Orin Kan: Ọba Àwọn Ọba
(“Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa” (Ifihan 19:16))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara
niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Eyi l’ọjọ t’Oluwa da,
O pe ‘gba na n’ti Rẹ
K’ọrun k’o yọ, k’aye ko yọ
K’iyin yi ‘tẹ na ka”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ọba gbogbo awọn ọba
Awamaridi Eledumare
Ẹnito f’omi se ‘ti igi
Aja iyẹwu rẹ
2.
Ọba gbogbo awọn ọba
To
s’awọ-sanmọ ni kẹkẹ rẹ
Oun
lo nrin lori ‘yẹ afẹfẹ
Ẹfufu
si lonisẹ rẹ
3. Ọba gbogbo awọn ọba
Ẹnito npe ‘na ran nisẹ
Niwaju ẹniti okun
Ati Jordani si pinya
4. Ọba gbogbo awọn ọba
Ẹnito fidi aiye sọlẹ
Le ori ipilẹ rẹ ti
Ko le sipo pada lailai
5. Ọba gbogbo awọn ọba
Aiye gbohun rẹ o wariri
Gbogbo igi igbo ntẹriba
Niwaju Ẹlẹda wọn
6. Ọba gbogbo awọn ọba
Niwaj’ ẹnit’ awọn oke nla nfo
gẹgẹbi agbo gbat’ awọn
oke kekere nfo b’ọd’agutan
7. Ọba gbogbo awọn ọba
To s’apata d’adagun omi
At’ okuta ‘bọn d’orisun omi
K’awọn enia rẹ le romi mu
8. Ọba gbogbo awọn ọba
O sọrọ o sure tere
O si gbawọn enia rẹ
La ninu ‘parun wọn
9. Ọba gbogbo awọn ọba
Ipilẹsẹ ati opin
Ẹnito mbẹ ti o ti wa
To mbọwa Olodumare
Comments
Post a Comment