O Kan Ìwọ Náà (2)

Ó KÀN ÌWỌ NÁÀ (2) Lati ọwọ ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI © ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI (2015) Email: segundare111@gmail.com Facebook: Olusegun Ogundare Twitter: Ogundare Olusegun Telegram: Olusegun O. Ogundare Vk.com: Olusegun Ogundare LinkedIn: Segun Ogundare Tumblr: olusegundare Veenner chat: Ogundare Olusegun O. WhatsApp: +2347037106880 Cellular: +2348026301717
ÒRÍ KẸRIN IDAJỌ ATI ÈRÈ AFURUNGBIN NÃ No ori yi ni a o ti wo idajọ ati ere afurungbin na. (1) Ìdájọ́ afurungbin na ko duro lori ìwà ati ise awọn olugbọ rẹ bikose wipe idajọ rẹ duro lori asẹ Ọlọrun to tẹle tabi asẹ Ọlọrun to pamọ. Eleyi ni wipe, nigbati a bá ran afurungbin na si ilu kan, tabi iletò kan tabi ijọ kan tabi orilẹ ede kan tabi boya eniyan kan, ohun to se pataki fun afurungbin na ni lati lọ jisẹ ti a ran si ilu tabi ijọ tabi orilẹ ede tabi ẹni na.... Boya awọn tabi ẹniti a ran-an si nã kò wa gbọ ọrọ Ọlọrun nã, tabi boya wọn ko gba ọrọ Ọlọrun na gbọ tabi gba ọrọ Olorun na wọle, eleyi ko ni nkankan se pẹlu afurungbin na, a ò ni fi eleyi se idajọ afurungbin na, ohun ti a o fi se idajọ afurungbin na ni wipe se o lọ jisẹ ti a ran-an tabi ko lọ? Lilọ jẹ isẹ ti a ran tabi àìlọ jẹ isẹ ti a ran-an ni a o fi se idajọ rẹ, ki ise wipe se awọn olugbọ rẹ gbagbọ tabi wọn ko gbagbọ. "Sugbọn Oluwa wi fun mi pe, ma wipe, ọmọde li emi: sugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o pasẹ fun ọ ni iwọ o sọ. "Ma bẹru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gba ọ: li Oluwa wi" (Jer 1:7-8) (Esek 3:18; 33:6; Num 20:11) Ninu iwe woli Jona a ri ka wipe, "Njẹ ọrọ Oluwa tọ Jona ọmọ Amittai wa, wipe, "Dide, lọ si Ninefe, ilunla ni, ki o si kigbe si i; nitori iwa buburu wọn goke wá iwaju mi" (Jon 1:1-2) Ọlọrun ran Jona woli Rẹ si ilu nla to njẹ Ninefe, sugbọn kini Jona se? "Sugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarsisi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ kan ti nlọ si Tarsisi: bẹli o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ, lati ba wọn lọ si Tarsisi kuro niwaju Oluwa" (Jon 1:3) A o ri wipe, woli Jona gbọ isẹ ti a rãn daradara, sugbọn ó yàn lati ma lọ jisẹ na lasiko na, o kọ isẹ na silẹ, o yan lati lọ si ilu miran, boya o fẹ lọ dá oko-òwò silẹ nibẹ ni a ò le sọ...sugbọn ohun to han gbangba ni wipe ko fẹ jisẹ na. Gbogbo awa oluka bibeli na ni a o si ranti wipe idajọ ti Ọlorun se fun nitori à ì fẹ lọ jisẹ rẹ nã ko nise pẹlu awọn ti a ran woli na si, bikosepe à ì pa àsẹ na mọ, à ì lọ jisẹ na. Nitori a ì lọ ni a se se idajọ rẹ, nitori à ì pa asẹ na mọ ni Olọrun se se idajọ rẹ.... Lẹhin o rẹhin to wa jisẹ na tan nkọ? Nse ni gbogbo ilu na ronupiwada ti nwọn si gba Ọlọrun gbọ, sugbọn to ba jẹ wipe gbogbo ilu na se ori kunkun, ti gbogbo ilu na ko gbagbọ, a o ni da woli Jona lẹjọ nitori àìgbagbọ awọn olugbe inu ilu na, ohun ti idajọ rẹ duro lori ni wipe ó mú ofin ati asẹ ti Ọlọrun fi fun sẹ. Woli Noa na ba awọn iran tirẹ sọrọ nipa ìkún omi to mbọ, sugbọn wọn ko gbagbọ, aigbagbọ awọn enia to wa lasiko Noa kọ li a fi se idajọ Noa, bikose gbigbọran to gbọran si ohun ti Ọlọrun sọ ni a fi se idajọ rẹ, ti a si fi gba Oun ati idile rẹ là (Gen 6-9; II Pet 2) Ohun ti a fi se idajọ Loti ni wipe o lọ jisẹ ti a ran si ilu na, aigbagbọ gbogbo awọn to lọ jisẹ na fun nilu Sodomu ati Gomorra kọ́ li a fi se idajọ rẹ bikose wipe o gbọran si asẹ awọn angẹli na o si pa á mọ (Gen 19; II Pet 2) Idajọ afurungbin na ko duro lori iwa ati ise awọn olugbọ rẹ bikose wipe o mu ọrọ ti Ọlọrun sọ fun sẹ, eleyi ni a o fi se idajọ rẹ. Bi a ba ran iwọ ati emi na sibikan ohun to jẹ ojuse wa ni lati lọ jisẹ na, awọn agbalagba gan ma nwipe, "ẹnito ran ni nisẹ la mbẹru, a ki i bẹru ẹniti a o jisẹ fun".... Bi a bá lọ jisẹ ti a ran wa, yala awọn enia gbagbo tabi wọn ko gbagbo, yala awon enia yipada tabi won ko yipada, ohun ti idajo na yio duro le lori ni wipe nje a lọ tabi a kò lọ? (2) Ọrọ ti afurungbin na sọ kọ ni a o fi se idajọ rẹ. Ohun ti mo nwi ni wipe ki ise ọrọ ti afurungbin na fi da ẹniti o ran nisẹ lohun nigbati a ran nisẹ na ni a o fi se idajọ rẹ. Ẹlomiran nigbati Ọlọrun ba pe é lati ran an nisẹ ohun ti yio sọ fun Ọlorun ni wipe oun ti gbọ ati wipe oun yio lọ se isẹ nã, sugbọn ti ko si ni kuro nibito wa, kò ni lọ jisẹ na. Ẹ jẹ ka wo apẹrẹ eleyi ninu iwe ihinrere Matteu. "Sugbọn kili ẹnyin nro? Ọkọnrin kan wà ti o li ọmọ ọkọnrin meji; o tọ ekini wa, o si wipe, ọmọ, lọ isisẹ loni ninu ọgba ajara mi. "O si dahun wipe, emi ki yio lọ: sugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. "O si tọ ekeji wá, o si wi bẹ gẹgẹ. O si dahun wi fun u pe, emi o lọ, baba: ko si lọ. "Ninu awọn mejeji, ewo li o se ifẹ baba rẹ? Nwọn si wi fun u pe, eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, lotọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn pansaga siwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun" (Mt 21:28-31) Ninu akọsilẹ orọ Jesu Kristi yi, a ri wipe ki ise idahun rere, ki ise idahun to dun mọ eniyan leti ni a fi se idajọ awọn ọmọ yi bikose igbesẹ ti wọn gbe lẹhin igbati wọn gba asẹ lati ẹnu baba wọn tan ni a fi se idajọ wọn. Didahun pẹlu ọrọ didun kọ́ ni a o fi se idajọ wa bikose gbigbe igbesẹ, bikose sise ohun ti a sọ. Ọpọ ninu wa nigbati awọn afurungbin ọrọ nã, awọn oniwasu bá bawa sọrọ Ọlọrun tan, a o fi ọrọ didun da wọn lohun, a o fi ohun to dun un gbọ leti da wọn lohun ki nwọn o ma ba binu, ki nwọn o ba le ma ro pe a ti yipada, ki nwọn o ba le ma ro wipe a ti di ẹda titun, sugbọn ki ise idahun ahọn yi nikan ni yio gbé wa de ijọba Ọlọrun, ki ise idahun ahọn yi nikan ni yio sọ wa di oluse ọrọ na, ayafi ki a gbe igbesẹ to ba idahun ahọ́n ọn wa mu.... Ọpọ awọn miran gẹgẹ bi itan Jesu yi ni yio gbọ ọrọ Ọlọrun tan ti ko si ni dahun rara, sugbọn lẹhin o rẹhin ti yio si bẹrẹ sini se ifẹ Baba to mbẹ li ọrun. Ọpọ miran wa ti yio dahun gẹgẹbi ọmọ keji na tise dahun, sugbọn nikẹhin ti yio si bẹrẹ sini se ifẹ Ọlorun. Awa eniyan le è da eniyan lẹjọ nipa idahun ti ẹni na fi fun wa, sugbọn o hàn gbangba wipe Ọlorun ko ni dajo pelu ìdahun wa, ohun ti Ọlọrun yio fi dajọ ni igbesẹ ti a gbe, ani sise ifẹ Ọlọrun nã. A o ni da afurungbin ọrọ na lẹjo nipa ọrọ to fi da Ọlọrun lohun nisaju bikose nipa sise ifẹ Ọlọrun na, titẹle asẹ rẹ. (3) Idajọ afurungbin na ko ni duro lori wipe "mo fẹ lọ jisẹ nã". A o ri wipe nigbamiran nkan ma n wu enia lati se sugbọn lẹhin o rẹhin ti ẹni na ko si ni se ohun na. Bi o ba wu enia lati dako sugbọn ti ẹni na ko sánlẹ̀, ko kọ ebè njẹ ẹni na ha le kore oko bi? Tabi boya ẹni na tilẹ fun awọn alagbase lowo lati ba oun sán ilẹ oko rẹ, tó tun fun wọn lowo lati kọ ilẹ na sugbọn ti wọn ko ba gbin nkan si njẹ o le è ni ere kankan bi? Idahun rẹ na ni wipe ko le ni ere kankan. Bẹna ni ti nkan ba nwu eniyan lati se sugbọn ti ẹni na ko se ohun na, a ò ni da ẹni na lẹjọ nipa ohun to nwù u lọkan lati se. Bi o ba nwu afurungbin ọrọ nã lati lọ jisẹ ọrọ na, lati lọ furungbin ọrọ na, sugbọn tó ba kunà lati gbe igbesẹ nã, a o ni da lẹjọ nitoripe, o nwù ú tabi nitoripe o nfẹ lati jisẹ na bikose pe a o dá a lẹjọ lori igbesẹ na to gbé. Bi o ba nwu eniyan lati ni igbala, bi enia ba nfẹ lati di ẹni igbala, sugbọn ti iru enia bẹ ba kuna lati gbe igbesẹ, tiru enia bẹ ba kuna lati fi aiye rẹ fun Kristi Jesu lẹiyẹ-o-sọka, Olọrun kò ni titori ifẹ to mbẹ lọkan rẹ dã lare, Ọlọrun ko ni sọ wipe nitori ife to fẹ Ọlọrun ninu ọkan rẹ to si fi sọ wipe oun nfẹ di ẹda titun gba ọkan rẹ gba ọkan ẹni na la bikose wipe njẹ o gbe igbesẹ lati di atunbi nitori lai gbe igbẹsẹ yi, ko ì ti di atunbi. Afurungbin na yio gba idajọ rẹ ki ise nitoripe o nifẹ ati furungbin bikose wipe o gbe igbesẹ lati furungbin na. (I. Apo 16:7; 26:32; Mt 27:24) (4) Idajọ afurungbin nã ko ni duro lori ironu rẹ lati furungbin. Ọpọ lo ma nronu lati se ohun kan sugbọn ti nwọn ko si ni pada se ohun nã. Bi eniyan ba ronu lati gbe igbesẹ kan tabi se ohun kan sugbọn ti ko si se ohun na bawo wa ni awọn eniyan yio se mọ wipe iru èrò bẹ wa sọkan ẹni na ri? Nitoripe ọmọ oninakuna yẹn gbe igbesẹ lori ero to sọkan rẹ, eleyi lo jẹ ka mọ ohun to ti là kọja ati awọn ero to wa sọkan rẹ lasiko wọnni. "Sugbọn nigbati oju rẹ walẹ, o ni, awọn alagbase baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyo, ati ajẹti, emi si nku fun ebi nihin. "Emi o dide, emi o si tọ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, baba, emi ti dẹsẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; "Emi ko si yẹ, li ẹniti a ba ma pe li ọmọ rẹ mọ; fimi se bi ọkan ninu awọn alagbase rẹ" (Lk 15:17-19) Eleyi ni Bibeli Mimọ sọ wipe Jesu sọ nipa ọmọ aburo yi, ti a npe ni ọmọ oninakuna. Ọmọ nã nigbati o wa ninu àìni ati airoju, ọmọ na ri ara rẹ gẹgẹbi ẹlẹsẹ, ọmọ na ri wipe ẹsẹ ti oun da ga pupọ jọjọ, ọmọ na lẹhin igbati o ri ara rẹ ni ikorita yi, o wa mọ wipe, orí bíbẹ́ kọ ni oògùn ori fifọ, ọmọ na yin irú baba rẹ ni àwo ọbẹ, o si mọ wipe lati jẹ ọmọkunrin, lati jẹ bale ile isẹ́ kekere kọ, nitorina omọ na ronu ohun to le se ti yio fun oun ni isinmi, ọmọ na ronu ohun ti yio se ti yio fun ni ifọkanbalẹ, irọrun ati alafia aiyeraiye, ọmọ na wa ri wipe ohun to yẹ ki oun o se ni ki oun o pada lọ sọdọ baba oun ki oun si tọrọ aforiji, ki oun bẹbẹ fun anu. Ọmọ yi ko ronu wipe baba oun yio gba oun pada gẹgẹ bi ọmọ rẹ nitoripe oun kuku ti gbe gbogbo ogun oun lọ ninu idile na, se eniyan ha le e gba ogun lẹmeji bi? Ko daju wipe o sese. Nitorina ọmọ na ko ronu ìmúbọ̀sípò gẹgẹ bi ọmọ, bẹ́ẹ̀ sini wipe ko ni lọkan wipe baba oun yio gbe oun gẹgẹ bi ọmọ pada, sugbọn ohun to ni lọkan ni wipe o nfẹ ma se isẹ agbase nibẹ, o npada lọ nisisinyi lati lọ farabalẹ. Lati lọ kẹkọ sí i lọdọ baba rẹ, o fẹ lọ fi agbara rẹ se isẹ owó nisisiyi, nitori oun na ti ri wipe, ohun ti enia ko sisẹ fun ki i tọjọ lọwọ ẹni, o fẹ pada lọ sisẹ lati ni àtùjọ lọdọ baba rẹ, o fẹ pada lọ lati lọ mọ asiri aseyori ati aseyege lọdọ baba rẹ, ohun to wa lọkan ọmọ na niyi, nitori o mọ wipe lati mọ bi enia tise nse aseyọri ati aseyege lẹnu isẹ, eniyan nilo ibiti yio fi í lọkan balẹ, ọmọ ẹ̀kọ́sẹ́ nilo ẹniti yio kó o mọra, ọmọ ẹkọsẹ nilo ọga ti yio fi ifẹ han si i, ti yio fi ifẹ salaye awọn nkan fun un. Ọmọ aburo yi si mọ wipe gbogbo ibiti oun nde lẹhin igbati gbogbo nkan ti tan lọwọ oun, wọn ko fi ifẹ han si oun, wọn kò kó oun mọra, eredi niyi ti oun ko se ri ounjẹ jẹ, eredi niyi ti nkan ko se ye oun, nitorina, ohun ti yio dara ni bi oun ba pada lọ si ibiti ifẹ wa lati lọ kọ ẹ̀kọ́ sí i. Melomelo awọn ọmọ ẹkọsẹ lode oni ni ko mọ isẹ nitori wipe awọn ọga wọn ko kó wọn mọra? Melomelo awọn ọmọ ile iwe ni ko mọ iwe wọn nitoripe awọn olukọ wọn ko fi ifẹ han si wọn? Aimọye awọn omọ lo di idakuda loni, ki ise nitori wipe awọn obi wọn ti ku kọ bikosepe nitoripe awọn ọmọ na ko ri ifẹ to peye lati ọdọ awọn obi wọn, nitorina awọn ọmọ na nse ohun àìtọ́, awọn ọmọ na nrin ìrìn àìtọ́, awọn ọmọ na darapọ mọ awọn ti wọn ko yẹ ki nwọn o darapọ mọ nile iwe, nibi isẹ, ladugbo, ninu ijọ ati nibi gbogbo. Aisi ifẹ to peye larin olusọagutan ti ise olori ijọ ati awọn ọmọ ijọ pẹlu ko jẹ ki ihinrere o fẹsẹ mulẹ ninu ijọ àní ati ninu aiye mọ. Aisi ifẹ to peye ninu ijọ mọ eleyi lo mu ki awọn eniyan o ma ni igbala to peye mọ, ayafi ẹniti Ọlọrun bá ràn lọwọ. Àìsí ifẹ to peye ninu ijọ mọ eleyi lo nmu ki awọn ọmọ ijọ miran mã kuro ni ibiti wọn wa lọ si ibomiran. Njẹ iwọ afurungbin na ha nfi ifẹ han si awọn ti o n furungbin na fun? Njẹ a ha nfi ifẹ sọrọ Kristi na fun awọn enia bi? Njẹ a ha nfi ifẹ se isẹ wa gbogbo ti a nse bi? Nitori àìsí ifẹ to peye, nibito wa to ti nse atipo ọmọ aburo to ti gba gbogbo ogun-un tirẹ tan lọwọ baba rẹ tun pinnu lati pada lọ sibiti oun yio ti ri ifẹ to peye, o ronu ninu ara rẹ lati pada lọ sibiti yio ti ri ifẹ to múná doko gba. Ẹ jẹ ka ka ẹsẹ ogun siwaju si ninu iwe Luku ori karundinlogun na lati gbọ ohun to sẹlẹ si ọmọ na. "O si dide, o si tọ baba rẹ lọ. Sugbọn nigbati o si wa li okere, baba rẹ ri i, anu se e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrun, o si fi ẹnu kò ó li ẹnu. "Ọmọ na si wi fun u pe, baba, emi ti dẹsẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi ko yẹ li ẹniti à bá ma pe li ọmọ rẹ mọ. "Sugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ pe, ẹ mu ààyò asọ wa kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ́; ẹ si fi orika bọ̀ ọ́ lọwọ, ati bata si ẹsẹ rẹ" (Lk 15:20-22) A ri gbangba ninu akọsilẹ yi wipe ọmọ aburo yi ko duro lori ironu rẹ nikan, sugbọn o gbe igbesẹ lẹhin igbati ero na wa sí i lọkan. Nipa igbesẹ to gbe nã ni baba rẹ fi se idajọ rẹ, ki ise nipa ero to ro lọkan rẹ, nitoripe ero to ro lọkan rẹ baba rẹ ko le è mọ̀ọ́. Sugbọn nigbati ọmọ na fi ero na si ise, ti ọmọ na gbe igbesẹ, to si tọ baba rẹ lọ, baba rẹ mọ ohun to wa lọkan rẹ, baba rẹ si dá a lẹjọ nipa igbesẹ na. Otitọ ni wipe Ọlọrun mọ ero inu eniyan, se nitotọ Ọlọrun tilẹ mọ̀ ọ́ li okere rere, ani Ọlọrun tilẹ mọ ohun ti a ò ti rò gan, sugbọn sibẹ, Ọlọrun nfẹ ki a fi awọn ero wa si ise, ko ba le da wa lẹjọ lati ipasẹ ohun ti a se. "OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi. "Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére." (Psa. 139:1-2) Ọlọrun ti mọ Esau gan ki a to bí i sinu aiye (Mal 1:2-3; Rom 9:10-13), sugbọn, Ọlorun ko fi awọn ero ọkan rẹ, ifẹ ọkan rẹ, ilepa aiya rẹ dá a lẹjọ ayafi igbati o se asemọse, ayafi igbati o sọ awọn èrò wọnni di igbesẹ, igbana ni Ọlọrun to wa dá a lẹjọ (Hb 12:16-17). Ọlọrun mọ ohun to mbẹ ninu Kaini, sugbọn Ọlọrun ko fi ero to mbẹ ninu rẹ dá a lẹjọ ayafi igbati o fi ero na si ise, igbana ni idajọ to wa sori Kaini (Gen 4) Nitorina, gbogbo ero yio wu ki o ma se alai wà lọkan wa, Ọlọrun ko ni fi da wa lẹjọ, ayafi igbati a ba ri ero na si ise. Bi enia ba nronu lati di onigbagbọ, sugbọn sibẹ ti iru enia bẹ kuna lati yipada ati lati fi aye rẹ fun Jesu, tiru enia bẹ ba kuna lati kọ ẹsẹ rẹ silẹ patapata lati ma tẹle Jesu, a o ni fi ero ọkan yi gbà á si ijọba ọrun, nitoripe ko fi ero na si ise. A o ni da afurungbin na lẹjọ nitoripe o ronu lati lọ furungbin, sugbọn a o da lẹjọ nipa igbesẹ na to gbe, nipa dí dide lati lọ fun irugbin na (Mt 25:34-46) (5) Irugbin ti afurungbin na nfun kò dabi irugbin ti a ngbin sinu oko aiye ti afurungbin na yio fi koere rẹ. Awọn olukore irugbin na ni awọn angẹli Oluwa. Nitorina, yálà awọn enia gbàgbọ́ tabi awọn eniyan ko gbagbọ, afurungbin na yio gba ere isẹ to se to ba ti gbin irugbin otitọ ati didara na pẹlu pẹlẹpẹlẹ tabi jẹjẹ. "Ọta ti o fún wọn li Esu; igbẹhin aiye ni ikore; awọn angẹli si li awọn olukore" (Mt 13:39) (Mt 25:32) Ohun ti mo nsọ ni wipe, bi Ọlọrun ba ran eniyan si ibikan ti ẹni na si lọ jisẹ na nibẹ, yala awọn enia na yipada si Kristi tabi wọn ko yipada si Kristi afurungbin na yio gba ere isẹ to lọ se nitoripe o ti mu asẹ Kristi Jesu sẹ. Sugbọn niti isẹ ti ẹni na lọ se nibiti a ran si, ko si bi ẹni na se fẹ kore isẹ na, nitoripe isẹ na nise pẹlu ọkan eniyan, ibiti isẹ to lọ jẹ na yio ti sisẹ ni ọkan eniyan, ẹmi ti Ọlọrun fi sinu eniyan ni isẹ na yio sisẹ le lori, nitorina, afurungbin na ko le kore wọn, nitoripe ohun airi ni isẹ na nsisẹ le lori, ohun ti enia ko si ri bawo lo se fẹ mọ igbato hù jade? Bawo lo se fẹ mọ igbato dàgbà? Bawo lo se fẹ mọ bose ndagba si? Tabi bawo lo se fẹ mọ igbato nso eso? Igbati irugbin ba nso eso na ni agbẹ ma nkore oko, sugbọn irugbin airi bawo leniyan se fẹ mọ wipe o ti hù jade tabi wipe o ti nso eso? A le ma sọ wipe, sebi igbati a bá ri ayipada ninu irin, iwa ati ise eniyan, o yẹ ki afurungbin na le sọ wipe eleyi, irugbin ti a gbin sinu ẹniyi tabi awọn ẹniyi ti nse daradara. Lapakan otitọ ni eleyi, sugbọn lọna miran kì í tun nse otitọ nitoripe awọn miran ma nlo ẹtan ati agabagebe, eredi niyi ti bibeli se wipe, "Okan enia kun fun ẹtan ju ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! Tani o le mọ ọ?" (Jer 17:9) Niti ode ara, a le è ri ayipada ninu iwa ati ise eniyan nitotọ sugbọn ko jẹ wipe ayipada na ko de inu, ko jẹ wipe ẹtan ni ẹni na fi se ohun ti a npe ni ayipada ti a nri na. Nitoripe, a o de inu rẹ, awa yio ma wipe lotitọ ati lododo loti yipada, sugbọn Ọlọrun to ri inu lo mọ wipe ẹtan ati agabagebe lo fi se é. Apẹrẹ pataki ni ti Judasi Iskariotu ẹnito fi Jesu han, bi Jesu se bẹrẹ isẹ ihinrere