Orin Kan: Ki Emi Le Ma Rin Niwaju Ọlọrun
(“Nítorí pé iwọ li o ti gba ẹ̀mí ọkan mi lọ́wọ́ ikú; iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mí lọwọ isubu? Kí emi ki o lè máa rìn níwájú Ọlọrun ni ìmọ́lẹ̀ awọn alayè.” (O. Daf. 56:13))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“L’ojojumọ la ngbe Ọ ga
Nigbati ilẹ ba mọ
T’aba kunlẹ lati yin Ọ
Fun anu ti owurọ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Niwọ se gba ọkan mi
Kuro lọwọ ‘dẹkun ọta
Ati kuro lọwọ iku
2. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Niwọ
ko se jẹ k’emi
Fi
ẹsẹ mi gbun okuta
Ati
kuro lọwọ isubu
3. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Ni imọlẹ awọn alaye
Ni iwọ se sanu fun mi
‘Gbati ko si ‘ranwọ mọ
4. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Ni iwọ se gba agbara
T’awọn ọta nlo lemi lori
T’osi sọmi d’ominira
5. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Niwọ se gbami lọwọ ọta
Ati awọn to dide simi
Tiwọ fun mi ni sẹgun
6. Ki nle ma rin n’waju Ọlọrun
Niwọ se tu ide mi
Wọ gbami lọwọ ikanu
Ati ‘rora isa oku
Comments
Post a Comment