Ó Kan Ìwọ Náà (1)
Ó KÀN ÌWỌ NÁÀ (1)
Lati ọwọ
ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI
© ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI (2015)
Email: segundare111@gmail.com
Facebook: Olusegun Ogundare
Twitter: Ogundare Olusegun
Telegram: Olusegun O. Ogundare
Vk.com: Olusegun Ogundare
LinkedIn: Segun Ogundare
Tumblr: olusegundare
Veenner chat: Ogundare Olusegun O.
WhatsApp: +2347037106880
Cellular: +2348026301717
ISBN:
ÀFIYÈSÍ PÀTÀKI:
Ẹnikẹni ko gbọdọ se atuntẹ tabi da ohunkohun kọ ninu iwe yi yàtọ̀ fun ilo ara rẹ nikan tabi fun sise iwadi laigba àsẹ lati se bẹ lati ọdọ onkọwe.
Òfin yi ko yọ ẹnikẹni silẹ yálà latari sise iwe ọlọrọ-geere yi i lori ìtàgé, lori ẹrọ asọ̀rọ̀mágbésì, lori fíimu, ẹ̀rọ-amohun-maworan tabi intanẹti. Ikilọ pataki ni o, o si ti dòfin.
Ilé Isẹ́ to tẹ iwe yi jade ni:
Ilé Isẹ́ to pin to si nta ni Ile Itawe ADURALAGBA (i.e. ADURALAGBA BOOKSHOP), Ilorin, Kwara-state, Nigeria. +2348038493921.
Facebook: Ogundare Richard
ÌBÀ
Ìbà ni fun Oluwa to njẹ Agbara, sugbọn ti awa eniyan npe ni alagbara. Agbara ni, Alagbara nã ni, sugbọn Òun kúkú l'AGBARA tó nfun gbogbo alagbara lagbara ti wọn nlo. Ìba ni fun Un fún agbara to fi fun mi lati kọ iwe yi jade, lai ba se tirẹ, ẹni àná ni ngo ba ti jẹ́, KÁBÍYÈSÍ O.
ÌDÚPẸ́
Ọpẹ pataki lọwọ awọn obi mi nipa ti ara, Alagba Ogundare Ayọdele ati Ogundare Shola, (ẹnito sun ninu Oluwa ni ọdun 2015) fun ilakaka wọn lori mi lati ri wipe mo dide laiye.
Mo dupẹ lọwọ awọn aburo mi gbogbo: Kẹmi, Pamilerin, Tola, Rotimi, ati Ife.
Ọpẹ mi ko lopin fun igbagbọ ti awọn ọmọ mi ninu ẹmi ni ninu mi, awọn bi: Ohiare Julius (ọmọ to fi ọrọ sisọ jọ baba rẹ minutes Ẹmi), Fatoyinbo Taiye, Segun Kayode, Ibiwoye Oluwaferanmi..
Mo dupẹ lọwọ awọn enia wọnyi: Kunle Peleyeju, Ọmọtọsọ Adeyẹmi, Ogunrinde Ariyọ, Iyafin Iyabọ Randle, Ojẹlade Kayode, Adeoye Funsọ, Makinde Adeoye, Jeje Olasunkanmi, Ayọbami Adegunlẹ, Gboyega Ọkẹ, Seyi Ajao, ologbe Peteru Adetimọlẹ, Ogunleye Supọ, Shola Idowu Samuel, Ọpẹyẹmi Fakunle, Awoyọde Adewumi, Fagbemi Shọla, Alongẹ Abiọdun, Oguntade Toyin ati idile wọn gbogbo. Adeyemi Anjorin (Canada), Adeyemo Adeyinka (America), Abiodun Gowan Samuel, Ofakunrin Olugbenga, Ejide Isaac, Oyerinde Ganiyu, Ọmọtọsọ Adéyẹmi, Iya agba Olowoniyan Hannah.
Mo dupẹ lọwọ onigbagbọ (CAN) to mbẹ ni Ilẹmẹsọ-Ekiti ati lorilẹ-ede Naijiria, Ijọ Aposteli ti Kristi (C.A.C) Oke-Pisga, Ado-Ekiti; C.A.C. Oke Majẹmu, Ogbomosọ, World Flaming Gospel Church, Ibadan, Imọlẹ Otitọ ati awọn ti aye kuna funmi lati darukọ sihinyi, gbogbo ni mo mọ riri wọn. Jesu yio mu gbogbo wa dele o. Amin.
Ọ̀RỌ̀ ÀSỌSÍWÁJÚ
ỌRỌ LÀTẸNU ONKỌWE
Iwe Ihinrere ti Matteu ori kẹtala jẹ iwe to kun fun oniruru owe, ati awọn afijọ ati awọn afiwe lati fi le mu ki oye ijọba Ọlọrun o yé eniyan gbogbo. Jesu sọ awọn ọrọ wọnyi ki a ma ba si ninu okunkun nipa awon ojuse wa ti a nilati se toba jẹ wipe lotitọ ati lododo ni a fẹ pada de ilu ọrun. Awọn owe gbogbo to mbẹ ninu iwe yi na ni a wo ni isisẹ ntẹle lati fi pese ero ati ọkan wa silẹ de ijọba aiyeraiye na….
Iranlọwọ Kristi Jesu ni mo rigba lati se eleyi, mo si nigbagbọ wipe bi iwọ na ba le è niwe yi, iwọ pẹlu yio ri ohun kan tabi meji kọ ninu rẹ, eleyi ti yio ran irin ajo igbagbọ rẹ lọwọ padà silu ọrun; Jesu yio si ran ẹ lọwọ lati se eleyi.
-Olusegun, 2016.
ÀKỌỌ́NÚ
Oju Ewe Akọle,
Iba,
Idupẹ,
Akọsọ/Asọsiwaju,
Akọọnu/Itọka
Ọrọ Lerefe,
Ipin Kinni
Ọ̀RỌ̀ LÉRÈFÉ ỌRỌ NIPA IWE
ỌNA WO LO GBA KAN Ọ?
Ẹkọ ti Olusọagutan ati olukọ wa ti bẹrẹ sini kọ wa lati nkan bi osu melokan sẹhin ni ẹkọ yi, ẹkọ na ni wọn fun ni akori gboro, "Ó KÀN IWỌ NA" pẹlu. Olukọ wa nigbato nside ẹkọ yi fun wa lọjọ akọkọ ti a o bẹrẹ ẹkọ yi fi ye wa wipe gẹgẹbi oniruru isẹ ti se wa laiye ọjọun ana ti ọlaju ko i ti de, ti imọ nipa ijinlẹ ko i ti pọ to bayi ati ti ihinrere ko i ti de, awọn baba wa igbanã nse isẹ. Isẹ ti onikaluku wọn nse le yatọ si ara wọn tabi ki awọn miran ma se isẹ kanna bi o ti se ri lode oni. Bi oniruru isẹ ti se wa yi ohun na lo mu ki aiye igbana wa lọkansoso ti onikaluku si mojuto isẹ tirẹ, ẹnikini ko se ilara ẹnikeji, bẹni wọn ko ma jà si olori ati owo ọ̀yà wọn, irufẹ eleyi ti ko si lode oni. Gbogbo wọn ti wa mojuto ipin isẹ wọn wọnni, a wa ri wipe lati mu ki ihinrere o le ye wọn yégéyégé Jesu wa mu ọ̀pọ̀ isẹ́ òójọ́ awọn eniyan wọnyi lati fi kọ wọn lẹkọ ijọba Ọlọrun. Eleyi ni wipe o fi ohun to ye wọn, Jesu fi ohun ti wọn mọ nipa rẹ, Jesu fi ohun ti wọn rí arídaju rẹ lati fi salaye ijọba Ọlọrun fun wọn, ki awọn eniyan igbana bà á le mọ wipe ọrọ nipa ijọba Ọlọrun yi kò yọ ẹnikẹni silẹ rara ati rara.
Ohun ti olukọ wa mu ki a mọ ni eleyi to si mu wa si aiye ode oni pẹlu lati fi salaye fun awa na wipe eyikeyi isẹ ti a le ma se, irufẹ ipokipo to wù ki a ma salai wà, ọrọ ijọba Ọrun yi kàn awa na pẹlu.
Ọpọ ninu awọn nkan to wa ninu iwe yi ni aye ko si fun olukọ wa lati sọ fun wa nigbati wọn fi nkọ wa lẹkọ na, sugbọn wọn ti wa kó gbogbo rẹ jọ sinu iwe yi: Ó KÀN Ọ́, yio dara bi iwọ na ba le è ni iwe na nitoripe wa ri oniruru ohun kọ́ ninu iwe na eleyi ti yio ran igbesi aiye igbagbọ rẹ lọwọ.
Mo ngba wa niyanju lati ni iwe yi ninu ile wa, ki a si tun rà a fun awọn ara ati awọn ọrẹ wa nipa sise eleyi a nmu ki ihinrere Kristi o tẹsiwaju na ni.... Bi a tile ra asọ torẹ, bi a ti le ra ẹbun fun awọn to nse ọjọ ibi ati oniruru ayẹyẹ ati ináwó gbogbo, ẹ jẹ ki a ra iwe yi na gẹgẹbi ẹbun fun awọn ololufẹ wa gbogbo. Jesu yio ran wa lọwọ lati se eleyi.
Lakotan mo gbadura wipe ki Ọlọrun ba wa ran olukọ wa lọwọ, ki o si tun fun ni ọgbọn, imọ ati oye lati ma salaye ọrọ ijinle bibeli fun wa.... Lopin gbogbo rẹ, ki Ọlọrun mu wa de ijọba Ọlọrun na nitoripe olori ayọ ati ilepa wa ni lati pada de ijọba Ọlọrun; nitori JESU KRISTI Oluwa wa. Amin
-Olusọagutan Alongẹ Abiọdun,
Ijọ Aposteli ti Kristi (C.A.C.) Oke Pisga,
Ado-Ekiti, Ipinlẹ Ekiti.
+2347034922038
ÒRÍ KÌNNÍ
ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE
AKORI Ẹ̀KỌ́: Ó KÀN Ọ́ (I)
BIBELI: Matteu 13:1-53
AKỌSORI:
"O si dahun wi fun wọn pe, ẹyin ni a fifun lati mọ ohun ijinlẹ ijọba ọrun, sugbọn àwọn ni a kò fifun" (Mt 13:11)
ASỌSIWAJU
Iwe ihinrere Matteu ori 13 ti a fẹ wò yi lo kun fun òwe Jesu, ẹsẹ bi marun to pari iwe yi, 54-58, ni ko nise pẹlu owe.
Ninu iwe yi, Jesu fi owe sọrọ ijọba ọrun fun gbogbo awọn olugbọ rẹ. Òwe meje ló hàn gbangba, eleyi ni wipe, wọn ni ibẹrẹ to jọ ara wọn pupọ, Jesu Kristi fihan wipe owe ni awọn wọnyi, sugbọn owe kẹjọ kò bẹrẹ bi ti awọn yoku.... Ọrọ mi yi nfihan wa wipe, owe mẹjọ ló wà ninu iwe ihinrere Matteu ori 13 yi.
Bi Oluwa ti mbẹ ati Ẹmi Rẹ, gbogbọ awọn owe mẹjẹjọ wọnyi ni a o gbé yẹ̀wò bi Jesu Kristi bá dá ẹmi wa si, ati pẹlu wipe tí ó bá fa bíbọ̀ rẹ sẹhin.
ÀGBÉYẸ̀WÒ
(1) Ọ̀NÀ TÍ A PÍN WỌN SI
Onkọwe ati oniwasu kan pin awọn owe mẹjẹjọ inu iwe yi si ọna mẹrin pataki. Ọna mẹrẹrin nã lo si nise pẹlu ara wọn. Oniwasu yi fi awọn owe wọnyi wé ijọ Ọlọrun, eleyi ni wipe iwọ ati emi jẹ ijọ Ọlọrun ni onkọwe ati oniwasu lori ẹrọ aiye-lu-ja-ara, intanẹti yi mba wi. O pin owe na si ọna mẹrin, ọna kọkan si ni owe meji-meji labẹ rẹ. Ẹ jẹ ka wo bó se pin awọn owe na.
Owe kinni ati ikeji lo nise pẹlu gbíngbin nkan...Eleyi ti a le pe ni asiko gbíngbìn (Mt 13:1-9; 24-30; Onw 3:1-2)
Bí a ba gbin nkan tan, yio hù jade yio si mã dàgbà.... Eleyi ni asiko idagbasoke ohun ti a gbin. Nitorina, owe kẹta ati kẹrin nise pẹlu idagbasoke...asiko didagba ni mo pe eleyi. (Mt 13:31-33)
Nigbati nkan ti a gbìn ba ti jade tan tó sì ndagba, yio bẹrẹ sini ni iye (value) lori.... Eleyi ni wipe, awọn eniyan yio ma sọ wipe, iye owo nkan bayi yio to eleyi bi a bá tàá. Mo pe eleyi ni asiko ìdíyelé. (Mt 13:44-46; Jn 12:5; Isa 52:3; Sak 11:12; Mt 26:15; Eks 21:32)
Ipin kẹrin ni ipin ti irugbin na ti nse ojuse rẹ...Eleyi ni asiko sise ojuse ẹni. (Mt 13:47-50; 52; Ond 9:8-15)
Owe wọnyi, gẹgẹ bi onkọwe yi, to nsọ nipa awa onigbagbọ ninu Kristi Jesu nã nfi oniruru ipò ti awa onigbagbọ nã le wa han. Awọn ipo nã sì ni ipo gbíngbìn; ipo híhù ati dídàgbàsókè; ipo ti ati n níye lori ati ipo sise ojuse ẹni. Onkọwe kan ninu bibeli wipe, iyebiye ni iku awọn ayanfẹ rẹ (Ps 116:15). Ẹnito ba niye lori ni iku rẹ ma njẹ iyebiye loju awọn eniyan to ba wulo fun, sugbọn ẹniti ko niye lori, to ba ku yio kan dabi igbati ẹranko lasan ku ni, se nitotọ, awọn miran ko niye lori to awọn ẹranko miran.
Ipo sise ojuse ẹni nsọ nipa ti enia ti njẹ ọmọ to wulo larin ilu, ladugbo, ninu ijọ, ninu idile, fun awọn obi, ani ati nibi gbogbo. O yẹ ki a yẹ ara wa wo, ki a si mọ tabi bere lọwọ ara wa, iru ipo ti a wà bayi?
ÌTUMỌ AWỌN ÒWE INU IWE IHINRERE MATTEU ORI 13 LÉRÈFÉ/KÚKÚRÚ
Tábìlì kínní
Ti a ba foju miran wo itumọ gbòòrò ti onkọwe yi fun gbogbo awọn owe mẹjẹjọ wọnyi, labẹ isọri igbeyawo, a o ri wipe lẹhin igbeyawo ti Ọlọrun ba si ti dahun si ìbálòpọ̀ lọ́kọ-láya tan, obinrin yio lọ si ipo ilóyún, lẹhin igbati irugbin yi, eleyi ti ise oyún ninu alaboyun nã ba ti dagba, yio di bíbí sinu aiye gẹgẹbi ọmọ. Ọmọ yi yio si ma dagba. Bi o ba se ndagba yi yio bẹrẹ isẹ́ kíkọ́ tabi tóbà jẹ laiye ode oni iwe kika. Lẹhin igbati o ba pari ẹ̀kọ́ rẹ (yala isẹ kikọ tabi iwe kikà) yio bẹrẹ sini se isẹ, yio di ẹniti a nko iye le lori, lẹhin eleyi, yio bẹrẹ sini se ojuse rẹ ninu ile tabi ninu ijọ, lawujọ, lorilẹ ede abbl. (Eks 2:3; I Sam 1:20-22; 3:19; Lk 1:80; 2:52)
Bẹna ni jijẹ onigbagbọ ninu Kristi Jesu tise ri, lẹhin igbati a bá ti gbin ọrọ Ọlọrun sinu aye wa nipa sisọ ọrọ Ọlọrun fun wa, ti a ba fi aye gba ọrọ na, tó sì ye, lẹhin igbati o ba yè yi, yio bẹrẹ sini dagba, yio bẹrẹ sini níye lori, yio si bẹrẹ sini se ojuse rẹ lẹhin igbati awọn eso rẹ ba ti jade ti a si nta.
Nihinyi lo yẹ ki a ti bere lọwọ ara wa wipe, "kinni awọn ojuse wa ninu ijọ ati nibi gbogbo?" Diẹ lara awọn ojuse wa niwọnyi:
Jíjèrèọkàn;
Adura gbígbà fun awọn olori, ijọ, orilẹ-ede ati awọn eniyan gbogbo;
Wíwá si apejọpọ dede (nitori o wipe ohun rere kan ki yio fa sẹhin lọdọ awọn to nrin dede);
Títọju awọn iransẹ Ọlọrun abbl (I Sam 12:23; Ps 84:11; I Kor 9:14; Gal 6:10; Eph 6:190 Kol 4:3 abbl)
Ibere mi wa ni wipe, ipò wo wa niwọ wa ninu mẹrẹrin ti a pin owe wonyi si? Se a sẹsẹ nrọbí rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun ni tabi ọrọ Ọlọrun ti yè ninu aye rẹ? Se ipo idagbasoke lo wa nitirẹ tabi iwọ ti dopin dídàgba ninu Ọlọrun? Se nitotọ gbogbo wa ló yẹ ko ma dàgbà lojojumọ ninu Kristi Jesu. (Gal 4:19)
"Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin." (Gal. 4:19)
Se iwọ niye lori ju wura ati fadaka aiye lọ lọdọ Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ ati lọdọ awọn ará, ati Ọlọrun, tabi iwọ ko já mọ nkankan ni?
Ẹnito ba niye lori ni Satani ma ndojú kọ, iru ẹni bẹ ni Satani ma nsọ pe ki awọn ọmọ ẹhin rẹ lo dojú kọ. Ko ni jẹ ohun iyalẹnu fun wa lati ri wipe awọn miran le ma ji oku dide, awọn miran le ma se isẹ iyanu nla sugbọn ki nwọn o ma niye lori lọdọ Satani bi ẹniti ko ma se isẹ iyanu wọnyi. Ẹnito ba nda ijọba Satani lamu, to npe ọpọ eniyan wa sinu Kristi, awọn wọnyi niye lori lọdọ Satani, nitorina Satani yio sa gbogbo ipa rẹ lati fẹ mu wọn wa silẹ.
Ni nkan bi ọdun diẹ sẹhin nigbati mo fi wa ni agbegbe Muritala nilu Ilọrin, baba kan sọ nipa ọmọde kan to ku ninu ijọ wọn funmi, ọmọde-kunrin na ko i ti niyawo, baba wipe nigbati gbogbo ijọ pejọ sibi isinku ọmọ na, wọn wipe gbogbo eniyan lo nsọkun, ti gbogbo wọn si nsọ nipa bi ọmọ na se ran isẹ iransẹ na lọwọ. Iru ọmọ yi jẹ ẹnito niye lori larin ijọ na. Bẹ sini a o ri awọn miran ninu ijọ yẹn ti nwọn yio ma sọ wipe awọn ni olukọ Ile Ẹkọ Ọjọ Isinmi, ti nwọn yio ma sọ wipe bi ko ba si tiwọn nkan ko ni se dada ninu ijọ na, wọn yio ma fọ́nnu, sugbọn sibẹ to jẹ wipe wọn ko niye lori loju awọn eniyan.
Isẹlẹ kan sẹlẹ ni igba aiye awọn aposteli eleyi ti a ka ninu iwe Ise Awon Aposteli ori kẹsan bẹrẹ lati ẹsẹ-kẹrindinlogoji siwaju, a ri ka wipe obinrin kan ti nwọn npe ni Tabitha kú, obinrin yi jẹ ẹnito niye lori larin ijọ to wa, tobẹ ti onikaluku nsọ niti awọn iranlọwọ to ti se fun awọn...bi o se ra asọ fun wọn, awọn to jẹ wipe nipasẹ rẹ ni awọn ọmọ wọn fi ri Yunifasiti lọ na bẹrẹ sini fa ọmọ na wa lati fihan aposteli Peteru idi to se nilati wa nkan se lori ọrọ iku rẹ. Dọrkasi se iyebiye ninu ijọ na. Njẹ iwọ na ha se iyebiye loju Ọlọrun ati ninu ijọ ti o wa tabi ninu ile ti o wa? (Owe 3:15; 6:26; Isa 13:12; 43:4; Ẹkun J. 4:2; I Pet 1:7, 19, II Pet 1:4)
Ibere ti a nilati dahun ni wipe, lati igbati a ti gbagbọ, látìgbà ti a ti sọ wipe a ti kuro lọmọ ọwọ ninu igbagbọ, kí wá lojuse wa ti a nse ninu Ọlọrun ati fun Ọlọrun? (Heb 5:12-14; 6: 1-2)
"Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile.
"Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni.
"Ṣugbọn onjẹ lile ni fun awọn ti o dagba, awọn ẹni nipa ìriri, ti nwọn nlò ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ sarin rere ati buburu." (Heb. 5:12-15)
"NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́ Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti igbagbọ́ sipa ti Ọlọrun,
"Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun." (Heb. 6:1-2)
(2) IBI Ọ̀RỌ̀ NÃ (VENUE)
"Nigbati a tilẹkun Sinagọgu mọ Jesu, O ngbe tẹmpili (ati ihinrere) lọ sita gbangba, nibiyi lo si ti nkọ awọn eniyan ni ahere, ìletò, ilu nla, opopona, leti okun tabi adagun omi lori oke ani ati ninu ile gbogbo"-Barclay lo sọ eleyi.
Iwe ihinrere Matteu ti a ti mu ọrọ yi sọ wipe leti okun ni Jesu ti mba awọn eniyan wọnyi sọrọ. Iwe Marku to ni akọsilẹ diẹ nipa awọn owe wọnyi na sọ wipe leti òkun ni Jesu ti npa awọn owe wọnyi, sugbọn onisegun Luku ko sọ ni pàtó ibiti Jesu ti npa owe yi.
Olusọagutan Spurgeon, orilẹ-ede Kanada lo gbe ti sisẹ iransẹ rẹ ni ọpọ ọdun sẹhin, olusọagutan Spurgeon wipe, "eniyan diẹ ni yio mã tògbé tabi sùn ninu awọn to ngbọ ọrọ Jesu lọjọna, nitoripe JESU lo joko nigbati ọpọ ninu awọn olugbọ rẹ duro lori ẹsẹ wọn" (Mt 13:1-2; I. Apo. 20:9-12)
"LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun.
"Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun." (Matt. 13:1-2)
Otitọ ni wipe awọn miran ko si ibiti wọn ko ti le è sùn, sugbọn ohun to daju ni wipe bi eniyan ba nà duro oorun nã kò ni dùn mọ eniyan.... Bi ọpọ eniyan ba duro, eniyan péréte ni yio tògbé tabi sùn lawujọ.
Ọpọ awọn to ma nsun lasiko ti ọrọ Ọlọrun bá nlọ lọwọ, ọpọ wọn lo ma nsun nitoripe ara tù wọn, sugbọn dídúró lori ẹsẹ̀ ẹni kì í mu itura wa, nitoripe nigbato ba ya ẹsẹ yio ma ro eniyan.
Itan sọ fun wa wipe ninu gbogbo awọn ajinhinrere to ma nti ilẹ adulawọ lọ wasu nilu Eyibo (Amẹrika) oniwasu Idahosa nikan lo ti ì gbé gbogbo awọn eyibo dide duro lori ẹsẹ wọn nigbato nwasu to si nwasu si wọn lọ titi to fi pari iwasu rẹ. (Emi gan wo fimu rẹ lori tẹlifisọn nilu Ibadan lọpọ ọdun sẹhin). Oniwasu Idahosa le se eleyi nigbana nitoripe agbara Ọlọrun to tayọ wa lara rẹ...ngo le sọ boya ẹlomiran tí ì se iru rẹ titi di oni yi lẹhin tirẹ. Ifẹ owó, ifẹ ipò, ìlépa wipe emi na fẹ́ gbe ijọ mi tabi ihinrere mi de ilu eyibo ti mú ki agbara Ọlọrun o díkù laiye ọpọlọpọ iransẹ Ọlọrun loni nitoripe ọ̀pọ̀ wọn, ohun àìyẹ, ohun àìbójúmu ni wọn ma nse lati ri wipe awọn kọja lọ sókè òkun.... Ọlọrun le è fi aàyè gbà wọn lati débẹ̀ nitotọ sugbọn yio fiya rẹ jẹ wọn gẹgẹ bo ti se fun woli Balamu. Awọn miran si le gba ọna to dara lọ, sugbọn lẹhin igbati wọn ba de nihinrere wọn yio di idakuda, lẹhin igbana lawọn ọmọ wọn yio di idakuda, tabi ẹ o gbọ isẹlẹ to sẹlẹ si ọmọ olusọagutan Kumuyi ni nkan bi ọdun mẹta sẹhin? Ki ise wipe ko dara ki a mu ihinrere lọ silu miran tabi orilẹ-ede miran kọ ni mo nsọ, sugbọn ohun ti mo nwi ni wipe bí a bá nse é, a nilati mã se lọna to ba ihinrere mu ati pẹlu ninu ikiyesara.
Awa nã loni gẹgẹbi Kristi Jesu se se, a nilati mu ihinrere lọ si opopona, inu ile wa, si ọdọ awọn ọrẹ wa, ori oke ani ati nibi gbogbo ti Ọlọrun ba ti fi ore-ọfẹ silẹ fún wa.
(3) IBITI JESU TI MBỌ
Ẹsẹ kínní iwe ihinrere Matteu 13 yi fihan wipe lẹhin igbati JESU da awọn akọwe ati awọn Farisi lohun niti àmì ti nwọn mbere lọwọ rẹ; ti o si tun sọ niti ìse awọn ẹmi esu fun wọn wipe ti nwọn bá lọ wọn a tun pada bẹ ibiti wọn ti jade kuro wo, ani ati lati pada wa sinu aye ti nwọn bá ti jade pẹlu ẹmi meje miran to buruju tirẹ lọ, eleyi ni wipe ẹmi esu mẹjọ ni yio pada wọnu aye ẹni na, ayafi ti ẹni na ba ti gba ki Ẹmi Mimọ kun inu aye oun. Fun apẹrẹ, tobajẹ wipe ẹgbẹrun kan (1,000) ẹmi esu lo wa ninu aye ẹni na tẹlẹ, ti a si le awọn ẹmi wọnyi jade, bi ẹni na ko ba sunmọ adura, ọrọ Ọlọrun, ko si fi aye gba Ẹmi Mimọ ninu aye rẹ, ẹmi wọnyi yio tun pada wa bẹ aye ẹni na wo, bi o ba si ri wipe ó sofo, yio pada lọ mu ẹgbẹrun lọna meje ẹmi àìmọ miran pẹlu ara rẹ lati wa ma gbe inu aye ẹni na...eleyi ni wipe gbogbo ẹmi ti yio ma gbe inu ẹni na nisinsinyi yio jẹ ẹgbẹrin (8000) ẹmi aimọ...
Ere idi niyi ti igbẹhin iru awọn eniyan bẹ se ma nburu ju isaju wọn lọ. Ẹyin na ẹ o ma ri ọpọ awọn ti wọn ma nle ẹmi esu jade ninu wọn? Lẹhin ọjọ melo kan igbe aiye wọn a ti tun buru ju ti tẹlẹ lọ, nitoripe awọn ẹmi na yio pada wọle sibẹ nigbati wọn ko ba ni ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ. Lati le ni Ẹmi Mimọ Ọlọrun ninu aye eniyan, eniyan ko le se laise wipe enia sunmọ Ọlọrun girigiri. Ere idi niyi ti Maria Magdalene, ninu ẹniti a ti le ẹmi esu jade ko se fi Jesu silẹ lẹhin igbati o ti ri itusilẹ kuro lọwọ awọn ẹmi na tan (Lk 8: 1-3; Mk 16:9)
"O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.
"Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
"Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn." (Lk. 8:1-3)
"Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade." (Mk. 16:9)
Jesu dawọn lohun bi eniyan se le pa ara rẹ mọ lai fi aàyè gba Ẹmi esu lati wọnu aye rẹ nipa sise ifẹ Baba Rẹ to mbẹ ni ọrun nikansoso.
Lẹhin igbato sọ eleyi di mimọ fun awọn akọwe ati awọn Farisi wipe awọn ẹbi ati ará òun nikan lawọn tó wà ninu Kristi Jesu to si nse ifẹ rẹ, lo jade kuro ninu ile ti nwọn ti jìjọ nsọrọ nã lọ sétí òkun. (Mt 12:38-50)
Ohun to seni lanu loni ni wipe ọpọlọpọ awa onigbagbọ la ò ò le fi ara wa se ẹbi ara wa mọ́, kò ribi igba awọn baba wa, ọ̀pọ̀ àgálámọ̀sà ati awọn ẹlẹtan lo mbẹ ninu Kristi Jesu loni, eleyi to fi mu ko sòro fun wa lati fi le dá mọlẹbi Kristi totọ mọ.
Awọn miran gan ti a tilẹ tun nro wipe wọn nse ifẹ Ọlọrun lotitọ nse latun ma nri wipe wọn a fẹ jọba lori gbogbo ijọ, nitorina wọn a ma tẹ ara wọn nikan lọrun láì se iranwọ fun awọn ara ninu ijọ.
Nipasẹ bayi, o nsòro lati le sọ wipe lagbaja tabi tamẹdun mọlẹbi mi ni, sugbọn ó rọrun fun wa lati sọ wipe ọmọ-ìjọ mi ni lagbaja tabi làkásègbè.
Awọn ọrọ ti Jesu tan imọlẹ si ni eleyi to fi wa jade kuro ninu ile nã lọ sétí òkun.
Mà á fẹ ki a kiyesi wipe Jesu ko fi ibinu jade, Jesu ko fi ìjà jade, Jesu ko fi ede àìyede jade.... Ọpọ wa ibinu la ma fi njade kuro ninu ile ti a ngbé, lẹhin igbati ẹlomiran bá bá enia jà tan ni yio wa mã bọ̀ ni sọsi, sibẹ, o nfẹ ki adura oun o gba, sibẹ, o nfẹ ki Ọlọrun O ri oun, sibẹ, o nfẹ ki Ọlọrun ranti Oun si rere..., njẹ ẹ si ro wipe o rọrùn bẹ? Ko daju bẹ.
Ẹ rò ó lọna yi, ká gbà wipe ọmọ wa tí a bí fẹ gba nkan lọwọ wa, sugbọn bó se mbọ nse lo fa ojuro dé ọdọ wa, kó wá wipe, "daddy mi, ẹ fun mi ni ₦ 50:00", njẹ ẹ o fun un? Ko daju bẹ, ayafi to ba jẹ wipe baba yẹn jẹ afọju tabi ki oju mã dun loku, gẹgẹbi oju se dun Isaaki ti ko fi da Jakọbu mọ yàtọ̀ si Esau (Gen 27:1,15-23)
Sugbọn ti ojú ko ba mã dun obi na, bi oju ọmọ nã se kọ́rẹ́ lọwọ ni yio kọkọ ri, ẹnito ba si jẹ obi rere ati obi gidi, ohun ti yio se ni wipe ko bere ohun to nse ọmọ na, ko ti ni fọhùn tabi fèsì lori ibere ọmọ nã.
Ibinu ẹlomiran yio si pọ tóbẹ́ẹ̀ gẹ ti yio tun farahan ninu isọrọ ati ihuwasi rẹ, eleyi ti yio mu ki obi ti ko lójú (tabi riran) gan o mọ wipe nkan nse ọmọ oun ti ko si ni dahun lori nkan to mbere nã lasiko na bikòse ko kọ́kọ́ bere nkan to nse. Bayi na ni Ọlọrun siwa. Ojú kò dun Ọlọrun, etí ko dùn Un,... gbogbo nkan to nsẹlẹ lo nri, nitorina nigbati a ba de iwaju rẹ pẹlu ibanujẹ, ifajuro (Neh 2:1-2) abbl. Ohun ti Ọlọrun yio ma bere lọwọ wa ni wipe "kilo nse ẹ? Kilode tinu rẹ ko dun? Kilode ti ayọ rẹ kò kún? (Gen 4:6-7) Ni gbaogbo asiko ti Ọlọrun nti ipasẹ Ẹmi Rẹ̀ ati Ero ọkan rẹ bere eleyi lọwọ rẹ, ìsìn yio ma lọ, lawọn asiko yi ni awọn to ndari isin yio ma wipe, "ẹ turaka...ẹ jẹ ki ọkan nyin se dede pẹlu Ọlọrun...abbl".
Ohun ibanujẹ míràn ẹ̀wẹ̀ ni wipe awọn miran to ndari isin gãn kò láyọ̀, nitorina ọkan iru ẹni bẹ yio wà ni ìwàyá ija pẹlu Ọlọrun nitorina kò ní le ri ohun kan pataki fi fún awọn olujọsin lọjọna lati ọdọ Ọlọrun, yio kó tirẹ ba awọn eniyan nã.
Ere idi niyi to fi jẹ wipe ki ise gbogbo eniyan lo le dari isìn, ki ise gbogbo eniyan lo le gba adura le ori adura lọjọjọ isinmi tabi ni awọn ọjọ ipade wa gbogbo, ayafi awọn ti ọkan wọn bá pe, awọn ti nwọn wá pẹlu inu-didun sinu ile ati siwaju Ọlọrun (Ps 100:4).
"Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀." (Psa. 100:4)
Ajinhinrere Charles Finney ninu ọrọ iriri rẹ si awọn iransẹ Ọlọrun nigba aye rẹ wipe, "ki ise gbogbo eniyan ni ọkan rẹ ma nmura tan nigbagbogbo lati gbadura, o wipe eleyi ki ise wipe ẹni na ko ni ẹmi Ọlọrun kọ, sugbọn fun idi kan tabi omiran, ẹlomiran ti a mọ si aladura gidi nigbamiran ọkan rẹ ko ni fẹ gbadura", o tẹ siwaju wipe nitorina, bi a ba ri iru eniyan bayi ti ọkan rẹ ko setan lọjọkan lati gbadura, nse ni ka ma fi ipa mu gbadura le awọn adura ti a ngba lọjọna bikose wipe ki a fi silẹ, titi ti ọkan adura rẹ yio fi pada. Bi ẹlomiran na ba si ri wipe ọkan oun ko mura lati gbadura lọjọ na, ti awọn to ndari isin si pe ẹni na lati gbadura, ko si ohun to buru nibẹ lati wipe ki wọn o ma se pe oun lọjọ na, eleyi ki ise wipe o dẹsẹ, eleyi ki ise wipe o ti pada ninu igbagbọ, sugbọn o nfẹ ki eniyan gbogbo di alabukunfun ninu isin lo se se eleyi.
Nitorina, awọn ti ọkan wọn se dede pẹlu Oluwa, irufẹ awọn wọnyi ni yio gbadura ti yio ni ina ninu, iru awọn wọnyi ni yio gbadura ti yio ni ipa rere laye awọn eniyan ninu ijọ, iru awọn eniyan wọnyi ni yio ri nkan gba lati ọdọ Ọlọrun fun awọn eniyan to wa labẹ rẹ tabi labẹ idari isin rẹ.
Ere idi niyi to se se pataki fun wa lati mã wa siwaju Ọlọrun pẹlu ọkan pipe ati inu didun nigba-gbogbo.
Ọrọ yi nsọ fun wa wipe ki ise igbagbọ nikan lo nilo lati mu dani pẹlu rẹ ti o ba nlọ jọ́sìn tabi gbadura. A mọ̀ wipe wíwá sinu ile Ọlọrun nfi igbagbọ wa han, ìbáà se igbagbọ kekere laní ti a fi tọ̀ ọ́ wa tabi igbagbọ nla laní ti a fi wá siwaju rẹ, ohun to daju ni wipe, a fi apẹrẹ igbagbọ han ninu wíwá siwaju Rẹ, eredi niyi ti onkọwe iwe Heberu se wipe,
"Nitori ẹniti ó bá ntọ Ọlọrun wá ko le sàì gbagbọ pe o nbẹ, ati pe oun ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a" (Heb 11:6b).
Bi o tilẹ jẹ wipe a fi igbagbọ hàn niti wí wá siwaju Rẹ tabi sinu ile rẹ, sugbọn a tun nilati lọ pẹlu inu didun.
Jesu ti inu ile jade lọ joko leti okun, sugbọn ki ise pẹlu ija tabi ede àìyedè lo fi kuro nibito ti kuro. Iwọ ati emi na nilati ri wipe inu wa dun, ọkan wa si mọ́ ji a to lọ sinu ile Ọlọrun. Nitorina ẹsẹ kinni yi nfi ibasepọ to mbẹ larin ori kejila ati ori kẹtala yi hàn.
(4) DIDABO BO ARA ẸNI
Nigbati awọn eniyan mọ ibi ti Jesu gbe wa, wọn bẹrẹ sini ransẹ si ara wọn tobẹ ti wọn fi pọ gidigidi, se ẹ si mọ wipe nigbati awọn eniyan ba ti pọ gidigidi wọn a fẹ ma kọlu, nitorina, Jesu "bọ́ sinu ọkọ̀, o joko" sibẹ o si nkọ wọn lati inu ọkọ na wa. Ohun ti Jesu se yi fi aye silẹ fun lati le sọrọ laisi idaduro tabi ikọlu, tabi ìyọlẹnu lati ọdọ awọn olugbọ rẹ wa. O fi aye silẹ ti yio fi ba awọn eniyan na sọrọ gidigi, ti yio si fi wọ wọn leti. Awọn olukọ tabi oniwasu na ninu apejọpọ nla ma n nilo iru nkan bayi ko wọn o ba le sọrọ Ọlọrun si awọn eniyan daradara laisi wipe awọn ero ndi ọrọ na lọwọ tabi dawọn lamu lasiko ti ọrọ Ọlọrun na ba nlọ lọwọ.
(5) IRU AWỌN TO MBA SỌRỌ:
Ki ise awọn ọmọ-ẹhin Rẹ nikan lo mba sọrọ bikose ọpọlọpọ eniyan. Ọpọlọpọ eniyan yi nfihan wipe oniruru eniyan lo pejọ siwaju rẹ lati gbọ ọrọ Rẹ lọ́jọ́ afiyesi yi.
Ohun to han siwa ni wipe, nibiti oniruru ènìyan bá wà, oniruru isẹ́ lo wa nibẹ. Awọn orisi isẹ́ to wa lasiko ìgbàa ti Jesu nã lo si farahan ninu owe wọnni tó pa fun awọn eniyan na lati sọ nipa ti ijọba ọrun fun wọn. Jesu lo awọn oniruru isẹ wọnyi lati fi ba awọn eniyan na sọrọ niti ijọba ọrun, o lò ó ki ọrọ nã bà á le yé wọn.
"Bi mo ba sọ ohun ti aiye yi fun yin, ti ẹyin ko si gbagbọ, ẹyin o ti se gbagbọ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun yin?" (Jhn 3:12)
Jesu nsọ ninu owe rẹ wọnyi si wọn wipe, bi o ba je àgbẹ̀ alada nla, ọrọ ijọba ọrun kan ẹ; bi o ba jẹ àgbẹ̀ alada kekere ọrọ ijọba ọrun kan ẹ; bi o ba jẹ onile-isẹ nla tabi kekere, ọrọ ijọba ọrun yi ko yọ ẹ silẹ; ti o ba jẹ alagbase tabi alagbaro tabi mọlé-mọlé iwọ gãn lọrọ ijọba ọrun yi sẹwo mọ́ lara; àìkì í mọ o lè sọ wipe onisowo ni ẹ ni tiẹ, Jesu Kristi nwipe kò sẹ́ni tọ́rọ̀ ijọba Ọlọrun kan jù ẹ́ lọ; iwọ wa le wipe, ohun ọ̀sìn niwọ yàn layo lati ma fi sisẹ́ ati lati ma fi pa owó, Jesu nwipe nitori tirẹ gãn ni a se gbe ijọba ọrun kalẹ̀; o wa sese kiwọ sọ wipe olori ile ni ẹ, olori ilu ni ẹ, olori adugbo ni ẹ, olori ẹgbẹ ni ẹ, àní olórí-kólórí yio wu ki o ma se alaijọ, Jesu nwipe nitori tirẹ ni ijọba Ọlọrun.