rẹ si gbogbo aiye na ni Judasi Iskariotu ti darapọ mọ isẹ nã, sugbọn o han lẹhin-o-rẹhin wipe ọkan Judasi Iskariotu ko se dede pẹlu Kristi Jesu, bi o tilẹ jẹ wipe o mba wọn wọle-wọde lasiko na. Ni gbogbo asiko yi, ti a ba ni ka fi isedede ti ara, iwo oju se idajọ awọn ọmọ ẹhin Jesu, o daju wipe Judasi Iskariotu pẹlu yio pegede...Sugbọn nigbati a ò se idajọ na lẹsẹkẹsẹ, nigbati a ò se ikore na lẹsẹkẹsẹ, nigbato ya, iru ohun to mbẹ lokan aiya Judasi Iskariotu farahan, eleyi to si se idajọ rẹ. Nitorina, a ò le dajọ enia nipa ohun ti a nri, afurungbin na ko le kore irugbin na nipa ohun to nfarahan nitoripe yio se asise, nitoripe ko ri ọkàn eniyan, ko mọ ọkan eniyan, sugbọn Ọlọrun to ri ọkan eniyan, to si mọ ẹniti iwa ati ise rẹ, ayipada tode ara to se fojuri ba awọn ero ọkan rẹ mu ni yio se ikore na nigbati asiko ba to. Ohun to kan afurungbin na ni o ni lati gbajumọ, ohun to kàn-an na ni fi fun irugbin na ni ibiti a ba ran an si. (6) Afurungbin yi yio sirò isẹ iriju rẹ. "Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ fun Ọlọrun" (Rm 14:12) Nitoripe afurungbin yi kọ́ ló ni isẹ, nitoripe a rán afurungbin yi ni, afurungbin na yio se isiro fun ẹnito ran nisẹ. Bẹ́ẹ̀ pẹlu ni gbogbo wa, ki ise àwa ni a ni ara wa gẹgẹ bi ọpọlọpọ wa ti se ma nro wipe sebi emi ni mo ni ara mi, bóbá se wumi ni ngo se ara mi. Rara o. Awa kọ ni a ni ara wa, ẹnikan lo fi ẹmi to mbẹ ninu erupẹ to njẹ ara na sinu wa, ẹni na to ni ẹmi na yio bere lọwọ awa tikarawa nigbose, lẹhin aiye yi, bi a se fi ara wa ba ẹmi na jẹ toba jẹ wipe a fi ara wa ba ẹmi na jẹ, tabi bi a se fi ara wa tún ẹmi na se to ba jẹ wipe a fi ara wa tu ẹmi ti Oluwa fi sinu wa se. A nilati ma ranti eleyi ni gbogbo igba. A nilati ma ranti wipe láì si ẹmi ninu eniyan, ara eniyan ko le è se nkankan, a ni lati ma ranti wipe nigbati ẹmi ba ti jade ninu enia, ohun ti a npe ni eniyan ko si mọ, ara ẹrupẹ yi yio pada si ilẹ, ara erupẹ yi ko le se nkankan mọ. Nigbati o wa jẹ wipe ara erupẹ ti eniyan ngbe kiri yi, lati irun ori wa, si ọpọlọ wa, si ọkàn-an wa, si inu wa titi de ẹsẹ wa, kì bá le da nkankan se laise wipe ẹmi ti Ọlọrun fi fun wa mbẹ nibẹ, njẹ o ha yẹ ki a si ma wipe awa ni a ni ara na bi? Ngo ro wipe o yẹ ki awa enia ma sọ bẹ́ ẹ̀ mọ, nitoripe sisọ eleyi nfi wa han wipe a npe ohun ti ki ise tiwa ni tiwa, a npa irọ mọ ara wa. Iru ohun ti ọkunrin kan ti ilẹ rẹ so eso ọpọlọpọ ni ọdun kan nro ti o si nfẹ se nipa ara rẹ ni eleyi gẹgẹ bi itan ti Jesu sọ. Ọkunrin yi ro wipe oun loun ni ara oun ati ọkan oun ati wipe bo ba se wu oun loun le è se ara oun, oun nilati se ohun gbogbo ti yio fun ọkan oun ni isinmi gẹgẹ bi eniyan, nitoritpe o ro wipe oun loun ni ọkan oun, nitoripe o ro wipe oun loun ni ara oun, sugbọn lopin gbogbo ero rẹ, lopin gbogbo ipinnu rẹ, lopin gbogbo ọgbọn ati agbara rẹ, Ọlorun fihan wipe tirẹ kọ ni gbogbo awọn ohun to npe ni tirẹ nã, nitoripe Ọlọrun bere ohun to ngbe ara na ro, eleyi ti ise ẹmi rẹ lọwọ rẹ, nigbati a si gba ẹmi rẹ kuro lọwọ rẹ, ọkan ti ọkunrin ọlọrọ yi nfẹ ko ni isinmi ko kuku le è ni isinmi mọ nitoripe ọkan na ko mọ Ọlọrun, nitoripe ọkan na ko ni Kristi Jesu ninu rẹ. Ara to wa ro wipe ko ni se wahala mọ na wa padà si erupẹ (Gen 3) ti o si di ounjẹ fun awọn idin ati ikán ninu ilẹ (Lk 12:13-21) Bi awa na nro wipe awa ni a ni ara wa ati wipe bó bá se wu wa ni a le è se é, a ntan ara wa jẹ ni o, Esu, ọta ẹmi wa lo nmu ero ibi na wa si ọkan wa, ki o ba àa le jogun ọkan wa, ki a bà á le ba ara wa lọrun apadi ninu iya aiyeraiye.... Nitoripe ọpọ wa ma nro wipe awa ni a ni ara wa, ati wipe ti a ba fun ara wa nisinmi, ti a ba fi ohun gbogbo ti ara wa nfe fun un, ọkan wa yio ni isinmi, ọkan wa yio balẹ, nipasẹ eleyi a o ni se aisan kankan tabi ki nkuku wipe a ò ni dede ma se aisan, nitorina a ma nro wipe o yẹ ki a tẹ ara wa lọrun, ki a lo ara wa bi o se tọ ati bi o se yẹ loju wa. Ero yi dara loju enia pupọ, sugbọn se nitotọ, ero yi ni a nlo lati fi han pe ero to wa ninu wa tabi lori wa na ni ọkan wa. Eleyi ni wipe sise eleyi ma nmu ki a ro wipe ironu eniyan lo njẹ ọkan enia. Ironu nikan kọ lo njẹ ọkan eniyan. Awọn ohun airi miran tun wa to mu ki ọkan eniyan má a jẹ ọkan eniyan. Ere idi niyi nigbamiran to jẹ wipe eniyan le ma ronu ohun rere, eniyan le è fun ara rẹ nisinmi, eniyan le è ma se wahala kankan sugbọn sibẹ ki ọkan rẹ ma balẹ, sugbọn sibẹ ti awọn aisan ọkan yio si ma farahan ninu aiye ẹni na, ani sibẹ ti ẹni na yio si ma rù. Awọn eleyi nwaiye nitoripe ki ise ironu nikan lo gbe ọkan eniyan ro, eleyi nwaiye nitoripe awọn ohun miran wa to so mọ́ ọkan eniyan sugbọn ti a ò le è fi oju ri. Ere idi niyi ti eniyan se nilati gba Jesu Kristi gbọ, nitoripe Ọlọrun nikan lo ri awọn ohun airi wọnni, Ọlọrun nikan lo si le ba wa bojuto. Nitorina rironu wipe awa lani aiye wa, awa lani ara wa, o yẹ ki a tẹ ara wa lọrun, o yẹ ki a jaiye ori wa daradara, o yẹ ki a se bi aiye se nse, olori ẹtan Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ ni lati jogun wa sinu iná aiyeraiye. Ti ọrọ Ọlọrun ba wipe ma se wọ asọ ọkunrin iwọ obinrin, tabi iwọ ọkunrin mase wọ asọ obinrin, a nilati mọ wipe ohun ti ẹnito ni ẹmi to mbẹ ninu wa nfẹ ni eleyi ki a si ma se. Ti ọrọ Ọlọrun ba wipe mase lo ẹgbà ọwọ ati tọrùn, ko yẹ ki a gba ki ero ara o bori ọrọ Ọlọrun yi ninu aiye wa, nse lo yẹ ki a gba ọrọ Ọlọrun na gbọ patapata. A ò nilo lati ma sọ wipe isẹ mi lo njẹ ki nse eleyi, isẹ mi lo njẹ ki nmura bayi, nitoripe a ni ẹmi ninu wa ni a se le ma se isẹ ara ti a nse, bi ko ba si ẹmi ninu wa mọ, ara ti a ngbe kiri ko ni le se isẹ ti a nse mọ. Njẹ nigbati ara ti a ngbe kiri ko ba le se ohunkohun mọ, ti a si ti fi ara na tako gbogbo ọrọ Ọlorun ti a ti gbọ, se awa na lérò pe a o jogun ijọba Ọlọrun bayẹn? Njẹ awa tikarawa ki yio ha da ara wa lẹjọ lopin aiye yi? Nitoripe ara wa ni a se le sisẹ, bẹ si ni nitoripe ẹmi wa ninu ara yi ni ara na se le e se isẹ ti a nse, nitorina, ohun to yẹ ni sise ni gbogbo igba ni lati ma tẹ Ẹmi Ọlọrun to mbẹ ninu wa lọrun, ki a ma si tẹ ara wa lọrun, ki a ma mu ifẹ ti Ọlọrun sẹ, ki a ma se mu ifẹ ti ara sẹ. "Njẹ nitorina, ará, ajigbese ni awa, ki ise ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi ma wa nipa ti ara" (Rm 8:12) Bi awa ba ngbe igbesi aiye wa lati tẹ ara lọrun, gẹgẹ bi ohun ti aposteli Paulu kọ soke yi, nse ni a nse eleyi lati fihan wipe ara wa se pataki ju ẹmi wa lọ. Bi a ba si gbe igbesi aiye wipe ara wa se pataki ju ẹmi wa lọ gẹgẹ bi ọkunrin ọlọrọ yẹn se se, aposteli Paulu wipe kíkú ni awa yio ku, a o ku nipa ti ara, bẹna ni a o si tun ku nipa ti ẹmi. (Lk 12:13-21; 16:19-31) "Nitori bi ẹnyin ba wa ni ti ara, ẹnyin o ku; sugbọn nipa ti Ẹmi bi ẹnyin ba npa isẹ ara run, ẹnyin o ye" (Rm 8:13) Bi a ba wà ni ti ara, eleyi ni wipe bi a ba ngbe igbesi aiye wa lati tẹ ara lọrun, kiku ni awa yio ku, sugbọn bi a ba ngbe igbesi aiye wa lati pa isẹ ara run, yiye ni awa yio ye. Iye ti a nsọ nihinyi ni wipe awa yio de ijọba Ọlọrun, awa yio sinmi lokan aiya Ọlọrun, eleyi ko tumọ si wipe a ò ni bọ ara erupẹ yi silẹ, nitoripe ti Jesu Kristi ko ba tete farahan lati gba awa ayanfẹ soke, gbogbo awa ti a wa lorilẹ aiye yio ku iku ti ara lọjọkan, a o bọ ara erupẹ yi silẹ ti ẹmi wa yio si pada tọ Ọlorun lọ (Onws 12:7), sugbọn lẹhin igbati a bá ti bọ ara erupẹ yi silẹ, ni aiyeraiye lọhun, nigbati Kristi Jesu ba de lati gba awọn ayanfẹ, awa na yio gba ara miran nipasẹ eleyi ti a o fi ba Ọlọrun jọba laelae, sugbọn leyi ko ni sese fun awọn ti wọn ko gba Jesu gbọ, ani awọn ti nwọn ngbe igbe aiye wọn lati tẹ ara lọrun. Ohun ti aposteli Paulu nwi ninu iwe Romu yi wipe ki a ma pa isẹ ti ara run na lo tun tan imọlẹ si ninu iwe Galatia ori karun, o wipe, "Njẹ mo ni, e ma rin nipa ti Ẹmi, ẹnyin ki yio si mu ifẹkufẹ ti ara sẹ" (Gal 5:16) Rinrin nipa ti ẹmi nise pẹlu kikan ifẹkufẹ ara gbogbo mọ igi, eleyi ni wipe a o ma mọ̀ọ́mọ̀ fi awọn ohun ti bibeli sọ wipe Ọlọrun ko fẹ sugbọn ti ara nfẹ ki a ma se silẹ, ti a o si ma tẹle awọn ohun ti Bibeli sọ wipe Ọlorun nfẹ ki a ma se. Bi ọrọ Ọlọrun ba wipe ma se kun ojú, ma se kun ètè, ma se kun ọwọ́, ma se mura bi ọmọ aiye, ma se irun bi awọn alaigbagbọ, otitọ ni wipe awọn nkan wọnyi nigbamiran le è nira fun wa lati se, sugbọn niwọn igbati a ba fẹ rin nipa ti Ẹmi, a o yàn lati se eleyi ti Olorun so na ni ki a ba le mu ifẹ Baba wa to mbẹ li ọrun sẹ, ẹnito jẹ wipe Oun lo ni ẹmi wa na, ti o si le bere rẹ lọwọ wa nigbakugba. Awa onigbagbọ na lo ma nsoro fun lati fi ẹ̀gbà ọrun silẹ, oruka imu silẹ, oruka eti silẹ, sugbọn ti ẹ ba wo awọn musulumi, a o ri wipe nse ni wọn yio fi asọ bo eti wọn ani ati gbogbo ara wọn. Njẹ ẹnito fi asọ bo gbogbo ori rẹ titi de gbogbo ọrun rẹ ha le fi ẹgbà si ọrun bi? Ti o ba se eleyi a jẹ wipe o fi owo sofun ni, a jẹ wipe alaini ọpọlọ ni, nitoripe ko si ẹniti yio ri awọn ohun na to fi seti tabi si ọrùn.... Awọn miran le è se eleyi to ba jẹ wipe nkan agbara wọn ni, to ba jẹ wipe nkan ti wọn fi ndabobo ara wọn ni, ani toba jẹ wipe agbara ti Esu baba wọn fun wọn lati ma lo ni. Sugbọn ti ki iba se wipe agbara ti Esu fun wọn lati ma lo ni, to ba jẹ wipe nitori oge tabi nitoripe wọn fẹ mu ifẹkufẹ aiye sẹ ni wọn se nlò ó, ajẹ wipe alaini ironu ni won nitoripe ko si ẹniti yio ri ohun na. Njẹ bi awọn alaigbagbọ ko ba nani awọn ohun aiye wọnyi, awọn to si jẹ wipe iru isẹ kanna ni a jijọ nse, ki ise wipe wọn da isẹ ti wọn kalẹ lọtọ, iru ọja kanna ni a jijọ n ná.., è é ha ti se ti awa pẹlu ko kuku gbiyanju loni lati kuku ma tẹ Ọlọrun lọrun, ki a si ma rin gẹgẹ bi o ti se fẹ, ki a ma mu ifẹ ti ara sẹ mọ. Gbogbo wa ni a o siro isẹ iriju wa. Gẹgẹ bi afurungbin na yio ti se siro isẹ iriju rẹ bẹ pẹlu na ni gbogbo awa ti a ngba irugbin na yio tise siro isẹ iriju wa. (Mt 12:36; 18:23; Lk 16:2; Hb 13:17; I Pt 4:15) (7) Afurungbin na yio ni ere laiye yi bẹni yio si tun ni ere laiye to mbọ na pẹlu. "Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakọnrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọrọrun gbà, nwọn o si jogun iye ainipẹkun" (Mt 19:29) Nitoripe afurungbin ọrọ na kọ́ ni yio se ikore awọn ohun to furungbin na ko tumọ si wipe ko ni gba ere lori awọn ohun to ti se nã. Afurungbin na yio gba ere awọn nkan to ti se laiye yi ati laiye to mbọ na pẹlu. Gẹgẹbi a ti nsọ tẹlẹ, yala awọn ti afurungbin na yio ba sọrọ gbagbọ tabi wọn ko gbagbọ, afurungbin na yio gba ere awọn ohun to ti se. Awa eniyan nigbamiran a ma nse asise niti wipe nigbati a ba nro wipe isẹ ẹ wa ko ni ere, nigbati a ba nro wipe awọn eniyan ko yipada lati gba ihinrere wa gbọ daradara, tabi boya wọn ko tilẹ gba ihinrere wa gbọ rara, nse ni a o ma ro wipe a ko ni ere lori awọn ohun ti a ti se, sugbọn eleyi ko ribẹ bi Ọlọrun se npín ere fun awọn isẹ ti a se nipa ti ẹmi ko nise pẹlu awọn ti a ba sọrọ nigbamiran, bi Ọlọrun se ma nsan ẹsan tabi pin ere na Oun nikan lo mọ̀ ọ́. Bi afurungbin ba bá gbogbo ilu sọrọ tabi boya o ba ijọ ti a ran si sọrọ na ti gbogbo awọn to ba sọrọ na ko si yipada, a ri wipe sibẹ Ọlọrun ma npin ere rẹ fun awọn afurungbin na lọna arà ati lọna iyanu. Nigbati woli Elija lọ sọ fun Ahabu wipe ojo ki yio rọ fun ọdun mẹta ati osu mẹfa, lẹhin igbati woli na jisẹ na fun ọba Ababu ati awon oloye tan, sibẹ awọn eniyan na ko yipada si ti Ọlọrun, eleyi to fà á ti ohun ti Ọlọrun sọ lati ipasẹ woli Elija fi wa si imusẹ. Sugbọn lasiko ti wahala ati idamu wa nilu na, Olorun ran ẹiyẹ lati lọ ma gbe ounjẹ fun woli na larọ ati lalẹ (I A. Ọba 17). Ọrọ yi nsọ fun wa wipe, bi afurungbin na ba ti sa ipa tirẹ, ti afurungbin na ba ti se ojuse tirẹ, Ọlorun mọ ọna ti yio gba lati fun un ni ere ohun to se yala awọn eniyan na yipada tabi wọn ko yipada. O le e jẹ wipe ohun ti afurungbin na kò mọ, tabi ẹniti afurungbin na ko mọ, ni a o lo fun lati fun ni ere isẹ na to se. Ohun to daju ẹwẹ si wa ni wipe lẹhin igbati afurungbin na ba ti gba ere ti aiye tan, yio tun gba ere ni aiye to mbọ na pẹlu lọdọ Baba rẹ to mbẹ ni ọrun to ba fi tọkantọkan ati otitọ inu se ohun na ti a gbe lé e lọwọ lati se. (Opin) ORI KARUN IRÚGBÌN NÃ Jesu nsọ nipa "irugbin, irugbin, irugbin", ibere akọkọ ti yio wa sọkan awa oluka owe Jesu yi ni wipe, kinni irugbin yi? (1) KÍNNI IRÚGBIN NA? Ninu iwe ihinrere Luku 8:11 ni a ti ri idahun to peye fun ohun ti irugbin na jẹ. "Njẹ owe na li eyi: irugbin li ọrọ Ọlorun" (Lk 8:11) Iwe ihinrere Matteu ori kẹtala wipe, "Nitorina, ẹ gbọ owe afurungbin. "Nigbati ẹnikan ba gbọ ỌRỌ IJỌBA, ti ko ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wa, a si mu eyi ti a fun si aiya rẹ kuro. Eyi li ẹniti o gba irugbin lẹba ọna" (Mt 13:18-19) Irugbin ti a nsọ nipa rẹ ni Luku wipe Jesu pè ni "Ọrọ Ọlọrun", nigbati Matteu ninu iwe tirẹ pè e ni "ọrọ ijọba". Irugbin ti afurungbin ọrọ na jade lọ lati furungbin rẹ na ni ọrọ to nsọ nipa ijọba Ọlọrun. (2) IRÚ AWỌN ỌRỌ WO? Awọn ọrọ to sọ nipa ti ijọba Ọlọrun ko duro lori ọrọ ironupiwada tabi igbala nikan, sugbọn ninu awọn ọrọ wọnyi ni a ti tun ri iwosan, imularada, ibukun, itunu, iwa-mimọ, Ẹmi Mimọ, itusilẹ, ibawi, ihuwasi, iribọmi ti ara ati ti Ẹmi, Adura abbl. A nile gbogbo awọn ọrọ wọnyi fun ise-rere wa, fun idagbasoke igbagbọ ati ihinrere, nitori láì si awọn ọrọ wọnyi o hàn wipe a kò ni pe ninu igbagbọ. Laiye ọjọun ana, ọrọ igbala nikan ni a ma ntẹnumọ julọ, sugbọn o ti wa han gbangba wipe, bi eniyan ba ni igbala nikan ti ko ni ibukun, tiru eniyan bẹ kò ba mura yio sọ igbala na danu.... Bi ẹnikan ba si wipe oun ti di atunbi ti Ọlọrun si tun bukun fun iru eniyan bẹ, ti ko ba ni iwa mimọ, laipẹ laijinna yio lo ibukun na bi ko se dara, nipasẹ eleyi ti awọn eniyan yio tun wa fi ma sọrọ odi si Ọlọrun to ro wipe oun ti gbagbọ, eleyi ti yio mu ki igbagbọ na su ẹni na.... Ohun miran ti mo si tun wa ri ninu ihinrere ni wipe ọpọ eniyan, ọpọ onigbagbọ ni ko ni ọrọ itunu lẹnu, bẹ sini awọn isẹlẹ to nsẹlẹ laiye loni fihan wipe a nilo ọrọ itunu ninu ijọ loni. Ninu ijọ loni bi ọmọde se nku bẹna ni awọn agbalagba nku, bi ọdọ se nku bẹni alaboyun nku, awọn miran gan won a ku pẹlu oyun inu wọn...bi a se nle ọmọ onigbagbọ kuro nile iwe bẹna ni a nle awọn onigbagbọ kuro ninu isẹ ti wọn nse, awọn miran yio ya owo lati sowo sugbọn ti wọn yio jẹ gbese lati bẹ, ti yio di wahala sọrun eniyan gbogbo.... Gbogbo awọn isẹlẹ ajalu ati arelu wọnyi na lo ndeba onigbagbọ lode oni, nipasẹ eleyi ti ẹsẹ̀ awọn onigbagbọ miran fi nmìn, nipasẹ eleyi ti awọn miran fi ma npadà ninu igbagbọ, nipasẹ ẹtan ati arekereke ti Satani (Mt 24:24b) fi tan wọn jẹ. Nitorina, ni pataki ati lododo, a nilo awọn onigbagbọ ti wọn ti ni iriri (Rm 5:4), a nilo awọn onigbagbọ ti wọn ti la nkan kọja lati le ma fi iriri wọn ba awọn eniyan sọrọ lati tù wọn ninu, ki iru awọn eniyan ti wọn ba bọ sinu irufẹ awọn oniruru isoro ati idamu bẹ́ẹ̀ le ni itunu, ifọkanbalẹ ati itura ninu Ọlọrun, ki nwọn o ba le mọ wipe ohun to sẹlẹ si wọn ki ise nitoripe Ọlọrun kọ̀ wọn silẹ tabi nitori aigbadura tabi nitori awọn nkan miran, sugbọn nitoripe "awa si mọ pe ohun gbogbo li o nsisẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pe gẹgẹbi ipinnu rẹ" (Rm 8:28) Nigbati awọn afurungbin ọrọ na tó ti la iru awọn isoro ati lasigbo wọnni kọja ba fi iriri tiwọn, suru wọn, itunu ti wọn ri gba lati ọdọ Ọlọrun kọ́ awọn eniyan wọnni, ẹsẹ ijọ yio tun mulẹ si i, igbagbọ awọn eniyan yio tun dagba sí i, awọn ti nwọn ti njẹ wàrà ati awọn ounjẹ ti kò le ninu igbagbọ tẹlẹ yio tun ri ile aiye gẹgẹbi Ọlorun ti se ri ile aiye, bẹni wọn yio si tun mọ Ọlorun Alaye sí i. "Olubukun li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọnu, ati Ọlọrun itunu gbogbo; "Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahala wa, nipa itunu na ti a fi ntu awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlorun wa, ki awa ki o le ma tu awọn ti o wa ninu wahala-ki-wahala ninu" (II Kor 1:3-4) Ẹ jẹ ki a ka ọrọ bibeli yi ninu ẹda bibeli miran ti a npe ni "Message Bible". "Gbogbo ogo fun Ọlọrun ati Baba Olori wa (tabi Ọga wa), Messiah na, JESU! Baba gbogbo anu! Olorun gbogbo igbimọ tabi igbaniyanju to nmu iwosan wa! "Ẹnito wá si ẹ̀gbẹ́ (tabi ọdọ) wa nigbati a nla asiko to le kọja, ki a si to sẹju pẹrẹ (tabi ki a to mọ nkan to nsẹlẹ) o mu wa lọ si ẹ̀gbẹ́ ẹlomiran to nla asiko to le kọja, ki a ba le duro ti ẹni na (tabi wà fun ẹni nã) gẹgẹbi Ọlọrun pẹlu ti duro