Orin Kan: Olúwa, Ete Eke Ni Ki A Mu Dakẹ
(“Àwọn ete eke ni ki a mu dakẹ: ti nsọrọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹgan si awọn olódodo.” (O. Dafidi 31:18))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara
niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Emi ‘ba n’ẹgbẹrun ahọn
Fun ‘yin Olugbala,
Ogo Ọlọrun Ọba mi,
Isegun ore rẹ ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ete eke ni k’ Oluwa
Ki o mu dakẹjẹ
Ete ti nsọrọ ohun ibi
Np’ẹnikeji lawujọ
2.
Ete eke ni k’ Oluwa
Mu
dakẹjẹ nidile
Ẹni
to nse inu didun
Lati
b’ọmọ ‘ya rẹ jẹ
3. Ete eke ni k’ Oluwa
Ki o mu dakẹjẹ
Ete yi nf’ẹnu rẹ fun ibi
At’ ẹtan lawujọ
4. Ete eke ni k’ Oluwa
Ki o mu dakẹjẹ
Ni igberaga ati lẹgan
Lete yi nsọrọ s’olododo
5. Ete eke ni k’ Oluwa
Ki o mu dakẹjẹ
Oro to mbẹ nin’ ọrọ rẹ
Ju oro paramọlẹ lọ
6. Olúwa, ‘wọ ni Ọlọ́run mi
Mo wa si ọdọ rẹ
Gba mi lọwọ ete eke gbogbo
To nd’ọdẹ lati mu mi
Comments
Post a Comment