Orin Kan: Fi Ãnu Han Fun Ẹni Òróró Rẹ̀
(“Ẹniti Ó fi gbala ńlá fún ọba rẹ̀, ó sì fi ãnu han fun ẹni òróró rẹ̀, àní fun Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.” (Orin Daf. 18:50))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Jesu a fẹ pade
L’ọjọ rẹ mimọ yi
A si y’itẹ rẹ ka
L’ọjọ rẹ mimọ yi
‘Wọ ọrẹ wa ọrun
Adura wa mbọ wa
Bojuwo ẹmi wa
L’ọjọ rẹ mimọ yi
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Wọ Ọlọrun airi
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Mo wolẹ niwaju rẹ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Tori ‘wọ lo npanu mọ
F’ẹgbẹgbẹrun enia
To mbẹ ninu aiye
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
2. ‘Wọ Olore ọfẹ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Lọdọ rẹ mo saw a
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
‘Wọ lo le dar’ ẹsẹ,
Aiseded ati ‘rekọja
Ji awọn enia rẹ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
3. ‘Wọ Ọlọrun ẹsan
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Mo sa sabẹ ‘yẹ rẹ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Bo ti wu ki o se
‘Wọ k’yo jẹ kawọn ika
Enia lọ laijiya
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
4. ‘Wọ Ọlọrun otitọ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Jes’Ọdagutan Ọlọrun
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
‘Wọ ti pe ka bere
Ohunkohun t’aba fẹ
Lọwọ Baba l’orukọ Rẹ
F’anu han f’ẹni-ororo rẹ
Comments
Post a Comment