tiwá (tabi wa fun wa)” (II Kor 1:3-4 (Message Bible)) Ọpọ onigbagbọ loni lo nro wipe ti a ba sá à ti gbagbọ ati gbagbọ na ni, nitorina bi o ba se wu wa ni a le má a huwà ninu ijọ, ninu ile, lawujọ tabi ani ati nibi gbogbo. Sugbọn eleyi ko ri bẹ, eredi niyi ti aposteli Paulu se sọ fun Timoteu ọmọ rẹ wipe, "Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ... "...Ki iwọ ki o le mọ bi o ti yẹ fun awọn enia lati ma huwa ninu ile Ọlọrun, ti ise ijọ Ọlọrun Alaye, ọwọn ati ipilẹ otitọ" (I Tim 3:14-15) Lara awọn irugbin ti afurungbin otitọ na nilati má a fun ni sisọ fun awọn eniyan bi o ti se yẹ lati ma huwa ninu ijọ Ọlọrun. Ọpọ wa ni a ò mọ bi ati se nhuwa ninu ile Ọlọrun, awọn miran nse ni wọn yio má a jẹ "chewing gum" nile Ọlorun, awon miran ti wọn kò tọ́ ọmọ, wọn ko loyun sinu, wọn ko se aisan, bi wọn se njẹun lasiko ti isin ati ọrọ Ọlọrun nlọ, bẹna ni wọn yio ma mu omi, wọn yio ma fi eleyi mu ki ọkan awọn miran sí kuro ninu ọrọ Ọlọrun to njade lọjọ na.... Afurungbin ọrọ na nilati jẹ ki awọn eniyan mọ bi ati se njoko ninu ile Ọlọrun. Awọn miran bi wọn ba ti de inu ile Ọlọrun nse ni wọn yio ko ẹsẹ sori aga, afurungbin na nilati jẹ ki nwọn o mọ wipe a kì í joko bẹ́ẹ̀ ninu ile Ọlọrun.... Ki ise pipa fonu tabi ẹro alagbeka wa nikan lo jẹ iwa àìbojumu ti awọn eniyan, ani awa onigbagbọ nilati mojuto nile Ọlọrun sugbọn a nilati mojuto awọn wọnyi na pẹlu. Bi awọn eniyan, ani awa onigbagbọ se nilati mọ̀ bi o ti se yẹ fun wa lati má a hùwà ninu ijọ Ọlọrun alaye, bẹ pẹlu ni a se nilati mọ bi o se yẹ ki a ma huwa ninu ile, larin ọpọ ero tabi awujọ abbl. Awọn miran wọn ko mọ bi a ti se nhuwa larin ero, awọn onigbagbọ miran ìwàa wọn ko dara ninu ile, afurungbin na nilati jẹ ki awọn eniyan mọ bi o ti se yẹ lati má a huwa nibi gbogbo. Jijẹ onigbagbọ tabi ọmọlẹhin Kristi Jesu kò sọ wipe ki a ma huwa àìyẹ ninu ile tabi lahujọ tabi nibi isẹ. Se nitotọ awa onigbagbọ gan lo yẹ ki iwa ati ise wa nibi gbogbo o jẹ ohun amuyangan, awa gan lo yẹ ki iwa ati ise wa o jẹ awokọse nibi gbogbo. Nitorina, afurungbin na nilati jẹ ki awọn eniyan to jẹ onigbagbọ o mọ iru iwa ati ise eleyi ti Oluwa Ọlọrun Eledumare nifẹ si. (Mt 10:16; Ps 105:4; 107:20;119:62; Lk 9:1ff; 18:1ff; I Tess 5:17; 3:10; 4:18; II Tim 3:16; I Pet 4:7; Y Jn 2) (3) Irugbin na ti afurungbin na nfun ni a npe ni ihinrere. "O si wi fun wọn pe, ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda" (Mk 16:15) Ọrọ Ọlọrun yi na ni a tun le è pe ni ihinrere. Aposteli Paulu wi niti ihinrere wipe, "Nitori emi ko tiju ihinrere Kristi: nitori agbara ỌLỌRUN ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ; fun Ju saju, ati fun Helene pẹlu" (Rm 1:16) (4) Ohun ti gbogbo irugbin na ti afurungbin na nfun duro le lori ni JESU KRISTI OLUWA, nitori Jesu Kristi Oluwa ni Ọrọ Ọlorun, oun ni ipilẹsẹ ati opin, Oun ni Alfa ati Omega... (Ifi 19:13) "A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun." (O. Daf. 19:13) Gbogbo ọrọ ti afurungbin na ba fún ti ko gba ore-ọfẹ ati òntẹ̀ Jesu Kristi, ọrọ ti ara ni, ko si si lara irugbin na. Irufẹ awọn ọrọ ti ara wọnyi ni o ma nso eso nipa ti ara, eleyi to ma nyọri si ibanujẹ ati ẹkun nigbose. Awa na gẹgẹ bi ọkan lara awọn afurungbin yala ninu ile, ninu ijọ nibi isẹ, ladugbo iru irugbin wo ha ni a nfun? Se irugbin ọrọ Jesu ni tabi irugbin sipa ti ara wa nikan? (5) Ki ise gbogbo irugbin na ti agbẹ na nfun lo bọ si ibikan "diẹ", "diẹ" lo mbọ sori ilẹ kọkan. Gẹge bi a ti sọ nisaju wipe nilẹ Palẹstini orisi ilẹ mẹrẹrin lo nwa lori ilẹ kọkan, eleyi mu ki irugbìn na bọ si ori orisi ilẹ mẹrẹrin na. Yatọ si wipe orisi ilẹ mẹrin lo wa ni ilẹ Palẹsitini, eleyi to mu ki awọn irugbin na bọ si orisi ilẹ mẹrẹrin wọnyi ohun miran tun ni wipe Ọlorun mọmọ jẹ ki awọn irugbin wọnni o bọ si orisi awọn ilẹ wọnyi ki awọn ohun to hu ni ilẹ kọkan bà á le jẹ apẹrẹ fun ilẹ keji tabi ilẹ omiran. Nipasẹ irugbin to bọ si ilẹ kinni a le fi mọ bi irugbin to bọ si ilẹ keji tabi ẹkẹta tabi ẹkẹrin ti se dara si. Ohun miran tun ni wipe ti irugbin wọnyi ba bọ si orisi ilẹ kanna, eleyi yio mu ki afurungbin na wà ninu ewu, nitoripe aisan tabi idamu to ba de sori ilẹ kanna ti gbogbo rẹ bọ si yio de ba gbogbo awọn eso na... tobẹ ti gbogbo awọn irugbin na le segbe tabi ko ma dara. Sugbọn to ba jẹ wipe wọn segbe ni, a jẹ wipe afurungbin na ti padanu, ti a ba fi oju ti eniyan wò o.
ORI KẸFA ILẸ̀ KÍNNÍ Onkowe kan wipe "ki" awọn ọrọ tabi iwasu Jesu bà a le yé wa, eniyan yio ti ti ara rẹ bọ ati ma tẹle Jesu, nitori laiba jẹ pe a ti jọwọ ara wa lọwọ lati má a tẹle E, koni sese fun wa lati ni oye lẹkunrẹrẹ nipa Rẹ, bẹna ni awọn ọrọ Rẹ koni ran wa lọwọ". (a) AWỌN AFIYESI DIẸ NIPA ILẸ KINNI YI (1) Irufẹ ilẹ kinni yi ma njẹ ilẹ to ma n ni alafo pupọ larin ara wọn, nitorina irugbin na ko ni le è wọlẹ daradara, (2) Ilẹ yi a ma le nitori ẹsẹ̀ to ngbabẹ lorekore, (3) Irugbin to bọ sori ilẹ yi, awọn kan ko wọlẹ daradara, (4) Nitori àì wọlẹ̀ daradara irugbin yi, awọn ẹiyẹ ati awọn ẹranko miran ri i, (5) Awọn ẹiyẹ ati awọn ẹranko miran wa sibẹ wọn si sà á jẹ, (6) Awọn miran to wọlẹ̀ lara awọn irugbin wọnyi nigbati wọn n hù jade gbongbo wọn farahan awọn eleyi ti awọn ẹiyẹ ati ẹranko tun ri ti wọn si sajẹ pẹlu, (7) Awọn irugbin ti ẹiyẹ ko sajẹ, nitori irin nigbakugba lori ilẹ na, awọn ohun alumọni inu ilẹ na ko se anfani fun irugbin to nhù jade na...otitọ ni wipe irugbin na nhù jade, sugbọn nse lo dabi igbati ko hu jade na ni. (8) Awọn miran to hu jade nitori irin rínrìn, nitori ọkọ (moto) to ngba ibẹ kọja lojojumọ, nitori ẹsin, ibakasiẹ, kẹtẹkẹtẹ abbl to ngba ibẹ kọja, nse ni wọn pada tẹ awọn irugbin na pa. (Lk 8:5) (9) Awọn ti ẹsẹ ko tẹ pa, awọn eranko to ngbabẹ: malu, ewurẹ, agutan, ẹlẹdẹ; wọn mu awọn to hu wọnni jẹ. (b) AGBEYẸWO NIPA ITUMỌ Lẹhin igbati Jesu pa owe yi fun awọn eniyan tan, ọrọ na ko ye wọn bẹ gẹgẹ ni ko ye awọn ọmọ ẹhin rẹ pẹlu, nitorina wọn bere itumọ owe na, eleyi ti Jesu si sọ fun wọn. Awa na nfẹ wo awọn nkan diẹ nipa itumọ ti Jesu fun owe ilẹ kinni yi. (1) KINI ILẸ YI? Ilẹ na jẹ eniyan kan tabi ọkan ẹnikan, ẹnikan to le gbọ ọrọ Ọlọrun. (2) Eniyan yi gbọ ọrọ Ọlọrun, tabi o ka ọrọ Ọlọrun tabi o ri ọrọ Ọlọrun (gege bi awọn aposteli) tabi o sọ nipa ọrọ Ọlorun (I. Apo 8:30ff) (3) Eniyan ti a nsọ nihinyi jẹ ẹnito ti gbọ́nju, o jẹ ẹnito ti le ronu tabi ẹnito ti le da ipinnu se (c) ISORO RẸ (1) Ko yé e (Mt 13:19). Ni ede Giriki "suniemi" ni wọn npe ni ki nkan ye enia. Eleyi nise pẹlu ki nkan o ye enia nipa ero rẹ ati ki eniyan o gba nkan na. Nkan le è ye eniyan sugbọn ki enia o ma gbà a. (II Kor 4:3-4; 3:14-16; Ef 4:17-19; Heb 5:11; Mk 3:5) (2) Dida ọrọ na nu lojukanna ti o gbọ́ ọ (Mk 4:15; I Sam 3:18) (d) KILO FA ISORO WỌNYI? (1) Yiyigbi ni aiya; nini enia lara tabi mimu inira tabi ara riro de ba enia; sise inudidun si ẹniti inira de ba (Lk 24:25) Ni ede Giriki, "porosis" ni a npe ni yiyigbi eleyi to tun tumọ si ifọju. (2) Aiya lile ni ohun keji to fa isoro yi. Ki wa lo nfa aiya lile? (i) Ọlọrun le mu aiya eniyan le gẹgẹ bi o ti se fun Farao, (ii) Esu na le mu aiya eniyan le (Heb 13:13) (iii) Eniyan na le mu aiya ara rẹ le. Awọn nkan mẹta ti mo kọ soke wọnyi lo ma nfa aiya lile ninu eniyan. ORISI AIYA LILE TO WA Aiya lile to dara (Jobu 6:10) Aiya lile ti ko dara (Jobu 9:4) Ẹ jẹ ka wo awọn iwe wọnyi (Eks 4:21; 7:14; 22; 8:15; Dt 2:30; 15:7; Jos 11:20; I Sam 6:6; II A. Ọba 17:14; II Kro 36:13; Neh 9:16-17 & 29; O.D 95:8; Heb 3:8; Owe 21:29; 28:14; 29:1; Isa 63:17; Jer 7:26; 19:15) Esekieli 3:7: Bi enia ba jẹ alafojudi, ẹni na yio ni ọkan lile... "Ṣugbọn ile Israeli kò ni gbọ́ tirẹ; nitori ti nwọn kò fẹ gbọ́ ti emi: nitori alafojudi ati ọlọkàn lile ni gbogbo ile Israeli." (Esek. 3:7) Ọpọ idile lo ndaru loni nitoripe iyawo jẹ alafojudi; ọpọ ijọ lo ndaru loni nitoripe awọn ọmọ ijọ jẹ alafojudi...awọn iransẹ Ọlọrun miran pẹlu jẹ alafojudi...se a ranti Kora, Datani ati Abiramu ninu iwe Numeri 16? Woli Esekieli ninu iwe yi wipe Olorun wipe bi Taiye ati Kehinde ni afojudi ati aiya lile jẹ, woli yi wipe ọrọ afojudi ati aiya lile tabi sisebọ aiya jẹ bi ìgbín ba fa ikarahun yio tẹle e. Danieli 5:20, woli Danieli wipe igberaga a ma mu ki inu tabi aiya enia o le nigbamiran...ti igberaga ba mu aiya eniyan le, eleyi yio fà á ti Ọlọrun yio mu eniyan kuro lori itẹ rẹ. Matteu 19:8 sọ wipe aiya lile a ma mu ki Ọlorun fi aye gba ohun ti ki ise ifẹ pipe rẹ lati sẹlẹ si eniyan ko sẹlẹ si i...(allows for permissible will of God)...bi enia ba se aiya rẹ le si ojulowo ati ogidi ifẹ Ọlọrun fun aiye enia, enia le è ku si ikorita to wa na lai wọ inu pipe ifẹ Ọlọrun lọ. (Mk 10:5) Marku 3:5. Bi a bẹ bẹrẹ iwe yi ni kika lati ẹsẹ kinni, a o ri wipe aiya lile a ma mu ki awọn enia o ma sọ́ enia lọwọ lẹsẹ lati wo ọna ti wọn yio gba mu ẹni na.... Bi enia ba mba ẹnikan gbe, ti o si nro wipe ẹniyẹn nikan lo ma mba oun sọrọ lojojumọ, to nro wipe ẹni na lo ma mba oun wi, nigbato baya ẹni na le ma sọ eni na fun asise rẹ ki o ba á le ri ẹsun si lẹsẹ tabi ko ba le sọ wipe se iwọ na ri bayi wipe o kò pé, iwọ na le se asise, o nse eleyi ki ise nitori ifẹ to ni si ẹni na, sugbọn nitori ki o le tabuku rẹ, nitori ki o le sọ wipe ko ha tan ọ bi? Sugbọn ẹnito ntọ sọna na ntọ sọna ninu ifẹ, oun mba sọrọ nitori ifẹ to fẹ ẹ, ifẹ to ni si, nitoripe ibawi ati itọsọna na mbẹ ninu ifẹ, sugbọn ẹni na nse ohun to nse nitori ilara ki ise nitori ifẹ. Ọpọ idile niru eleyi ti ma nsẹlẹ. Larin awọn alagba, larin awọn igbimọ ijọ eleyi a ma sẹlẹ, larin ẹgbọn si aburo, eleyi a ma sẹlẹ, larin afẹsọna eleyi a ma sẹlẹ nitoripe awọn enia na ma nro pe ẹnito nsọrọ ju na tabi ẹnito ntọ enia sọna ju na ti fẹ di ọga le awọn lori, nitorina, ọna lati ma gbà fun wọn lati di ọga ni wọn yio ma a wa. Aiya lile a ma mu ki enia wa isubu ẹlomiran, a ma mu ki enia fiyesi alebu ẹlomiran, a ma mu ki eniyan ma wo ohun ti ẹlomiran mọ̀ọ́ se daradara lati fi sọ pe tirẹ ti pọju, talo ran-an nisẹ? Tabi lati sọ wipe se oun nikanni? Marku 6:52: Onkọwe yi Marku tun jẹ ki o ye wa wipe aiya lile a ma mu ki eniyan o ma ronu tabi ki eniyan o ma ranti isẹ iyanu tabi ore ti ẹlomiran ti se fun eniyan.... Eleyi ni ko se jẹ iyalẹni fun wa lati ri wipe ọpọ awọn ti eniyan se ore fun nigbamiran ibi ni wọn ma fi nsan fun ẹni na. Eleyi ni ko jẹ ko ya wa lẹnu wipe awọn iyawo miran wọn a ma sọ nipa ọkọ wọn wipe kilo se fun awọn ti ẹnikan ko se ri? Aiya lile yio mu ki enia gbagba awọn iranlọwọ, awọn igbenija, awọn idabobo, igbasilẹ ti ẹlomiran ti se fun wa. (Neh 9:16-17) ...Ki a ma wa sọ wipe Ọlọrun. Marku 8:17 jẹ ko ye wa wipe, aiya lile a ma mu ki eniyan o bẹrẹ sini se aroye, a ma mu ki enia o ma sakiyesi nkan papa nkan to dara; aiya lile a ma mu ki eniyan o ma woye...nigbati enia ba nse eleyi irufẹ ẹni na ko ni le gba gbogbo ohun to ba sẹlẹ si i gẹgẹ bi wipe Olorun mọ̀ si ohun na (Rm 8:28). Nigbati ẹniyi ko ba ti ri awọn nkan to sẹlẹ si gẹgẹ bi ohun ti Olorun mọ si, gẹgẹ bi ohun ti Olorun yio lo lati sisẹ fun ire oun, nigbana ni yio ma binu, nigbana ni inu rẹ ki yio dun (Ps 37). Nigbati a o ba ni aiya lile mọ, nigbana ni a o siwọ aroye sise, nigbana ni a o ma sakiyesi nkan, nigbana ni a o le ma woye nigbati a ba nse eleyi, Satani ko ni le ri aye lori irugbin ọrọ na to mbẹ lọkan wa, nigbati a o ba ni aiya lile mọ, a o le ronu daradara lori awọn ohun ti a ti gbọ, nigbana ọrọ na yio le sisẹ ninu aiye wa. MARKU 16:14: Jesu ninu akọsilẹ yi fi ara han fun awọn ọmọ ẹhin rẹ lati le fi idi ọrọ ti nwọn ngbọ mulẹ fun wọn. Ninu sise eleyi lo ti bá àìgbagbọ ati aiya lile wọn wi.... Gẹgẹbi ati se nwo lati ibẹrẹ, a ri wipe, aigbagbọ ati aiya lile pẹlu jẹ ọrẹ-meji to fi ara mọ ara wọn mọ́tí-mọ́tí. Aiya lile yi, gẹgẹ bi ati sọ nisaju wipe ilẹ kinni to jẹ ilẹ ẹ̀bá ọna na le, eleyi lo fa ti ọrọ na ko se ye ẹni na lẹhin igbato gbọ ọrọ na tan, eleyi lo fa to se da ọrọ na nu lojukanna to gbọ ọrọ na tan, nitoripe aiya rẹ le, eleyi ko jẹ ki ọrọ na, irugbin na to gbọ rilẹ̀ si ọkan rẹ, eleyi ti ọrọ na ko se se é ni anfani kankan. "O ti fọ wọn loju, o si ti se aya wọn le; ki wọn ma ba fi oju wọn ri, ki wọn ma ba fi ọkan wọn mọ, ki wọn ma ba yipada, ki emi ma ba mu wọn larada" (Jhn 12:40) Iwe Ise Awọn Aposteli jẹ ki a mọ wipe eniyan le pẹ ninu ijọ sugbọn sibẹ ki ọkan rẹ le, eniyan le pẹ lọdọ ọkọ, oun ati ọkọ tabi oun ati aya rẹ tile jijọ ma gbe fun opọlọpọ ọdun sugbọn sibẹ ti ọkan rẹ yio si le, judasi Iskariotu ti wa lọdọ Kristi Jesu o ti to ọdun mẹta, sugbọn sibẹ gbogbo ọrọ ti Jesu nsọ ko mu ki ọkan rẹ o rọ, ko mu ko ni iyipada ọkan. Gehasi iransẹ woli Elisa ti wà lọdọ woli na ki ise ọjọ meji tabi mẹta mọ, sugbọn sibẹ o si ni ọkan lile, a o i ti fi ọwọ tọ ọkan na patapata, ọkan na ko i ti ni iyipada patapata, eleyi lo fa ti owo ati dukia se wọ̀ ọ́ loju, eleyi lo fa to se gba ègun sori ara rẹ, eleyi lo fa ti ohun to yẹ ko jẹ tirẹ ninu ẹmi ati nipa ti Ọlọrun ko se jẹ tirẹ. (I. Apo 19:8-9; 2 A. Ọba 5) Ọkan lile ko ni jẹ ki ọrọ Ọlọrun wọ inu aiye wa, ọkan lile ko ni jẹ ki aiye wa o tẹsiwaju, ọkan lile yio gbe wa lọ si ọrun apadi. Aposteli Paulu ninu iwe rẹ si awọn ara Romu 9:18 wipe, "Nitorina ni o se nsanu fun ẹniti o wù ú, ẹniti o wù ú a si mu u ni ọkan le" Ọrọ yi fihan wa wipe bi ọkan enia ba le, iru enia bẹ ko ni ri anu gba nitoripe irufẹ ẹni na yio ma sọ ọrọ àìyẹ si ọna na, yio ma sọ wipe ojusaju ni Ọlorun nse, yio ma sọ wipe Ọlorun ko se daradara. Njẹ awa na ko ha ma sọrọ àìyẹ si ọna na bi nitori ohun ti a nlà kọja? (3) Ilẹ na ko fi aye gba idagbasoke kankan nitoripe awọn ohun to le mu ki irugbin dagba daradara ko si nitosi, nitoripe omi ko le ma duro sibiti irugbin na yio ti ri lo fun didagbasoke rẹ, awọn omi ati irugbin jinna rere si irugbin na.... Awọn kokoro aifojuri to ma nmu ki ilẹ o se daradara lo jinna si ilẹ yi, nitori awọn idi wọnyi, ilẹ na ko fi aye gba irugbin na lati dagbasoke ati lati le se daradara. Nitori a ti tẹ ara rẹ lọrun, ẹni na ko fi aye gba idagbasoke ọrọ Ọlọrun kankan ninu aiye rẹ. Fasiti ayaba ninu iwe Esteri ori kinni ẹsẹ kọkanla ni ọba Ahaswerusi ransẹ si wipe ki o wa siwaju oun, sugbọn nitoripe o nro wipe oun ti tó tán, nitoripe o nro wipe ko si ẹni to lẹwa bi toun, nitori o nro wipe kini ọba yio se laisi oun nibẹ? Nitori o nro wipe ko sẹni to tun dabi toun lorilẹ ede nã, o kọ̀ lati fetisi awọn iransẹ ti ọba ran si i lati wa farahan niwaju oun, sebi ti enia ba fetisilẹ lati gbọ nkan ni yio ma ronu lori rẹ, Fasiti ayaba ko tilẹ fetisilẹ lati gbọ ọrọ asẹ ọba rara debi wipe yio ronu le ọrọ na lori, ohun to nse ni iyẹwu tirẹ lo ká a lara, ohun to nse lo tẹ́ ẹ lọrun nipasẹ eleyi to fi tàpá si asẹ ọba, nipasẹ eleyi ti ko fi fi aye gba ọrọ ọba, nipasẹ eleyi ti ọrọ na ko se gbilẹ ninu rẹ tobẹ ti ìrẹ̀ ẹ rẹ fi se ere bẹ́kùn-bẹ́kùn, to si fi ẹsẹ ara rẹ tú ìfun ara rẹ jade. Bi ohun ti awa na ba nse ba kawa lara ju ọrọ Ọlọrun lọ, eré e bẹ́kùn-bẹ́kùn ni a nse, a jẹ wipe a o se ara wa lese gẹgẹ bi Fasiti se se ara rẹ lese ni. Bi ọrọ ara wa, ọmọ wa, isẹ wa, ile wa, ba kawa lara ju ọrọ Ọlọrun ti a ngbọ lọ, a ò ni le fi aye silẹ fun ọrọ Ọlọrun na lati dagba ninu aiye wa. Ẹ jẹ ki a ranti olori Alufa Eli na pẹlu, ọrọ awọn ọmọ rẹ lo ká a lara ju ọrọ Ọlọrun lọ, o gbe awọn ọmọ rẹ ga ju ofin ati ilana Ọlọrun lọ, nigbati a tun ran awọn onisẹ si i, mo woye wipe iye ọdun to ti nse olori alufa ti ko sí i lori tobe gẹ ti ko fi gbe ọrọ na ti woli na ti a ran si yẹwo, ko fun ọrọ na laiye lati dagbasoke rara ati rara...olori alufa Eli ro wipe majẹmu ti Ọlorun ti ba idile oun da ko si ohunkohun to le yipada bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ntẹnumọ gidigidi fun wipe ewu mbẹ lóko longẹ rẹ ati wipe oun gan to njẹ loungẹ ọhun ewu loun na, sugbọn nse ni olori alufa Eli kọ eti didi, ó kọ eti to ndun rẹ si awọn ọrọ na, ko fi aiye fun ọrọ na lati dagba ninu aiye rẹ. (I Sam 2-3) Kaini pẹlu ko fi aye fun ọrọ na lati dagba ninu aiye rẹ, bi Ọlorun se nsọrọ bẹna ló nyi Ọlọrun danu eleyi to fa iparun fun oun na. (Genesisi 4) Ọlọrọ ti Jesu sọ owe rẹ ninu iwe ihinrere Luku 16:19-31 na ko fi aye fun ọrọ Ọlọrun na lati dagba ninu aiye rẹ, isẹ, isẹ, isẹ sa ni lojojumọ, eleyi ko mu ki awọn ọrọ to gbọ na o wọnu ilẹ lile ọkan rẹ lọ ki a ma wa sọ wipe yio tilẹ hù jade. Eleyi na ni ọkunrin ọlọrọ yi se titi to fi ku to si ba ara rẹ ninu ina ọrun apadi. Iwọ na njẹ o ha nfi aye