Orin Kan: Ọkàn Mi Ti Mura, Ọlọrun

(“Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi ó kọrin, emi ó sì máa korin iyìn.(O. Daf. 57:7))



Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“L’ojojumọ la ngbe Ọ ga

Nigbati ilẹ ba mọ

T’aba kunlẹ lati yin Ọ

Fun anu ti owurọ”

Ẹniti o Kọrin Yi:



Orin Titun na Nìyí

1. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati ma fiyin fun Ọ

Ngo ma gbe orukọ rẹ ga

Niwọn ‘gba mow a laiye

 

2. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati ma korin si Ọ

Larin oniruru enia

To mbẹ lorilẹ aiye

 

3. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati gbe Ọ ga gidi

Ju gbogbo awọn ọrun lọ

‘Tor’ ogo rẹ j’aiye lọ

 

4. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati sin ọ nibikibi

Pẹlu agbra at’ẹmi mi

Ati gbogbo ipa mi

 

5. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati f’ogo f’orukọ rẹ

‘Tori ‘wọ Olugbala mi

Lagbara at’ orin mi

 

6. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati ma gbe Ọ leke

‘Tori iwọ ni ko jẹ ki

Oju ‘reti mi ti mi

 

7. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun

Lati ma dupẹ fun Ọ

‘Tori ‘wọ ko jẹ k’ọta mi

Ki nwọn bori Ẹmi mi

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan