Orin Kan: Afunrugbin Na
(“Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn..” (Matt. 13:3))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mase foiya ohunkohun
Ọlọrun yio tọ Ọ
Ma gbe ibi ikọkọ rẹ
Ọlọrun yio tọ Ọ
Ègbè
Ọlọrun yio tọ Ọ
Lojojumọ lọna gbogbo
Oun yio ma tọju rẹ
Ọlọrun yio tọ Ọ”
Orin Titun na Nìyí
1. Ni akoko ifunrugbin
Afunrugbin kan jade
‘Tor’ asiko wa f’ohun gbogbo
Afunrugbin kan jade
Ègbè
Afunrugbin na jade
Lati lọ fun irugbin rẹ
Ọrọ ‘jọba ọrun
Ohun ni irugbin na
2. Afunrugbin na jade lọ
Lati lọ funrugbin
Orisi ilẹ mẹrin ni
‘Rugbin to fọn bọsi
Ègbè
3. Ilẹ akọkọ l’ẹba ọna
Mbi tawọn kan bọsi
‘Wọn ẹiyẹ wa wọn si sajẹ
‘Tor’ ọrọ na o ye wọn
Ègbè
4. Awọn to bọ sor’ apata
Ko ni gbongbo ‘nu wọn
‘Gbati nunibini dide
Lọgan ni wọn kọsẹ
Ègbè
5. Awọn kẹta bọ sarin ẹgun
Ẹgun si fun wọn pa
‘Niyan aiye ‘tanjẹ ọrọ
Fun ọrọ na pa ‘nu wọn
Ègbè
6. Awọn to bọ silẹ rere
Gbọrọ na o ye wọn
Wọn meso wa ni ọgbọngbọn
Ọgọta at’ọgọrun
Ègbè
7. Irugbin ‘wọ ‘funrugbin na
Lọrọ ‘jọba Ọlọrun
Ilẹ to nfunrugbin na si
Lọkan enia laiye
Ègbè
8. Orisi ọkan mẹrin ni
Ọkan enia ‘nu aiye
‘Gbọn eyi to bọ silẹ rere
Lo nso ‘niruru eso
Ègbè
9. S’ọkan rẹ paya f’ọrọ rẹ
‘Yin ara at’ ọrẹ
Jẹk’ọrọ Ọlọrun to ngbọ
Bọ silẹ rere ‘nu rẹ
Ègbè
10. F’aiye fun ọrọ Ọlọrun
Jẹk’o rilẹ ‘nu rẹ
‘Gbayi n’iwọ pẹlu yo ma
S’ọpọlọpọ eso
Ègbè
Comments
Post a Comment