fun ọrọ na lati dagba laiye rẹ? Nje emi na ha nfi aye silẹ fun ọrọ na lati dagba laiye mi? Se isẹ wa njẹ ki a le fi aye silẹ fun ọrọ na lati wọnu ilẹ aiye wa lọ bi? Se ọmọ wa, aya wa, afẹsọna wa, ẹkọ wa, ile iwe wa, ilepa wa, abbl na njẹ ki a le fi aye silẹ fun ọrọ na lati dagba ninu aiye wa bi? Samsoni alagbara nitori ilepa ati di alaya ko fi aye silẹ fun ọrọ Ọlọrun lati wọ oun leti debi wipe yio tilẹ ri aye dagba soke ninu aiye rẹ, nigbati baba rẹ nsọ fun wipe sebi awọn ọmọbinrin wa larin awọn eniyan Israeli, ko tilẹ jẹ ki ọrọ na o délẹ̀ to fi da baba rẹ lohun wipe, ẹniti oun fẹ́fẹ́ niyẹn ki wọn o fẹ́ ẹ fun oun. "Samsoni si sọkalẹ̀ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini. "O si goke wa, o si sọ fun baba on iya rẹ, o si wipe, emi ri obinrin kan ni Timna ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini: njẹ nitorina ẹ fẹ ẹ fun mi li aya. "Nigbana ni baba on iya rẹ wi fun u pe, ko si obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakọnrin rẹ, tabi ninu gbogbo enia mi, ti iwọ fi nlọ ni obinrin ninu awọn alaikọla Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ pe, fẹ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi" (Ond 14:1-3) Samsoni ko jẹ ki ọrọ awọn baba ati iya rẹ o delẹ̀ to fi hán wọn pàkà, to fi da wọn lóhùn, eleyi ni wipe ko tilẹ ronu lori ọrọ na rara, eleyi ni wipe ko fi aye fun ọrọ na lati dagbasoke ninu aiye rẹ, igberaga wipe agbara wa ti kó si lori, igberaga wipe ọmọ majemu ni ti ko si lori, igberaga wipe Nasiri ni ti ko si ni ori, eleyi lo fà á ti ko se fi aiye silẹ fun ọrọ na lati wọ ilẹ aiye rẹ debi wipe yio tilẹ dagbasoke. Otitọ ni wipe ẹsẹ to tẹle ẹsẹ yi, ani ẹsẹ kẹrin iwe Onidajọ ori kẹrinla yi wipe, "Sugbọn baba ati iya rẹ ko mọ pe ati ọwọ OLUWA wa ni, nitoripe on nwa ọna lati ba awọn Filistini ja. Nitoripe li akoko na awọn Filistini li alasẹ ni Israeli" (Ond 14:4). Bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun nwa ọna lati ba awọn Filistini ja, ati lati tú awọn ọmọ Israeli silẹ labẹ isinru wọn, sibẹ iba fi aye silẹ fun ọrọ na lati wọnu aiye rẹ lọ, àì fi aiye silẹ fun ọrọ na ni ipilẹsẹ iparun rẹ, nitoripe lati igbana lọ loti bẹrẹ sini jọ ara rẹ lju lati igbana lọ loti bẹrẹ sini se asise, lati igbana lọ lo ti mu ọrọ Ọlọrun, ofin ati ilana Ọlọrun gbogbo ti a fi kọ ni yẹpẹrẹ, lati igbana lọ loti njaiye familete ntutọ, lati igbana lọ loti nro wipe ohun gbogbo ti oun ba se asegbe ni ati wipe bi oun ba tilẹ se asemọse, Ọlọrun yio yipada fun oun, lati igbana lọ lo ti nlo ọrọ Ọlọrun fun imọ ti ara re nikan, o nlo ọrọ na lati tẹ ara rẹ lọrun ko lo ọrọ na gẹgẹ bi o ti se tọ ati bi o ti se yẹ mọ... eleyi lo bẹrẹ isubu rẹ. Njẹ bayi na ha kọ ni awa na lode oni? Njẹ ki ise nitori ati lọkọ ni a ò se fi aye silẹ fun oro Olorun lati ri aye ninu aiye wa? Nje ki ise nitori ati laya, nitori ati lọkọ, nitori ati lọ sile iwe, nitori ati di ilumọmika oloselu, nitori ati kọ ile, nitori ati di olokiki oniwasu abbl ni a ko se fi aye silẹ fun ọrọ Olorun ninu aiye wa? Awa na nse bi Samsoni, a gbe imọ wa nipa ọrọ Ọlọrun ti sẹgbẹkan ki a ba le tẹ ara wa lọrun, ki a ba le tẹ ile wa lọrun, ki a ba le tẹ ọmọ wa lọrun, ki a ba le tẹ ijọ wa lọrun, ki a ba le tẹ ẹbi wa lọrun, ki a ba le tẹ awọn obi wa lọrun, awa na nse bi ti Samsoni, awa na nse bi olori alufa Eli, a n wipe Ọlorun ti ba wa da majẹmu na ko si ohun to le yipada mọ, awa na nwipe Olorun ti ba ijọ wa da majemu na ko si ohun to le yipada mọ bi a tilẹ ntẹsiwaju ninu ẹsẹ, awa na nsọ wipe Ọlọrun ti ba awọn baba nla wa da majemu na, ohunkohun ko le è yipada bi a tilẹ nse aigbọran si ọrọ ati ọna na, bi a o tilẹ fi aye gba ọro Olorun na ninu aiye wa mọ lati dagbasoke, bi a tilẹ nlọ ọrọ na lati tẹ ara wa lọrun, bi a tilẹ nlọ ọrọ na lati fi mu ki ọrọ̀ ati okiki wa o pọsi, eleyi ko ja mọ nkankan ki a sáà ti ma fi orukọ Jesu kún gbogbo rẹ. Ohun ti a nse yi na ni Samsoni se. Ohun ti a nse yi na ni olori alufa Eli se. Gbogbo wa ni a si mọ ohun to gbẹhin awọn mejeji. Bi o tilẹ jẹ wipe Samsoni ri ore-ọfẹ gba nigbẹhin, sugbọn ranti wipe olori alufa Eli ati awọn ọmọ rẹ ko ma ri ore ofẹ ironupiwada gba nitiwọn, wọn padanu ẹmi wọn, wọn segbe, wọn si lọ si ọrun apadi. Njẹ gbogbo ọrọ, gbogbo awọn nkan ti awọn ọmọ Eli wa fi ojukokoro ati àì gba ọrọ Ọlorun laye ninu aiye wọn kojọ njẹ talo ha ni gbogbo ohun na lẹhin igbati wọn ku tan? Ori olori lo ni i, ẹlomiran lo ko ire wọn na lọ. Bi awa na ba fi àì fi aye gba ọrọ Ọlọrun to awọn nkan jọ ninu aiye, nse lo yẹ ki a mọ daju wipe ẹlomiran ni yio ko gbogbo awọn ohun na lọ. Isẹ, ọmọ, aya, ọkọ, ilepa ohun aiye gbogbo ko jẹ ki ẹniti aiya rẹ jẹ ilẹ ẹba ọna na o fi aye gba idagbasoke kan bi o ti nwù ki o kere mọ fun irugbin ọrọ ijọba na ti a bá a sọ. (4) Nitoripe ọna awọn eniyan ti ọkan wọn jẹ ilẹ ẹba ọna na jẹ ọna aiye, nitoripe gbogbo imọ wọn jẹ ti aiye to nsegbe lọ yi, irugbin na ko ri aye duro ninu ọkan wọn fun isẹju kan pere. Iru awọn eniyan wọnyi ni Jesebeli aya ọba Ahabu gbogbo ilepa ati inọga wọn lati jogun aiye ni, awọn ko ronu tabi lepa lati de ọrun rara, gbogbo afojusun wọn bi wọn yio se ni ile aiye ni, bi wọn yio se jẹ ọba ni, bi ìran-ìran wọn yio se ma sàkoso lọ lailai ni afojusun ati erongba wọn. (I A. Ọba 21:25; 9:30 ff; Ifi 2:20) Balaamu ni ẹlomiran to jẹ wipe ọna rẹ ati gbogbo ilepa rẹ lati ni ile aiye ni, o nfẹ jẹ woli tabi alafọsẹ to lowo ju ni gbogbo aiye, nitorina o sare si ere aisododo, o fi ọgbọn ẹwẹ, ọgbọn arekereke, ani o fi ọgbọn Satani ko ọrọ jọ. (II Pet 2:15; Juda 11; Ifi 2:14) Ẹ ma jẹ ka gbagbe aya Loti (Gen 19:26; Lk 17:32); Abimeleki (Ond 9-10) abbl. Ọna aiye ni ọna wọn, ilepa aiye ni ilepa wọn, gbogbo ero wọn ti aiye yi ni, nitorina gbogbo ọrọ ti afurungbin na nfún ko ri aye ninu ilẹ aiye wọn lẹsẹkẹsẹ ti afurungbin na ba ti furungbin na lọrọ na ma ndi mimu kuro lọkan wọn, Satani yio mu ọrọ na kuro loju kanna. Njẹ gbogbo ilepa tirẹ na kì í ha ise ti aiye nikan bi? Njẹ ki ise bi wà á se jẹ olowo julọ ni gbogbo agbaiye lo wa lọkan rẹ? Njẹ ki ise bi idile rẹ nikan yio se ma sakoso gbogbo orilẹ ede aiye nikan lo wa lọkan rẹ? Njẹ ki ise wipe ò njá ile ẹlomiran bo tirẹ mọlẹ nitoripe o nfẹ ni gbogbo aiye? Mo fẹ ki a mọ wipe ki ise wipe Ọlọrun lòdì si owo níní, sugbọn se ọnà tó tọ́ lo ngba lati ní i? Bi gbogbo ilepa ati gbogbo ero rẹ ba jẹ ti aiye yi nikan, o daju wipe awọn ọrọ ijọba na ti afurungbin na yio ma fọn ko ni le duro nilẹ aiye rẹ lojukanna ti a ba fún ọrọ na ni yio kuro lọkan rẹ. (5) Ohun asán aiye lo sọ ọkan wọn di yiyigbì, irubọ ti ko ni ìyè ninu lo sọ ọkan wọn di yiyigbi, ani awọn eto ilana isin to ti fẹrẹ dabi igbati awọn babalawo tabi awọn onifa tabi awọn abọrisa ba nse irubọ lo ti sọ ọkan wọn di yiyigbi.... Se iran keferi na ni wa tẹlẹ-tẹlẹ, ati gbe awọn ilana ati eto isin nidi orisa wọnu sinsin Ọlọrun Alaye, eleyi pẹlu si ti sọ ọkan wa di yiyigbi, eleyi ti mu ki ọkan wa sebọ si ọrọ afurungbin na. (Kol 2:8) Ohun asan aiye yi sọ ọkan wa di yiyigbi nipasẹ eleyi ti ọrọ afurungbin na ko se ye awọn eniyan na, ọrọ afurungbin na ko nitumọ si wọn. Nigbati ọrọ afurungbin na ko si ti nitumọ si awọn eniyan na, esu wa o si mu eleyi ti afurungbin na fún si ọkan ẹni na kuro, nitoripe ọrọ na ko nitumọ si ẹni na tẹlẹ, ẹni na ko tilẹ mọ boya nkankan kuro ninu ọkan oun tabi ko kuro, nitoripe ohun ti eniyan ba mọ itumọ ati iwulo rẹ leniyan ma nkárà mọ, ohun ni eniyan ma mbojuto. (6) Awọn ti ọkan wọn dabi ilẹ kinni yi jẹ awọn ti wọn kunà lati yi iwa wọn pada. Bibeli wipe, "Ara Etiopia le yi àwọ̀ rẹ pada, tabi ẹkun le yi ilà ara rẹ pada? Bẹni ẹnyin pẹlu iba le se rere, ẹnyin ti a kọ ni iwa buburu" (Jer 13:23) Awọn wọnyi gbọ ọrọ ijọba Ọlọrun eleyi ti o jẹ irugbin ti afurungbin na fún, sugbọn sibẹ wọn kuna lati yi iwa wọn pada, wọn sé aiya wọn le si awọn ọrọ afurungbin na. "Ẹ ma se aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju" (Ps 95:8) Njẹ awa na loni ko ha ma se aiya wa le si awọn ọrọ ijọba Ọlọrun ti a ngbọ? Njẹ awa na ha nyipada ti a si nse atunse lẹhin igbati a bá gbọ ọrọ Ọlọrun tan? Nitoripe awọn eniyan wọnyi kuna lati yipada, nitoripe awọn eniyan wọnyi dabi awọn ara Etiopia ti ko le yi àwọ̀ wọn pada, nitoripe awọn eniyan wọnyi dabi ẹkun ti ko le yi ila ara rẹ pada, ẹni buburu ni pẹlu wa lati mu eleyi ti a fi si ọkan wọn kuro, wọn si ntẹsiwaju ninu okunkun biribiri titi di ọjọ idajọ nla ni. "Ati awọn angẹli ti ko tọju ipo ọla wọn, sugbọn ti wọn fi ipo wọn silẹ, awọn ni o pamọ ninu ẹwọn ainipẹkun nisalẹ okunkun de idajọ ọjọ nla na" (Juda 6) (7) Ohun to fà á ti ọrọ afurungbin na ko se nipa kankan ninu aiye awọn enia na ni wipe iru awọn eniyan to ni orisi aiya yi wọn kì í ronu nipa ẹlomiran, ohun ti ara wọn nikan, ohun ti ile wọn nikan, ohun ti isẹ wọn nikan ni wọn ma nro lojojumọ.... Ninu ọrọ wọn, "emi, emi" lo pọ̀jù nibẹ. (Lk 12:14-21) "Ki olukuluku nyin ki o mase wo ohun tirẹ, sugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran" (Fil 2:4) Bo dara fun ẹlomiran kò kàn wọn, bi ko dara fun ẹlomiran kò kàn wọn, bi ẹlomiran nsaisan, ko kan wọn...ohun to sàá kan wọn ni wipe ki awọn ati ohun gbogbo to nse tiwọn ti wa ni alafia, ki aiye wọn ti ma tẹsiwaju sí i, ko si ohun to kan wọn nipa ti ẹlomiran. Nitori àì bikita fun ẹlomiran Ọlorun papa fi aye silẹ fun Esu lati wọnu aiye wọn, ani ati lati mu irugbin ọrọ ijọba na ti afurungbin na ti fun si ọkan wọn kuro. Bi awa na ba nronu nipa ti ara wa nikan, a jẹ wipe awọn ọrọ afurungbin wọnni ko wọnu ilẹ ọkan wa, ohun to si daju ni wipe nigbose, Satani, ẹnibuburu ni, ni yio wa mu awọn ọrọ na kuro lọkan wa. (8) Ẹ̀sẹ̀ ti se aiya awọn eniyan to ni iru ọkan bayi le, otitọ ni wipe wọn ngbọ ọrọ ijọba na sugbọn ko ye wọn nitori ẹ̀sẹ̀ tó sé aiya wọn le. "On si wipe, lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, ni gbigbọ, ẹ gbọ, sugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri ẹ ri, sugbọn ẹnyin ki yio si mọ oye. "Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ, si mu ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o ma ba fi eti wọn gbọ, ki nwọn ki o ma ba fi ọkan wọn mọ, ki nwọn ki o ma ba yipada, ki a ma ba mu wọn li ara da" (Isa 6:9-10) Bibeli ẹwẹ tun wi nibikan wipe, "Aiya wọn sẹ́bọ́ bi ọ̀rá" (Ps 119:70a) Nitoripe igberaga ti sé aiya wọn bọ, ni ede miran ti yio ye wa daradára, nitoripe igberaga ti kun wọn ni aiya, nitorina gbogbo ọrọ ijọba na ti afurungbin na nfun sori ilẹ ọkan wọn ko le wọnu ilẹ ọkan wọn na, nitorina ọrọ afurungbin na gbogbo ko ye wọn. Njẹ a o ranti Kaini ọkunrin akọkọ to jẹ apaniyan ninu aiye gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli (Gen 4). Ọkunrin yi nitoripe ẹ̀sẹ̀ kún-un ni aiya, ọrọ ti Ọlọrun mba sọ lati kiyesara, ọrọ ti Ọlọrun mba sọ lati se eleyi to dara kò yé e, nitoripe "satani ti kun un li ọkan lati se buburu ni awọn asiko wọnni (I. Apo 5:3; Jhn 13:27). Bi ẹsẹ ba ti sé aiya enia le, yio fi aye silẹ fun Satani lati kun eniyan lọkan, eleyi ni wipe Satani yio ti kọ́kọ́ mu ọrọ na kuro lọkan eniyan, lẹhin eleyi ni ẹni na yio wa ma tẹsiwaju ninu iwa aìyípada rẹ, ti ẹni na yio si wa ma sọ ọrọ òdì si Ọlọrun ati si ọmọ Rẹ ati si orukọ rẹ "O si ya ẹnu rẹ ni ọrọ-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ odi si orukọ rẹ, ati si agọ rẹ, ati si awọn ti ngbe ọrun" (Ifi 13:6) Ẹsẹ to kun wọn lọkan ko jẹ ki ọrọ na o ye wọn, ẹsẹ to dabi ọ̀rá pupọ lọkan wọn ko jẹ ki ọrọ na o nitumọ si wọn bi o tilẹ jẹ wipe wọn ngbọ bi afurungbin na tise nsọrọ̀.... Ẹsẹ aigbagbọ dabi ọra to se aiya wọn le; ẹsẹ agbere dabi ọra to kun wọn lọkan; ẹsẹ irede oru jẹ ọ̀rá to se aiya wọn le; ẹsẹ ìjà na jẹ ọ̀rá buburu ti Satani fi se aiya wọn le, ...ngo ni se alai mẹnu ba awọn ẹsẹ to farasin na to dabi ọ̀rá to se aiya wọn le, eleyi ti kò jẹ ki ọrọ Ọlọrun na nipa ninu aiye wọn, iru awọn ẹsẹ wọnyi ni ẹsẹ ibinu lainidi, ẹsẹ to farasin ni, ẹsẹ ti enia ko le tete ri ni; ẹsẹ erokero si ara ẹni ati si ọmọnikeji ẹni; ẹsẹ bi gbogbo eniyan yio se ma se ẹru ẹni; ẹse bi eniyan yio se dalẹ̀ ẹnikeji ẹni nitoripe a ò fẹ ko dide...awọn ẹsẹ wọnyi farasin, awọn ẹsẹ wọnyi ko tete nfarahan, iru awọn ẹsẹ wọnyi lo sé aiya awọn eniyan wọnyi le gẹgẹbi ọra eleyi to nmu ki wọn o gbọ ọrọ Ọlọrun lotitọ ati lododo sugbọn ti ọrọ na ko si ye wọn. "Nitorina bi a ti fi awọsanma ti o kun to bayi fun awọn ẹlẹri yi wa ka, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo ti si apakan, ati ẹsẹ ti o rọrun lati di mọ wa, ki a si ma fi suru sure ije ti a gbe ka iwaju wa" (Heb 12:1) Gẹgẹ bi ẹsẹ to farahan ati awọn eleyi to sinmi si ọkan ẹni na se sé aiya rẹ bọ gẹgẹ bi ọra bẹ pẹlu ni awọn ẹsẹ to rọrun lati di mọ enia na ko jọwọ rẹ lọwọ lọ lati le di ominira, awọn ẹsẹ to rọrun lati di mọ eniyna wọnyi fọ awọn ẹni na loju lati riran li okere (II Pet 1:9). Awọn ẹsẹ to rọrun lati di mọ eniyan bí i mimu ohun ti ise ti ọkunrin wọ, awa obinrin, tabi ọkunrin ko ma mu ohun ti ise ti obinrin wọ nitoripe aiye ti di aiye ọlaju, nitoripe àsà to wópọ̀ laiye lode oni ni, nitorina awa na le ma se é... Nigbati irufẹ awọn ẹsẹ to rọrun lati di mọ eniyan wọnyi na ba ti wa lokan aiya enia, yio se aiya ẹni na le gẹgẹ bi ọra tobẹ ti yio fi ma gbọ ọrọ Ọlọrun na sugbọn ti ko si ni yé e. (9) Ero ti ko duro lori iriri ati ero ti ko mu ọpọlọ dani lo nmu ki ọrọ Ọlọrun na o ma ye ẹni na. Ero wọnyi lo nmu ki ẹni na sé aiya rẹ le. Fun apẹrẹ ti ẹniti ko de Eko ri ba fẹ lọ si Eko, ti awọn to ti de ilu Eko ri tabi ilu to fẹ lọ na ri ba sọ fun ẹni na wipe awọn ohun bayi bayi ni ẹni na yio ba lọhun, nse lo yẹ ki iru ẹniti ko de ilu na ri yẹn o gba tawọn eniyan wọnyẹn wọle ko si mura dani lati le koju awọn ohun ti yio ba nibi to nlọ na. Sugbọn tiru ẹniyi ko ba fi ọrọ na pè, tiru ẹniyi ko ba fẹ mu lati ara omi ọgbọn awọn eniyan wọnyi nigbato ba de ilu to nlọ na ti awọn nkan na bá wá nfarahan, a o ri wipe ki ise ẹbi ẹnikẹni mọ bikose ẹbi ti ẹni na. Bẹ gẹgẹ ni iru awọn eniyan wọnyi, ero ti ko mu ọpọlọ dani, ero ti ko ni iriri ninu lo mu wọn ma gba ọrọ na gbọ, ero yi lo mu ki nwọn o se aiya wọn le. Afurungbin ọrọ na sọ fun wọn wipe, "Ko si si ẹniti o goke re ọrun, bikose ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wa, ani ọmọ enia ti mbẹ li ọrun" (Jhn 3:13) "Ẹniti o ti oke wa ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wa ti aiye ni, a si ma sọ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wa ju gbogbo enia lọ" (Jhn 3:31) Ninu ọrọ afurungbin yi ni o ti sọ fun awọn enia wipe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wa nikan na lo le sọ fun awọn enia bi ọ̀run tise ri ati ọna ti awọn eniyan le è gbà pada de ọrun.... Sugbọn nitori ero ti ko mún ọgbọn dani, nitori àì ni ìrírí awọn enia na wọn tako ọrọ na, wọn ko gba ọrọ na gbọ, wọn nwipe eleyi ha ti se le ribẹ? "Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ? Etise wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wa?” (Jhn 6:42) Nitori àì mọ agbara Ọlọrun, o nse awọn enia na ni kayefi ọrọ ti Jesu sọ wipe Oun ni ounjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ, o nse wọn ni kayefi wipe, Oun, Jesu, ni Otitọ ati Iye na, nitori àì ni iriri, nitori àì ni ero to ba ti Bibeli mu, wọn kọ ọrọ Jesu silẹ, wọn wa li òpè sibẹ, wọn wa li ailoye sibẹ. Nitoripe ọrọ Jesu ko ye awọn eniyan na Jesu na bere lọwọ wọn ere idi ti ọrọ Oun ko se ye wọn? "Etise ti ede mi ko fi ye nyin? Nitori ẹ ko le gbọ ọrọ mi ni" (Jhn 8:43) Àì ni iriri nipa ọrun, àì ni oye nipa ọrun, àì ni ero to ba ti ọrun mu ko jẹ ki ọrọ afurungbin na o ye awọn eniyan wọnyi, àì fẹ gba ọrọ ti ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wa sọ mọ ti ara wọn lo mu ki nwọn o se aiya wọn le. Njẹ awọn ero wipe "Olorun ko bimọ, ẹnikan ko bí I" na ko ha ti sé aiya wa le si gbigba Kristi Jesu gbọ? Njẹ nitori àì tí ì ni iriri nipa ẹniti o ti di atunbi nitotọ ko ha ma mu wa dẹiyẹ si ọrọ igbala bi? Njẹ nitori wipe gbogbo enia ngba ọna ẹ̀rü di olowo ati ọlọ́rọ̀ na ko ha ti mu ki awa na má gbagbọ wipe Oluwa Ọlọrun Eledumare ọba to sọ Abrahamu di alabukun fun na si nsọ enia di alabukun fun loni ati wipe O le è sọ awa na di alabukun fun? Njẹ nitoripe ẹsẹ ti di pipọ ati wipe ifẹ ọpọlọpọ si ti di títù loni. "Ati nitori ẹsẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutu" (Mt 24:12) ìse ki ise eleyi na kò ha ti mu ki awa na ma sọ wipe ko si ohun to njẹ iwa-Mimọ lode