Orin Kan: Ìwọ Nikan Ni Mo Sẹ Si
(“Ìwọ, ìwọ nikansoso ni mo sẹ si, ti mo se buburu yi niwaju rẹ: ki a le da Ọ lare, nigbati iwọ ba nsọrọ, ki ara rẹ ki o le mọ, nigbati iwọ ba nse idajọ.” (O. Daf. 51:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Eyi l’ọjọ t’Oluwa da
O pe ‘gba na n’ti rẹ
K’ọrun ko yọ, k’aiye ko yọ
Kiyin yitẹ na ka”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
Bi ‘seun ifẹ Rẹ
Ani bi ‘rọnu ọpọ anu rẹ
Nu rekọja mu nu
2. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
Wẹ mi ni awẹ mọ
Kuro nin’ aisedede mi
Wẹ mi mọ nin’ ẹsẹ mi
3. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
‘Tori ‘wọ nikan ni
Emi sẹ si ti mo si se
Ibi wọnyi niwaju Rẹ
4. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
‘Tori ninu ẹsẹ
Ni iya mi si loyun mi
Nin’ aiseded’ la bi mi
5. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
‘Tori emi ti jẹwọ
Gbogbo ‘rekọja mi fun ọ
Ati gbogb’ ẹsẹ mi
6. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
Gbam’ lọwọ ẹbi ẹjẹ
Ahọn mi yo si ma kọrin
Ododo rẹ kikan
7. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
Ti ewe hissopu
Bọnu ẹjẹ rẹ ‘yebiye
Ko si fi wẹ mi mọ
8. ‘Wọ Ọlọrun sanu fun mi
Wa sọmi di mimọ
B’iwọ ba sọ mi di mimọ
‘Gbana lemi o mọ
9. ‘Gbana lemi to le ma kọ
Gbogbo awọn ẹlẹsẹ
Ni ọna ihinrere rẹ
Wọn yio si yipada si Ẹ
Comments
Post a Comment