Orin Kan: Èrè Ń Bẹ Fún Olódodo
(“Bẹli eniyan yóo si wípé, “Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo; nítòótọ́, on li Ọlọrun ti o ń ṣe ìdájọ́ ayé.”.” (O. Daf. 58:11))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Iye wa ni wiwo Ẹnit’a
kan mọgi,
Iye wa nisinsinyi fun ọ
Njẹ wo o ẹlẹsẹ k’o le ri ‘gbala
‘Wo ẹnit’a kan mọ ’gi fun
ọ
Ègbè
Wo! Wo! Wo k’o ye
Iye wa ni wiwo, Ẹnit’a
kan mọ ‘gi
Iye wa nisisinyi fun ọ”
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Mase dẹkun lati ma s’ododo
Nitori Ọlọrun ri gbogbo isẹ rẹ
Mase dẹkun lati ma s’ododo
Ègbè
Lotọ, Lotọ ni
Lotitọ lere mbẹ fun awọn olododo
‘Tor’ Ọlọrun lo nse ‘dajọ laiye
2. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Ọrẹ, ara, at’ ẹbi le kọ ẹ silẹ
Nitori ‘sẹ ododo eyi t’oun nse
Mase dẹkun lati ma s’ododo
Ègbè
3. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Inu Ọlọrun ma dun si ẹ
N’tori iwọ ni o nmu ifẹ rẹ sẹ
Mase dẹkun lati ma s’ododo
Ègbè
4. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Mase darapọ m’awọn ẹni ibi
Lati ma kun isẹ ibi wọn lọwọ
Mase darapọ m’awọn ẹni ibi
Ègbè
5. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Ileri Ọlọrun le pẹ diẹ
sugbọn ma ranti pe bileri pẹ dalẹ kan
Ayọ rẹ yio jade lowurọ
Ègbè
6. ‘Wa gbọna ‘wọ ọrẹ mi, to nsisẹ ododo
Mase dẹkun lati ma s’ododo
Ma foriti ni gbagbọ ọj’ayọ rẹ de tan
Tiwọ yio jere isẹ rẹ gbogbo
Ègbè
Comments
Post a Comment