oni bi? Njẹ nitoripe a bọ́ sinu isoro, wahala ati idamu ti a ò si ri ẹnikẹni sọrọ itunu fun wa, njẹ awa na ko ha ti ma ro wipe ko si ọrọ itunu ninu ihinrere nipasẹ eleyi ti awa tikarawa fi nro wipe mimu ọti nikan ni a le fi pa ironu rẹ? Njẹ nitoripe awọn omidan ti a ngbadura nipa rẹ, ati awọn ti a mba sọro wipe a nfẹ ko jẹ iyawo wa ko gbà siwa lẹnu, njẹ awa na ko ha ma ro wipe a o fẹ alaigbagbọ gẹgẹ bi aya, sebi ki a sa ti fẹ iyawo ni? Njẹ nitori àì rọ́kọ ti ọjọ si ti nlọ lori wa, njẹ a ò ha ti lọ so ara wa papọ mọ ọkunrin alaigbagbọ bi? Nitori ai ni iriri, nitori ai ni ero to dapọ mọ ti Ọlọrun, aiya awọn enia wọnyi se le, wọn si da ọrọ na nu lojukanna ti nwọn ngbọ. (10) Bi afurungbin na, tise nfunrungbin ọrọ na, iru awọn eniyan wọnyi gbọ ọrọ na sugbọn lojukanna ti wọn ngbọ ọrọ na ni wọn nda ọrọ na nu. Se a mọ wipe ọrọ ti enia ko ba fẹ fiyesi, ọrọ na ko ni duro ninu ọpọlọ eniyan, iru awọn ọrọ wọnyi ni awọn Yoruba npe ni bi o se gba eti ọtun wọle bẹna lo ngba ti osi jade, eleyi ni wipe ọrọ na ko nibugbe ninu ọkan ẹni na, ọrọ na ko ri ibi duro si ninu okan ẹni na, ki ise wipe ẹni na kò gbọ ọrọ na sugbọn ọrọ na to ngbọ ko fi ààyè fun un lati joko sinu ọkan rẹ. Bi ọmọ ile iwe kan tabi agbalagba pẹlu ba nkawe nibiti ariwo wa, boya kò sì sí ibiti o ti le ka iwe na ni asiko na, iru ẹnito nkawe na ko ni fiyesi ariwo to ngbọ lọtun-losi, nitori ti o ba fiyesi ariwo na, ohun to nka na ko ni yé e...tabi ẹnito ngbọ ẹrọ asọrọmagbesi (radio) tabi to nwo ẹrọ amohunmaworan nibiti ọpọ èrò wa ti nwọn si nsọrọ̀ fata-fata, iru ẹni na lati gbọ ọrọ ti nwọn nsọ yegeyege ko gbọdọ fiyesi ariwo to ngbọ lọtun losi nitori toba fiyesi, afaimọ koma ma gbé òjó fun aina ninu ọrọ to ngbọ na. Eleyi pẹlu ni awọn ti nwọn mba ẹlomiran lati ọna jinjin sọrọ lori ẹrọ alagbeka ma nse nitori ti nwọn ko ba pa ọkan pọ lati gbọ ti ẹniti wọn mba sọrọ lori afẹfẹ na yio di awuyewuye. Awọn apẹrẹ wọnyi na lo nsọ nipa ti irufẹ awọn eniyan ti ọkan wọn wa lẹba ọna wọnyi, nitoritpe wọn nfi ọkan wọn si nkan miran yatọ si ọrọ ti afurungbin ọrọ ijọba Ọlọrun na nfún, nse ni wọn nda ọrọ na nu lẹsẹkanna ti nwọn ngbọ́ ọ. Ni ọjọ afiyesi kan ọba Dafidi pe Joabu olori ogun rẹ lati lọ ka awọn eniyan Israeli, bi ọba Dafidi se sọ ọrọ yi ni Joabu olori ogun sọ wipe ki ọba mase jẹ ki awọn o se eleyi, sugbọn ọba Dafidi da ọrọ Joabu nu lẹsẹkanna ti o si wipe àsẹ oun gbọdọ̀ di mimusẹ (II Sam 24:2-4 & I Kro 21:3-4) Iru awọn eniyan wọnyi na bi nwọn se ma nse niyi, bi nwọn ba gbọ ọrọ igbala, ọrọ tiwọn ni wọn a fẹ ko bori ọrọ igbala ti nwọn ngbọ nã..., ero tiwọn ni wọn a fẹ ko bori ọrọ Ọlorun ti nwọn ngbọ na. Bi afurungbin ọrọ ijọba ba wipe laisi ironupiwada ati iyipada si Ọlorun patapata, enia ko le de ọrun rere nse lawọn enia na yio wipe eniyan bi tiwa na ni Jesu, awọn miran yio tilẹ wipe talo de, ọrun to pada wa ri, wọn a ni irọ nla ni awọn eniyan npa. Mo ka itan kan ninu iwe kan nipa ọkunrin kan ti wọn sọ wipe o sẹsẹ nkọ nipa isẹ alufa nilu Amerika, ni nkan bi igba ọdun o le diẹ sẹhin. Wọn ni ọkunrin na, nitori ko i ti mọ Bibeli daradara ati wipe ko i ti mọ bi ase nse iwasu daradara, o wa mu iwasu kan lara awọn iwasu ọga rẹ, ọrọ bibeli yi na lo fi se iwasu ninu ijọ to lọ lojọna. Ọrọ bibeli to fi si fi se iwasu na ni wipe, "Niwọn bi a si ti fi lelẹ̀ fun gbogbo eniyan lati ku lẹkansoso, sugbọn lẹhin eyi idajọ" (Heb 9:27) Bi o se nsọ ọrọ yi ninu ijọ lọjọna wọn wipe ẹnikan wa lori ijoko na to nda ọrọ na nu pẹlu awọn ẹkọ to ti kọ nile ẹkọ bibeli... Lẹhin igbati isin ọjọ na pari wọn ni ẹni na lo ba oniwasu na lati sọ wipe ko si ohun to njẹ idajọ bi enia ba ti ku, o pari na niyẹn.... Wọn wipe sugbọn nse ni oniwasu na ntẹnumọ ọrọ bibeli yi... Wọn ni ẹni na tun bere awọn ibere lọwọ ẹni na, wọn ni o bere wipe nibo ni Kaini ti ri iyawo rẹ? Wọn ni idahun ti oniwasu na fi da lohun ni ọrọ to wa ninu iwe Heberu yi, wọn ni o wipe oun ko mọ nkankan miran mọ.... Bayi na ni ọpọ eniyan ti ọkan wọn jẹ iru ilẹ yi ti se ma nda ọrọ Ọlorun ti nwọn ba gbọ nu lẹsẹkẹsẹ ti nwọn ba ti gbọ́ ọ. Njẹ iwọ na ko ha si niru ikorita yi? Njẹ emi na ko ha si niru ikorita yi? Njẹ ki ise wipe nse ni a nda ỌRỌ ỌLỌRUN ti a ba ngbọ dànu lẹsẹkẹsẹ ti a bá ti gbọ ọ. Se ki ise isoro ti a nla kọja ni a fi ma nda ọrọ Ọlọrun ti a ba gbọ danu lojukanna ti a ba ti gbọ ọ? Se ki ise awa ni a ma nsọ wipe tó bá jẹ wipe Ọlọrun wà, kò yẹ kiru isoro tabi idamu yi de ba wa? Se ki ise awa ni a ma nsọ wipe kini Ọlọrun now to se fi aye gba iru eleyi lati sẹlẹ si wa ti a ó si tipasẹ bẹ da ọrọ ti a gbọ nă nu lai ronu lé e lori? Se awa nă kò si ni ipo awọ to ma nsọ wipe to ba jẹ wipe Ọlọrun wà o se le jẹ ki ọmọ òòjọ ko kú? Ti a o wa ma wipe ko si Ọlọrun, nitorina ko nilo lati gba Jesu Kankan gbọ wipe irọ patapata ni awọn eniyan npa fun wa ti a ó si da ọrọ nă nù…. Irufẹ awọn eniyan to niru ọkan to dabi ilẹ ẹbá ọnà nibiti irugbin ọrọ nă bọ si yi, lojukanna ti wọn ba ti gbọ ọrọ Ọlọrun ni wọn mă nda ọrọ nă nu. (11) Olusọ-agutan Spurgeon nigba aiye rẹ sọ wipe awọn ti nwọn ni iru ọkan ti ẹ̀bá ọ̀nà yi ohun to ma nsẹlẹ si wọn ni wipe nse ni Esu ati Satani ani Ẹnibuburu ni ma nkọja lori ọkan wọn pẹlu awọn ẹgbẹ́ ogun rẹ. Awọn ẹgbẹ́ ogun ti Satani ma nmu kọja lori ọkan nã nigbakugba ni ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ òdì gbogbo; ìréra aiye; ifẹkufẹ aiye; irọ ati ẹtan; àní ati oniruru gbogbo. "Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki ise ti Baba, bikose ti aiye." (1 Jhn. 2:16) O tẹsiwaju lati tun wipe, kẹ̀kẹ̀ ẹsin igberaga nkọja loru irufẹ ọkan awọn eniyan wọnyi, eleyi nã ló mú ki aiya wọn sébọ́ pẹlu ọ̀rá ati aiya wọn fi yigbì lati gbọ ati lati gba ọrọ nã. "Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: sugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ tinutinu mi gbogbo. "Aiya wọn sebọ bi ọrá; sugbọn emi o se inu-didun ninu ofin rẹ" (Ps. 119:69-70) Olusọagutan Spurgeon tun tẹsiwaju wipe, ẹsẹ̀ mámónì ọ̀kánjúà ngba ọkan na kọja lorekore, ani tọsàn-toru titi ti ọkan na fi le bi okuta alùmọndi ti ko le yipada mọ́. "Ko si ẹniti o le sin oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yan ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sin Oluwa pẹlu mammoni" (Mt. 6:24) "Oluwa, oju rẹ ko ha wà lara otitọ? Iwọ ti lù wọn, sugbọn ko dun wọn; iwọ ti run wọn, sugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le ju apata lọ; nwọn kọ lati yipada" (Jer. 5:3) Njẹ kì íse iru awọn nkan to nkọja lori ọkan iwọ ati emi na niwọnyi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ ti ọkan wa fi le, to bẹẹ̀ gẹ́ ti a fi kuna lati yipada. (12) Ọkàn ti ẹba ọna yi jẹ ọkàn to ntà to nrà, nitorina, gbogbo irugbin ọrọ na ti afurungbin na nfun ni ko yé e, eredi niyi ti ọkan yi se dà bi okuta alumọndi, eredi niyi ti ọkan na ko se yipada, eredi niyi ti o fi nda ọ̀rọ̀ afurungbin nã nù lẹsẹkanna ti wọn ba ti gbọ́ ọ. Nitoripe ọkan na jẹ ọkan to nsòwò, ọkàn to nrà to ntà, ko ri aye fun nkan miran yàtọ̀ si ọjà tita lọ. Njẹ a ha ri onsowo to ma nri aye lati ba awọn eniyan rojọ́ tabi sọrọ nigbati awọn ti nwọn fẹ bawọn rajà ba wa niwaju wọn? Nigbati awọn onibara ba de si iwaju awọn to ntaja, awọn onsowo kò ní ri aye ti ẹlomiran, se nitotọ awọn onisowo miran gan ko ni roju ri aiye lati dá ọmọ wọn lóhùn mọ, bẹ sini woli Isaiah wipe kò rọrun fun abiyamọ lati gbàgbé ọmọ rẹ. "Obinrin ha le gbagbe ọmọ ọmu rẹ bi, ti ki yio fi se iyọnu si ọmọ inu rẹ? Lotọ, nwọn le gbagbe, sugbọn emi ki yio gbagbe rẹ" (Isa. 49:15) Ninu iwe yi, a ri wipe woli Isaiah tipasẹ Ẹmi Mimọ sọ wipe ko rọrun fun abiyamọ lati gbagbe ọmọ ọmú rẹ...sugbọn, ó tún wipe o sese ki wọn o gbagbe nigbamiran, awọn asiko to sese fun wọn lati gbagbe na niru awọn asiko yi, lawọn asiko ti onsowo tabi ontajà bá ri awọn onibara rẹ, wọn le yi ọmọ tì si ẹ̀gbẹ́ kan, wọn le ma tete dásí ọmọ nã. Bẹ ẹ̀ gẹgẹ niru awọn eniyan ti nwọn ni ọkàn to mbẹ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà yi, wọn a máa tà wọn, wọn a má a rà, ọkan wọn kún fun òwò sise, nitoripe ọkàn wọn kún fun òwò sise bayi, wọn á da ọrọ afurungbin náà nù lẹsẹkanna ti nwọn ba ti gbọ́ ọ, wọn ko ni nání ọrọ nã, wọn kọ ni ka ọrọ na si rara. Njẹ títà rira tó ha nlọ lọkan wa lorekore njẹ o ha nmu ki awa nã ma kiyesi awọn ọrọ Ọlọrun ti a ngbọ bi? Awọn agbagba Yoruba wipé "etí kì í gbọ́ méjì", ati wipe, "eniyan ko le è le eku meji kó má pòfo", nitoripe ọkan wa ti wa ninu títà rira, a ò fiyesi nkan miran mọ, a ò fiyesi ọrọ Ọlọrun ti awọn afurungbin na ngbọ́ mọ́. Nigbati Jesu Kristi wọ inu tẹmpili to mbọ ni Jerusalẹmu lọ, bibeli ninu akọsilẹ rẹ wipe ó rí awọn tò ntà to nrà ninu tẹmpili nã, o si bẹrẹ lẹsẹkanna lati ma le wọn jade kuro ninu tẹmpili, nitoripe Jesu ri wipe wọn ti dá ìyapa silẹ, Jesu ri wipe wọn ti mu ki ọkan awọn eniyan o ma se dede pẹlu ọrọ ti awọn afurungbin nsọ ninu tẹmpili, Jesu ri wipe awọn eniyan wọnyi ti nmu ki ọkan awọn eniyan ma wo ohun aiye ju awọn ohun ti ọrun lọ, Jesu ri pe nipa títà rira yi, awọn eniyan ko ka Ọlọrun si to ti tẹ́lẹ̀ mọ bikose wipe ohun asán aiye nikan ni nwọn nwò.... "Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalẹmu, "O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati adaba ni tẹmpili ati awọn onipasiparọ owó jòkó: "O si fi okun tẹrẹ se pàsán, o si le gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si da owo awọn onipasiparọ owo nù, o si bi tabili wọn subu. "O si wi fun awọn ti nta adaba pe, ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ mase sọ ile Baba mi di ile ọjà títà" (Jhn. 2:13-16 tun wo Lk. 19:46; Mk. 11:15) Tità rírà to gba ọkan iru awọn eniyan wọnyi kan, kò jẹ́ ki nwọn o tilẹ ronu nipa ọrọ ijọba na ti afurungbin na nsọ, nigbati afurungbin na ba nsọrọ nipa Kristi Jesu ati ijọba Rẹ, nse lawọn eniyan na yio mã ronu nipa ohun ti wọn fẹ́ tà, nse ni wọn yio ma ronu nipa ohun ti wọn fẹ́ rà, ọkan wọn kò ni se dede pẹlu afurungbin na, ọkan wọn kò tilẹ ní sí nibi ọrọ ti afurungbin nã nsọ. Se nitotọ awọn miran tilẹ wa si tẹmpili tabi ilé ìjọ́sìn nã lati ta ọja ni, awọn miran wá lati pade onisowo nla kan ni, sugbọn wọn kò wá nitori ọrọ ijọba Ọlọrun. Ki ise ohun to buru bi onisowo nlá ba wa ninu ijọ kan ti awọn kan wa pade rẹ ninu ijọ na, sugbọn ohun to buru ti a ntọka si ni wipe ọpọlọpọ iru awọn ti nwọn nwa wọnyi ọkàn wọn kò sí ninu ọrọ Ọlọrun to njade lọjọna bikose nipa bi wọn yio se ri iru awọn eniyan nla na lati gbé isẹ nla fun wọn, lati fun wọn lowo nla... nitorina ni gbogbo igbati oniwasu na ba nwasu eleyi ni yio ma lọ ti yio ma bọ̀ lọkan wọn ti ọkan wọn kò sì ni papọ̀ si ọrọ Ọlọrun na, ti ọkan wọn kò ní ronu nipa ọrọ na ki a ma tilẹ wa wipe gbígbé e yẹ̀wò ati yiyípadà. Irufẹ eleyi na lo ma nsẹlẹ si awọn olósèlú, ọpọ awọn to ntẹle wọn lọ si ijọ ti nwọn nlọ, wọn ko lọ sibẹ lati lọ gbọ ọrọ Ọlọrun bikose lati fi ara wọn han gẹgẹbi ẹnito ntẹle ati ẹnito nse ti oloselu na, nitorina ọrọ gbogbo ti oniwasu ba nsọ ni ọjọ na kò ní kàn wọ́n, nse ni ọn yio ma da ọrọ na nù tí nwọn ko si ni sisẹ́ lori rẹ eleyi na lo fàá ti ayipada to dabi alárà kò se sí ninu eto isejọba wa lorilẹ ede Naijiria, eredi niyi ti ẹsẹ ati okunkun se ngbilẹ si, bi o tilẹ jẹ wipe ọ̀pọ̀ awọn oloselu wa gbogbo fi ara han gẹgẹbi "ẹlẹ̀sìn". Ti mba ni ki nsọ nipa ti awọn alakọwe nkọ? Ani awọn olùkọ́ ati awọn akẹkọ wọn? Awọn olukọ ti wọn ni ijọ tabi da ijọ silẹ yio ma fi eleyi pe awọn ọmọ ile iwe, ani awọn akẹkọ labẹ wọn lọ sínú ijọ tiwọn. Ọpọ awọn akẹkọ lo ma ndarapọ mọ ijọ wọn, ki ise nitoripe aiye wọn ti yipada, sugbọn nitori ati wá ojurere awọn olukọ wọn boya ninu idanwo tabi ninu iwadi wọn ti nwọn yio se fun ile-iwe na (Project work).... Awọn eniyan miran a ma lọ siru awọn ìjọ bayi, ki ọmọ wọn bà á le ri ile iwe giga wọ̀ kíá-kíá nigbato ba pari ile iwe mẹwa.... Otitọ ni wipe awọn eniyan pupọ nlọ sinu ijọ na nitori olukọ na, sugbọn won ko lọ lati le ri ayipada, wọn ko lọ lati le mọ ìfẹ́ Ọlọrun siwaju ati siwaju sí i. Wọn ngbọ ọrọ na nitotọ, sugbọn lojukanna ti wọn ngbọ́ ọ ni wọn nda ọrọ nã nù. Kò si igba kankan ti irufẹ awọn eniyan wọnyi dé ikorita ti awọn pẹlu ti sọ gẹgẹbi awọn Samaria wipe otitọ ni wipe nitori tiyin ni mo se nwa si ijọ yi tẹlẹ... sugbọn lẹhin igbati mo de emi pẹlu wá dá Ọlọrun mọ funra mi. "Nwọn (awọn ara Samaria) si wi fun obinrin nã pe, ki ise nitori ọrọ rẹ mọ li awa se gbàgbọ́: nitoriti awa tikarawa ti gbọ ọrọ rẹ, awa si mọ pe, nitotọ èyi ni Kristi nã, Olugbala araiye" (Jhn. 4:42) Títà rírà to nkọja lori ilẹ irufẹ ọkan awọn eniyan wọnyi, tita-rira lati wọ ile iwe giga Yunifasiti, Polytechnic (gbogbonse) abbl ko jẹ ki ọrọ Ọlọrun ti nwọn ngbọ́ kó yé wọn.... Tità-rirà to nlọ lai dawọ duro lori ọkan irufẹ awọn eniyan wọnyi lati di ìlú-mọ̀míká oloselu, lati gba Kọntirati (contract) nla jẹ ki nwọn o yigbì ni aiya ti nwọn kò si gbàgbọ́.... Irú tita rira wo na lo mbọ lọ́kàn awa na bi a tise wà yi, eleyi ti ko jẹ ki ọrọ na ti a ngbọ gbogbo kó yé wa? Sé tita-rira ati lọ silu eyibo ni? Se tita rira lati lọkọ tabi ni aya ni? Se tita rira lati pari Yunifasiti tabi Poly ni? Se tita rira ati bimọ ni? Iru tita rira wo ni ko jẹ ki awọn ọrọ ti a ngbọ se wa ni anfani? Gbogbo awọn tita rira wọnyi ni a nilati fi silẹ ki a si di titun ninu ero ati ise wa. "Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bẹ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ, itẹwọgba, eyi ni isẹ-isin nyin ti o tọ̀nà. "Ki ẹ ma si da ara nyin pọ mọ aiye yi: Sugbon ki Ẹ PARADA LATI DI TITUN NI IRO-INU NYIN, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si se itẹwọgba, ti o si pe" (Rm. 12:1-2) (13) Wọ́n wà ninu òwúsúwusù ati okunkun birimu birimu aiye (lack of understanding) nitori a-ó-dà-a-ó-dà ile aiye (I want to become this, I want to become that...aspiration and pursuit to become something in life did not let them understand the word) "Nitorina mo wi fun nyin, ẹ mase se aniyan nitori ẹmi nyin, ohun ti ẹ o jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmi ko ha ju onjẹ lọ? Tabi ara ko ha ju asọ lọ? "Tani ninu nyin nipa aniyan sise ti o le fi ìgbọnwọ kan kun ọjọ aiye rẹ? "Njẹ bí Ọlọrun bá wọ koriko igbẹ li asọ bẹ́ẹ̀, eyiti ó wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li asọ, ẹnyin onikekere igbagbọ? "Nitorina, ẹ mase se aniyan, wipe, kili a o jẹ? Tabi, kili a o mu? Tabi, asọ wo li a o fi wọ wa?" (Mt. 6:25, 27, 30-31) Nitori a-ó-dà, a-ó-dà nile aiye ni kò jẹ ki ọrọ Ọlọrun na o ye awọn eniyan ti nwọn ni ọkan to dabi ilẹ tó wà lẹba ọna yi. Ọpọlọpọ awọn eniyan wọnyi, bi o tilẹ jẹ wipe wọn nwa sinu ijọ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn nka bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe wọn nka oniruru iwe iwasu gbogbo, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ngbọ iwasu lori amohunmaworan, ati lori ẹrọasọrọmagbesi, redio..., sugbọn sibẹ̀ ko yé wọn nitori ilepa ati da nkan ti ẹnikan ko da ri ninu aiye. "O si se, bi nwọn ti nlọ, o (Jesu) wọ ileto kan: obinrin kan ti a npe ni Marta si gbà á si ile rẹ. "O si ni arabinrin kan ti a npe ni Maria, ti o joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ ọrọ rẹ. "Sugbọn Marta nse iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wa, o ni, Oluwa, iwọ ko kuku su si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan se aisinmi? Wi fun un ki o ran mi lọwọ. "Sugbọn Jesu si dahun, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nse aniyan ati lãlã nitori ohun pupọ: "Sugbọn ohun kan li a ko le se alaini. Maria si ti yan ipa rere náà ti a ko le gbà lọwọ rẹ" (Lk. 10:38-42) A o ri ninu iwe ihinrere ti onisegun Luku yi wipe Marta nitori a-ó-dà, a-ó-dà ile aiye, o nfẹ tẹ́ Jesu lọrun, o nlọ, o mbọ lati pese ounjẹ, sugbọn ó da ọrọ Ọlọrun nù, ko tilẹ wò ó rara.... Nigbati Maria joko lẹba ẹsẹ Jesu to si ngbọ ọrọ Ọlọrun to nfetisi ẹ̀kọ́ rẹ to si nse ipinnu lati mú u lò. Njẹ kì í ha ise ohun to nsẹlẹ si awa nã niyi? Nitori ki a le mã dáwó daradara ni Sọsi, nitori ki a lè ra ọkọ̀ fun olusọagutan, nitori ki a le ran awọn ọmọ opó nile iwe, nitori ki a lè mã fun àwọn opó to mbẹ ninu ijọ wa lowo ni kò jẹ ki a ri aye fun ọrọ Ọlọrun mọ, eleyi ni ko jẹ ki a ri aye fun adura mọ, eleyi ni ko jẹ ki awọn iwọnba ọrọ Ọlọrun péréte ti a ngbọ gãn kó yé wa mọ. A-ó-dà, a-ó-dà ni gbogbo eleyi. Otitọ ni wipe a nilo owó fun itẹsiwaju ihinrere, a nilo owo lati mã