Orin Kan: Olúwa, Ọlọ́run Aláàánú
(“Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́” (Eksodu 34:6))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara
niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Eyi l’ọjọ t’Oluwa da,
O pe ‘gba na n’ti Rẹ
K’ọrun k’o yọ, k’aye ko yọ
K’iyin yi ‘tẹ na ka”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Olúwa, Ọlọ́run alãnú
Ọba aiyeraiye
Ẹnito fi ‘gbala
nla han
Fun awa ọmọ rẹ
2.
Olúwa, Ọlọ́run alãnú
Ibukun
f’orukọ rẹ
‘Wọ
to dari ẹsẹ wa ji
To
si tan gbogb’arun wa
3. Olúwa, Ọlọ́run alãnú
Ọba Olurapada
‘Wọ to r’ẹmi wa kuro ninu
Iparun ojiji
4. Olúwa, Ọlọ́run alãnú
‘Wọ to pọ niseun
Iseun ‘fẹ rẹ ati ‘yọnu
Lo fi de aye wa lade
5. Olúwa, Ọlọ́run alãnú
To fohun didara tẹwa lọrun
Igba ewe wa lo sọ di
Ọtun gẹgẹbi ti idi
6. Olúwa, Ọlọ́run alãnú
Ranti mi si rere
Gẹgẹbi ọpọ anu rẹ
S’awọn to f’orukọ rẹ.
Comments
Post a Comment