Nitorina, ni fifi arabalẹ ka gbogbo awọn owe wọnyi, ni a ò ti ri wipe nse ni Jesu mẹnuba oniruru isẹ to wa lasiko na, awọn eleyi to si wà ni ibamu pẹlu awa na lode oni, yala ọmọwe ni ẹ tabi alaimọwe; talaka ni ẹ tabi ọlọ́rọ̀; olori (ilu) ni ẹ tabi ọmọ-ẹhin; ẹlẹ̀sìn ni ẹ tabi iwọ ko tilẹ lẹ́sìn kankan; arugbo ni ẹ tabi màjèsín; bale ni ẹ tabi ọ̀dọ́; obinrin ni ẹ tabi ọkunrin...gbogbo eniyan patapata lọ̀rọ̀ igbala ati ọ̀rọ̀ ijọba Ọlọrun ti a nsọ nipa rẹ yi kan.
(6) Ẹ̀YÁN (TABI IRU) ỌRỌ TÓ LÒ
Iru ọrọ to lo yatọ si ki a sọ wipe iru ede wo ló lò. To ba jẹ èdè tó lò ni a fẹ́ sọ, a o ri daju pe, ede Heberu na ni yio lo lati fi ba ọpọlọpọ eniyan to rọ̀gbà yí i ka na sọrọ...Ede yi ni awọn to ntumọ bibeli wa ba wa tú si oniruru ede loni, nitori a ni bibeli ti a kọ ni ede Ibo, ede Ebira, ede Hausa abbl a se eleyi lati mu ihinrere súnmọ gbogbo eniyan, lati mu ki enia gbogbo o gbọ nipa igbala, ki o ma ba si awijare fun ẹnikẹni
"A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati se ẹri fun gbogbo orilẹ ede, nigbana ni opin yio si de" (Mt 24:14)
Sugbọn ki ise ede ti Jesu Kristi lò lati fi ba awọn olugbọ rẹ sọrọ̀ le lori ni mo nsọ nipa rẹ nihinyi bikose ẹ̀yán tabi iru ọrọ tó lè lati fi bawọn sọrọ. Iru ọrọ to lo na si ni "òwe".
"O si fi owe ba wọn sọrọ ohun pupọ" (Mt 13:3).
Eleyi ni wipe ki ise ọrọ geere lo fi ba awọn eniyan wọnni sọrọ lọjọna lọhun.
Awọn agbagba Yoruba, awọn baba wa wipe, "bi ilu àgídìgbó ni òwe ri, awọn ọlọ́gbọ́n lo ma njó o, bẹ sini awọn ọ̀mọ̀ràn lo mã n mọ̀ ọ́". Eleyi ni wipe bi a ba nfi owe ba eniyan sọrọ nigbamiran, o sese ki eniyan o ma mọ ohun ti ẹni na nsọ, bi ọgbọn ati lakaye ẹni na kò bá i ti de iru ikorita nã. Sugbọn, bi ọgbọn ẹni na bá ti de iru ikorita ti ẹni nã ti nsọrọ, ọrọ na yio yé e. Sugbọn fun ẹniti ọrọ na kò ye, ẹni na ni ẹtọ lati lọ bere lọwọ ẹnito mba sọrọ nã ko la ọrọ òwe na ye oun, ko tumọ ọrọ na fun oun ketekete. A o si ri wipe eleyi na ni awọn aposteli se, ti nwọn si mã nse
nse nigbakugba ti Jesu ba ti fi òwe sọrọ sí wọn sugbọn ti ko si ye wọn (Mt 13:10; Jhn 8:43; II Kor 4:3).
Nihinyi, o yẹ ki a duro diẹ lati bere lọwọ ara wa wipe "njẹ awọn ọrọ Ọlọrun ti mo ngbọ, njẹ awọn ọrọ Ọlọrun ti mo nkà, njẹ o n yémi bi?" (I. Apo 8:30)
Bi awọn ọrọ Ọlọrun ti a ngbọ, ati awọn eleyi ti a nka ba nfiwa sinu okunkun ju ki o mú wa wá sinu imọlẹ lọ, òkùnkùn un wa yio ti pọ̀ tó? Eleyi ni yio ma mu wa se ìsekuse, sugbọn sibẹ ti a o ro wipe ohun to tọ̀nà ni a nse.
Ninu otitọ inu wa ni a o mã se ohun wọnni gẹgẹ bi ọba Abimeleki ti se, (Gen 20:5-7) lai mọ wipe inu Ọlọrun ko dun sí i. Ni ikorita yi, a le mã sọ asọtẹlẹ, a le ma la àlá ko ma wá si imusẹ, a le ma fi ede fọ̀, a le mã le ẹmi esu jade, a le mã tumọ bibeli bo se ye wa (sugbọn ko ni si agbara Ọlọrun nibẹ (I Kor 2:4; 4:20; I Tess 1:5)); a le mã se oniruru isẹ iyanu gbogbo..., a le e jẹ ọlọ́lá, olówó, ọlọrọ...sugbọn sibẹ ko jẹ wipe inu okunkun biribiri ni a ti nse eleyi. Ere idi niyi ti Jesu se wipe ki ise gbogbo awọn to npe mi ni Oluwa, Oluwa ni yio wọle ijọba ọrun ati pe awọn miran yio wa lọjọ wọnni ti nwọn o si wipe lorukọ Rẹ ni a le awọn ẹmi esu jade, mu alaisan lara da... Jesu wipe sugbọn Oun yio jẹ́wọ́ fun wọn wipe òtítọ́ ni ẹ se gbogbo eleyi lorukọ mi, nitoripe mo bu ọ̀wọ̀ ati ọlá fun orukọ mi, nitorina ko si ẹniti yio pe orukọ nã ti ngo ni da lohun, Jesu wa wipe Oun yio pari ọrọ na si wipe, ẹ kuro lọdọ mi, nitoripe ngo fi igbà kankan mọ yin ri. (Mt 7:21-23)
Eleyi ni wipe wọn nse ohun gbogbo ti wọn nse ni otitọ inu wọn, sugbọn Ọlọrun kò fọwọ si i, bẹni inu Ọlọrun kò dùn sí i. (Gen 20:3-7)
A o ri wipe Mose se iru eleyi nã nigbato dagba tan, sugbọn nitoripe Ọlọrun ko fọwọ si ọna nã, iya jẹ ẹ́, o di isansa ati alarinkiri ni aginju fun ọjọ diẹ ki ọba Farao o ma ba pa á koto di wipe o ri awon ọmọbinrin meje kan ọmọ alyfa Midiani kan, awọn ti o ran lọwọ, ti nwọn si mu lọ sọ́dọ̀ baba wọn, nibẹ lo si wa ngbé, ìkan ninu awọn ọmọbinrin wundia meje yi na lo fẹ gẹgẹbi aya (Eks 2:12-22; 3:1; 4:18; 18; I. Apo 7:22-30)
Saulu to pada wa di aposteli Paulu na se iru eleyi, tinu-tinu rẹ lo fi ngbógun ti ijọ Ọlọrun, o ro wipe ohun to tọna loun nse, afi igbati Ọlọrun farahan wipe, "ohun inira ni fun lati tàpá si ẹgun" (I. Apo 9; 26:12- )
Ọpọ miran na lo nse ohun ti nwọn ro wipe o tọ̀nà loju wọn loni, sugbọn to jẹ wipe loju Ọlọrun ohun ti nwọn nse ko tọna, ohun ti wọn nse ko jẹ inu dídùn fun Ọlọrun.
Ninu Samueli keji ori kẹfa, a o ri wipe ọba Dafidi rò lọkan rẹ lati gbe apoti ẹri kuro nibi to wa, sugbọn ọna to gba gbé e ni ko tọna, eleyi tó mu ko fa iku àìtọjọ fun Ussa (Num 3:10; 4:15; 7:9)
"DAFIDI si tun ko gbogbo awọn akọni ọkunrin ni Israeli jọ, nwọn si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.
"Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.
"Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na.
"Nwọn si mu u lati ile Abinadabu jade wá, ti o wà ni Gibea, pẹlu apoti-ẹri Ọlọrun; Ahio si nrìn niwaju apoti-ẹri na.
"Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro.
"Nigbati nwọn si de ibi ipakà Nakoni, Ussa si nà ọwọ́ rẹ̀ si apoti-ẹri Ọlọrun, o si dì i mu, nitoriti malu kọsẹ.
"Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun." (2 Sam. 6:1-7)
Nitorina, awọn ohun ti a nse tinutinu wa wọnni, awọn ohun ti a nse ninu otitọ inu wa wọnni, bi imọlẹ Ọrọ Ọlọrun ko ba se àfọ̀mọ́ rẹ fun wa, tó ba jẹ wipe nitoripe awọn kan nse lase nse é, a jẹ wipe asise ni a nse, a jẹ wipe ijọba Ọlọrun wa kò i ti daju.
Jesu Kristi fi owe ba awọn eniyan na sọrọ, oniruru owe lo lò lati fi ba wọn sọrọ ki ọrọ ijọba ọrun bà á le ye wọn yégéyégé, ko ma ba si àríyànjiyàn, eleyi ni wipe bi owe kan ko ba ye wọn, ikeji tabi ikẹta yio ye wọn.
Ohun miran ti a ó tun ri nipa awọn owe wọnyi ni wipe, awọn owe na nfihan wipe oniruru ipele lo wa ninu aiye, oniruru ipele lawa eniyan ati awa onigbagbọ na wa. Gbogbo ipele wọnyi ni Kristi Jesu dahun si ninu owe rẹ wọnyi.... Ó bá ẹnito wà ni ipele "professor" ninu igbagbọ sọrọ, bẹna lo ba awọn ti nwọn wa ni "kindergaten" tabi ile iwe alakọbẹrẹ ninu igbagbọ ati ihinrere sọrọ. Iru ipo wo lo wà ninu igbagbọ ati ninu Jesu? Gbogbo ipò tabi ati ipele wọnyi ni Ọlọrun dahun si pẹlu awọn owe wọnyi....
ÌTUMỌ̀ ÒWE
Owe to wà ninu bibeli fẹrẹ to àádọta (50)
Ni ede Giriki wọn npe owe ni "parabole", nigbati wọn npe owe ni ede Heberu ni "masal" eleyi to tumọ si lati jè si ẹ̀gbẹ́ ọna, tabi lati ju si ẹgbẹ.
Nitorina owe jẹ gbígbé ohun meji tabi jubẹlọ sẹgbẹ ara wọn lati mu ki ẹkọ nã ó yéni yegeyege tabi lati fi ohun ti a fi pamọ́ hàn.
Itumọ miran fun owe ni wipe, o jẹ itan aiye, àfiwé ati àfijọ aiye to ni itumọ ohun ọrun
Ẹ̀KỌ́ OWE
Lọpọlọpọ igba ẹkọ kan tabi koko ọrọ kan ni owe sábà ma nkọ awọn eniyan...bi iru awọn eleyi to wa ninu iwe ihinrere Matteu ori kẹtala yi, eleyi to nsọ nipa ijọba ọrun. Fun apẹrẹ itan ti Jesu sọ ninu Luku 10:25-37 se àfọ̀mọ́ ẹniti nse ẹnikeji eniyan fun amofin ani ati gbogbo ọmọlẹhin Kristi pata.
Ẹ ma jẹ ki a gbagbé wipe ẹkọ ti owe nkọ tabi salaye yi ni a ma ngbe ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn ohun tabi èrò tabi ẹkọ kan to le è sókùnkùn si eniyan tabi kó ma ye eniyan saju asiko nã. (Lk 16:19-31)
Apẹrẹ nilẹ Yoruba, wọn á ní, "ẹniba lé eku meji yio pòfo"...eleyi nfẹ ki eniyan ma fọkan si ohun to nse daradara.
IWÚLÓ ÒWE
(1) Owe nsisẹ lori ero eniyan, nitori eniyan ma ntete ranti itan daradara. Ọmọ mi kan ninu ẹmi nigbati o jẹ olori awọn kan ni Yunifasiti Ilọrin, o wa bere lọwọ mi wipe oun ko mọ bi a ti se mba eniyan sọrọ Ọlọrun, nitorina o wipe ki nsọ fun oun ọna ti oun le ma gbe gba lati ma kọ awọn eniyan lọrọ Ọlọrun daradara. Mo bere lọwọ rẹ awọn nkan to mọ nipa kikọ awọn eniyan lọrọ Ọlọrun o dahun. Lẹhin igbato dahun tan mo wa wi fun wipe ni afikun ko tun ma sọ itan fun awọn eniyan nigbato ba nsọ ọrọ Ọlọrun, mo wi fun wipe iriri ti fihan mi wipe, bi awọn to ngbọ ọrọ Ọlọrun ba gbagbe àkòrí ọrọ, bi wọn ba gbagbe ẹsẹ bibeli ati awọn nkan miran, wọn kì í saba gbagbe itan ti won ba gbọ lati fi ifi ọrọ Ọlọrun rẹ na mulẹ.
(2) Owe nsisẹ lori ọkan eniyan lati tìwọ́n lati sisẹ ati lati se iwadi lori ohun ti wọn gbọ tabi ti wọn ti gbọ.
(3) Owe ma nse àfọmọ́ ọ̀rọ̀: Òwe ma njẹ ki ohun tabi ọrọ ti ko ye eniyan tẹlẹ o ye ẹni nã.
(4) A le lo owe lati fi itumọ ọrọ tabi nkan pamọ loju alaimọkan tabi opè. Fun apẹrẹ nigbati Natani nfi owe ba oba Dafidi sorọ (II Sam 12)
(5) Owe ma nfi otitọ pamọ kuro loju awọn ti nwọn ko le ronu tabi awọn ti a ti fọ́ loju pẹlu erokero ati erosege-sege to mu wọn dájọ́ àìyẹ. Nitorina, owe ma nsọ wipe ojuse eniyan ni lati wadi nkan daju ki o ba le di otitọ ibẹ̀ mu. Awọn baba wa ninu bibeli awọn agba ori kẹrin ẹsẹ karun wipe, "owe lẹsin ọrọ, ọrọ lẹsin owe, bi ọrọ ba sọnu owe la o fi wá a". Ohun ti mo nwi lede miran ni wipe owe ma nfi otitọ han ẹnito ba nfẹ mọ otitọ yio si fi otitọ pamọ kuro lọdọ ẹniti ko ba fẹ mọ otitọ.
(6) Òwe ma now ènìyàn níjà si ohun to gbọ: Yatọ si wipe owe le jẹ ki eniyan mọ nkan tabi ko fi nkan pamọ kuro loju ẹni, owe ma npe eniyan níjà si ohun tó gbọ́ tabi si ohun kan ninu aiye eniyan lati se.
OHUN TI OWE KI ISE TABI OHUN TI OWE YÀTỌ̀ SI
A nilati mọ wipe owe yatọ si ìtàn arosọ tabi itan eleyi ti a ti fi orukọ tabi awọn ise kan pamọ́ kuro loju awọn eniyan tabi oluka iwe nã. Awọn orukọ tabi awọn ise ti a fi pamọ́ wọnyi ni awọn eniyan to ba ka itan na nilati ronu jinl e gidigidi le lori lati fi le mọ ẹni na tabi ilu na tabi ohun na ti olukọ tabi olusọ itan na nsọ nkan le lori. Fun apẹrẹ itan ti Ọlọrun ni ki Natani woli sọ fun ọba Dafidi nigbato dá ẹsẹ niti ọràn Uriah ara Hitti (II Sam 12: 1-12).
A o ri wipe awọn ise, orukọ ati ohun gbogbo to wa ninu itan Natani si ọba Dafidi na ni a fi pamọ́ patapata to jẹ wipe lati wadi awọn ẹniti itan na mba sọrọ, enia nilati ronu jinlẹ ki o si se ọpọlọpọ iwadi ko to le ri ọkodoro ọrọ nã.
Sugbọn awọn owe Jesu Kristi wọnyi ni pataki julọ awọn tó wà ninu iwe ihinrere Matteu ori kẹtala yi yàtọ̀ si wọn nitorina, a nilati sãpọn lati ri wipe a o fi oju itan lasan mu awọn owe wọnyi.
ORI KEJI
ALAYE DIẸ LORI ILẸ
Mo ti salaye nisaju wipe, "ohun pupọ" tabi owe pupọ wọnyi ni Jesu sọ ko ba fi le ye gbogbo eniyan to ngbọ ọrọ rẹ, ati pẹlu pe ko bàá le ba ipele kọkan pade ti onikaluku awọn ti nwọn wa niwaju rẹ lati gbọ ọrọ rẹ lọjọna lè bọ́ si (Mt 13:3). Ki a to tẹsiwaju, yio dara ki a mọ wipe awọn nkan diẹ wọnyi nipa ilẹ Israeli ati isẹ àgbẹ̀ ẹ wọn laiye ọjọun àná.
(i) Laiye ọjọun ana nilẹ Israeli, ki o to di wipe wọn yio kọ ilẹ wọn, wọnni wọn yio ti kọ́kọ́ fún awọn irugbin wọnni sori awọn ilẹ ti wọn fẹ́ gbin nkan si. Lẹhin igbati wọn ba se eleyi tan ni wọn yio sẹ̀sẹ̀ wá kọ ilẹ nã.
(ii) Yio dara ki a mọ wipe ilẹ kikọ tiwọn lọhun yàtọ si ilẹ kikọ tiwa nihinyi nitoripe ilẹ wọn le, ati wipe nse lo dabi asálẹ̀, nitorina ki ise ọkọ́ ọlọ́wọ́ bí i tiwa ni wọn nlo bikose ẹranko ni wọn nlo lati kọ ilẹ ẹ wọn ati laiye ode oni awọn irinsẹ nla, bi katakata ti wọn fi nkọ oko ni wọn nlo.
(iii) Ohun miran ni wipe, nitoripe ilẹ wọnyi dabi asalẹ, ani ilẹ ẹ pápá eleyi tó gbẹ gidigidi, orisi ilẹ mẹrẹrin ti Jesu fi se àkàwé ninu owe rẹ yi ni a le ri ninu oko kan soso.
(iv) Ohun afiyesi miran ni wipe, ki eniyan o to jẹ afunrugbin, ẹni na yio jẹ ẹnito ngba irugbin, beni yio si tun jẹ ẹnito njẹ irugbin.
Eleyi nsọ fun wa wipe, ki iwọ ati emi ó tó le nifẹ si fifun irugbin, a o jẹ ẹnito ngba irugbin ati ẹnito njẹ irugbin. Se a mọ wipe awọn kan wa ninu aiye ti nwọn ko nifẹ si jijẹ ohun ti a gbin? Awọn miran ẹran nikan lounjẹ wọn. Nitorina, fun iru awọn to jẹ wipe ẹran nikan ni wọn njẹ, iru awọn eniyan wọnyi kò le è nifẹ lati di afunrugbin, wọn le nifẹ lati di ọdẹ tabi pẹja-pẹja sugbọn wọn kò ni fẹ di afunrugbin. Njẹ iwọ ati emi na ha nifẹ si ati gba irugbin lọwọ Ọlọrun? Njẹ a ha njẹ irugbin ti Ọlọrun fun wa bi? Lede miran njẹ a njẹ ọrọ̀ Ọlọrun?
"Mo si tọ angẹli na lọ, mo si wi fun un pe, fun mi ni iwe kekere ni. O si wi fun mi pe, gba ki o si jẹ ẹ tan; yio mu inu rẹ korò, sugbọn ni ẹnu rẹ yio dabi oyin" (Ifi 10:9)
Njẹ kini ọrọ Ọlọrun ti aposteli Johannu sọ yi tumọ si? Eleyi ni wipe ọrọ Ọlọrun dùn ún sọ, o rọrùn lati sọ wipe onigbagbọ nimi, o rọrùn lati sọ wipe Jesu ngbala, o rọrun lati sọ wipe Jesu nwosan, o rọrun lati sọ wipe Jesu nse oniruru isẹ iyanu. Eleyi lo tumọ si wipe ki ọrọ na dùn lẹnu eniyan.