tọjú awọn opó ati awọn alaini ninu ijọ wa, sugbọn awọn eleyi a ò gbọdọ gba wọn laye lati gbá ọrọ Ọlọrun sẹgbẹ kan ninu aiye wa, a ò gbọdọ gba eleyi laye lati sọ wá di òpè ninu Kristi Jesu ati ọrọ rẹ, a ò gbọdọ gba eleyi laye lati sọ wá di alailoye ninu ọrọ afurungbin na. Isẹlẹ afiyesi pataki kan sẹlẹ ninu iwe Ise Awọn Aposteli ori karun, isẹlẹ na ni ti Anania pẹlu Safira aya rẹ. Ohun ti ko farasin ninu akọsilẹ nã ni wipe nitori a-ó-dà, a-ó-dà awọn tọkọ-taya yi, wọn di etí wọn si ohùn kẹ́lẹ́-kẹ́lẹ́ ti Ẹmi Mimọ mba wọn sọ, wọn ko gba ọrọ ti awọn aposteli mba wọn sọ laye lati yé wọn, eleyi to mu iparun aiyeraiye wa fun wọn. Njẹ kini awa na nlepa lati dà ti ko jẹ ki ọrọ Ọlọrun gbogbo ti a ngbọ́ kó ye wa? Kini awọn aniyan wa gbogbo ti a fi gbá ọrọ Ọlọrun tì si ẹgbẹ kan? Gbogbo bi o tilẹ se le wù ki awọn nkan wọnyi o ma se alai dára tó, nse ló yẹ ki a se bi Maria, ki a fi arabalẹ ma gbọ ọrọ nã, ki a si ma fiyesi wọn. (14) Ìlépa pupọ kò jẹ ki ọrọ Ọlọrun o yé awọn eniyan ti nwọn ni ọkan to dabi ti ilẹ ẹ̀bá ọ̀nà yi. "Sugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ sinu idanwo ati idẹkun, ati sinu were ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã ri enia sinu iparun ati ègbé" (1 Tim. 6;9) Ilepa pupọ nipa ati da nkan ninu aiye ki i jẹ ki ọrọ Ọlọrun o ye irufẹ awọn eniyan ti nwọn ni ọkan to dabi ilẹ ẹ̀bá ọna yi. Ilepa lati di ọlọrọ, ilepa lati jẹ olori ninu ijọ ati larin ilu ati lorile ede ki i jẹ ki ọrọ Ọlọrun o ye wọn. "Emi kọwe si ijọ: sugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, ko gbà wá. "Nitorina bi mo ba de, emi o mu isẹ rẹ ti o se wa si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa; ẹyini ko si tẹ́ ẹ lọrun, bẹni òn tikararẹ ko gba awọn ara, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o nda wọn lẹkun, o si nle wọn jade kuro ninu ijọ" (3 Jhn. 1:9-10) Ifẹ lati jẹ olori ijọ mu ki Diotrefe o ma se bose wù ú, eleyi pẹlu lo mu kí ó sé ọkan rẹ le si Ọrọ ihinrere nã. Nitori ati jẹ olori nse lo nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ lojojumọ si awọn to jù ú ninu ẹmi, nitori ati jẹ olori o sé ilẹkun ile rẹ mọ awọn alejo ati ará, kò gba alejo, ohun tó tun wa se pabambari ni wipe kò gbà ki awọn miran ti wọn fẹ se ãnu ti wọn si tun nfẹ gba awọ̀n alejo awọn ara ó gbà wọn ni alejò sile wọn... eleyi lo nse nigbakugba tobẹ gẹ ti ọrọ Ọlọrun ko fi yé e mọ. Lẹhin igbati Solomoni ọba Israeli kú awọn eniyan ko ara wọn jọ lati fi ẹ̀hónú han si Rehoboamu ọmọ Solomoni toun na ti gun ori àpèré awọn baba nla rẹ gẹgẹbi ọba lori Israeli. Wọn si wi fun ọba titun na, Rehoboamu, pe otitọ ló dàbí igbati asiko baba rẹ tu ilu wá lara, nitoripe a ò ba awọn ara ita jagun, sugbọn ko si itura pupọ ninu ijọba baba rẹ nitoripe ara kò tu awa ti a wà ninu ile. "Rehoboamu si lọ si Sekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Sekemu lati fi i jẹ ọba. "O si se, nigbati Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o wà ni Egipti sibẹ gbọ, nitori ti o ti sá kuro niwaju Solomoni ọba, Jeroboamu si joko ni Egipti. "Nwọn si ransẹ pè é, ati Jeroboamu ati gbogbo ijọ Israeli wá, nwọn si sọ fun Rehoboamu wipe, "Baba rẹ sọ ajaga wa di wuwo: njẹ nitorina, se ki isin baba rẹ ti o le, ati ajaga rẹ ti o wuwo, ti o fi si wa li ọrun, ki o fẹrẹ diẹ, awa o si sin ọ" (1 A. Ọba 12:1-4) Wọn jẹ ki ọba titun na, Rehoboamu, mọ wipe ara ni àwọn ninu ijọba baba rẹ, ki o ba awọn dín ìnira na kù.... Ọba dá ìgbà fun wọn lati wa gbọ esi, nigbati awọn eniyan na de, esi ti ọba fun wọn kò dùn mọ́ wọn, nitorina, awọn ẹ̀yà mẹwa ninu mejila ya kuro wọn si lọ dá duro, wọn yan Jeroboamu, ọmọ Nebati lati jẹ ọba wọn. Lẹhin igbati ọba Jeroboamu di ọba tan, ó rò ninu ara rẹ wipe awọn eniyan na le padà lọ ba Rehoboamu ọba Juda, nitorina ó gbé awọn ètò ati ilana kan kalẹ ti eleyi ko fi ni sese fun awọn eniyan Israeli na lati pada lọ si ọdọ ọba Juda to njẹ Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọmọ Dafidi. "Jeroboamu si wi li ọkan rẹ pe, nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi. "Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati se irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalẹmu, nigbana li ọkàn awọn eniyan yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mí, nwọn o si tun pada tọ Rehoboamu, ọba Juda lọ. "Ọba si gbìmọ̀, o si ya ẹgbọrọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, o pọju fun nyin lati ma goke lọ si Jerusalẹmu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wa! "O si gbe ọkan kalẹ ni Bẹteli, ati ekeji li o fi si Dani. "Nkan yi si di ẹ̀sẹ̀: nitoriti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani. "O si kọ ile ibi giga wọnni, o si se alufa lati inu awọn enia, ti ki ise inu awọn ọmọ Lefi" (1 A. Ọba 12:26-31) Nitori ilepa lati wa ni ọba lori Israeli ni ọba Jeroboamu se pa ilana ati ofin Ọlọrun tì tí o sì da ere fun awọn eniyan lati ma sìn, Jeroboamu ọba mu awọn eniyan Israeli sẹ̀ si ofin kinni ninu ofin Mose woli ti o wipe, "Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi" (Eks. 20:3) Ọba Jeroboamu mu ki awọn eniyan na pa Ọlọrun tì lati lọ mã sin orisa. Jeroboamu ọba ti gbagbe wipe Ọlọrun lo ran oun lọwọ lati gun ori oye nã, o ti gbàgbé wipe láì bá si ti Ọlọrun ni, o sese ki oun ti kú. Sugbọn nitori ilepa lati da nkan, nitori ilepa ati fi idi ara rẹ mulẹ gẹgẹbi ọba, ó wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi se àdá, o lọ da ọgbọ́n sí i. Melomelo awọn iransẹ Ọlọrun, awọn alufa, awọn woli, awọn ajinhinrere...lo ti kó awọn eniyan sìnà loni nitoripe wọn nfẹ lati lorukọ ninu ijọ, wọn nfẹ lati wà ni ipò adari ni irandiran wọn, wọn nfẹ fi ọgbọ́n mu awọn eniyan mọ́lẹ̀ sinu ijọ wọn. Nitori ati se eleyi awọn pẹlu yio gbé eto ati ilana kalẹ ti ko ba ihinrere mu, bẹ sini wọn yio sọ wipe Ọlọrun ló paá lasẹ fun awọn lati gbe irufẹ ètò bẹ kalẹ̀ tabi wipe Ẹmi Mimọ ló bá awọn sọrọ bẹ́ẹ̀. Awọn etò miran, ati awọn ọrọ miran ti awọn miran nsọ ti wọn si ngbe kale ló má a nhàn wipe ko si ni ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun, sugbọn sibẹ wọn yio yí i mọ Ọlọrun. Nigbati gbogbo eniyan bá sì ti tẹ́wọ́ gbàá, wọn yio ma sọ wipe tó bá jẹ wipe ko si ni ibamu pẹlu ọna Ọlọrun ni, awọn eniyan ìbá tí í tẹwọ gbà á. Awọn ilepa wọnyi ma nmu ki òye ọrọ Ọlọrun o má ye awọn eniyan tobẹ gẹ ti Esu yio si fi wa lati wa mu irugbin na kuro lọkan awọn eniyan na.... Sebí kò kúkú yé wọn tẹlẹ. (15) Wiwò ti awọn to ni ọkan to dabi ilẹ tó wà lẹba ọna na nwo awọn ẹlomiran ko jẹ ki ọrọ afurungbin nã ó yé wọn. Lọpọ igba ti awa ajihinrere ojúlé dé ojúlé ba jade lọ lati wasu, nigbati a bá mba awọn èniyan meji tabi mẹta ti nwọn jọ jẹ ọrẹ tabi ti wọn jọ nsere sọrọ papọ, o ma n nira fun awọn eniyan wọnyi lati se ipinnu, o ma n nira fun wọn lati fi aye wọn fun Kristi Jesu. Èrè ìdí ni wipe ẹnikini yo ma woju ẹnikeji lati mọ ohun ti ẹni na yio se, bi wọn yio se ma wo ara wọn ni eleyi ti nwọn ko si ni yipada si Kristi Jesu. Nigbati ẹlomiran bá sì se eleyi lọjọ na ti kò yipada, ẹni na le è ma ri ọjọ́ keji, tabi o tilẹ sese ki ẹni na ma ni ju wakati melo kan lọ ti yio lò si mọ laiye. Nitori wiwo ti ẹni na nwo eniyan, ẹni nã yio padanu ọkàn ati aye rẹ si ọrun apadi, nitoripe, "Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹkansoso, sugbọn lẹhin eyi idajọ" (Heb. 9:27) Wíwò ti ẹni na nwo awọn ẹlomiran yio mu ki ọrọ Ọlọrun ti ẹni na ngbọ o mase ye ẹni na. Bi awọn ọ̀rẹ́ mẹta tabi jubẹlọ ba lọ si isọji tabi ile ijọsin lati lọ gbọ iwasu, iru eleyi na lo ma nsẹlẹ sí wọn ti yio si mu ki nwọn o sé aiya wọn le, ti nwọn ko si ni yipada, ti wọn ko si ni di ẹni igbala. Ninu iwe ibẹrẹ ohun gbogbo ti a npe ni Gẹnẹsisi a kà nipa tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan ti wọn se ohun ti ko tọna, eleyiun ni ni bibá baba wọn sùn, ti wọn si tipasẹ bẹ loyun ti nwọn si bi ọmọ fun baba wọn. Ninu iwe yi, ohun tó hàn gbangba ni wipe nse ni aburo wo ohun ti ẹ̀gbọ́n sẹ se lati se eleyi. "Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji pẹlu rẹ; nitoriti o bẹru ati gbe Soari: o si ngbe inú ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji. "Eyi akọbi si wi fun atẹle rẹ pe, baba wa gbó, kò sì sí ọkọnrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ wa wa gẹgẹ bi ise gbogbo aiye. "Wa, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sun ti i, ki a lè ni iru-ọmọ lati ọdọ baba wa. "Nwọn si mu baba wọn mu ọti waini li oru nã, eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sun ti baba rẹ; on ko si mọ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. "O si se, ni ijọ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sun ti baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sun ti i, ki awa ki o le ni iru-ọmọ lati ọdọ baba wa. "Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sun ti i, on ko si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. "Bẹni awọn ọmọbinrin Lọti mejeji loyun fun baba wọn" (Gen. 19:30-36) Awọn nkan ti awọn omidan-binrin mejeji ti ri ti awọn eniyan nse ni Sodomu ki Ọlọrun tó gba wọn kuro ni ilu nã ti Ọlọrun si pa ilu nã run ni awọn mejeji pinnu lati se yi.... Boya eyi aburo kì bá ma se eleyi, sugbọn nigbati o ri wipe ẹgbọn oun se aseyọri lori rẹ, oun pẹlu kò bèsù-bẹ̀gbà lati se é. Wíwò ti aburo wo èyí ẹgbọn-ọn rẹ mu ki aiya rẹ séle, o mu ko se gẹgẹbi ẹgbọn rẹ na tise pẹlu. Bi ọpọ awọn miran ti ma nse na ni eleyi pẹlu, ti wọn se ma ndi ibajẹ, ti wọn se ma ndi ẹni ẹgbin, ti wọn yio si wá yan agbere ati pansaga láàyo. Nigbati omidan ti ko i ti mọ ọkọnrin ri ba nro wipe ọjọ nlọ lori oun, ti ẹnito ro wipe oun nfẹ sì sọ wipe ko jẹ kawọn ni ibalopọ ki awọn tó fẹ́ ara awọn, ko jẹ ki awọn ni ibalopọ lati fihan wipe lotitọ ati lododo ló nifẹ oun, rironu wipe ọjọ nlọ yio mu ki ẹni na o gbe ọrọ Ọlọrun tì sẹgbẹkan ti yio si subu sinu ẹ̀sẹ̀ nla yi..., rironu wipe ko si ẹlomiran tó lè dabi lagbaja tabi tamẹdun yio mu ki awọn miran o subu sinu iru ẹsẹ yi gẹgẹbi awọn ọmọbinrin sese. A ó ri mọ wipe awọn ọmọbinrin Loti wipe, "kò si si ọkọnrin kan li aiye mọ́". (Gen. 19:31b) Irọ patapata ti Satani fun irugbin rẹ si ọkan awọn omidan na lo jade to si mu ki aiya wọn séle si ọna ati igbala Ọlọrun. Tó bá jẹ wipe Rutu na wo Orpa ni, oun pẹlu ìbá ma se iru orire to se laiye (Rutu 1). To ba jẹ wipe ìkan lara awọn olè ori igi wo ẹnikeji rẹ ni, oun pẹlu iba sé aiya rẹ le ti iba si pari irin ajo rẹ si ọ̀run apadi. "Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi se ẹlẹyà wipe, bi iwọ ba se Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. "Sugbọn eyi ekeji dahun, o mba a wi pe, iwọ ko bẹru Ọlọrun, ti iwọ wa ninu ẹbi kanna? "Niti wa, nwọn jare nitori ere ohun ti a se li awa njẹ: sugbọn ọkọnrin yi kò se ohun buburu kan. "O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ. "Jesu si wi fun u pe, lotọ ni mo wi fun ọ, loni ni iwọ o wa pẹlu mi ni Paradise" (Lk. 23:39-43) Bi awa nã ba nwo eniyan lori ọrọ ati fi aye wa fun Jesu, o daju wipe a ò ni gba Kristi Jesu gbọ. Bi a ba ngbé igbagbọ wa lori ti ẹlomiran, o daju pe a ò ni gba Jesu gbọ. Bi omidanbinrin kan ba nwo ọrẹ rẹ, o sese ko ma lọ́kọ laiye, nitoripe eniyan yàtọ si arã wọn. Wíwò ti iru awọn eniyan ti nwọn ni ọkan to dabi ilẹ ẹba ọna yi nwo awọn miran, ani ni pataki julọ awọn alaigbagbọ ati alafara eniyan n mú ki ọro Ọlọrun ti awọn afurungbin nfun ó má se yé wọn. (16) Nitoripe awọn eniyan ti nwọn ni iru ọkan to mbẹ lẹba ọna yi nfẹ fi ogún tabi ọrọ̀ silẹ fun awọn ọmọ wọn, eleyi ma nmu ki òye ọrọ Ọlọrun o mase ye awọn miran. "Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ nyin wa; emi ki yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wa nkan nyin, bikose ẹnyin tikarayin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati ma to isura jọ fun awọn obi wọn, bikose awọn obi fun awọn ọmọ wọn" (2 Kọr. 12:14) Ohun to daju ni wipe gbogbo òbí lo ma ngbadura to si ma nfẹ ki awọn o fi nkan silẹ de ọmọ awọn. Ohun tó tún daju miran ni wipe ki ise gbogbo wọn lo nle se eleyi, fun oniruru ìdí. Sugbọn awọn miran nitori ìlàkàkà ati ìlépa lati se eleyi wọn a ma gbagbe ọrọ Ọlọrun ki nwọn o ba à le mu ipinnu na sẹ. Saulu ọba àkọ́kọ́ ni Israeli nitori ati fi ogun silẹ fun awọn ọmọ rẹ, ani ati ni pataki julọ nitori ati ri wipe Jonatani ọmọ oun lo gun orí oyè lẹhin oun bẹrẹ sini gbógun ti Dafidi, o bẹrẹ sini se ohun ti ko bojumu tobe to tun fi pada sinu ẹsẹ biba òku sọrọ. "Saulu si wi fun awọn iransẹ rẹ̀ pe, ẹ ba mi wa obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọrọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iransẹ rẹ si wi fun u pe, wo, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọrọ. "Saulu si pa ara dà, o si mu asọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkọnrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wa si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ ọ, fi ẹmi abokusọrọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ fun ọ wa oke fun mi" (1 Sam. 28:7-8) Ọlọrun tun wi nibomiran bayi wipe, "Ki a mase ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkọnrin, tabi ọmọ rẹ obinrin la ina ja, tabi ti nfọ afọsẹ, tabi alakiyesi-igbà, tabi asefaiya, tabi ajẹ, "Tabi atuju, tabi abá-iwin-gbimọ, tabi oso, tabi abokulo. "Nitoripe gbogbo awọn ti nse nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi si ni OLUWA Ọlọrun rẹ se lé wọn jade kuro niwaju rẹ" (Deut. 18:10-12) Bi awa na ba nlepa lati fi ogún silẹ fun awọn ọmọ wa lọnakọna, a ò ni se alai gbe ọrọ Ọlọrun tì si ẹgbẹ kan lati mu ifẹ ti ara wa sẹ. (17) Irugbin ti afurungbin na fun nitoripe ó wà lẹba ọna, awọn kan ko wọnu ilẹ̀ nibẹ̀, wọn farahan nita, eleyi to mu ki ẹiyẹ na le rí i ti o si fi sà á jẹ.... Awọn ọrọ Ọlọrun ti iru awọn eniyan wọnyi ngbọ, nse ni wọn yio tun lọ fi tó ẹlomiran leti, wọn yio lọ bere ìmọ̀ràn lori ọrọ nã nitoripe wọn nro wipe igbagbọ ko yẹ ko le to bẹ, nitoripe wọn nro wipe ofin ati ilana nã ti le ju. Nigbati awọn ti wọn lọ ba nã yio ba gbà wọ́n nimọran, awọn miran yio gbà wọn nimọran to lodì si ti ọrọ Ọlọrun, eleyi ti yio fi wọn sinu okunkun sibẹ. Bi ọrọ afurungbin na kò bá ye eniyan, boya ọrọ nipa bi onigbagbọ se nilati ma wọ asọ, boya ọrọ nipa bi ọmọbinrin se nilati ma mura, boya ọrọ nipa bi idile se yẹ kori; boya ọrọ nipa ibukun abbl. Nse lo yẹ ki eniyan lọ si ọdọ olusọagutan rẹ tabi ẹniti eniyan mọ wipe o jẹ ojulowo onigbagbọ fun ẹkunrẹrẹ alàyé lori awọn ọrọ nã, ki íkàn ise ẹnikẹni ni eniyan le tọ̀ lọ fun alaye lori ọrọ nã. Nigbati Absalomu gba ìmọran miran lori ọrọ Dafidi baba rẹ, eleyi lo fa ti ko fi se aseyọri. "Imọ Ahitofeli ti imá gba nijọ wọnni, o dabi ẹnipe enia mbere nkan li ọwọ Ọlọrun: bẹni gbogbo imọ Ahitofeli fun Dafidi ati fun Absalomu si ri" (2 Sam. 16:23) Ẹ jẹ ka gbọ ohun to sẹlẹ ni ori kẹtadinlogun iwe Samueli keji nã. "Absalomu si wipe, njẹ pe Husai ara Arki, awa o si gbọ eyi ti o wa li ẹnu rẹ pẹlu. " Hudai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o se bi ọrọ rẹ̀ bi? Bi ko ba si tọ bẹ, iwọ wi. "Husai si wipe, iwọ mọ baba rẹ ati awọn ọmọkọnrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkan bi amọtẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkọnrin, ki yio ba awọn enia na gbe pọ li oru. "Kiyesi i o ti fi ara rẹ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si se, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ subu, ẹnikẹni ti o ba gbọ yio si wipe, iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ Absalamo lẹhin. "Ẹniti o si se alagbara, ti ọkan rẹ si dabi ọkan kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara. "Nitorina, emi damọran pe, ki gbogbo Israeli wọjọ pọ sọdọ rẹ, lati Dani titi di Beerseba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọpọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na. "Absalomu ati gbogbo ọkọnrin Israeli si wipe, imọ Husai ara Arki sàn ju imọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi imọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wa sori Absalomu" (2 Sam. 17:5-11 & 14) Bi awa na ba gba imọran miran lori ọrọ igbala, o daju wipe a ò ní ní igbala ti a o si pari irin ajo wa si ọrun apadi. Nitoripe ọrọ ti awọn eniyan wọnyi ngbọ ko ye wọn ti nwọn sì tun lọ gba imọran lọdọ awọn eniyan miran, eleyi mu ki nwọn o túbọ̀ wa ninu okunkun sí i. (18) Nigbati iru awọn eniyan