotọ wọn yio gbimọ pọ
Sugbọn ‘mọ wọn yio dasan
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
6. Ohun ‘ja ọta si mi
Wọn ki yio le s’ohun kan
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Ni aye ati l’ọrun
7. Lẹkan l’Ọlọrun sọrọ
Lẹkeji ni mo gbọ pe
Tirẹ Ọlọrun lagbara
Comments
Post a Comment