Sugbọn aposteli Johannu tẹsiwaju wipe, nigbati o jẹ iwe na tan ti o si de inu rẹ, o koro. Eleyi ni wipe ọrọ Ọlọrun ko rọrun lati se, ni pataki julọ nigbati ọrọ Ọlọrun ba mba wa wi, ni pataki julọ nigbati ọrọ Ọlọrun ba fi ihoho wa han, nigbati ọrọ Ọlọrun ba fi àlébu wa han, nigbati ọrọ Ọlọrun ba fi ibiti a kù si han wa, yio kan wa lara gógó, yio dun wa denu egungun, yio dabi ọyún inu egungun si wa, yio ma ro wa lara. Eleyi lo tumọ si wipe nigbati o de inu rẹ o si koro.
Nigbati mo fi wa ni Ifasiti Ilọrin, mo fẹ fẹ ọmọbinrin kan, mo wa lọ ki ni inu yara rẹ, nigbati mo de ọdọ rẹ ti awa jijọ nsọrọ mo wa bere lọwọ rẹ wipe bawo nile ijọsin nijẹta? O wipe ko dun rara. "Kinidi ti ko se dun?" Mo bere lọwọ rẹ. O wa dahun wipe, "nitoripe o dabi ẹnipe oun nikan ni wọn fi se iwasu lọjọ na". Mo wa wifun wipe, "inu mi dun si i", o dahun wipe "oun ti mọ wipe “ẹ o sọ bẹ"”. Mo wipe idi ti inu mi se dun si ni wipe nitoripe ọmọ Ọlọrun ni ọrọ Ọlọrun ma mba wi, ki iru ọmọ na ba le se atunse".
Bi ọrọ Ọlọrun ba mba wa wi, a ma dun wa, sugbọn nitori kini o se mba wa wi? O mba wa wi nitori ki a le se atunse, ki a le yi ọna wa pada, ki a si le di mimọ. Njẹ awa na ha nfẹ ibawi Ọlọrun bi? Njẹ a ha njẹ ọrọ Ọlọrun? Njẹ a ha ngba ki ọrọ Ọlọrun sisẹ ninu aye wa?
Owe akọkọ ti a fẹ wo lo nise pẹlu isẹ agbẹ. Awọn oniwasu ati awọn onkọwe kan npe owe yi ni "owe awọn ilẹ̀", nitoripe orisi ilẹ mẹrin ni Jesu sọ owe nipa rẹ nihinyi. (Mt 13:3-8; 19-23) Sugbọn gẹgẹ bi awa ko se si ni ilẹ Palestini tabi Israeli tabi ni ilẹ Hausa, apa ariwa orilẹ ede yi, Nigeria, ngo gbiyanju lati mu ọrọ owe Jesu yi sunmọ wa ki o ba le ye wa, bẹni ngo gbiyanju lati sọ wọn lọ́nà ti igbalode ti ko si ni mu itumọ̀ rẹ kuro tabi dinku.
Lati inu ọrọ oke yi, nigbàti mo fi arabalẹ ka iwe owe akọkọ yi, ti mo si wò ó fínní-fínní, mo ni ngo pe owe akọkọ na lówe àgbẹ̀ igbalode tabi àgbẹ̀ alada-nla (mechanized farming).
Awọn agbẹ alada nla ni apa ihinyi wọn a mã lo irinsẹ igbalode bi katakata lati pa ilẹ̀ ati lati kọ oko wọn. Awọn katakata yi nigbati wọn ba nsisẹ lori ilẹ wọnni, boya ilẹ le tabi ilẹ kò le, boya ilẹ jẹ́ oju ọ̀nà tẹlẹ tabi ko jẹ oju ọna kò kàn wọn, nse ni wọn yio kọ gbogbo ilẹ nã.
Gẹgẹbi awa àgbẹ̀ ti se mọ, a o ri wipe ki a to le kọ ilẹ si ibikan pãpã ibiti a ò lò rí, tabi ibito pẹ ti nwọn ti lò ó gbẹhin, nse ni a o kọkọ ri wipe a sán gbogbo igbo nã ti a si tun nilati pa awọn igi miran tó wà lori ilẹ nã tó lè fẹ se idiwọ fun isẹ ti a fẹ se nã ati awọn ohun ti a o gbin sinu rẹ.
Iru ilẹ ti a nsọ yi nã yio ni ọna ti enia tabi àgbẹ le gba dénú oko nã tabi ki a kuku wipe ilẹ yi yio ni ààlà pẹlu awọn oko miran, lọpọ̀lọpọ ìgbà awọn ààlà (Owe 22:28; 23:10) wọnyi lo ma njẹ́ ọna ti awọn agbẹ ma ngba wọnu oko wọn, awọn ọna ti wọn si tun ngbàjade na pẹlu. Awọn oko miran gãn le pàlà pẹlu ọna nla tabi ọna tótóbi boya eleyi to wọnú ilu. Mo ro wipe eleyi ye wa diẹ? Ohun keji ti ngo fẹ se àfọ̀mọ́ rẹ kó tó di wipe a yẹ owe Jesu yi wò ni kínní-kínní ni wipe, awọn ilẹ miran a ma wa lẹgbẹ apata ati lori apata, eleyi to mu ki owe Jesu yi na o nise pẹlu apá ibiti a wà yi gidigidi.
Ohun afiyesi kẹta ni wipe, ilẹ̀ ti wọn ko bá lò rí, tabi ilẹ tó pẹ́ ti nwọn ti lò ó gbẹhin ti onílẹ̀ na wa fi silẹ fun igba diẹ, gẹgẹ bi Ọlọrun pẹlu ti se sọ fun awọn ọmọ Israeli pẹlu wipe ki nwọn o ma ni ọdun isinmi fun ilẹ wọn.
"Oluwa si sọ fun Mose ni oke Sinai pe,
"Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, nigbati ẹyin ba de ilẹ ti mo fi fun yin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isinmi kan mọ fun Oluwa.
"Ọdun mẹfa ni iwọ o fi gbin oko rẹ, ọdun mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgba ajara rẹ, ti iwọ o si ko eso rẹ jọ;
"Sugbọn ọdun keje ki o si jasi igba isinmi fun ilẹ nã, isinmi fun Oluwa: iwọ ko gbọdọ gbin oko rẹ, bẹni iwọ ko gbọdọ rẹwọ ọgba ajara rẹ.
"Eyiti o ba lalẹ̀-hù ninu ikore rẹ iwọ ko gbọdọ ja, bẹni iwọ ko gbọdọ ka eso ajara rẹ ti iwọ ko rẹ lọwọ: nitoripe ọdun isinmi ni fun ilẹ nã." (Lef 25:1-5)
Ọlọrun wa wipe, ti wọn ba kọ lati se eleyi, oun yio fi ipá mu wọn se é nipa rírán wọn lọ si igbekun fun ọpọ ọdun, o ni nigbati wọn ba wà ni igbekun yi, ilẹ na yio sinmi lasiko nã.
A o ri wipe Ọlọrun pẹlu ko kó iyán isinmi kere rara. Isinmi kuro lẹnu isẹ ẹni, isinmi ilẹ.... Sugbọn lode oni, nitori ati là, nitori ati dolokiki, nitori ati di ilu mọ̀míká, nitori ki gbogbo eniyan o le ma tẹriba fun wa, nitori ki a le sọ wipe nitoripe a ò se ọ̀lẹ la se ni awọn nkan ti a ni, ọpọ wa ni ki isinmi lẹnu isẹ wa.... Nigbati ẹlomiran ba gba ààyè isinmi gan nse ni yio tun lọ si ibomiran lọ mã sisẹ nibẹ, nitorina, ọpọ wa di olokunrun, ọpọ wa nse àìsan lati ìgbà de igba, ani se nitotọ awọn miran tilẹ nku ikú àìtọ́jọ́ (Mk 6:31; Eks 31:17; Jhn 4:6; Heb 4:9).
A nilati kọ́ bi a se nfun ara ni isinmi... mo woye wipe wíwá si iru ipade arin ọsẹ wọnyi gan n mu ki a le ni isinmi kuro ninu làálàá wa gbogbo lati igbati ilẹ ti mọ.
KINNI ISINMI? Isinmi jẹ didẹkun rironu lori awọn aniyan ati ilepa aiye gbogbo to mbẹ lọkan wa nigbati a bá nse nkan miran, tabi ki a tilẹ ma se nkankan rárá bikose sisere pẹlu aya ati àwọn ọmọ wa, jijẹun to dara, ri rin kiri layika, sisun abbl.
Lasiko ti à nse awọn nkan wọnyi, ọkan wa ko ni sare kiri mọ́, ọkan wa yio sinmi, ara wa yio sinmi, ẹjẹ wa na yio ma se daradara, awon eleyi ti yio mu ki a wà ni alafia iru eleyi ti aposteli Johannu sọ wipe oun ngba ni adura fun awa ará, ani ayanfẹ.
"Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le máa dara fun ọ, ki o si máa wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ" (III Jhn 2)
"Jẹ ki awọn ti nse oju rere si ododo mi, ki o ma ho fun ayọ̀, ki inu wọn ki o si máa dun; lootọ ki wọn ki o mã wi titi pe, Oluwa ni ki a ma gbega, ti o ni inu-didun si alafia iransẹ rẹ" (Ps 35:27)
Nipasẹ eleyi, ọrọ inu iwe Psalmu 91:16 ti o wipe,
"Ẹmi gigun ni emi o fi tẹ́ ẹ lọrun, emi o si fi igbala mi hàn án",
Yio sẹ mọ wa lara. Igbati a ba fun ọkan ati ara wa ni isinmi, igbana ni a le ri igbala Ọlọrun (Eks 14:13; Luku 19-Sakeu).
Igbati a bá duro jẹ, igbati a bá ni isinmi, igbati a bá gbe ọkan kuro ninu awọn ohun asán aiye gbogbo ti a nlepa, igbati a bá mọ wipe ohun ti Ọlọrun bá fẹ́ ki a dà ni a ó dà, nitori awọn ti nwọn nfẹ da ohun ti Ọlọrun ko sọ wọn da, idakuda nã ni wọn ma ndà gbẹhin, awọn ti nwọn ma nfi gọ̀gọ̀ fa ohun ọwọ́ wọn kò tó, o padà mã njale wọn lori ni tosi ma nsọ wọn da idakuda tabi ko seku pawọn lojiji. Njẹ o ranti Kaini? Njẹ o ranti Absalomu? Njẹ o ranti Adonijah? Abbl. Gbogbo awọn wọnyi lo lepa ati da nkan ti Ọlọrun ko ti sọ won da, eleyi to se iku ojiji pa wọn. (Gen 4; 2 Sam 16-18; I Ọba 1)
Nitorina lasiko ti a bá le gbiyanju lati fun ọkan ati ara wa ni isinmi kuro ninu awọn ilepa aiye gbogbo, nigbati ni a ó ri igbala Oluwa, nigbayi ni a ó mọ Oluwa si i, nigbayi ni a ó ni ẹmi gigun ati alafia.
Ọpọ onigbagbọ loni lo nku iku ojiji ati iku àìtọ́jọ̀. Kilofa? Ọpọ wa lati ko ohun aiye si ọkàn ju, ati fẹran ohun aiye ju, ati nlepa aiye ju. Ki ise gbogbo awọn aisan to nse wa nã lo ntipasẹ ìgbóguntì ọ̀tá wa, ki ise gbogbo iku mọto ti ọpọ nku nã lo ti ipasẹ ọfà ọta idile tabi eyikeyi ọ̀tá wa. Ki ise gbogbo ijakulẹ ti a n ni nã lo ni ọwọ́ aiye ninu, sugbọn ọpọ idamu, ijakulẹ, aisan, iku aitọjọ ti ọpọ awa onigbagbọ nku lode oni, afọwọfa wa wà ninu ọpọ wọn, nitori à ì le fun ọkan ati ara wa nisinmi. Fun apẹrẹ nitori kinni ọpọ wa se ma nti ara wa sinu biribiri àìlọ́jọ́? Ọpọ wa nse e nitori ilepa aiye, nitori ati di ilu mọ̀míká, nitori o nfẹ ki wọn o mọ oun gẹgẹbi wọn ti se mọ lagbaja, o nfẹ ki wọn o mọ oun gẹgẹbi wọn se mọ làkásègbè, bẹni ko mọ wipe lagbaja ati lakasegbe ti gbogbo aiye mọ loni, ki ise adura ati awẹ nikan lo mu ki aiye o mọ awọn miran, sugbọn nitoripe irufẹ awọn eniyan wọnyi ti sapamọ sabẹ Bibeli, wọn sapamọ sabẹ ihinrere lati sèké wipé awẹ ati adura lo sọ wọn da nkan ti wọn da, gbogbo èniyan na yio gbagbọ, oun na pẹlu gbagbọ, o si nfẹ dabi tirẹ nitorina o bẹrẹ adura ati awẹ ọlọjọ gigun. O le de ibikan ki agbara ati okun rẹ ma gbe awẹ yi mọ, sugbọn yio ma ti ara rẹ lati ma gba awẹ na lọ nipasẹ eleyi ti yio fi pa ara rẹ lara, ti yio di alaisan ati olokunrun. Nigbati eleyi ba sẹlẹ tan, lẹsẹkanna ọ̀tá ni gbogbo eniyan yio ma pariwo, lẹsẹkanna esu ni gbogbo eniyan yio ma kigbe..., sugbọn, a o ni ranti wipe o sese ko jẹ wipe ifẹkufẹ ara rẹ lo tì í sise, ifẹkufẹ ara rẹ lo sọ ọ́ di alaisan ati olokunrun.
"Ki ẹnikẹni ti a ndanwo mase wipe, lati ọwọ́ Ọlọrun ni a ti dan mi wo: nitori a ko le fi buburu dan Ọlọrun wo, Oun na ki isi idan ẹnikẹni wò:
"Sugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ fà á lọ ti a si tan a jẹ.
"Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba loyun, a bi ẹsẹ: ati ẹsẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bi iku." (Jak 1:13-15)
Ki ẹmi wa bà á le gun, ki a ba a le ni igbala, ki a ba a le gbádùn nkan gbogbo ti a sisẹ fun, ẹ jẹ ki a kọ bi a se nfun ara ati ọkan wa nisinmi. Awọn eyibo ti Ọlọrun fi diẹ ninu asiri ile aiye han, won mọ bi a se nfun ara ẹni nisinmi, won a sere lọ ati awọn ati aya wọn, boya nigbati awọn ọmọ ko si nile...Lasiko ti awọn ọmọ wọn tun wa ni isinmi lati ile iwe wọn, wọn a gbe awọn ọmọ wọnyi wọn a sere lọ, wọn a fun ara ati ọkan wọn nisinmi kuro ninu làálàá, kòókòó-jànán-jànán ile aiye gbogbo. Nigbati wọn ba tun pada de, wọn a tun wa pẹlu ọgbọn titun, okun titun, imọ titun, oye titun, adura titun, wọn a tun di ẹniti gbogbo eniyan nfẹ lati ri.... Ko si ohun to wipe ki awa na ma se eleyi. A le lọ sori oke lai gba àwẹ, bi a ba ti lọ pẹlu ọkàn pipe ati ọkan funfun, a le ri nkan mú bọ̀ ju ẹnito lọ gba biribiri ọlọgọrun ọjọ lori oke lọ....
Nitorina, Ọlọrun wipe ti awọn ọmọ Israeli kò bá kọ́ bi a ti nfun ara ẹni ati ilẹ ẹni ni isinmi oun yio fi ipá mu wọn se é....
Boya iru awọn ilẹ to pẹ ti a ti lo gbẹhin yi, nigbati àgbẹ̀ bá wá fẹ bẹrẹ síní lò ó, awọn ẹ̀gún ati oniruru koriko kò ní sàì ti hù jade nibẹ. Ohun ti mo wa woye ni wipe, nigbati enia ba ro awọn koriko nã danu, laipẹ laijinna wọn yio ti tun hù padà kódà bi agbẹ tabi afurungbin bá fun irugbin sinu oko nã lojukanna to ro ilẹ nã tán, igbakan ni awọn ẹ̀gún tabi koriko wọnni yio hu jade tabi ki nwọn o tilẹ saju awọn ohun ọgbin na hù jade nigbamiran. Nigbati eleyi ba si sẹlẹ, wọn yio ma ba irugbin na jàsí ounjẹ ati oòrùn, nigbamiran wọn yio hù tabi ga bo irugbin na mọlẹ ti nwọn ko ni jẹ kó ri ounjẹ ti yio fi dagba jẹ tobẹ ti nwọn yio fi pa á. Ohun ti mo nfẹ mu jade pẹlu gbogbo awọn alaye wọnyi ni wipe, gẹgẹbi onkọwe yẹn se wipe ni ilẹ Palẹstini, orisi ilẹ mẹrin wọnyi lo ma nwa ninu okò kan, bẹna lemi na nfẹ ki a mọ wipe, o sese fun wa na lapa ihin lati ri orisi ilẹ mẹrẹrin ninu oko kanna.
AKORI: ÒWE KINNI:
AGBẸ ALADA NLA- ILẸ̀ KÍNNÍ
ASỌSIWAJU
Jesu Kristi ninu Owe ilẹ yi fihan wipe orisi ilẹ mẹrin ló wà, orisi ilẹ mẹrẹrin wọnyi ni wọn si wipe o le è pe sinu ilẹ tabi oko kan nilẹ Palẹstini, bẹ pẹlu ni mo tun sọ wipe o sese ki a ri ilẹ mẹrẹrin na ninu oko kan ni apa ibiti a wà yi.... Ẹwẹ mo ni ngo pe agbẹ yi ni agbẹ alada nla nitoripe mo wòye wipe ko si bi eniyan yio se jẹ agbẹ alada nla ti ko ni ba orisi ilẹ mẹrẹrin na pade ninu oko rẹ.
Iwe ihinrere mẹta ninu iwe ihinrere mẹrin to wa ninu majẹmu titun lo sọrọ nipa owe Jesu yi. Awọn iwe ihinrere na ni eleyi ti Matteu, Marku ati Luku kọ. Awọn iwe ihinrere mẹtata wọnyi nia ni a ó lò lati se atọkun wa, ati lati ràn wa lọwọ lati le wo ọrọ owe Jesu yi daradara ninu ẹkọ (ipele) yi. Ninu awọn ori ati awọn esẹ wọnyi ni a o ti ri awọn ọrọ nipa owe yi ka: Matteu 13:4, 19-20; Marku 4:3, 14-15; ati Luku 8:4-5, 11)
AFIYESI NIPA OWE KINNI
(i) Owe yi nsọ nipa orisi ọkan mẹrin to wà ninu oniruru eniyan. Ọkan kinni yatọ si ekeji; ekeji ko ba ẹkẹta mu; bẹ pẹlu ni ẹkẹta ko se dede pelu ẹkẹrin. Orisi ọkan mẹrerin wọnyi ló pé sinu eniyan.
"O si fi owe ba wọn sọrọ ohun pipọ, o wipe, wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin;
"Bi o si ti nfun u, diẹ bọ́ si ẹba-ọna, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si sà a jẹ.
"Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti ko li erupẹ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ;
"Nigbati orun si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn ko ni gbongbo, nwọn si gbẹ.
"Diẹ si bọ sarin ẹgun; nigbati ẹgun si dagba soke, o fun wọn pa.
"Sugbọn omiran bọ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọn" (Mt 13:4-8)
Orisi ilẹ mẹrẹrin niwọnyi, orisi ilẹ mẹrerin wọnyi na lo nse apere orisi ọkan mẹrin ti a le pin ọkan eniyan to wa ninu aiye si. Awọn obi wa nigbati a wa ni kekere wọn yio pe gbogbo wa jọ lati ba wa sọrọ, lati gbawa niyanju. Bi wọn se pe wa jọ ti nwọn mba wa sọrọ yi, a ri wipe ọkan wọnyi na lo pe sinu awọn ọmọ gbogbo. Ẹlomiran ninu awọn ọmọ na nigbati wọn ba ti ba sọrọ ni yio ti yipada, ẹlomiran ko si ni yipada nigbati wọn ba ba sọrọ tan, ẹlomiran yio yipada ni ipilẹse sugbọn nigbato ba ya, nitoripe ọrọ ti o gbọ na ko ni gbongbo ninu rẹ nse ni yio tun pada si ẹsẹ arọ, ti yio si tun ma se ohun ti wọn so wipe ko gbọdọ se mọ, eleyi ni ọrọ ti o bọ sori ilẹ apara. Ẹlomiran yio yipada ni ibẹrẹ yio yipada, sugbọn nitori awọn ọrẹ buburu to yi ka, nse ni awọn ọrọ to ngbọ lati ẹnu wọn, awọn iwa ati ise wọn yio fun ọrọ na pa ninu ọkan rẹ ti yio si tun pada sinu iwa buburu. Njẹ awa na ko ha ma ka tabi gbọ nigbati awon miran to njale ba nsọrọ, wọn yio ma wipe awọn ko fẹ se, tabi awọn sẹsẹ bẹrẹ ni...wipe awọn ọrẹ awọn lo ti awọn se ohun ti awọn nse. Eleyi nsọ wipe, awọn ọrẹ wọnni ti wọn kuna lati yago fun ti fun ọro na pa ninu aiye wọn.