ti nwọn ni ọkàn to dabi ti ẹ̀bá ọna wọnyi ba lọ yọku wo ìse ati iwà awọn alaigbagbọ, eleyi yio jẹ ki aiya wọn o séle tobẹ ti nwọn ko si fi ni yipada. "Dina ọmọbinrin Lea, ti o bi fun Jakọbu si jade lọ lati wo awọn ọmọbinrin ilu nã" (Gen. 34:1) Ohun ti Dina lọ wo lo mu ki wahala o de ba, eleyi lo mu ki ẹsẹ o wọle, ti ogun si bẹrẹ larin awọn ọmọ baba rẹ ati ilu ti nwọn ngbe. Wiwo ise ati iwa awọn alaigbagbọ a mã mu ki ọrọ Ọlọrun o ma ye eniyan nigbamiran, ere idi niyi ti aposteli Paulu se wipe, "Ki a mã wo Jesu olupilẹsẹ ati alasepe igbagbọ wa; ẹni, nitori ayọ ti a gbe ka iwaju rẹ, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ ọ̀tún itẹ Ọlọrun" (Heb. 12:2) (19) Lilọ sibiti awọn alaigbagbọ wa bi ile ọti; ibiti nwọn ti nmu sigá ati igbó; ile agbere; ibugbe awọn olè ati ọlọsà abbl. Eleyi le mu ki ọrọ Ọlọrun ti eniyan ngbọ o ma ye eniyan. "Ibukun ni fun ọkọnrin na ti ko rin ni imọ awọn enia buburu, ti ko duro li ọna awọn ẹlẹsẹ, ati ti ko si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgan" (Ps. 1:1) Ninu Iwe Owe bibeli wipe, "Asiwere nfi ẹbi ẹsẹ sẹsin" (Owe 14:19a) (20) Sise isẹ́ to le mu ki eniyan o wa ninu ewu àìgbagbọ gẹgẹbi ọtí tità, igbó tabi Kokeeni tita; asẹwo sise abbl le è mu ki ọrọ Ọlọrun ti eniyan ngbọ o ma ye eniyan. Iru isẹ ti awọn miran nse niyi, ti nwọn o si ma wipe sebi ki a ti ni owo ni, nigbati a bá si ni owo na tan isẹ ihinrere la o fise, a ó fi kọ ile ijọsin fun Ọlọrun ni, a ó mã fi san owo awọn olusọagutan ijọ wa ni abbl. Nigbati a bá si ti nronu bayi, a o ni ma ri ohun to buru ninu ẹsẹ dida, a o ma yigbì ni aiya, ọrọ Ọlọrun na ko si ni ye wa. Aposteli Peteru wi fun Simeoni wipe owo ko le ra ẹbun ati ore-ọfẹ Ọlọrun, nitorina ki owo rẹ sègbé pẹlu rẹ. "Sugbọn Peteru dá a lohun wipe, ki owo rẹ segbe pẹlu rẹ, nitoriti iwọ rò lati fi owo ra ẹbun Ọlọrun" (I. Apo. 8:20) Olọrun nfẹ ki a lowo, sugbọn saju ohun gbogbo Ọlọrun nfẹ ki a kọkọ fi ọkan wa fun oun na lati ipasẹ Kristi Jesu. "Ati eyi, ki ise bi awa ti ro ri, sugbọn nwọn tètèkọ́ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun" (2 Kor. 8:5) Isẹ ti irufẹ awọn eniyan ti nwọn ni ọkan wọn lẹba ọna yi nse ma ngba ọrọ Ọlọrun sẹgbẹ kan laiye wọn, ti nwọn yio si jẹ alaigbagbọ sibẹ. (21) Kikọ ilé sibito lewu, nipasẹ eleyi wọn ma nwà nipo àìloye nipa ọrọ Ọlọrun. Awọn miran ko bikita nipa ibiti wọn fẹ kọ ile si, wọn yio lọ ra ilẹ sẹgbẹ ile awọn asẹwó, wọn yio lọ kọ ile si ẹ̀gbẹ́ ẹ "hotẹli", wọn yio lọ gba ile si ẹgbẹ awọn to nta ọtí, nipasẹ eleyi wọn yio mã ri ìríkuri lojojumọ, wọn yio ma gbọ igbọkugbọ, awọn ọmọ wọn na yio ma ri awọn eleyi na pẹlu tobẹgẹ ti ọkan wọn yio fi yigbì, tobẹ gẹ ti ọrọ Ọlọrun na ko fi ni ye wọn mọ. (22) Sise àfarawé kì í jẹ ki ọrọ Ọlọrun na o yé awọn ti ọkan wọn dabi ilẹ ẹ̀bá ọna. Nigbati awọn ọmọ Israeli wo iwa ati ise awọn orilẹ ede ti o yi wọn ka, awọn na wipe awọn nfẹ dabi tiwọn, nitorina wọn lọ ba olori Alufa ati woli Samueli wipe ki o yan ọba fun wọn gẹgẹbi awọn orilẹ ede ati ilu gbogbo to yíwọn ká. "Gbogbo awọn agba Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama. "Nwọn si wi fun u pe, kiyesi i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ ko si rin ni iwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma se idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ede" (1 Sam. 8:4-5) Nigbati awọn eniyan wọnyi bere fun ọba gẹgẹbi awọn orilẹ-ede alaigbagbọ gbogbo tó yí wọn ka, Ọlọrun wi fun iransẹ rẹ, woli Samueli, wipe ki ise oun-Samueli-ni wọ́n kọ̀ bikose Oun, Ọlọrun.... Wọn ri ohun ti nwọn nfẹ, eleyiun ni ni ọba, sugbọn lati igbana ni ètò isejọba ilẹ Israeli ti wọnu wahala lọ. Nigbati awa na ba nfẹ se bi ọmọ aiye, ohun to daju ni wipe idamu ati wahala to mba awọn ọmọ aiye na yio ma ba awa na jà. "Bayi li Oluwa wi, ẹ mase kọ iwa awọn Keferi, ki ami ọrun ki o ma si damu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ede" (Jer. 10:2) Sise afarawe awọn eniyan ani ni pataki julọ awọn alaigbagbọ gbogbo yio mu ki oye ọrọ Ọlọrun na o mase yé wa. Awọn miran si wa to jẹ wipe ki ise alaigbagbọ ni wọn nse afarawe wọn bikose onigbagbọ, sugbọn sise afarawe awọn eniyan wọnyi nigbamiran ma nmu ki oye ọrọ Ọlọrun o ma ye eniyan nigbamiran, sise afarawe wọn ma nfa wahala sinu aiye eniyan. Fun apẹrẹ awọn miran a wipe awọn la àlá ohun bayi, bayi sẹlẹ, bi awọn si se jí saiye na ni ohun na sẹlẹ̀.... Awọn miran yio wipe awọn gbọ́ ohùn kan wipe ki awọn se nkan kan tabi ki awọn mase se nkankan, wọn yio wipe nigbati awọn si tẹlé tabi gbọran si ohùn na ni iyanu ti bẹrẹ sini sẹlẹ.... Fun idi eleyi ọpọ awọn onigbagbọ tikarawọn yio ma duro de àti lá àlá tabi ati gbọ ohùn kan ninu etí i wọn kótó di wipe wọn gbe igbesẹ kan tabi omiran, se nitotọ awọn miran a ma wà ni irufẹ ikorita yi fun ọpọ ọ̀sẹ̀, ọpọ osu tabi ati ọpọ ọdún... lẹhin o rẹhin wọn ko si tun ni la àlá tabi gbọ ohun kankan lori irufẹ ohun na.... Ẹ mase sìmí gbọ ki ise wipe lílá àlá ko dara tabi gbigbọ ohùn kò dara, nitoripe pẹlu ore-ọfẹ Ọlọrun emi pẹlu ni iru awọn ẹ̀bùn wọnyi, sugbọn ìrírí ti fihan mi wipe oniruru ọna ni Oluwa Ọlọrun Eledumare fi mã mba eniyan lò, a ní lati mọ wipe gẹgẹbi awọn ti a nbi se yatọ si ara wọn, ti a si mba onikaluku lò lọ́nà ọ̀tọ̀tọ̀, bẹ pẹlu ni awa ọmọ Ọlọrun gbogbo na jẹ́ lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun pẹ̀lú si mba onikaluku wa lò ni ọtọ̀-ọ̀tọ̀, nitorina a ò nilati duro lori ọna kan, a o ni lati ma sọ wipe bi Ọlọrun tise bá lagbaja lò bẹna lo gbudọ ba awa na lò, ti o ba wu Ọlọrun o le lo ọnà kanna, ti o ba si tun wù u o le e lo ọna miran lati ba wa lo. Ohun to se pataki ni wipe a nilati ri daju wipe a wà ninu ifẹ rẹ, a nilati ri daju wipe ọmọ Ọlọrun ni wá. Gbogbo onka bibeli lo mọ wipe woli Elisa lo gba ipò woli Elija nigbati ó rí isẹpo meji agbara rẹ gbà, sugbọn sibẹ, a ò ri ninu gbogbo akọsilẹ woli Elisa pe angẹli Oluwa farahan tabi wipe Oluwa rọ̀jò iná le ori awọn ọta rẹ. Rara o. Sugbọn sibẹ isẹ iyanu nla ati awọn isẹ iyanu akanse se lati ọwọ woli na, gbogbo eniyan igba tirẹ lo mọ wipe woli ti Ọlọrun gbà fun ni.... A ò tún ni gbagbe wipe Josua lo gba ipo lọwọ woli Mose, bẹ sini woli Mose lo ọ̀pá lati se ọpọ isẹ iyanu, sugbọn bẹ kọ lo se ri fun woli Josua, oun ko lo ọpá lati se isẹ iyanu gẹgẹbi ọga rẹ, woli Mose, sugbọn oun lo ọrọ Ọlọrun lati se awọn isẹ nla ati isẹ alagbara gbogbo lasiko rẹ.... Ti a ba tun wo inu majẹmu titun, a o ri wipe bi Ọlọrun se ba aposteli Peteru lò yàtọ̀ si bi Ọlọrun tise ba aposteli Paulu lò, bẹ sini Ọlọrun kanna ni wọn nsisẹ fun, ihinrere kanna ni wọn npokiki rẹ.... Bi iwọ ati emi na tise npokiki Jesu loni, bi iwọ ati emi na tise jẹ apẹrẹ afurungbin na ninu ile wa, ninu ijọ wa, ni ayika wa, ni ilu wa, ninu ẹgbẹ́ wa abbl, a nilati ma mọ̀ wipe oniruru ọ̀nà ni Ọlọrun fi le ba eniyan lo, ti o ba wu Ọlọrun Eledumare O le è lo orisi ọna kanna ti o ba si tun wù u ẹwẹ o le e lo orisitisi ọna lati fi ba awa ọmọ Rẹ lò, nitorina, a ò nilati fojusọna si ọnà kansoso, a ko nilati ma rò ó wipe ọna ti Ọlọrun gba ba lagbaja lò ló dara julọ nigbati awọn ọna yoku ko dara tó. Nigbati a bá ti bẹrẹ sini ro eleyi, a o bẹrẹ sini gbe igbagbọ wa kuro ninu Ọlọrun, a o ma lepa lati fẹ dabi ti lagbaja, eleyi ti yio mu ki a jẹ́ àjèjì ati àlejò si ẹbun ati ore-ọfẹ Ọlọrun, eleyi ti yio mu ki aiya wa yigbì ti oye ọrọ na ko si ni yé wa mọ. Eleyi pẹlu wà ni ibamu pẹlu ọrọ ati ni ọkọ tabi ni aya, bẹ pẹlu ló nse pẹlu ohun gbogbo ti a bá fẹ́ yàn. Nitoripe ti a bá nro wipe nitoripe ọrẹ mi fẹ ọ̀mọ̀wé, o di dandan fun emi na lati fẹ ọmọwe, eleyi le mu ki aiya wa ó sé le ti ọkan wa yio si yigbì nipasẹ eleyi ti a ò fi ni ri awọn miran ti Ọlọrun nmu wa soju ọna wa lati fẹ́. Tabi boya a nro wipe ni Yunifasiti tabi ni "Polytekiniki" tabi boya lati ile iwe Girama ni wọn ti bẹrẹ sini fẹ ara wọn, ti awa na ba nse iru afarawe yi, ti a sì bẹrẹ sini fojusi wipe ọna ti iyawo wa tabi ọkọ wa nilati gba jade ni eelyi, a o tilẹkun ọkan wa mọ awọn ọna miran gbogbo ti Ọlọrun ngbà lati fi ba eniyan lò, tobẹgẹ to jẹ wipe a ó fi akoko wa sòfùn sugbọn ti a ó si ma di ẹbi ọrọ na ru Ọlọrun wipe oun ni ko dahun adura wa. Bẹ gẹgẹ ni to ba jẹ wipe a fẹ́ kọ́sẹ́, ti o ò mọ iru isẹ ti a fẹ kọ tabi iru eleyi to yẹ ki a yàn; tabi boya a fẹ lọ si ile iwe ti a o mọ iru "course" ti o yẹ ki a mu, ti a ba nronu wipe iru isẹ tabi iru "course" ti lagbaka se yi na ni o yẹ ki nse dandan, o le mu ki a sé ọkàn wa le, ki a si di alailoye nipa ọrọ Ọlọrun. Ohun to se pataki to si se kókó fun wa gẹgẹbi ọmọ Ọlọrun ni lati ri daju wipe a di ẹda titun ati lati ma fi ọna wa le Ọlọrun lọwọ ninu adura gbígbà, ti a bá nse eleyi, o di dandan fun un lati tọ́ ìsísẹ̀ wa. Nipa sise àfarawe awọn ẹlomiran, iru awọn ti wọn ni ọkan to dabi ti ẹ̀gbẹ́ ọna wọnyi wọn a ma sé aiya wọn le, ti nwọn yio si ma sọrọ ti ko dara ati eleyi ti ko dun gbọ leti si Ọlọrun, laimọ wipe kò sí ẹ̀bi kankan lọwọ Ọlọrun.
(b) IPA OLUKỌ NINU ISORO YI Awọn olukọ pẹlu ni ipa lati ko lori ọrọ Ọlọrun yiye awọn eniyan to niru ọkan bayi, Lẹhin igbati olukọ na bá gba ọrọ ti o fẹ sọ fun awọn eniyan lati ọdọ Ọlọrun tan, oun pẹlu nilati sisẹ lori ara rẹ lati ri daju wipe ọrọ na yé awọn eniyan na. Ki ọrọ Ọlọrun o ba le ye awọn eniyan daradara, awọn nkan wọnyi nilati jẹ otitọ nipa awọn olukọ ọrọ Ọlọrun na: (i) Awọn olukọ wọnyi nilati dá ntọ́ funra wọn, eleyi ni wipe awọn pẹlu nilati jẹ ẹnito dara, ẹnito duro ninu ọrọ na ki nwọn o ba le ma fi apẹrẹ rere lelẹ lẹhin igbati wọn ba ti sọrọ na tan, (ii) Awọn olukọ wọnyi nilati jẹ ẹnito jinlẹ̀ ninu ọrọ na ki nwọn o ba le fi òkodoro ọrọ na han awọn olugbọ wọn, (iii) Awọn olukọ wọnyi nilati jẹ ẹnito ni iriri daradara nipa ọrọ na ati ọna yi lati le sọrọ jade ninu iriri fun imudagbasoke ijọ ati pẹlu ki o ba le yé awọn irufẹ awọn eniyan báwọ̀n yi, (iv) Awọn olukọ wọnyi nilati jẹ ẹnito nse suru pẹlu irufẹ awọn eniyan wọnyi lati ma fi pẹlẹ́ kutù ati ọpọlọpọ suru fi ọrọ na ye wọn (E) OHUN TI KI ISE ÌSÒRO RẸ̀ Ni ìpín to kọja ati wo diẹ ninu awọn ohun to jẹ isoro ọkan to dabi ilẹ ẹba ọna yi. Ninu ìpín yi ẹwẹ a tun fẹ wo diẹ lara awọn ohun ti ki ise isoro ọkan yi gẹgẹbi awọn akọsilẹ inu iwe ihinrere mẹtẹta to sọrọ nipa ilẹ kínní yi. A nilati se eleyi ki a ma ba gbe ọmọ ọbà awọn itumọ ọrọ bibeli wọnyi fun ọ̀sun. (1a) Àìgbọ́ kì íse isoro awọn eniyan wọnyi: ẹ jẹ ka gbọ ọrọ ti Jesu sọ ninu itumọ rẹ. "Awọn ti ẹba ọna ni awọn ti o gbọ..." (Lk. 8:12a) Iwe ihinrere Marku nitirẹ wipe, "Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọna, nibiti afunrugbin ọrọ nã; nigbati nwọn si ti gbọ́..." (Mk. 4:15a) Nigbati iwe ihinrere Matteu na wipe, "Nigbati ẹnikan bá gbọ́ ọrọ ìjọba" (Mt. 13:19a) Jesu Kristi ninu itumọ rẹ fun awọn owe wọnyi wipe irugbin na ti afurungbin na nfún ni ọrọ Ọlọrun na ti awọn eniyan kan tabi ẹnikan gbọ lati ẹnu awọn oniwasu gbogbo. Awọn ti nwọn gbọ ọrọ yi le è gbọ́ ọ larin ijọ, ninu ile, lori ẹ̀rọ-asọrọmagbesi (redio), lori ẹrọ amohunmaworan (tẹlẹfisọn) abbl. Gbogbo ibi yio wu ki awọn eniyan wọnyi o ma se alai ti gbọ ọrọ na ohun to han kedere ni wipe wọn gbọ́ ọ. Àìgbọ ọrọ Ọlọrun ki ise isoro awọn eniyan na. Laiye ọjọun ana ki ihinrere to de ilẹ adulawọ, a ri wipe orisa ni awọn baba nla wa ma nsìn julọ, ọpọlọpọ nse eleyi nitoripe wọn kò gbọ nipa ihinrere ti Kristi Jesu rara. Ninu itan Jesu nipa ọkunrin ọlọrọ kan ati Lasaru ninu iwe ihinrere Luku 16:19-31, a ri wipe awọn mejeji ni wọn gba wipe awọn ti gbọ ọrọ lati ẹnu awọn afurungbin ọrọ nã, nigbati ẹnikan gba ọrọ na gbọ́ tòsì nmulo, ẹnikeji ko gba ọrọ na gbọ, o si tẹsiwaju ninu iwa ati ise rẹ gbogbo, awọn mejeji lẹhin igbati àkókò ti a da fun wọn ninu aiye pé wọn kú, ẹmi wọn si padà tọ Ọlọrun ti o ni í lọ. "Nigbana ni erupẹ yio pada si ilẹ̀ bi o ti wà ri, ẹmi yio si pada tọ Ọlọrun ti o fi i fun ni" (Onw. 12:7) Ninu ọrọ ọkunrin ọlọrọ yi si Abrahamu, a o ri pe ko sọ wipe oun ko gbọ ọrọ na ri, ko si awijare kankan lẹnu rẹ.... Bẹ́ẹ̀ pẹlu niwọ ati emi na, kò lè si awijare kankan fun wa ti a ba fi pàdánù ijọba Ọlọrun. Nitorina, ohun to dara, to se pataki to si se kókó fun wa ni wipe awọn ọrọ Ọlọrun wọnni ti a ngbọ ki a ma mu wọn lo, ki a yipada si ti Ọlọrun patapata ki a si di ẹda titun. (b) Bi iwọ ti o nka iwe yi ba wipe o ò gbọ ọrọ Ọlọrun ri, sugbọn o nka nipa rẹ, nitoripe ìwé yi pẹlu ti o nka yi iwe ọrọ Ọlọrun ni, nitorina ọna yi tun jẹ ọna miran ti Ọlọrun fi mba awọn eniyan sọrọ nipa ara rẹ. Njẹ awọn nkan ti o nka wọnni njẹ o ha n mulo? O lè fẹ sọ wipe awọn miran ti o nka ko yé ẹ, sugbọn awọn eleyi to yé ẹ wọnni bawo ni o se nmu wọn lò si? Ọna miran lati tun gbọ nipa ihinrere, nipa Kristi Jesu ni nipa kika ọrọ rẹ, bi o bá ti kà á, o ti gbọ nipa ọrọ na niyẹn. "Olubukun ni ẹniti nka, ati awọn ti o ngbọ ọrọ isọtẹlẹ yi i, ti o si npa nkan wọnyi ti a kọ sinu rẹ mọ; nitori igba kù si dẹdẹ" (Ifi. 1:3) (2) Riri awọn ohun kan tabi omiran nipa Ọlọrun yi ki ise isoro awọn miran lara wọn. Nitoripe wọn ti ri ohun kan tabi omiran nipa ọlanla ati títóbi Ọlọrun sugbọn sibẹ wọn yàn lati ma tẹle ọrọ rẹ, ki aiye wọn o ma ba yipada ati ki a ma baá gbàwọ́n lọ̀. Awọn ọmọ Israeli ni ilẹ Egipti ri ọpọlọpọ isẹ nla ati isẹ agbara Ọlọrun, se nitotọ awọn ara Egipti pẹlu le è jẹri si awọn isẹ akanse ati awọn isẹ agbara Ọlọrun. Gbogbo awọn nkan wọnyi ti nwọn nri, ni Ọlọrun fi npe ọkàn awọn eniyan pada wa si ọdọ arã rẹ. Eredi pataki ti Ọlọrun fi nse gbogbo awọn nkan wọnni ti o se nilẹ Egipti ki ise lati fi pa awọn eniyan run, sugbọn lati fi sọ fun gbogbo awọn eniyan wipe Ọlọrun kan wa, ati pe ki nwọn o gba Òun gbọ. Sugbọn o seni lanu wipe pẹlu gbogbo nkan ti awọn eniyan ri, sibẹ wọn ko gbagbọ.... Bẹ gẹgẹ na ni laiye ode oni pẹlu gbogbo awọn isẹ agbara, pẹlu gbogbo awọn isẹ akànse ti Ọlọrun nse jakejado agbaiya ti awọn eniyan nri, eredi ti Ọlọrun fi nse wọn ni lati mu awọn eniyan wá si ọdọ ara rẹ, o nse awọn nkan wọnyi lati fi sọ fun awọn eniyan wipe oun ni Ọlọrun, ati wipe ki awa eniyan fi aiye wa fun oun patapata. Sugbọn ohun ibanujẹ ni wipe awa eniyan dípò ti a ó fi bẹru Ọlọrun ti a o si yipada sí i patapata nitori awọn nkan ti a ri nã, nse ni a ntẹsiwaju ninu ẹsẹ wa gbogbo. Riri awọn nkan iyanu, riri awọn isẹ́ akanse Ọlọrun ki ise isoro awọn eniyan wọnyi bikosepe awọn eniyan wọnni yàn lati se ohun to wù wọn. (3) Sisọ ki ise isoro awọn eniyan wọnyi, nitoripe ọpọ wọn gãn lo nsọ ọrọ Ọlọrun kiri sugbọn sibẹ wọn ko yipada, nse ni wọn jẹ olusọ nikan ti wọn ki isi ise olùse ọrọ Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ sini olùse ọrọ Ọlọrun nikan ni a ó da lare. "Sugbọn ki ẹ jẹ oluse ọrọ na, ki o má si se olugbọ nikan, ki ẹ mã tan ara nyin jẹ" (Jak. 1:22) Sisọ ọrọ Ọlọrun kakiri, lilọ lati ojule de ojule; ijọ kan si omiràn abbl ko sọ eniyan di oluse ọrọ nã, bẹ sini oluse ọrọ Ọlọrun nikan ni yio jogun ijọba Ọlọrun. (4) Ibiti wọn wa kọ ni isoro awọn eniyan wọnyi. Awọn miran yio ma sọ wipe ibiti awọn wa ni kòjẹ́ ki awọn gbọ ọrọ afurungbin nã, sugbọn eleyi ko ribẹ fun awọn wọnyi nitoripe ibiti wọn wa gãn ni ọrọ ihinrere nã ti kàn wọ́n lara gẹgẹ bi o se kan Sakeu lara lori igi to wà (Lk. 19). Bẹ pẹlu ló kan Namani adẹtẹ̀ lara nibito wa ninu iyara ọlá ati ọlà rẹ. (2 A. Ọba 5) Nitorina ko si áwijare kankan fun wọn, ngo gbọ́ tabi ngo mọ ko si ninu ọrọ awọn eniyan na nitoripe ọrọ Ọlọrun kàn wọ́n nibiti wọ́n wa gãn. Bi ẹlomiran bá se nkan ti ko dara ninu aiye ti a bá wa sọ fun wipe ohun to se nã ko dara, o le wipe sebi oun kò gbọ́ tẹlẹ, o le wipe oun sẹsẹ de adugbo na ni tabi wipe oun sẹsẹ de inu ilu na, sugbon eleyi ko ribẹ fun ẹniyi nitoripe afurungbin ọrọ na tọ̀ wọn lọ sibiti wọn wà gãn ni. (F) ÀBÁJADE ISORO YI Pẹlu ore-ọfẹ Ọlọrun a ti ri wipe isoro ti awọn ọkàn ti nwọn dabi ilẹ ẹ̀bá ọna nã ní ni wipe ọrọ na ko ye wọn, nitoripe ọrọ na kò yé wọn yi, nse ni wọ́n da ọrọ na nù lojukanna ti nwọn gbọ́ o.... Nigbati a ti wá ri eleyi, a wá nfẹ mọ abajade isoro yi. (1) Jesu ninu owe nã kì ó tó sọ itumọ rẹ wipe, "awọn ẹiyẹ sì wá" (Mt. 13:4; Mk. 4:3). Awọn ẹiyẹ wọnyi ni o sọ ninu itumọ rẹ wipe o tumọ si "ẹni-buburu ni" (Mt. 13:19); "Satani" (Mk. 4:15) ati "Esu" (Lk. 8:12) Awọn ẹiyẹ wọnni ti ise Esu wọn ko sọ pe ki afurungbin na ma furungbin, sugbọn lẹhin igbati afurungbin na furungbin na tán, awọn ẹiyẹ na farahan lati se isẹ wọn. Nihinyi ni a ti ri wipe Satani ko ni sọ pe ki eniyan o ma lọ sile