Gẹgẹ bi aiye ti se ndi aiye igbalode, awọn eniyan nisinsinyi ma nsọ wipe awọn ko fẹ bi ọmọ pupọ, awọn miran yio wipe awọn ko tilẹ fẹ bi ju ọmọ kan lọ. Yala o bi ọmọ kan tabi meji, orisi ilẹ wọnyi to nse apẹrẹ orisi okan wọnyi na lo mbẹ ninu eniyan.
Ẹ jẹ ka wo owe kan ti Jesu pa niti baba kan to ni ọmọ meji, eleyi fi mba awọn ti wọn wipe awọn ko fẹ bi ọmọ pupọ wi pe, orisi ilẹ wọnyi na lo ma nwa ninu wọn. Ninu iwe ihinrere ti Matteu 21: 28-31
"Sugbon kili ẹnyin nro? Ọkunrin kan wà ti o ni ọmọ ọkunrin meji; o tọ ekinni wa, o si wipe, ọmọ, lọ isisẹ loni ninu ọgba ajara mi.
"O si dahun wipe, emi ki yio lọ: sugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ.
"O si tọ ekeji wa, o si wi bẹ gẹgẹ. O si dahun wi fun u pe, emi o lọ, baba: ko si lọ.
"Ninu awọn mejeji, ewo li o se ifẹ baba rẹ? Nwọn wi fun u pe, eyi ekinni. Jesu si wi fun wọn pe, lotọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn pansaga siwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun".
A ri wipe ọmọ meji pere ni Jesu sọ wipe baba yi bi, ninu awọn ọmọ mejeji, a si ri ẹniti ọkan rẹ ki ise ilẹ rere nigbati enikeji ni okan to nse apẹrẹ ilẹ rere.
Orisi ọkan wọnyi lo mbẹ ninu awọn ọmọ ti a mbi, orisi okan wọnyi lo mbẹ ninu gbogbo ijọ jakejado aiye. Orisi ọkan wọnyi lo mbẹ ninu oniruru ẹgbẹ. Awọn obi wa ti won ma mba wa soro nigbayẹn bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko ni igbala, sugbọn nitoripe wọn ti daiye saju wa, nitoripe wọn ti ni iriri ti a ko i ti niri, nitoripe wọn ti la oniruru ohun kọja eleyi ti awa ko i ti la kọja, nse ni wọn yio ma bawa sọrọ lati inu iriri wọnyi wa. Sugbọn ọpọ ọmọ loni, nigbati won ba mba wọn sọrọ bayi, ohun ti wọn yio ma wi ni wipe, aiye ti laju, aiye ti di aiye kọmputa, nitorina imọran yin ko le sisẹ fun oun... Sugbọn bibeli ninu iwe Owe ori kinni, keji, kẹta wipe ọmọ mi bi awọn ẹlẹtan ba ntan ọ iwọ mase gba...ọmọ mi to ọrọ mi wọnyi si okan rẹ. Otitọ ni wipe awọn obi wọnyi le ma i ti ni igbala, sugbọn latinu iriri wọn wọnyi, a o kọ ẹkọ nla nibẹ ti a ba le gbọ ọrọ ti wọn nsọ.
Ọrọ obi si ọmọ na dabi ọrọ olori ijọ si awọn ọmọ ijọ ni. Nigbamiran, awọn miran wa ti eniyan ma nro wipe ko ni gbọ ọrọ ti a nsọ, o si le jẹ wipe awọn ni wọn yio wa gbọ ọrọ na ti wọn yio si ma mulo nigbato ba ya nigbati awọn ẹniti eniyan fojú si lara wipe wọn yio gbọ ọrọ na wọn ko si ni gbọ, wọn ko ni gbà á, bẹni wọn ko si ni mu ọrọ na lò. Orisi ọkan mẹrin lo mbẹ ninu awọn ọmọ wa bi o ti se jẹ wipe orisi ọkan mẹrin lo mbẹ ninu ijọ.
(ii) Afurungbin tabi olufunrugbin na fun irugbin na ni, eleyi ni wipe ki ise wipe irugbin wọnni dà silẹ lati ọrun kọ́...Eleyi nsọ fun wa wipe, irugbin yi jẹ eleyi ti afunrungbin na mọ̀ọ́mọ̀ fun sinu oko na. Nigbati enia kan ba dide to si mba awọn ọmọ rẹ sọrọ, nse lo nmọ-ọ-mọ se, nigbati oniwasu ba jade lọ lati wasu nse lo nmọ̀ọ́mọ̀ se ohun na. Nigbati awọn mama wa to wa nibiyi ba mu iwe ti a tẹ ninu ijọ yi ti wọn si fi fun eniyan kan, nse ni won mọ̀ọ́mọ̀ se eleyi. Irugbin na kò la ilẹ̀ hù sugbọn olufunrugbin na mọ̀ọ́mọ fun irugbin na sinu oko na ni.
(iii) Irugbin tabi eso yi: A nilati mọ iru irugbin na. A nilati mọ boya orisi kan ni irugbin na tabi o ju orisi kan lọ. Ko si afunrugbin ti yio fẹ fun irugbin sinu oko rẹ ti ko si ni fẹ mọ irufẹ irugbin ti oun nfẹ gbìn si oko oun.
(iv) Awọn ilẹ ti irugbìn na bọ si: A ti ka wipe orisi ilẹ merin ni awọn ilẹ na.
(v) Isoro ti ilẹ kọ̀ọ̀kan ni gan, o yẹ ki a mọ̀ ọ́.
(vi) Abajade irugbin yi ko duro lori irugbin na bikose lori ilẹ to bọ́ si, eleyiun ni ni ọkàn na. Ohun ti a nwi nihinyi ni wipe, irugbin tabi eso yi ki ise wipe ko ni iye ninu kọ́, se a mọ wipe awọn irugbin kan wa ti wọn kò ni iye ninu, sugbọn irugbìn yi ni iye ninu, irugbin to dara ni. Nitoripe irugbin yi dara, ó yẹ ki o hù (tabi sọ) jade ni a nwi nihinyi, sugbọn nigbati àgbẹ na wa ri wipe irugbin na hu ni awọn ilẹ kan ti irugbin na ko si hu ni awọn ilẹ miran, à ì hu ni awọn ilẹ ti irugbin wọnyi ko ti hu ki ise nitoripe irugbin na ko dara kọ, sugbọn nitori ipo ti ilẹ na wa lofa ti irugbin na ko se hu.
(vii) Ohun miran tun ni wipe, à ì hù irugbin yi le ma nise pẹlu bi afunrugbin na ti se gbin irugbin na bikose wipe a ì hù rẹ waiye latari ipo ti ilẹ na wa.
AFUNRUGBIN NA (KAN)
"O si fi owe ba wọn sọrọ ohun pipọ, o wipe, wò o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin" (Mt 13:3).
A o wo awọn nkan diẹ wọnyi labẹ afunrugbin, ohun akọkọ ni, tani afunrugbin na?
(1) TANI AFUNRUGBIN NA? Afunrugbin na ni oniwasu, boya ajinhinrere (efanjelisi), woli, aposteli, olukọni, olusọagutan, awọn olorin ti wọn nfi orin wọn wasu, awọn elere ori itage fun Kristi, awọn onkọwe ihinrere, awọn obi ti wọn nwasu ọrọ Ọlọrun si ọmọ wọn, awọn ọmọ ijọ ti wọn jade lọ lati lọ sọrọ Ọlọrun abbl. Awọn wọnyi ni afunrugbin na. Bi iwọ ati emi na ba nsọ ọrọ Jesu fun ẹlomiran, boya nipa iwe kikọ, boya nipa igbesi aiye wa layika ati ayida, eleyi ti a nsọ fun awọn ara ati ibatan wa, boya ninu ijọ, se a ri wipe awọn ọmọ wa se ajọdun kan laipẹ yi ti a si fun wọn ni ẹro agbohunsafẹfẹ lati sọrọ, a le ri ẹlomiran lara awọn to wa nijoko ti ori rẹ yio wu bi awọn omọ na ti se ti wọn yio si fẹ darapọ mọ won, awọn ọmọ wọnyi na ni afunrugbin wọnyi gẹgẹ bi iwọ ati emi na ti se nse. Gbogbo ẹnito ba ti nsọ ọro Kristi Jesu na ni afunrugbin na.
(2) Afunrugbin yi ti joko, o ti ronu, bẹni o si ti se iriso ohun to fẹ se ki o to lọ bẹrẹ sini fọn irugbin na. Ko si ẹniti yio fẹ se nkan ti ko ni kọkọ joko se isiro ohun to fẹ se ki o to bẹrẹ sini se, ayafi to ba jẹ wipe ẹni na wa ninu ide esu loku, ayafi to ba si tun jẹ wipe ogun kó ẹni na lẹru loku. Bi eniyan ba fẹ lọ irin ajo, irufẹ ẹni na yio joko se isiro yio ronu wipe se asọ meji tabi mẹta loyẹ ki oun mu dani lọ si irin ajo ti oun nfẹ lọ? Yio fẹ mọ iye owo ti yio mu dani ti yio to fun irin ajo na. Bẹ pelu ni agbẹ to fẹ dako, yio fẹ mọ iye irugbin ti yio to fun oko na, toba ma nilo owo, iye ti oun nilati mura kalẹ fun isẹ na.
"Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ ile-isọ, ti ki yio kọ joko ki o siro iye owo rẹ, bi on ni to ti yio fi pari rẹ.
"Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile solẹ tan, ti ko le pari rẹ mọ, gbogbo awọn ti o ri i a bẹrẹ si ifi i se ẹlẹya.
"Wipe, ọkunrin yi bẹrẹ si ile ikọ, ko si le pari rẹ.
"Tabi ọba wo ni nlọ iba ọba miran jà, ti ki yio kọ joko, ki o si gbero bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ wa ko on loju?
"Bi bẹkọ nigbati onitọhun si wa li okere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhun alafia" (Lk 14:28-32).
Afunrugbin yi ti joko o si ti se isiro ki o to dawọle isẹ ifunrugbin na.
(3) Afurungbin yi ti gbadura, bẹni o si ti bere wipe ki Ọlọrun pèsè irugbin ti oun yio gbìn fun oun...irugbin to dara to si ni iyè (life) ninu ni afunrugbin na bere fun lọwọ Ọlọrun. Ki ẹnikẹni to jade lọ lati ba ẹlomiran sọrọ, papa ọrọ Ọlọrun, irufẹ ẹni na yio ti fi ọkan rẹ gbadura si Ọlọrun fun itọsọna, yio ti ba Ọlọrun sọrọ lati fun oun ni ohun ti oun yio ba ẹni na sọ. Iba se iwe na ni yio fun ẹni na, iru iwe ti yio fun ẹni na ti yio mu eso rere jade yio ti bere rẹ lọwọ Ọlọrun.
(4) Lẹhin igbati afunrugbin yi bere irugbin rere lọwọ Ọlọrun tan, nse lo bẹrẹ sini gbe igbesẹ lori ohun na to fẹ se.
(5) Afunrugbin yi wa bẹrẹ sini wa awọn irugbin na to fẹ gbin. Asiko wiwa irugbin wọnyi ni
asiko bibeli kika, asiko gbigbọ ati gbigba ẹkọ, asiko adura gbigba abbl. Lawọn asiko wọnyi, afunrugbin na nwa awọn irugbin ti yio gbin ni. Gẹgẹbi mo ti sọ wipe agbẹ alada nla ni ngo pe agbẹ yi, agbẹ alada nla yi le ma ni owo tó tó lati fi bẹrẹ isẹ na, nitorina ni asiko yi yio lọ wa owo, yio lọ wa ọna ti yio fi ri owo fun isẹ na.
(6) Afunrugbin yi yio wa ilẹ ti yio fun irugbin wọnyi si. Gẹgẹbi a se wa nihinyi bayi, ti mo ba fẹ da oko sihinyi, ngo wa ibiti ngo da oko na si larin yi ti yio ti mu eso jade, ti ngo ti ni pa ẹlomiran lara...bẹni agbẹ yi na se se. Lẹhin igbati satani mu ẹsẹ wọnu aiye tan, nigbati Ọlọrun fẹ fun irugbin miran sinu aiye, nse lo wa ẹniti yio lo, o ri Noah o si lo lasiko na. Lẹhin igbato pari pẹlu Noah, Olorun nwa fẹ fi apẹrẹ lelẹ wipe bi Oun ti se nfẹ ki awa eniyan o ma gbe ninu aiye niyi, nitorina o tun wa ẹnikan, nipasẹ ẹniti yio fi fi apẹrẹ na lelẹ, ẹniti O si ri na ni Abrahamu, lati ipasẹ Abrahamu yi ni Ọlọrun ti wa nfun irugbin sinu aiye, Ọlọrun wa bẹrẹ sini fi apẹrẹ lelẹ fun eniyan wipe bi Oun ti se nfẹ ki a ma se ninu aiye niyi...Lati ipasẹ Abrahamu loti bọ sori Isaaki, Jakọbu titi ti Jesu fi wa to si mu ihinrere wa, lati ipasẹ Jesu yi na ni awọn aposteli se jade lati ma funrugbin ọrọ na. Gẹgẹbi Ọlọrun ti se wa ẹniti yio funrugbin na sinu aye rẹ, bẹ pẹlu ni loni, Ọlọrun pẹlu ma nsọ fun awon eniyan iru ibiti o nfe ki wọn o funrugbin si.
"O si wi fun mi pe, ọmọ enia, lọ, tọ ile Israeli lọ ki o si fi ọrọ mi ba wọn sọrọ.
"Nitori a ko ran ọ si enia ede ajeji ati sisoro, sugbọn si ile Israeli" (Esek 3:4-5)
Ninu iwe yi ni a ti ri ka wipe Ọlọrun sọ fun woli Esekieli wipe oun ko ran si ilẹ ajeji, oun ko ran si Egipti, Etiopia, tabi awọn ilu miran gbogbo bikose si awọn ọmọ Israeli. Lọpọ igba, nigbati Ọlọrun ba pe eniyan, Ọlọrun a ma sọ fun wọn ibiti Oun nfẹ ki wọn o lọ lati lọ sisẹ. Bi a ba ran eniyan si Ekiti, to ba lọ si Ilọrin, o le ma se daradara nibẹ. Nihinyi ni awọn oludasilẹ ati awọn alasẹ ti nilati ma kiyesi ara ki wọn o to ma gbe eniyan kakiri, nitoripe nitoripe isẹ agbara se lọwọ enia ni ibi to wa, eleyi le ma tumọ si wipe isẹ agbara yio se lọwọ rẹ nigbati wọn ba gbe lọ si ibomiran ti Ọlọrun ko ran ẹni na lọ. Iwọ ati emi, a ran wa si awọn ọmọ wa, iyawo tabi ọkọ wa, ibatan wa, ilu wa, ani ati awọn ti wọn wa ni ayika wa.
(7) Afunrugbin yi fi awọn irugbin tó gbìn silẹ fun Ọlọrun lati rọ̀jò sí i, nitori o mọ wipe Ọlọrun ni o nmu ki iri ati ojo ọrun rọ si ori awọn ohun ti eniyan ba gbìn.
"Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu oòrùn rẹ ran sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọjo fun awọn olotọ ati fun awọn alaisotọ" (Mt 5:45).
Afurungbin yi mọ wipe ki ise ojuse oun ni rirọ ojo si irugbin na ti oun ti fọ́n bikose ojuse Ọlọrun, nitorina, lẹhin igbati o se ojuse tirẹ tan, o fi iyoku silẹ fun Ọlọrun.
(8) Agbẹ tabi afurungbin yi kiyesi awọn ibiti irugbin na bọ́sí kò sì gbiyanju lati mu wọn kuro bikosepe o fi wọn silẹ, nitori kò mọ eleyi ti yio se daradara ninu awọn irugbin wọnni tó fọ́n si ori awọn ilẹ nã.
"Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ ki yio funrugbin; ati ẹnii o si nwoju awọsanma ki yio se ikore.
"Bi iwọ ko ti mọ ipa-ọna afẹfẹ, tabi bi egungun ti idagba ninu aboyun; ani bẹni iwọ ko le mọ isẹ Ọlọrun ti nse ohun gbogbo.
"Ni kutukutu fun irugbin rẹ, ati li asalẹ mase da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ ko mọ eyiti yio se rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna" (Onws 11:4-6)
A o kiyesi ọrọ kan ni ẹsẹ kẹfa yi, onkọwe na wipe ni kutukutu fun irugbin rẹ, eleyi ni wipe ni igbati eniyan wa ni ọmọde tabi ni asiko ọdọ gẹgẹbi awọn arabinrin Toyin Oguntade bayi, oun tun kere simi lọjọ ori, nitorina kutukutu loun si wa si wa, ati emi na si ẹyin mama ati baba mi. Ni asiko ti arabinrin wa yi wà, oniwe yi nwipe ki o ma fun irugbin na, eleyi ni wipe ki o ma sọ ọrọ Ọlọrun, ko ma sọ si awọn ọrẹ rẹ, ko ma sọ lori afẹfẹ, lori awọn watzup, facebook ati lori awọn ohun miran gbogbo ki o ma sọ ọrọ Jesu yi.
Onkọwe yi tun wa tẹsiwaju, o wipe, "ati li asalẹ mase da ọwọ rẹ duro". Asiko asalẹ yi nsọ nipa asiko agba tabi agbalagba, asiko ti awọn baba wa ati iya wa wa, fun apẹrẹ baba Ọbatiku ma nwipe ko si ohun ti awọn nreti mọ bayi bikose iku, eleyi ni wipe wọn wa ni asiko asalẹ, ni asiko yi na ni bibeli nsọ wipe wọn tun nilati ma fun irugbin wọn, ni asiko yi bi awọn ọmọ wọn ba wa ba wọn lalejọ, wọn nilati tun ma ran awọn ọmọ wọn leti wipe se lotitọ ati lododo ni wọn mọ ibiti awọn yio ti lo aiyeraiye wọn? Wọn nilati ma sọ fun awọn ọmọ wọn, awọn aburo wọn, awọn ojugba wọn wipe aiyeraiye daju, wọn ni lati ma jẹ ki won o mọ wipe bi a fẹ a o ku, bi a ko fẹ a o ku, ayafi ki gbogbo eniyan mura silẹ de aiyeraiye rẹ, ayafi ki eniyan mura silẹ de ọrun rere, eleyi na ni fifun irugbin ni asalẹ.
(9) Afunrugbin yi mọ isẹ rẹ nisẹ, ò sì nse isẹ na, ko farawe ẹnikẹni kò kọ́ ìse ẹnikeni tabi ki a kuku wipe o gbaju mọ isẹ to nse, kò sọ wipe oun nfẹ ma se isẹ lagbaja tabi tamẹdun nitoripe o mọ wipe gẹgẹ bi a ti ni ẹ̀yà ara pupọ ninu eniyan bẹni oriruru isẹ wa ninu aiye, eleyi to n mu ki aiye dun gbe, eleyi to nmu ki ohun gbogbo se wẹ́gí ninu aiye. Eleyi ni wipe afunrugbin yi ko sojukokoro isẹ onisẹ (I Kol 12:12; Kol 3:5)
(10) Nitoripe afunrugbin yi mọ isẹ rẹ gẹgẹbi isẹ to si nse e loju mejeji, eleyi lo mu ko mọ àkókò ifurugbin eso nã. O funrugbin na lasiko tó tọ́ ati asiko to yẹ gẹgẹbi ati se mọ wipe bibeli pẹlu wipe,
"Olukuluku ohun li akoko wa fun, ati igba fun isẹ gbogbo labẹ ọrun.
"Igba bibini, ati igba kiku, igba gbíngbìn ati igba kika ohun ti a gbin" (Onws 3:1-2).
Ohun ti mo nfẹ yànàná nihinyi ni wipe a nilati mọ igbati a o ma ba awọn eniyan sọrọ, asiko ti eniyan le gbọrọ lo dara lati ma ba eniyan sọrọ ki ise asiko ti ko le gbọrọ, diẹ lara igbati awọn eniyan ko le gbọrọ, tabi ti wọn ba gbọ ọrọ ti ko ni ye wọn niwọnyi:
(i) asiko ọmọde, bi a ba sọ fun ọmọ ọdun meji ko gba Jesu gbọ, ko le ye lasiko yi, otitọ ni wipe o gbọ ọrọ ti a nsọ lasiko na sugbọn ọrọ na ko le ye e
(ii) Lasiko ti eniyan ba mu ọti yó. Ẹnito mu ọti yo ko ni mọ itumọ orọ ti ẹ nsọ fun lasiko ti ọti wa loju rẹ na, nitorina, bi eniyan ba ba ẹnito ti mu ọti yo sọrọ, yio gbọ nitotọ, o tilẹ le min ori wipe oun ti gbọ, bẹni oun si ti gba ọrọ ti ẹ nsọ si oun, sugbọn ko yé e, nigbati ọti na ba ká kuro loju rẹ ti ẹ ba bere lọwọ rẹ wipe se o ranti ohun ti ẹ ba sọ lana ohun ti yio fi da yin lohun ni wipe oun ko ranti mọ. Asiko yi jẹ asiko to jẹ wipe wọn yio gbọ ọrọ sugbọn ko ni ye wọn. Asiko ti èniyan le gbọ ọrọ ti yio ye e ni asiko ti eniyan le funrugbin ọrọ Ọlọrun,
(iii) Asiko ti eniyan wa lẹsẹkan aiye ẹsẹ kan ọrun, lasiko ti eniyan ko mọ boya ohun wa laiye mọ, ni asiko yi bi eniyan ba mba eniyan sọrọ ẹni na le ma min ori rẹ sugbọn ko jẹ wipe ko gbọ ohun ti ẹ nsọ, lasiko yi ti eniyan ba ro wipe ẹni na ti gbọ ohun ti a nsọ, nse ni a ntan ara wa jẹ, nitoripe o le ti kọja sọhun tan,
"Nwọn si rin lati Beteli lọ; o si ku diẹ ki nwọn ki o de Efrati: ibi si tẹ Rakeli: o si sòro jọjọ fun u.
"O si se nigbati o wa ninu irọbi, ni iyagba wi fun u pe, mase bẹru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu.
"O si se bi ọkan rẹ ti nlọ (o sa ku) o sọ orukọ rẹ ni Ben-oni: sugbọn baba rẹ sọ ọ ni Benjamini.
"Rakeli si ku, a si sin i li ọna Efrati, ti ise Betlehemu" (Gen 35:16-19)
Nihinyi a ri wipe Rakeli aya Jakọbu ninu irọbi rẹ ti wa lẹsẹkan aiye ẹsẹkan ọrun, gbogbo ohun ti iyagba wi fun bọ si asalẹ ilẹ leti rẹ ni, ko le mu ohun na lo mọ, bẹni ọrọ ti a ba ẹniti o ti nku lọ sọ nigbamiran ki i so eso kankan, sugbọn loju tiwa, nitoripe o n min ori, nitoripe o nsọ wipe hẹn-hẹn, a ma nro wipe ọrọ ti a mba wọn sọ na wọ wọn leti, nigbamiran, a tilẹ ma nwipe nigbati ẹni na de opin iku lo fi aiye rẹ fun Jesu laimọ wipe ko si akọsilẹ kankan to jọ iru rẹ lọrun.
(iv) Ẹnito ba jẹ asiwere bi eniyan ba ba sọrọ lasiko yi ko le ye, ayafi ti ẹni na ba ri itusilẹ kuro ninu awọn ẹmi to fi sinu ide na ni ohun ti a mba sọ le ye ti yio si ronupiwada.
Niru awọn asiko wọnyi, wọn jẹ asiko ti afunrugbin ọrọ Ọlọrun ko yẹ lati ma funrugbin nitoripe wọn jẹ asiko asalẹ, wọn jẹ asiko ti irugbin ọrọ na yio bọ silẹ ti yio si jóná.
"Bi eso igi wura ninu agbọn fadaka, bẹni ọrọ ti a sọ li akoko rẹ" (Owe 25:11).
(11) Afunrugbin yi ki ise ọlẹ
"Ọlẹ enia wipe, kiniun mbẹ li ọna; kiniun mbẹ ni igboro.
"Bi ilẹkun ti iyi lori iwakun rẹ̀, bẹli ọlẹ lori ẹni rẹ.
"Ọlẹ pa ọwọ rẹ mọ sinu isasun; ko si le yọ ọ jade wá si ẹnu rẹ.
"Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ ju enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọn dahun ọran" (Owe 26:13-16).
Ohun to daju ninu iwe yi ni wipe eniyan le mọ isẹ rẹ sugbọn kiru eniyan bẹ má a se ọlẹ, sugbọn ti ọkunrin afunrugbin yi ko ribẹ.
"Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgba-ajara ẹniti oye ku fun:
"Si kiyesi i, ẹgun kun bo gbogbo rẹ, ẹgun iwepe si bo oju rẹ, iganna okuta rẹ si wo lulẹ.
"Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkan mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gba ẹkọ.
"Orun diẹ si i, òògbé diẹ, ikawọkopọ lati sun diẹ.
"Bẹli osi rẹ yio de bi ẹniti nrin; ati aini rẹ bi ọkọnrin ti o hamọra ogun" (Owe 24:30-34)
(12) Afunrugbin yi kò jẹ ọlọgbọn loju ara rẹ
"Iwọ ri ẹnikan ti o gbọn li oju ara rẹ? Ireti mbẹ fun asiwere ju fun u lọ." (Owe 26:12).
Eleyi ni wipe afunrugbin yi ngba ọgbọn ẹlomiran kun ti ara rẹ, ere idi niyi to se funrugbin na si oniruru ilẹ, ere idi niyi ti o se nlo awọn ohun igbalode lati fun irugbin na. Ibere ti a nilati ma bere lọwọ ara wa ni wipe njẹ a ngba ọgbọn ẹlomiran kun tiwa bi? Se ki ise wipe igbe aiye ẹniti o gbọn loju ara rẹ ni a ngbe bayi?
(13) Afunrugbin yi ko duro ninu ile lati má a fi ẹnu funrugbin na tabi ki o ma pasẹ fun awọn osisẹ lati inu ile rẹ, sugbọn, oun pẹlu "jade lọ lati funrugbin" nã. (Mt 13:3b). Ninu iwe Samueli keji ori kọkanla ẹsẹ kinni a ka itan pataki kan nibẹ eleyi to sẹlẹ nigba aiye ọba Dafidi ẹni bi ọkan Ọlọrun
"O si se, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima JADE OGUN, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iransẹ rẹ pẹlu rẹ, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si do ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalẹmu." (2 Sam 11:1)
Asiko ti awọn ọba ma njade ogun ni, sugbọn ọba Dafidi kuna lati jade ni ọdun na. Sugbọn ni ti afunrugbin yi, oun "jade lọ lati funrugbin" (Mt 13:3b) na, ko duro sile, ko ma ran awọn ọmọ isẹ rẹ lati lọ ba oun funrugbin na, bi o tilẹ ran awọn ọmọ isẹ rẹ sibẹ, oun pẹlu tun jade lọ lati lọ se ipa tirẹ, lati lọ wo bi wọn se se isẹ na si.
(14) Afunrugbin yi ko tiju isẹ rẹ. Ni aiye ọjọun ana nigbati a fi ma ngbọ Redio O-Y-O, wọn ma nsọro kan ninu Redio na, ohun ti wọn si ma nsọ na nl wipe "isẹ ẹni nisẹ ẹni, ma tiju isẹ rẹ, ikán kì í tiju a nmọle, èérà ki i tiju a nyẹna, alanpandẹdẹ ki i tiju a n mọ ogiri ni gbangba, isẹ ẹni nisẹ ẹni, ma tiju isẹ rẹ, isẹ, isẹ ki i pani, àìse rẹ gan nijọngbọn". Okunrin afunrugbin yi ko tiju isẹ rẹ. Jesu na wipe ẹnikẹni to ba ntiju Oun ninu aiye ẹsẹ yi Oun pẹlu yio tiju rẹ nijọba Baba Oun.
"Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọrọ mi, ni iran pansaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ pẹlu awọn angẹli mimọ" (Mk 8:39; Lk 9:26).
Ohun to han ni wipe ẹnikẹni to ba ntiju isẹ rẹ ko ni le se isẹ na gẹgẹbi o ti se tọ́ ati bi o ti se yẹ. Bẹni bi enia ba ntiju ọrọ Ọlọrun ati sọrọ na jinlẹ le sòro diẹ fun ẹni na.
(15) Afunrugbin yi ko ro ara rẹ si alaiyẹ tabi ẹniti o kere si awọn akẹgbẹ re to nse isẹ miran...lédè miran, afunrugbin yi ko fi aye gba oniruru aisan to ma nda awọn ti wọn ro wipe awọn kere lamu ninu aiye rẹ eleyi ni awọn eleyibo npe ni "inferiority complex". Ẹ jẹ ka ka ohun ti Woli Jobu sọ.
"Sugbọn emi ni iye ninu gẹgẹ bi enyin: emi ki ise ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani ko mọ nkan bi iru wọnyi?" (Jobu 12:3)
"Ohun ti enyin mọ, emi mọ, pẹlu emi ki ise ọmọ-ẹhin nyin" (Jobu 13:2).
Ohun ti nwọn npe ni "inferiority complex" yi ẹ jẹ ki nse alaye rẹ fun wa, kágbà wipe emi ati enikan jijọ se kekere, sugbọn nigbato ya, Olọrun tete da oun lohun saju emi, irin ajo rẹ laiye yara, o tete wọle iwe giga, bo se npari ile iwe giga na lotun wọ Yunifasiti, laipẹ laijinna o tun ti risẹ, o ti niyawo o ti bimọ, bẹna lo nlọ sile eyibo bi ẹni lọ si ọja-ọba, ohun to fi nse ẹsẹ rìn ju ni ọkọ ofurufu... Nitoripe iru ẹni yi ti ju mi lọ nipa ti ara yi, eleyi lẹ fẹ ma da otutu simi lọkan, tobẹ gẹ ti ngo fi ma wo ara mi bi alaiyẹ, eni kekere, ẹniti kò pe lẹgbẹ rẹ, eleyi ni wọn npe ni "inferiority complex", awọn aisan to korajọpọ lati ma da ẹniti ko i to ẹnikeji rẹ lamu ni wọn npe bẹ. Nitori wipe mo nri ara mi bi alaipe lẹgbẹ rẹ, eleyi yio ma mu ki nma le ba sọrọ, eleyi yio ma mu mi gbọ̀n bi mo ba fẹ ba sọrọ nitori mo nwo ara mi, mo ri ara mi gẹgẹbi ẹnito kere si, gẹgẹbi ẹniti ko i ti se aseyọri to tirẹ.
Tabi ni ọna miran ẹwẹ, bi awọn olusọagutan ba fẹ se ipade nihinyi, ti oniruru wọn si ngbe ọkọ nla nla wa, sugbọn ti olusọagutan wa ko gbe ọkọ kankan wa, kódà o tilẹ tun le jẹ wipe bata to wọ wa gan ti jẹ leti, nigbati awọn yoku ba nsọrọ, ko ni fẹ sọrọ, eru yio ma bà á lati sọrọ, koda bi Ọlọrun ba tilẹ ba sọ ohunkohun gan o le ma fẹ sọ, nitoripe yio ma wo ara rẹ gẹgẹbi ẹnito kere si awọn eniyan na. Eleyi ni wọn npe ni "inferiority complex", wiwo ara ẹni si alaiyẹ, alaiba ẹgbẹ pe.
Sugbọn ti afunrugbin yi ko ma ribẹ, nitoripe ko ri ara rẹ si alaiyẹ niwaju awọn eniyan yoku, niwaju awọn osisẹ yoku, nitorina ko bẹru, ko gbọ̀n lóhùn lati sọ ọrọ na nibikibi ati nigbagbogbo.
(16) Afunrugbin na ki ise pidan-pidan (magician). Awọn pidan-pidan ni yio funrugbin lọjọkan, ti yio si hu lojọkan, ti yio si dagba lọjọkan, ti yio si ma so eso lọjọkanna. (opin)
ÒRÍ KẸTA
ÀMÚYẸ AFURUNGBIN OTITỌ (AFURUNGBIN ỌRỌ ỌLỌRUN)".
Òwe kinni na ni a si nwo ti mo sọ wipe o nise pẹlu àgbẹ̀ alada nla ni a o wo. Iwe bibeli ti a nwo na ni Mattiu 13:1-53
Akori gboro ti mo fun ẹkọ wa na ni ó kàn ọ́, ẹ jẹ ki a tẹsiwaju lati ibi ti a ti duro….
Diẹ lara awọn ohun ti a gbe yẹwo sẹhin na ni wipe,
1) Ibiti Jesu ti mbọ, a ri wipe ko fi ibinu kuro nibito wa tẹlẹ, mo wa wipe ọpọ miran to ba fẹ da ijọ silẹ loni ibinu ni wọn ma fi nkuro ninu ijọ nã.
2) Ibi to ti ba awọn eniyan na sọrọ, a ri wipe eti odo ni Matteu pe, nigbati Marku sọ wipe inu ile loti ba awọn eniyan na sọrọ, sugbọn onisegun Luku ko sọ ibi ti Jesu ti ba awọn eniyan na sọrọ ninu akọsilẹ tirẹ.
3) A wo iru awọn eniyan ti Jesu mba sọrọ lọjọ na, a si ri wipe, gbogbo eniyan pata lo mba sọrọ, ere idi niyi to se fi oniruru owe ba wọn sọrọ lọjọ na, oniruru owe yi lo fi ba wọn sọrọ ki o ba le fi ba oniruru isẹ ati awọn eniyan pade ninu ọrọ rẹ si wọn lasiko na..
4) A wo itumọ Owe, Ẹkọ Owe, Iwulo Owe, ati bẹbẹlọ lọjọ na.
5) Lẹhin eleyi ni a wa bẹrẹ agbẹ alada nla, eleyiun ni owe kinni, a si wo awọn afiyesi diẹ nipa owe kinni; a wo nkan nipa Afurungbin nã...
Sugbọn no Ori yi, lagbara Jesu ohun ti a fẹ gbe yẹwo ninu ọrọ yi ni "ÀMÚYẸ AFURUNGBIN OTITỌ (AFURUNGBIN ỌRỌ ỌLỌRUN)".
ÀMÚYẸ AFURUNGBIN OTITỌ (ỌRỌ ỌLỌRUN)
Diẹ lara awọn amuyẹ afurungbin otitọ niwọnyi:
1) Afurugbin Ọrọ Ọlọrun ko le è se irugbin na.
"Sugbọn o dahun, o si wi fun wọn pe, ese ti ẹnyin pẹlu nfi ofin atọwọdọwọ nyin ru ofin Ọlọrun?" (Mt 15:3)
Eleyi ni wipe ki ise àdábọwọ ni awọn irugbin na; ki ise àròsọ ni irugbin nã; ki ise èébú ni irugbin nã...awọn miran ninu awọn ti wọn ma nsọ wipe awọn nfún irugbin na nigbati èdè àìyedè ba wà larin oun ati ọmọ ijọ rẹ, nse ni yio mã fi ọmọ ijọ na se iwasu lori pẹpẹ; awọn miran, nitoripe àjálù dé bá ọmọ ijọ rẹ, nse ni yio má a yọ̀ ti yio ma sògo ti yio si ma wipe nitoripe ọmọ ijọ na ko san idamẹwa rẹ ni àìsàn tabi ajalu na se jálù u, awọn miran yio tilẹ tun wipe ajalu miran to buru ju eleyi lọ mbọ...nitori o rò wipe tabi nitori ó mọ̀ wipe wọn ko san idamẹwa wọn.
Iru ẹni na ti gbagbe wipe, awọn miran a mã san idamẹwa wọn dede, bẹni wọn a ma san-án pé pérépéré pẹlu sugbọn sibẹ ti àjálu ati àrélù yio ma jálù wọn.
To ba jẹ wipe iru Jobu wa laiye ode oni se ẹ ro wipe ko ni ma san idamẹwa rẹ pé perepere ni? Kódà mo woye wipe yio tun mã san-án lé gẹgẹ bi awọn kan ti se ma nfọ́nnu wipe awọn ko san idamẹwa nikan bikose idamarun tabi jubẹlọ.... Sugbọn sibẹ àjálù-àrélù to koja sísọ lo de ba Jobu laiye igba na. Irufẹ awọn ti wọn ma nsogo lori idamu ati wahala awọn ọmọ ijọ wọn nitori àìsan idamẹwa tabi àìda owo ninu ijọ tabi àì dasi isẹ Oluwa tó loju wọn, iru awọn wọnyi ni aposteli Paulu fi apẹrẹ rere lélẹ̀ fun niti wipe Oun pẹlu nfi ọwọ ara rẹ sisẹ ki o ma ba àa di àjàgà ati ẹru wuwo si ijọ lọrun.
Dipo ti awọn ènia wọnni yio se mã fi awọn enia na wasu, dipo ti wọn yio se mã hun ọrọ jade latinu ero ara wọn, ọrọ ti ko tinu Ẹmi Mimọ wa, nitoripe awọn kan kò dáwó ninu ijọ, è é ha tise ti awọn na kò kọ́ iwa ati ise aposteli Paulu, niti wipe ki awọn tikarawọn mã fi ọwọ́ ara wọn sisẹ.
"Nigbati mo si wa pẹlu nyin, ti mo si se alaini, emi ko jẹ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo se alaini awọn ara ti o ti Makedonia wa fi kun u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ ki emi mase jẹ ẹrù fun nyin, bẹli emi o si ma pa ara mi mọ." (II Kor 11:9; 12:13-15)
Afurungbin otitọ tabi ọrọ Ọlọrun yi ki ise ẹniti yio ma fi ọmọ ijọ rẹ gegun lori aga iwasu, irufẹ ẹniyi ki ise ẹniti yio ma binu wipe awọn ọmọ ijọ oun lọ gbadura lori oke tabi wipe wọn lọ si ijọ miran lọ gbadura. Otitọ ni wipe gẹgẹbi eniyan, o ma nka wa lara nigbati a ba ri wipe awọn ọmọ ijọ wa nlọ gbadura nibomiran, sugbọn eleyi kò yẹ kó yọri si ibinu fun wa, eleyi ko yẹ ko fa ti a ó fi ma gegun fun iru awọn omọ ijọ tabi ọmọ ẹhin bẹ ẹ̀, ohun to yẹ ki a ranti ni wipe eniyan yatọ si ara wọn, fun idi eleyi ihuwasi, isesi eniyan yatọ si ara wọn pẹlu, eleyi na lo fàá to fi jẹ wipe lasiko ti eniyan ba nla inu ogun kan tabi omiran kọja oniruru ohun ni ẹni na yio ma fẹ se lati fi le bọ ninu ogun na, eleyi lo si ma nfa ti awọn eniyan se ma nlọ si ibomiran fun ọna abayọ si ohun ti wọn nla kọja.
Gẹgẹ bi eniyan tise yatọ si ara wọn yi, bẹna loti se hàn gbangba wipe ti a ba ko eniyan meji jọ, koda ki nwọn o jẹ Taiye ati Kehinde, ki a si mu wọn la isoro kan kọja, bi awọn mejeji yio se huwa ninu isoro ati ogun na yio yatọ si ara wọn, bi awọn mejeji yio se ma wa ọna abayọ si isoro kanna yio yatọ si ara wọn.
Afurungbin otitọ na jẹ ẹniti o (yẹ ki o) mọ eleyi nitorina ko ni ma fi awọn ọmọ ẹhin na gegun bikose ki o ma gbà wọn niyanju gẹgẹ bi o ti se ri ore-ọfẹ gba lọwọ Ẹnito ni irugbin na, ko si ma ràn wọn lọwọ pẹlu adura.
2) Afurungbin otitọ jẹ ẹnito ma ntọ Baba lọ nikọkọ.
"Nigbati iwọ ba ngbadura mase dabi awọn agabagebe: nitori nwọn fẹ ati ma duro gbadura ni sinagọgu ati ni igun ọna ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lotọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gba ere wọn na. Sugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkun rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ikọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ikọkọ yio san á fun ọ ni gbangba" (Mt 6:5-6)
Ohun keji to jẹ ohun àmúyẹ fun awọn oniwasu otitọ ni wipe wọn a ma lọ si ọdọ Baba wọn ni ikọkọ, wọn a ma ba Ọlọrun sọrọ nikọkọ, wọn a ma wa oju Ọlorun fun awọn eniyan, wọn a ma bere ohun ti Ọlorun ní fun awọn enia. Wọn a ma se eleyi ni ibiti awọn enia ko ti le ri wọn, wọn a ma gbadura si Eledumare ki o le fun wọn lounjẹ fun awọn ọmọ Rẹ, wọn a ma gbadura lati mọ inu Ọlorun fun awọn eniyan. Awa na ri ka ninu Bibeli wipe wọnni Jesu yio si yẹra si ibikan ni aginju, tabi wipe Jesu dide ni kutukutu ki ilẹ tó mọ́ lati ba Ọlọrun sọrọ, lati bere ohun to yẹ ki Oun (Jesu) o se ni ọjọ nã
"O si dide ni owurọ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi ijù kan, nibẹ ni o si ngbadura"(Mk 1:35)
Gbogbo wa ni a o ranti wipe saju ki isẹ iransẹ Kristi Jesu to bẹrẹ loti gba awẹ fun ogoji ọsan ati oru. (Mt 4) Sibẹ lẹhin igbato se eleyi tán o tun wa mba Ọlọrun sọrọ lorekore, lojojumọ lati fihan awa ọmọ lẹhin Rẹ ohun to yẹ ki awa na ma se pẹlu
"Nigbana ni Jesu dahun, o si wi fun wọn pe, lotọ, lotọ ni mo wi fun nyin, ọmọ ko le se ohunkohun fun ara rẹ, bikose ohun ti o ba ri pe Baba nse: nitori ohunkohun ti o ba nse, wọnyi li ọmọ si nse bẹ gẹgẹ" (Jhn 5:19)
Nigbati afurungbin otitọ na bá bá Ọlọrun sọrọ ni kọ̀kọ̀, oun pẹlu yio le ma se gẹgẹbi ohun ti baba ti fihan nikọkọ ni gbagba. Ohun ti woli Mose se ni eleyi, yio bere lọwọ Ọlọrun nikọkọ ohun ti Olorun fẹ se, lẹhin igbati Ọlọrun ba ti fi eleyi hàn fun-un, oun pẹlu yio wa se ohun na nigbangba. Bi awa afurungbin otitọ na ba ri bi awọn eniyan wọnyi loni, awọn enia inu aiye ko ni se alai ma wò wá tìyanu-tiyanu nigbati a bá jade si gbangba lati fún irugbin orọ nã.
(3) Afurungbin otitọ kò mọ ilẹ rere tabi buburu, sugbọn ó mọ ibiti Ọlọrun ran oun si tabi ibiti Ọlorun ko ran oun lọ. Mo nsọ ninu ẹ̀kọ́ wa to kọja wipe ki ise gbogbo awọn iransẹ Ọlọrun nã ni Olorun fun nisẹ gbogbogbo, awọn miran wà to ran nisẹ pàtó, o ran awọn miran si ilu kan pato, bi iru awon eniyan na ba kọ lati lọ sibiti wọn ran wọn, wọn le ma se daradara nibiti wọn lọ. Awọn miran lẹhin igbati wọn ti wa nibiti wọn ran won tan, awọn alasẹ wọn a gbe wọn kuro nibẹ lọ si ibomiran nigbati wọn ba gbe wọn lo sibomiran tan, yàtọ si wipe isẹ agbara ati akanse le è ma se lọwọ wọn mọ́, Ọlọrun pẹlu tun le è ká ààbò rẹ kuro lori wọn, nitoripe wọn se àìgbọran si ọrọ ati asẹ rẹ. Nigbati Ọlọrun bá ká ààbo rẹ kuro lori wọn, nigbana ni a o ri wipe wọn yio subu sinu oniruru ẹsẹ ti wọn yio si wa di orin ibajẹ lẹnu ọmọ araiye. Afurungbin ọrọ nã mọ ibiti Ọlọrun ran oun si, o mọ ijọ ti Ọlọrun ran oun si, o mọ ilu, ipinlẹ tabi ati orilẹ ede ti Ọlọrun ran oun si, sugbọn ko mọ ilẹ̀ rere tabi buburu nibiti Ọlorun rán-an si nã.
Fun apẹrẹ boya afurungbin na jade lọ lati lọ kede ni adugbo kan ni ilu kan, nigbato ba nkigbe lati sọ ọrọ na, awọn to wa nile igbọnsẹ le mã gbọ ọrọ na, awọn kan le sẹ̀sẹ̀ ma jị lori ibusun wọn, awọn kan le ma wo tẹlefisan lọwọ ki ọrọ na ma ta si wọn leti. Gbogbo awọn to ngbọ ọrọ yi, afurungbin yi ko mọ iru ẹniti ọrọ na yio ti yè daradara lara wọn.
Tabi boya ninu ijọ wa, ki Olusọagutan ma ba awa eniyan sọrọ, boya awa mẹwa la wà lori ijoko, olusọagutan wa to jẹ afurungbin yi ko mọ ẹniti aiye rẹ jẹ ilẹ rere ninu wa ati ẹniti aiye rẹ jẹ ilẹ buburu larin wa, sugbọn olusọagutan yio sá à ma furungbin ọrọ na silẹ aiye gbogbo wa. Fun apẹrẹ ẹ o ranti woli Jona. Woli Jona ko mọ wipe gbogbo ilu Ninefe yio yipada, oun sáà gbọran si ọrọ Ọlọrun to si lọ wasu ni ilu na, sugbọn gbogbo ilu na si yipada si Ọlọrun lẹhin iwasu rẹ. Bi o tise yẹ ki ijọ na ma ri ni eleyi, sugbọn a ri wipe gbogbo ijọ ko ri bẹ.
(4) Afurungbin nã mã nmọ̀ wipe arin ìkokò ni a ran oun lọ.
"Wò ó, mo ran nyin lọ gẹgẹbi agutan sarin ikoko..." (Mt 10:16a).
Eleyi ni wipe nibikibi yio wu ki afurungbin na ma se alai lọ, nibikibi yio wu ki afurungbin na ma se alaisọ wipe ibẹ̀ ni a ran oun si, arin ìkokò ni, arin ọta to gbóná girigiri ni.
(5) Lẹhin igbati afurungbin na ba ti furungbin ọrọ na tan, nse ni yio fi ohun tó ti se le Ọlorun lọwọ. Ojuse afurungbin na ni lati furungbin, ani lati sọrọ Ọlọrun, bi o ba ti pari ojuse tirẹ, eleyiun ni ni sisọ ọrọ na fun awọn eniyan, yio tun wa lọ fi ọrọ to ti bá awọn enia sọ níkọ̀kọ̀ le Ọlọrun lọwọ, ki Ọlọrun mu ki ọrọ na se rere, ki Ọlọrun mu ki ọrọ na bọ si ilẹ rere lọkan gbogbo awọn ti wọn ti gbọ ọrọ nã
"Emi gbìn, Apollo bomirin; sugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wa:
"Njẹ ki ise ẹniti o ngbìn nkankan, bẹẹni ki ise ẹniti nbomirin; bikose Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.
"Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti nbomirin, ọkan ni wọn jasi: olukuluku yio si gba èrè tirẹ bi isẹ tirẹ
"Nitori alabasisẹpọ pẹlu Ọlọrun ni àwa, ẹyin ni ọgbà Ọlọrun, ati ile Ọlọrun" (I Kor 3:6-9)
Awọn miran yio gbọ ọrọ ti afurungbin sọ larọ, sugbọn wọn ko ni ronu le lori titi di igbati wọn ba fẹ sun lálẹ́. Ẹlomiran lẹhin osu kan tó gbọ́ ọrọ ni yio to ronu le lori.
Ere idi niyi to se pọn dandan fun afurungbin na lati fi irugbin na to ti fọ́n si awọn ilẹ na le Ọlorun lọwọ fun amojuto, sísọ́ ati didabobo lọwọ ẹiyẹ buburu gbogbo ati mímú-dagba soke.
(6) Ojuse afurungbin yi kọ́ ni lati kórè (harvest) awọn ere oko na. Nitoripe afurungbin yi kò dà bí àgbẹ̀ aiye, nitorina ki ise ojuse rẹ ni lati kore irugbin na nigbato ba dagba tán tó sì nso eso. Eleyi ni wipe kò ní àká ti ìbá mã kore oko na si, sugbọn ẹnito ri ọkàn ati ero eniyan ló ni àká lati kore oko na si, oun ni yio si se eleyi nigbato baya, nipasẹ awọn angẹli rẹ.
"Ọta ti o fun wọn ni Esu; ikore nã si ni opin aiye; awọn angẹli si ni awọn olukore" (Mt 13:39)
(7) Ojuse afurungbin yi ni lati funrungbin, lati bomirin irugbin to fọ́n gẹgẹ bi awọn agbẹ igbalode tise ma nse, ati awọn agbẹ ti wọn ngbin ẹ̀fọ́ ati awọn ewebẹ gbogbo. Ojuse rẹ miran tun ni lati tọju awon irugbin wọnni.
"Oluwa Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi sinu ọgba Edẹni lati mã ro o, ati lati mã sọ ọ" (Gen 2:15(tun wo awọn iwe wọnyi: Gen 4:2; Rm 12:3-8))
Ohun to je ojuse afurungbin yi ni èdè to le gba yewa ni wipe, yio sọ ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan, yio ma tọ́ awọn enia sọna, yio ma gbà wọn nimọran, yio ma gbadura fun wọn, yio ma bẹ̀ wọ́n wò
"Oluwa si wipe, "Simoni, Simoni, wo o, Satani fẹ lati gbà ọ́, ki o le kù ọ bi alikama:
"Sugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ rẹ ma se yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si pada bọ, mu awọn arakunrin rẹ lọkan le" (Lk 22:31-32)
"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi ninu gbogbo iranti yin ti mo nse.
"Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun yin ni emi nfi ayọ bẹbẹ" (Fil 1:3-4)
Boya a ri lara awọn ọmọ ijọ tabi awọn to ti ba sọrọ ti wọn nfẹ itọsọna lori isẹ kan ti wọn fẹ yan, afurungbin na yio tọ́ wọn sọna wipe eleyi ni kó yan, ko ma se yan ìyẹn, boya ọmọ ile iwe to fẹ mu isẹ kan ti yio lọ fun ni Yunifasiti.
Afurungbin yi a ma gba awọn enia nimọran, boya idile ti ko fẹ duro daradara, boya ọkọ ati iyawo ti ede aiyede wa larin wọn, boya omiran to sẹ̀sẹ̀ de ile ọkọ, afurungbin yi yio tọ sọna, yio gba nimọran bi a ti se mba ọkọ tabi aya ẹni gbé.
Gẹgẹ bi Jesu Kristi ti se gbadura fun Peteru bẹni afurungbin yi nilati ma gbadura fun awọn eso to ni ninu ẹmi nã. Apẹrẹ iru eleyi na lari ninu aposteli Paulu.
(8) Afurungbin na jẹ ẹnito ma ngba ẹnu ọna wọnu oko rẹ. Gẹgẹ bi olusọagutan tise ma ngba ẹnu ọna wọnu agbo agutan bẹna ni afurungbin na se ma ngba ẹnu ọna wọnu oko nã.
"Lotọ, lotọ ni mo wi fun yin, ẹniti ko ba gba ẹnu-ọna wọ inu agbo agutan, sugbọn ti o ba gba ibomiran gun oke, oun na ni ole ati ọlọsa" (Jhn 10:1)
(9) Afurungbin na ma nyọ̀ nigbato ba ri irugbin na to sọ jade. Afurungbin na kì í yọ̀ nitori awọn nkan ara tó rí bí i ilé kíkọ́, mọto rira, aseyọri nile iwe, ọmọ bibi abbl. Ki ise wipe awọn nkan wọnyi ko dara sugbọn awọn nkan na kọ́ ni idunnu rẹ bikose wipe awọn ayipada ẹmi to daju to ri ninu aiye ẹni na.
"Njẹ bi o ba si ri i, lootọ ni mo wi fun nyin, oun yio yọ̀ nitori agutan naa, ju mọkandinlọgọrun iyoku ti ko nu" (Mt 18:13)
Ohun ti mo nwi ni wipe, gẹgẹbi awọn agbẹ se ma nfó fun ayọ nigbati wọn ba ri wipe awọn ohun ti wọn gbin sinu ilẹ hù jade, ti wọn yio si ma fi ọpẹ fun Ọlọrun wipe awọn ẹiyẹ buburu ko yọ awọn irugbin na jẹ, ti wọn yio ma dunnú wipe awọn irugbin na ko jóná, bẹna ni afurungbin ọrọ na ti se ma nyọ̀ nigbati o ba ri wipe ayipada ti ẹmi dé ba awọn ti oun mba sọrọ.... Nigbati ẹnito nse agbere ko ba se agbere mọ, inu afurungbin na yio dun, nigbati ọmuti ba fi ọti mimu silẹ, inu afurungbin na yio dun; nigbati ẹnito ngbe sokoto rẹ si bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí ba bẹrẹ sini wọ sokoto na daradara, inu afurungbin na yio dun.... Ayipada tòótọ́ lo ma nmu inu afurungbin na dun, ki ise awọn ayipada nipa ti ara, ki ise awọn ayipada nipa ohun aiye nini nìkan.
(10) Afunrungbin ọrọ nã mã nmú irugbin na lọ si ibiti awọn ilẹ na wa ni.
"O (Jesu) tọ awọn tirẹ wa, awọn ará tirẹ ko si gbà á" (Jhn 1:11)
Nigbati awọn ti a ran Jesu si ko fi gbogbo agbara gba Jesu, igbana ni Jesu yipada si enia gbogbo to mbẹ ninu aiye, to si wa pe enia gbogbo ninu aiye sọdọ rẹ.
"Sugbọn, iye awọn ti o gbà á, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gba orukọ rẹ gbọ" (Jhn 1:12)
Jesu ko joko sọrun lati ma fun irugbin na, sugbọn o sọkalẹ wa sinu aiye lati wa fun irugbin oro na. Bẹna ni awọn afurungbin ọrọ na lode oni, wọn a lọ si ilu ti wọn ba ran wọn si, wọn a lọ si ileto ti wọn ba ran wọn si, wọn a lọ si igberiko ti wọn ba ran wọn si lati lọ furungbin na nibẹ.
"Iran kan si han si Paulu ni òru: Ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si nbẹ ẹ wipe,
"rekọja wa si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ!"
"Nigba ti o si ti ri iran na, lọgan a mura lat lọ si Makedonia, a gbàá si pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn" (I. Apo. 16:9-10)
(11) Afurungbin ọrọ na ma nwa ilẹ rere ti yio furungbin ọrọ na si. Bi o tilẹ ti jẹ wipe ko le da ilẹ rere mọ yatọ si ilẹ buburu nigbamiran, nitoripe
"Oluwa ki iwo bi enia ti nwò; enia a ma wo oju, Oluwa a ma wo ọkan" (I Sam 16:7b).
Nitoripe oju ni afurungbin yi nri ki ise ọkan, bẹna ni yio ma fi ẹmi mimọ inu rẹ pẹlu adura gbigbona girigiri wadi lọwọ Ọlọrun eleyi to jẹ ilẹ rere ati eleyi ti ki ise ilẹ rere. (Mt 18:11 ff)
(12) Afurungbin ọrọ na ngba ọrọ na tabi irigbin na lati ọdọ Baba rẹ ti ise Ọlọrun.
"Nigbati wọn ba si fi yin le wọn lọwọ, ẹ mase saniyan pe, bawo tabi kinni ẹyin o sọ? Nitori ti a o fi ohun ti ẹyin yio sọ fun yin ni wakati kanna" (Mt 10:19)
Ọlọrun lo nfun afurungbin na ni ọrọ to ba onikaluku lara mu. Nigbati afurungbin yi ba ri ojulowo ọrọ gba lati ọdọ Ọlorun ti o ba si sọ ọrọ na, awọn miran a ma binu ninu ijọ, awọn miran yio wipe "o dabi ẹnipe ẹnikan ti lọ ba pasitọ sọ ọrọ mi loni", " o dabi ẹnipe ija ti emi ati bale mi ja lọjọsi ko i ti tán ninu wọn, nitorina wọn lọ fi ẹjọ mi sun olusọagutan, eredi niyi to se nfimi sọrọ lori pẹpẹ"....
Nigbati afurungbin na ba gba ọrọ na lati ọdọ Ọlọrun to ba si sọ ọrọ na, ọrọ na yio tu asiri ikọkọ gbogbo, ọrọ na yio sọ ẹnito ro wipe ati da asọ bo ìhòhò oun si ihoho gedengbe loju ara rẹ tobẹ gẹ ti yio fi ro wipe nse ni gbogbo eniyan ti mọ asiri oun, yio ro wipe olusọagutan ti mọ asiri oun, yio ro wipe wọn ti bẹrẹ sini fi oun se ọrọ sọ larin ijọ ati larin ilu, laimọ wipe Ẹmi Mimọ lo tu asiri rẹ, ati wipe o sese ki olusọagutan ma mọ ohunkohun nipa ẹni na kọja ohun ti Ẹmi Mimọ ngbe jade lẹnu rẹ na lọ.
"Nitori, ọro Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mu ju idakida oloju meji lọ, o si ngunni ani titi de pinpin ọkan ati ẹmi niya, ati orike ati ọ̀rá inu egungun, Oun si ni olumọ ero inu ati ete ọkan" (Heb 4:12)
Ọrọ Ọlorun ti a fi fun afurungbin na lati ipasẹ Ẹmi Mimọ lo fi asiri ẹni na han, lo fi iwa ẹsẹ ẹni na han, Ọrọ Ọlọrun ti afurungbin na nfun lo fi bi ẹni na se ri han gedegbe fun un to si npe e fun atunse, ironupiwada ati iyipada patapata lati ọdọ ẹni na.
"...ki o si da nyin loju pe, ẹsẹ nyin yio fi nyin han" (Num 32:23b)
Afurungbin yi, ẹnikẹni yio wu ko jẹ, boya iyawo to mba ọkọ rẹ sọrọ Ọlọrun ninu ile ni, boya awọn obi to mba awọn ọmọ wọn sọrọ Ọlọrun, boya awọn osisẹ ti nwọn mba ara wọn sọ ọrọ Kristi Jesu nibi isẹ wọn ni,...ani irufẹ ẹni na yio wu ki o mase alai jẹ yio ti so ara rẹ papọ mọ Ẹmi Kristi Jesu ninu ẹmi (eniyan) to mbẹ ninu rẹ, nipasẹ siso ara rẹ papọ mọ Ẹmi Mimọ yi, Ẹmi Mimọ to si ri ohun gbogbo, to wa ni ibi gbogbo, to mọ ohun gbogbo yio wa ma fi asiri ikọkọ han fun ẹni na, eleyi ti yio wa ma gba ẹnu ẹni na sọ jade.
"Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma se awari iyara inu" (Owe 20:27)
Ẹmi eniyan to mbẹ ninu ẹni na ni fitila ti Ọlọrun nlo lati fi wá gbogbo kọrọ̀ inu ẹni na, ẹmi yi na lo nfi ero jínjìnnà to mbẹ ninu eniyan han, ẹmi yi na lo nfi ohun ti ẹni na nro ni ọna jínjìn han, ẹmi yi lo ma nsọ nipa ọjọ iwaju ẹni na lati ipasẹ ero rẹ... Ohun ti eniyan ko i ti se, ohun ti awọn ti wọn nri eniyan lojukoju ko ro wipe eniyan le è se lailai, sugbon to jẹ wipe ẹni na yio se lọjọ iwaju, ẹmi yi lo ma nfi ohun ọjọ iwaju na han fun Ẹmi Mimọ to bẹ gẹ ti Ẹmi Mimọ yio se wa gbé e jade.
"Ọkan eniyan kun fun ẹtan ju ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! Tabi o le mọ̀ ọ́?
"Emi Oluwa, ni iwa awari ọkan eniyan, Emi ni ndan inu wo, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọna rẹ, ati gẹgẹ bi eso isẹ rẹ" (Jer 17:9-10)
Ko si ẹnito le mọ ọkan enia, ko si ẹnito le mọ ohun to mbẹ ninu ọkan eniyan, sugbọn nipasẹ Ẹmi Mimọ to njọba lori ẹmi eniyan yi, ohun gbogbo to sapamọ sinu enia, ohun gbogbo to wa ni kọrọ-kọ́ndú inu eniyan, ohun gbogbo to wa ni ibi kọlọfin ninu eniyan ni yio tan imọlẹ si, ti Oluwa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ yio si ri ohun na, ti Oluwa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ yio si ti ẹnu awọn iransẹ rẹ, ani awọn afurungbin gbogbo gbe ọrọ na jade. Ere idi niyi to se jẹ wipe ẹlomiran ti eniyan nwo, ti eniyan nri, ti eniyan nmọ̀ si onigbagbọ loni, nigbati Ẹmi Ọlọrun yio ba sọrọ nipa ẹni na, Ẹmi Ọlọrun le è wipe apaniyan ni, sugbọn awa bi enia a ó ma wò ó gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, kodà o le jẹ wipe oludasilẹ ni, sugbọn sibẹ Ẹmi Mimọ yio ma sọ wipe ki ise ọmọ Oun, nitoripe Ẹmi Mimọ nipasẹ ẹmi eniyan to fi fun ẹni na ti tan imọlẹ si gbogbo ikọkọ ẹni na, o ti wadi rẹ titi de ọna jinjin rere, o si ti ri wipe ko yẹ ni ẹniti a ba ma pe ni ọmọ Ọlọrun ati wipe ki i tilẹ ise ọmọ Ọlọrun.
Awọn enia ma nwipe ẹniti ko ba i ti lówó lọwọ ki a ma se kà á si onigbagbọ, wọn a tun ma wipe ẹniti ko ba i ti de ipo nla, ipo giga, ki a ma i ti kàá si onigbagbọ, ẹlomiran wọn a wipe, nigbati ko ba i ti niyawo tabi ni ọkọ ki a ma iti kà á si onigbagbọ. Kinidi ti wọn se nsọ bẹ? Idi ni wipe gbogbo awọn nkan wọnyi lo ma nyi eniyan pada.
Mo wa woye wipe, ki ise awọn nkan wọnyi gan lo ma nyi awọn eniyan pada bikose wipe ọkan awọn eniyan wọnni gan buru jai funrawọn, ọkan wọn gan kún fun ẹtan funra wọn, sugbọn loju tiwa, nitoripe a nri wipe wọn jafafa, loju tiwa, nitoripe a nri wipe wọn nse dede ninu ijọ tabi nibi gbogbo, loju tiwa nitoripe ìsesí ati ihuwasi wọn gan fẹ jọ ti Kristi Jesu, a o ti ro wipe ọmọ Ọlọrun ni wọn, a o ti ro wipe onigbagbọ ni wọn. Sugbọn nigbati Ẹmi Oluwa ba wa wo ẹmi inu wọn ti gbogbo asiri si han tan, ti o wa gbe ọrọ na jade pe wọn jinna si ọrun rere, kayefi yio wa ma se wa.
Ki Saulu to di ọba ni ilẹ Israeli, o han wipe o nse dede bẹna lo si nse daradara ninu ofin ati ilana woli Mose ti wọn nlo, eredi niyi ti Ọlọrun se yàn an lati di ọba lori awọn eniyan rẹ, sugbọn, lẹhin igbati o di ọba tan, ohun to ti wa ni kọlọfin ati ikọ̀kọ̀ ọkan rẹ farahan to bẹ gẹ to fi kuro lọdọ Ọlọrun patapata. Ohun to wa ni kọlọfin ọkan rẹ yi ni Ẹmi Mimọ Ọlọrun to mbẹ ninu woli Samueli ri to fi sọrọ wipe ijọba rẹ ko ni duro ati wipe Ọlọrun ti wa ẹlomiran fun ara rẹ to san jù ú lọ.
"Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ ko hu iwa ọlọgbọn: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li asẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ lori Israeli lailai.
"Sugbọn nisisiyi ijọba rẹ ki yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ ọkunrin ti o wù u li ọkan rẹ, Oluwa pasẹ fun u ki o se olori fun awọn enia rẹ, nitoripe iwọ ko pa asẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ" (I Sam 13:13-14)
Irekọja akọkọ ti Saulu ọba se ni eleyi, a ó si ri wipe to ba jẹ niti eniyan ni, koda to ba jẹ niti woli Samueli gan ni, o yẹ ki a si fi oju fo asise na, ki a si fi ewe ọmọ mọ́ ọba Saulu leti wipe ki o mase ran iru asọ bẹ soro mọ, sugbọn Ọlọrun ki ise eniyan, Ọlọrun kọ ni Samueli, nitoripe Ọlọrun ti wadi ọkan ọba Saulu, Ọlọrun si ti ridi rẹ lẹsẹkanna, nitorina ni Ọlọrun se wipe Oun ti wa ẹlomiran fun ara Oun ti yio mu gbogbo ipinnu ati ifẹ Oun sẹ lati wa jẹ ọba ati alakoso lori awọn eniyan na.
Riri ati mímọ eniyan lati ọna jinjin rere na lo mu ki Ọlọrun kọ gbogbo awọn ẹgbọn Dafidi silẹ ti Ọlọrun si fi yan Dafidi ni ọba.
"Sugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, mase wo oju rẹ, tabi giga rẹ; nitoripe emi kọ̀ ọ́: nitoriti Oluwa ki iwo bi enia ti nwo; enia a ma wo oju, Oluwa a ma wo ọkan" (I Sam 16:7)
Otitọ ni wipe awọn ẹgbọn Dafidi jẹ akikanju jagunjagun, otitọ ni pe awọn ẹgbọn Dafidi jẹ ilumọmika ninu isẹ ogun na, otitọ ni wipe gẹgẹ bi iwoye ti eniyan, wọn kun oju iwọn lati di ọba ni ilẹ Israeli, sugbọn ẹmi enia ti mbẹ ninu wọn ti fi asiri aiye wọn han ni gbangba si Ọlọrun, eleyi to mu ki Ọlorun wi fun iransẹ rẹ wipe oun ki i wò bi eniyan ti se nwo.
Lọpọ igba niru isẹlẹ yi ma nsẹlẹ ninu ijọ, tabi bi eniyan ba lọ bere nkan lọwọ Ọlọrun. Ohun tabi ẹniti eniyan ro wipe o yẹ ki Olorun o mu tabi yàn, Ọlọrun le e wipe Oun ko yan awon eniyan na, nitoripe Ọlọrun ti ri ohun to farasin ninu aiye wọn eleyi ti awa ko si ri.
Baba Adegunlẹ nigba aiye wọn sọ fun mi pe nigbati awọn fẹ fẹ iyawo, wọn wipe awọn mu orukọ awọn mẹta lọ si ọdọ awọn aladura, wọnni ẹnikan ni wọn mu ninu wọn, nigbati wọn sọ wipe ki oun ma fẹ awọn yoku. Baba wa wipe, sebi awọn ko i ti gbagbọ nigbayẹn ati wipe aiye ko i ti di aiye ọlaju tabi igbalode bi ti eleyi nigbayẹn, wọn wipe awọn ọrẹ awọn tun mu awọn lọ si ile babalawo, wọn ni babalawo bi meji ti awọn de ọdọ wọn, wọn ni orukọ ti aladura yẹn mu na ni awọn na mu, wọn wa wipe, sugbọn ikan ninu awọn babalawo wọnyẹn lo wa tu isu de isalẹ ikoko to si salaye fun awọn idi ti awọn ko se gbọdọ fẹ awọn mejeji yoku. Baba Adegunlẹ wi fun mi wipe baba yẹn wipe, se o ri orukọ ti o kọ sinu iwe yi, (nitoripe baba na ko mọ iwe ka) o ni ere idi ti o kò se gbọdọ fẹ ẹ ni wipe ẹlẹmi kukuru ni.... Wọn tun wipe wọn fi orukọ kẹta yẹn han oun wipe se o ri ẹniyi nitirẹ, ẹni aiye ni, ilepa ohun aiye ni yio ma le sá a, bẹ sini iwọ (Adegunlẹ) niyi ẹni ọrun ni ẹ, nitoripe ilepa awọn ohun ti ise ti ọrun lo wa lọkan rẹ ti wa ma lé ninu aiye..., nitorina o ko gbọdọ fẹ oun na pẹlu...
Baba Adegunlẹ si wipe bi baba yi se wi bẹ na lori, nitoripe ẹnito sọ wipe ki ise ẹlẹmi gigun na ko pẹ pupọ to fi ku, nigbati ẹni keji na wa bẹrẹ sini ta ọti, ati awọn ohun ti ọmọ Ọlọrun ko yẹ lati ma mã ta, ati wipe òde ariya loni, ode ariya lọna ni ti obinrin na....
Kilojẹ ki nsọ itan yi? Bi o tilẹ jẹ wipe agbara okunkun ni awọn babalawo na nlo lati ri nkan sugbọn nipasẹ agbara na, ẹmi inu awọn eniyan na fi ohun kan tabi meji han nipasẹ awọn eniyan na. Nigbati agbara okunkun le fi eleyi han, melomelo wa ni agbara Jesu, ani Ẹmi Mimọ yio se fi ohun ijinlẹ nipasẹ eniyan han ju eleyi lọ, ani koda ohun ti eni na ko i ti se, tabi ohun ti awọn eniyan ko tilẹ ro wipe ẹni na tabi awọn ẹni na le e se lailai yio di fifihan si gbangba nipasẹ Ẹmi Mimọ.
Nigbamiran ẹwẹ, ohun ti Ẹmi Mimọ na fihan ẹni na gan le e ma ro wipe lailai ohun ko le è se iru rẹ, sugbọn sibẹ, Ẹmi Mimọ yio ma tẹnumọ wipe yio se ohun na ti ko ba tilẹ eleyi to buruju bẹ lọ. Ẹ jẹ ki a ka irufẹ isẹlẹ yi ninu iwe Awọn Ọba keji ori kẹjọ.
"On (woli Elisa) si tẹ oju rẹ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì í; enia Ọlọrun na si sọkun"
Bibeli ede eyibo kan tumọ ẹsẹ yi bayi,
"Nigbana ni Elisa tẹjumọ Hasaeli gidigidi, o si bẹrẹ sini ka ohun to wa lọkan rẹ. Hasaeli ri wipe oun wa nihoho tabi asiri oun tu, nitorina o gbe oju rẹ silẹ. Nigbana ni eniyan Mimọ (Ọlọrun) na sọkun" (Message Bible).
"Hasaeli si wipe, èése ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahun pe, nitoriti mo mọ ibi ti iwọ o se si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi ida pa, iwọ o si fọ ọmọ wẹ́wẹ́ wọn tutu, iwọ o si la inu awọn aboyun wọn.
"Hasaeli si wipe, sugbọn kinla? Iransẹ rẹ ise aja, ti yio fi se nkan nla yi? Elisa si dahun wipe, Oluwa ti fi han mi pe, iwọ o jọba lori Siria" (2 A. Ọba 8:11-13)
Lati esẹ kẹjọ ni ọrọ yi ti bẹrẹ, a ri wipe ọba Sira to njẹ Benhadadi se aisan gidigidi, oba yi ko si mọ boya oun yio bọ́ ninu aisan na tabi oun ko ni bọ, nitorina o ran iransẹ rẹ, Hasaeli, lati lọ ba oun bere lọwọ Ọlọrun ohun to fẹ sẹlẹ si oun. Lẹhin igbati enia Ọlọrun na sọ fun iransẹ na ohun ti Ọlọrun sọ nipa ohun to wa bere na; Ọlọrun wa ti ipasẹ Ẹmi rẹ to mbẹ ninu aiye iransẹ rẹ fi ayé ọkunrin na hàn, ọkunrin na gan ko gbagbọ wipe oun le è se ohun ti Ọlọrun tipasẹ iransẹ rẹ sọ nã, ere idi niyi to se wipe, "kinla? Iransẹ rẹ ise aja, ti yio fi se nkan nla yi?" (2 A. Ọba 8:13b)
Nigbamiran ti Ẹmi Ọlọrun ba sọ nkan ijinlẹ nipa aiye ẹlomiran, ẹni na gan le ma gbagbọ wipe oun le è se ohun na. Ki a ma tilẹ wa sọ wipe awọn miran gan ko ni gbagbọ wipe ẹni na le se ohun na, iba se ohun rere tabi ohun buburu gẹgẹbi ti ọkunrin Hasaeli ti.
Afurungbin na yio gba ọrọ tabi irugbin na lati ọdọ Ọlọrun yio si fọn sita, nitoripe ọdọ Ọlọrun ni afurungbin na ti gba ọrọ nã, awọn ohun ikọkọ, awọn ohun ijinlẹ ni yio ma jade lati ẹnu afurungbin na tobẹ ti awọn eniyan yo ngbọ ọrọ na yio ma ro wipe ẹnikan ti ba afurungbin na sọrọ nipa oun.
"Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya ya ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere han" (Ef 6:19)
Nipa adura, afurungbin nã yio sọ ohun ijinlẹ jade.
(13) Afurungbin ọrọ nã ki i fi irugbin nã sòfùn (waste). Ibere ti yio wa si ọkan wa ni wipe njẹ bawo ha ni oniwasu se le fi ọrọ Ọlọrun sòfùn? Ẹ jẹ ki a ka iwe ihinrere Matteu ori karundinlogun.
"Jesu si ti ibẹ kuro, o si lọ si agbegbe Tire on Sidoni.
"Si wò ó, obinrin kan ara Kenaani ti ẹkùn na wa, o si kigbe pè e, wipe, Oluwa, iwọ ọmọ Dafidi, sanu fun mi; ọmọbinrin mi li ẹmi esu ndaloro gidigidi.
"Sugbọn ko si dá a lohun ọrọ kan. Awọn ọmọ ẹhin rẹ wa, nwọn bẹ̀ẹ́, wipe, rán an lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ wa lẹhin.
"Sugbọn (Jesu) o dahun wipe, a kò rán mi, bikose si awọn agutan ile Israeli ti o ni.
"Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u wipe, Oluwa ran mi lọwọ.
"Sugbọn O dahun, wipe, ko tọ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun aja" (Mt 15:21-26)
Ninu iwe ihinrere yi, a ri wipe obinrin ara Kenaani kan lọ mbere iranlọwọ, itusilẹ fun ọmọ rẹ lọwọ Jesu Kristi. Jesu wa da obinrin na lohun wipe, ohun to mbere lọwọ Oun lati se yi, bi oun ba se é nse ni yio dabi igbati oun fi nkan sòfùn, nitoripe oun mọ awọn ti wọn rán oun si.
Bẹ gẹgẹ ni awọn afurungbin kan loni. Awọn afurungbin kan wa to jẹ wipe awọn kan ni a ran wọn si, bi iru afurungbin yi ba lọ sibiti a kò ran-an si, sise eleyi nfi iru ẹni bẹ han gẹgẹbi ẹnito nfi nkan sofun, eleyi ti ko ni jẹ ki irugbin na mu eso to dara jade, yatọ si wipe ko ni mu eso to dara jade, irufẹ ẹni na pẹlu tun le è ri igbóguntì ọ̀tá.
A nilati jẹ ki eleyi rinlẹ si ọkan wa wipe, nitoripe eniyan ti ri ẹbun kan gba lọwọ Ọlọrun, eleyi ko tumọ si wipe o le mã se bi o ba wù u, eleyi ko tumọ si wipe o le lọ ma sọ ọrọ nibiti wọn ko ti ni gba ọrọ rẹ laise wipe Ọlọrun ran nibẹ̀. Fun apẹrẹ ki eniyan wipe oun ti lagbara bayi, nitorina o wa kọja lọ sinu ijọ ti ko gba ihinrere gbọ, awọn ijọ to jẹ wipe ipilẹ ijọ wọn oògùn ni, ko wa lọ mã tako ipilẹ ijọ nã, sise eleyi nigbati ki ise wipe enia gbọ itọsọna pató le fi enia han gẹgẹ bi ẹnito nfi ọrọ na sòfùn, eleyi le mu ki wahala nla o deba ẹni na tabi ati idile rẹ. Ti ki iba ise wipe wọn pe eniyan lati wá bá wọn sọrọ ninu ijọ yi, tabi wipe Ọlọrun ba ẹni na sọrọ gẹgẹbi woli Jona, bi ẹni na ba lọ nsọrọ nibẹyẹn, fifi irugbin na sofun ni eleyi. Eleyi yatọ si wipe a mba alaigbagbọ sọrọ nibi isẹ tabi lọfisi tabi ninu ọkọ̀ abbl.
(14) Afurungbin yi na ma njẹ lara irugbin wọnyi...eleyi ni wipe oun pẹlu yio ti di agutan tabi ọmọ Ọlọrun.
"Wò ó, mo ran nyin lọ gẹgẹbi agutan sarin ikoko" (Mt 10:16a)
Ẹniti nkan ko ba se ri le e má mọ̀ bi ohun na ti ẹni na nla kọja tise ri lara. Wọn ma nsọ ede kan, wọn a wipe, awọn Fulani ma nwi fun ẹnito ba fẹ ta oògùn fun wọn wipe "se ó se ọ́ rí", wọn wipe bi ẹniti o fẹ ta ogun na ba wipe ko se oun ri, wọnni awọn Fulani na ko ni bá a ra ogun na nitori wọn a wipe kò mọ bi o se nse eniyan, nitorina o le jẹ wipe ogun tabi ohun ti ko dara ni yio fi fun awọn, o le è mã fi oògùn ẹ̀tẹ̀ pa lapálàpá.
Bẹ pẹlu ni afurungbin ọrọ nã, bi ẹniti yio furungbin ọrọ yi ko ba i ti la iru ohun to fẹ sọ nipa rẹ kọja, o le ma ri ọrọ na sọ jinlẹ fun awọn eniyan. Bi afurungbin yi tikararẹ ko ba ma jẹ ninu irugbin na ti oun pẹlu fẹ fọ́n fun awọn eniyan, ọrọ nã le è ma ni itumọ, tabi ti yio ba ni itumọ ọro na le è ma jinlẹ lọkan awọn eniyan na. Bi ọrọ na ko ba si ni ijinlẹ ninu, o sese ko ma ni ipa rere ninu aiye awọn ẹlomiran to ngbọ.
Ohun to mu ki ọrọ Jesu Kristi yi o yatọ patapata lati le è ran gbogbo eniyan lọwọ na ni wipe Oun pẹlu ti la awọn nkankan kọja gẹgẹ bi awa pẹlu ti se nla awọn nkan kọja, oun pẹlu a dán an wo, nitorina, awa ti a ndan wo nisinsinyi o mọ iru irora, inira ati idamu ti a nla kọja.
"Nitori a ko ni olori alufa ti ko le sai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, sugbọn lailẹsẹ" (Heb 4:15)
Afurungbin ọrọ nã, nitoripe oun pẹlu ti jẹ irugbin nã, ati nitoripe o tun njẹ irugbin nã, o ti ni iriri nipa irugbin na, nipasẹ iriri yi ni yio fi sọ ọrọ ijinlẹ fun awọn to mba sọrọ nipasẹ iriri yi ni eso to nfun na yio se dùn lẹnu awọn ti wọn ba mu eso nã lati jẹ ẹ́.
"Ati suru nsisẹ iriri; ati iriri ni nsisẹ ireti.
"Ireti ki si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọkan lati ọdọ Ẹmi Mimọ wa ti a fifun wa" (Rm 5:4-5)
Apá Kejì mbọ̀ lọ́nà….
Comments
Post a Comment