ijọsin, Satani ko ni sọ wipe ki afurungbin na o ma furungbin, eleyi ni wipe Satani kò ni sọ wipe ki awọn oniwasu o ma wasu, nitori nigbamiran Stani mọ wipe oun kò ni agbara lori awọn eniyan na. Nitorina Satani ko ni di awọn oniwasu lọwọ lati lọ wasu, sugbọn lẹhin igbati wọn ba ti furungbin na tan ni yio farahan lati se isẹ tirẹ.... Njẹ kini isẹ ti Satani yio se lori iru ọkan to mbẹ lẹba ọna na? Ẹ jẹ ka ka bibeli. "...Awọn ẹiyẹ sì wá, nwọn si sà á jẹ" (Mt. 13:4; Mk. 4:4) "Awọn ẹiyẹ ojú ọrun si sà á jẹ" (Lk. 8:5) Isẹ ti ẹiyẹ na se lori irugbin na ni wipe o sà á jẹ lẹhin igbati afurungbin na furungbin na tan.... Itumọ ti Jesu Kristi wá fun ifarahan ati ìse awọn ẹiyẹ na niyi: "Nigbati ẹnikan bá gbọ ọrọ ijọba, ti ko ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wa, a si mu eyiti a fun si aiya rẹ kuro..." (Mt. 13:19) "Awọn wọnyi si ni ti ẹ̀bá ọna, nibiti a funrungbin ọrọ nã; nigbati nwọn si ti gbọ, lojukanna Satani wá, o si mu ọrọ na ti a fọ́n si aiya wọn kuro" (Mk. 4:15) "Awọn ti ẹ̀bá ọna li awọn ti o gbọ; nigbana li Esu wá o si mu ọrọ na kuro li ọkan wọn..." (Lk. 8:12) Jesu Kristi ninu awọn ọrọ rẹ wọnyi fi Esù hàn gẹgẹbi ẹiyẹ to wa lati sa irugbin na jẹ. Èsù ni ẹiyẹ nã ti yio wa lati mu ọrọ na ti a fọ́n si aiya awọn eniyan na kuro. A o ri wipe Esu ko ni sọ wipe ki èniyan ma lọ gbọ ọrọ Ọlọrun sugbọn lẹhin igbati eniyan ba gbọ ọrọ na tan, Satani yio wa mu ọrọ na kuro ti ko ba yé ẹni nã. Ere idi niyi ti ọpọ ko se yipada bi o tilẹ jẹ wipe oniwasu npariwo, bi o tilẹ jẹ wipe oniwasu nsọrọ na tọ̀sán-tòru, sugbọn sibẹ awọn eniyan na wọn ko ni iyipada ọkan, nitoripe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ti nwọn ngbọ ọrọ na ni Satani ti wa mu ọrọ na kuro. Abajade akọkọ fun isoro irugbin tó bọ́ si ilẹ ẹ̀bá ọna yi ni wipe eso na kò wọ ilẹ daradara, apakan awọn eso na farahan, nitorina ẹiyẹ rí wọn o si wa, o wa sà á jẹ, bẹ pẹlu ni Esu nigbati o ri ọrọ Ọlọrun ti awọn afurungbin na fun sinu eniyan nã wipe kò yé e daradara, o wa o si mu irugbin ọrọ nã kuro lọkan ẹni na. (2) Awọn miran lara awọn irugbin tó bọ́ si ẹ̀bá ọna na yẹ̀pẹ̀ díẹ̀ bòó loju, nitorina awọn ẹiyẹ tabi ati ẹranko kò rí i, sugbọn bi o tilẹ jẹ wipe wọn kò rí i, sibẹ irugbin na ko se daradara nitoripe nse ni awọn eniyan, awọn ẹranko gbogbo ntẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ bi wọn se nlọ ti wọn mbọ eleyi pẹlu kò jẹ́ ki irugbin na o se daradara nitoripe nse ni wọn tẹ irugbon na pa. "Afurungbin kan kade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ si ẹba ọna; a si tẹ ẹ mọlẹ,..." (Lk. 8:5) Nitoripe ilẹ ti ẹsẹ ngbà daradara ni, nse ni wọn tẹ irugbin na pa tobẹ ti ko fi hù jade. Bẹna ni ọrọ Ọlọrun ti awọn eniyan ngbọ, nitoripe wọn fi aye gba awọn oniruru èrò ti ko ba bibeli mu, awọn èrò ti ara, nse ni wọn tẹ ọrọ na pa ninu aiye ẹni na. "Nitori lati inu, lati inu ọkan enia ni iro buburu ti ijade wa, pansaga, agbere, ipania, "Ole, ojukokoro, iwa buburu, itanjẹ, wọbia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwere: "Lati inu wa ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ" (Mk. 7:21-23) Abajade keji látàrí isoro yi ni wipe awọn èrò buburu tó gba ọkan ẹni na kan mu ki awọn ọrọ na to ti gbọ o ma le se nkankan ninu aiye ẹni na mọ́, awọn ero na sọ ẹni na di alaimọ wọn si tẹ ọrọ na pa ninu aiye ẹni na. "Sugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkan li o ti wa; nwọn a si sọ enia di alaimọ" (Mt. 15:18) Awọn ohun to nti inu jade lati ipasẹ ero enia na ni awọn wọnyi ti ọnkowe Matteu tun kọ yi: "Nitori lati inu ọkan ni iro buburu ti ijade wá, ipania, pansaga, agbere, ole, ẹri-èké, ati ọrọ buburu; "Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ: sugbọn ki a jẹun li àìwẹwọ́ ko sọ enia di alaimọ" (Mt. 15:19-29) Ko si ẹnito nse búburú to dede nse é lọjọkan, irufẹ ẹni bẹ́ẹ̀ yio ti ma ro ohun na fun ọjọ pipẹ lasiko tiru eniyan bẹ ba nro ohun yi, asiko na ni èrò lati se buburu na yio ma tẹ awọn ọrọ Ọlọrun to ti gbọ pa ninu aiye rẹ. Apẹrẹ kan pataki to le tete wa si iranti wa ni ti Kaini ọkunrin akọkọ ti a bi nipa ibalopọ obinrin ati ọkunrin ati eniyan kẹta lorilẹ aiye. Bibeli jẹ kó yé wa wipe lẹhin igbati ẹbọ Kaini kò se itẹwọgba, o "binu gidigidi, oju rẹ si rẹwẹsi" (Gen. 4:5b). Eleyi ni wipe bi inu se bí i tó, ibinu na farahan loju rẹ tobẹ gẹ ti gbogbo eniyan to wa nigbana fi mọ wipe o mbinu. Awọn miran yio binu, sugbọn wọn kò ni jẹ ki ibinu na hàn loju wọn, sugbọn, Kaini ko ri ibinu na pa mọra rara. Lẹhin isẹlẹ yi, ọrọ Ọlọrun wá tọ Kaini wá wipe, "Èése ti inu fi mbi ọ? E si ti se ti oju rẹ fi rẹwẹsi? Bi iwọ ba se rere, ara ki yio ha ya ọ? Bi iwọ ko ba si se rere, ẹ̀sẹ ba li ẹnu ọna, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, iwọ o si ma se alakoso rẹ" (Gen. 4:6-7) Ọrọ Ọlọrun to tọ Kaini wa yi ni wipe ki Kaini o se pẹlẹpẹlẹ ki o si kọ́ bi a se nse rere, ko fi aye gba nkan rere lati ma rin soke, rin sisalẹ ninu ọkan rẹ, ki o mase fi aye gba ero buburu rara, ki Kaini o jẹ ki ọrọ Ọlọrun ti oun, Olori Awọn Afurungbin nsọ le so eso ninu aiye rẹ, ko jẹ ki ọrọ Ọlọrun na o ribi duro si ninu ilẹ̀ ọkan rẹ. Sugbọn o seni lanu wipe Kaini kò gbọ́ eleyi, bikosepe ero buburu na, awọn ero ìkà na lo nlọ to mbọ lori ilẹ ọkan rẹ tó bẹ gẹ to fi tẹ awọn ọrọ Ọlọrun to ngbọ na pa ninu aiye ati ọkan rẹ, tobẹ gẹ to si fi se iku pa arakọnrin rẹ. "Kaini si ba Abeli arakọnrin rẹ̀ sọrọ: o si se, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abẹli arakọnrin rẹ, o si lù u pa" (Gen. 4:8) Ero buburu niti ipaniyan na tẹ ọrọ Ọlọrun na pa ninu ọkan Kaini, o si gbe ero na jade, o si lu Abẹli aburo rẹ ati ọmọ iya rẹ pa. Bi ero buburu na se nse ninu aiye awọn ti ọkan wọn dabi ilẹ ẹ̀bá ọna na ni eleyi, awọn ero buburu na yio tẹ awọn irugbin ọrọ Ọlọrun na pa ninu aiye irufẹ awọn eniyan wọnyi to bẹ ti nwọn yio si wa ma fi èrò buburu na se ìwà hù nibi gbogbo ti nwọn ba de. (3) O seése ki a ri lara awọn irugbin na ti yio hù lori ilẹ na, sugbọn nitoripe ilẹ na jẹ ilẹ̀ ẹ̀bá ọ̀nà a ri mọ wipe awọn irugbin na to ba hù ko ni se daradara. Eredi ni wipe ilẹ̀ ẹ̀bá ọ̀nà yi ma njẹ ilẹ to ni alafo pupọ nitorina omi òjò to ba rọ si ilẹ na kì í duro nibẹ bikosepe ko wọ ilẹ lọ ko si ma se anfani fun irugbin nã tó hù jade. Bẹna ni ọrọ Ọlọrun to bọ si ori ilẹ to dabi ẹba ọna yi, bi irugbin na tilẹ hù, awọn omi ti irugbin na nilo lati dagba ko ni duro lori ilẹ na, nitorina irugbin na tó hù ko ni se rere. Inú awọn eniyan le mã dùn wipe irugbin na hù, sugbọn sibẹ ko ni le mu eso jade. Irufẹ awọn eniyan to niru ọkan wọnyi ni o ma nfi ojojumọ kọ ẹkọ, sugbọn awọn ẹkọ wọnni ko wulo fun wọn. "Nwọn nfi igbagbogbo kẹkọ, nwọn ko si lè dé oju imọ otitọ" (2 Tim. 3:7) Irugbin ọrọ yi ju lori ilẹ aiye (ọkan) awọn eniyan wọnyi nitotọ, sugbọn sibẹ, irugbin na ko se daradara, irugbin na ko mu eso kankan jade, irugbin na kàn ngbilẹ lasan ni. "O si pa owe yi fun wọn pe; ọkọnrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgba ajara rẹ̀; o si de, o nwa eso lori rẹ, ko si ri nkan. "O si wi fun olusọgba rẹ pe, sa wò ó, lati ọdun mẹta li emi ti nwa iwo eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ese ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? "O si dahun o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ li ọdun yi pẹlu, titi emi o fi tu ilẹ idi rẹ yika, titi emi o si fi bu ilẹdu si i. "Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi ko ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ké e lulẹ" (Lk. 13:6-9) Apẹrẹ iru ohun ti a nsọ niyi. Igi ọ̀pọ̀tọ́ ti agbẹ yi gbìn sinu ọgbà na kan "ngbilẹ lasan" ni, sugbọn kò so eso. Igi ọpọtọ yi to asiko to yẹ ko ma mu eso jade, sugbọn kò mu eso kankan jade. Lẹhin igbati olusọgba tun bẹbẹ wipe ki a fi igi na silẹ, a o rika wipe o tun mu eso jade. Ninu ẹ̀bẹ̀ olusọgba na o han wipe kò dá olusọgba na loju wipe igi na yio so eso, ó kàn bẹbẹ fun asiko diẹ fun igi na ni. Bẹ gẹgẹ ni irugbin tó bá hù lẹba ọna lasiko to yẹ ko mu eso jade ko ni mu eso jade, nse ni yio kan ma gbilẹ lasan. Eleyi ni ti iru ọkan to wa lẹba ọna lẹhin igbati ó gbọ́ ọrọ Ọlọrun tan, nse ni gbogbo eniyan ri lẹsẹkanna wipe irugbin ọrọ Ọlọrun na ti hu jade ninu aiye ẹni na, nse lo dabi ẹnipe irugbin na nse dada ninu aiye ẹni na, gbogbo ipade adura ni ẹni na nlọ, gbogbo ipade ẹkọ bibeli ni ẹni na nlọ, gbogbo ìpàgọ́ ati ori oke ni a ti nri ẹni na, sugbọn sibẹ ẹni na ko ni eso lasiko to yẹ ko ma mu eso jade. Awọn miran yio tilẹ ma wi niti ẹni na ni iru asiko bayi wipe awọn ọta idile baba ni ko jẹ ko ni eso, awọn miran yio wipe awọn ọta idile iya rẹ ni, awọn miran yio wipe ọta lati ile aya rẹ ni, awọn miran yio wipe ọta ibi isẹ rẹ ni, se nitotọ awọn kan le è wipe ègún lo fà á; èpè lo fàá; majẹmu ikọkọ tabi gbangba kan lo fàá; a tilẹ tun le ri ninu awọn eniyan ti yio wipe àìkàwé lo fàá; àìlowo lọwọ lo fàá; àì niyawo lo fàá; nitoripe o yàgàn ni ko se ti i so eso...sugbọn ó hàn wipe gbogbo eleyi kò nise pẹlu siso eso ti a nwi. Otitọ ni wipe o dara ki eniyan lówó lọwọ, o dara ki eniyan kọ ile, o dara ki eniyan ni mọto; o dara ki eniyan lọ́kọ tabi ni aya; o dara ki eniyan bi ọmọ ani ati ki eniyan ma se awon nkan rere gbogbo, sugbọn gbogbo awọn nkan rere wọnyi kọ́ lo ma nmu eniyan so èso ti ẹmi ti a nsọ nipa rẹ. Gbogbo oluka bibeli ni yio ranti wipe ọkunrin ọlọrọ to wa ninu iwe ihinrere ti Luku 16:19-31 yẹn se gbogbo nkan rere ti awa eniyan na ma nsọ wipe ó yẹ ki eniyan o se ninu aiye, sugbọn sibẹ ko so eso kankan ninu ẹmi. O dara ki Ọlọrun sẹ́ ogun gbogbo fun eniyan ki eniyan si wa ni alafia gẹgẹbi ọba Solomoni ti se wa ni alafia nigba tirẹ, o dara ki Ọlọrun pa gbogbo ọta idile baba ati ti ìyá eniyan lẹnu mọ; o dara ki eniyan bọ́ lọwọ ègún idile àna, egun idile baba ani ati gbogbo oniruru ègún gbogbo, o dara ki eniyan o ma si ninu majẹmu kankan, sugbọn gbogbo eleyi kọ́ lo di eniyan lọwọ lati so eso fun Ọlọrun ninu ẹmi.... Irugbìn ti a gbin sori ọkan to dabi ilẹ ẹ̀bá ọna na hu nitotọ, o mu inu ẹnito gbìn-ín dun fun igba diẹ, sugbọn ìdùnnú ẹni na kò pẹ́ titi nitoripe kò so eso kankan. Iru awọn eniyan wọnyi ni aposteli Paulu ninu iwe rẹ si Timoteu ọmọ rẹ wipe, "Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, sugbọn, ti nwọn sẹ́ agbara rẹ" (2 Tim. 3:5) Otitọ ni irugbin na hù, otitọ lo han loju bi irugbin didara, sugbọn ni asiko to yẹ ko ma so eso la mọ̀ wipe ki ise irugbin tó yẹ ni dídásí ni. Iru awọn eniyan wọnyi a mã wasu ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan bi ti Judasi Iskariotu, iru awọn eniyan wọnyi a ma dá owo ninu ijọ bi ti Anania ati Saffira aya rẹ; iru awọn eniyan wọnyi a ma se bi ẹnipe awọn ti di atunbi bi ti Simeoni ninu iwe Ise Awọn Aposteli ori kẹjọ; iru awọn eniyan wọnyi le ma fi orukọ Ọlọrun ẹnikan le awọn ẹmi Esu jade bi ti awọn ọmọ Skefa (I. Apo. 19:13-17) Sugbọn sibẹ alaileso niwọn, awọn eniyan ko ri ohun pataki gbamu niti aiye wọn ti awọn fi le ma tẹsiwaju ninu Kristi Jesu na. Wọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, wọn nfi ojojumọ kọ́ ẹ̀kọ́ sugbọn sibẹ kò se wọn ni anfani kankan eleyi to le è mu ki aiye wọn o fi ma so èso. Irugbin ẹba ọna miran le wù, sugbọn isoro rẹ ni wipe ko ni le so eso daradara tabi ko ma so eso kankan, nitorina yio di kike lulẹ ati wiwọ lọ sinu iná, eleyi ni wipe ẹni na ki yio jogun ijọba Ọlọrun. (4) Nitoripe ilẹ ẹba ọna yi jẹ ilẹ to ni alafo pupọ, ati ilẹ to ma nni awọn okuta nla nla, nitorina, awọn ohun alumọni to yẹ ko sisẹ fun irugbin na ninu ilẹ ko ni si nibẹ, wọn yio wa nibiti gbongbo irugbin na ko le de nipa eleyi ti irugbin na kò ní fi se rere. Bẹ pẹlu ni awọn ọrọ Ọlọrun to yẹ ki o se irugbin ọrọ na lore, awọn ọrọ Ọlọrun to yẹ ko mu irugbin na se daradara ni ko si ni àrọ́wọ́tó gbongbo irugbin na to hù lẹna ọna na. Eleyi ni wipe nigbati ẹlomiran bá ní igbala tan, awọn ọrọ miran to nilo fun imuduro ati idagbasoke rẹ ninu igbala ko ni nifẹ si awọn ọrọ na, eleyi ti yio mu ki irugbin igbala na pãpã o dòkú ninu aiye rẹ nigbose ti yio si di apadasẹhin. Awọn ẹlomiran niru ikorita yi, wọn yio gbe ẹ̀kọ́ kan ga nigbati wọn yio dagunla tabi kọ ẹhin si awọn ẹkọ miran, wọn le wipe ẹkọ iwa mimọ nikan ni tawọn, wọn le wipe ẹkọ igbeyawo nikan ti tawọn abbl. Nigbati wọn ba gbe awọn ẹkọ wọnyi ga, wọn yio yan awọn ẹkọ yoku ni ìpọ̀sì, eleyi ti yio tun wa se àkóbá fun irugbin eleyi ti a ro tabi ti a ri wipe ó hù ninu aiye wọn nã. Kini idi? Idi ni wipe awọn ẹkọ yoku wọnyi ló dabi awọn ohun elo ti yio se ẹkọ ti ohun gbàgbọ lore, sugbọn nitoripe o sé ilẹkun ọkan rẹ mọ awọn ẹkọ na, awọn ẹkọ na jinna si arọwọto rẹ, wọn ko si le se irugbin to hu ninu aiye rẹ na lanfani. Gẹgẹbi ẹya ara ko se le ya ara wọn nipa kuro lara wọn, bẹna ni gbogbo ọrọ ati gbogbo ẹkọ inu bibeli. Gbogbo wọn lo nsisẹ papọ mọ ara wọn. Abajade isoro miran na ni wipe awọn ohun alumọni inu ilẹ ẹba ọna na wa ni ibito jìnnà si irugbin na, eleyi to ba tilẹ hù lara wọn, nitorina irugbin to hu na ko se rere. (5) Ilẹ ẹba ọna ko ni awọn kokoro aile fojuri to nmu ki ilẹ o se daradara nitosi tabi ki o ma tilẹ ni wọn rara, nitorina awọn omi ati awọn ohun gbogbo ti ilẹ na nilo fun ati mu irugbin dagba ni ko ni si ni àrọwọtó eyikeyi irugbin na to bá bọ si ẹba ọna. Irufẹ awọn eniyan ti wọn ni iru ọkan ẹba ọnà yi, awọn eniyan ti wọn le se wọn lanfani ninu igbagbọ nse ni wọn ma njìnnà si wọn, nitoripe wọn ko fẹ ma gbọ otitọ ọrọ Ọlọrun, wọn ko nifẹ si ọrọ Ọlọrun ti yio bá aiye wọn wi. "Nitoripe igba yio de, ti nwọn ki yio le gba ẹ̀kọ́ ti o ye koro; sugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti etí nrin nwọn o lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. "Nwọn o si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ nwọn o si yipada si ìtàn asán" (2 Tim. 4:3-4) Iru awọn eniyan ti nwọn ni ọkan to dabi ilẹ ẹba ọ̀na yi, wọn a ma sa fun awọn ti yio ba wọn sọ otitọ ọrọ Ọlọrun ti nwọn yio si ma yan ọrọ to wu wọn lati gbọ fun ara wọn, wọn yio ma gbe olukọ dide fun ara wọn, wọn yio ma gbe alufa ati woli dide fun ara wọn lati le ma sọ ohun ti nwọn nfẹ gbọ fun wọn. Bi nwọn se nse eleyi na ni wọn yio tun jìnnà si ẹmi mimọ, wọn ko ni fi aye silẹ idari Ẹmi Mimọ, wọn yio ma sọrọ òdì si awọn ohun gbogbo ti nwọn ko mọ nkan nipa rẹ. "Sugbọn awọn wọnyi nsọrọ-odi si ohun gbogbo ti nwọn ko mọ" (Juda 1:10a) Bi awọn kokoro àilefojuri ati awọn ohun abẹ̀mi miran ko tilẹ sisẹ ninu ilẹ na mọ, bẹ pẹlu ni awọn eniyan ti ọkan wọn dabi ilẹ ẹ̀bá ọna yi jinna si awọn ohun gbogbo, awọn ẹni gbogbo to le è se wọn lanfani lati mu igbesi aiye wọn dagba. Gẹgẹbi irugbin to ba sèsì hù ninu ilẹ ẹba ọna na ko ti ni ri nkan ti yio mú u dagba bẹ na ni awọn ti nwọn ni ọkan to dabi ilẹ yi ko ní ri ohun ti yio mu wọn dagba, lopin eyiti irugbin na yio ku. (G) KINIDI TI ESU FI SE ELEYI? Satani kì í dede se nkan laini itori ninu, Olorun nikan lo le se nkan laini tori ninu. Ninu akọsilẹ to wa ninu iwe ihinrere ti Luku ni a se ri idi ti Satani fi wá lati mu ọrọ na kuro ninu ọkan awọn ti nwọn gbọ ọrọ na. (1) KI NWỌN O MA BÃ GBAGBỌ: Satani ti mọ wipe nigbati ọrọ Ọlọrun ti awọn eniyan wọnni gbọ́ bá sinmi lokan aiya wọn, nigbati wọn ba ri aye joko ronu lori ohun ti wọn gbọ, nigbana ni wọn yio le yipada ti nwọn yio si le gbagbọ, oun, Esu, si niyi ko fẹ ki gbogbo eniyan o ronupiwada, nitorina lo se wá to si sé aiya awọn eniyan wọnni le lẹhin igbati wọn gbọ ọrọ na tan, tó si wa mu ọrọ na kuro lọkan wọn.... Ó se gbogbo eleyi nitoripe kò fẹ ki nwọn o gbàgbọ́. Bi a bá mba eniyan sọrọ to ba wa ọrùn rẹ kì to si se aiya rẹ le si awọn ọrọ ti a nsọ na, ohun ti yio tẹle awọn ohun to se wọnni na ni wipe Satani yio wa lati mu awọn ọrọ̀ wọnni na kuro lokan aiya rẹ, eleyi ti yio si yọri si wíwà ati titẹsiwaju ni ipo àìgbagbọ rẹ, nipasẹ eleyi na ni yio se parun lojiji ti ko si ni si atunse mọ́. "Ẹniti a ba mbawi ti o wa ọ̀run ki, yio parun lojiji, laisi atunse" (Owe 29:1) Idi àkọ́kọ́ ti Satani fi wa mu ọrọ na kuro lọkan awọn ti nwọn gbọ́ ọ ni wipe ki nwọn o ma ba gbagbọ. "Awọn ti ẹba ọna li awọn ti o gbọ: nigbana ni Esu wá o si mu ọrọ na kuro li ọkan wọn, ki nwọn ki o ma ba gbagbọ, ki a ma se gba wọn la" (Lk. 8:12) (2) KI NWỌN O MA BA DI ẸNI IGBALA: Idi keji ti Satani se wa mu ọrọ na kuro lọkan awọn wọnyi ni wipe ki nwọn o ma ba ri igbala, ki nwọn o ma ba di atunbi, ki wọn o ma ba jogun ijọba Ọlọrun. Owe awọn agba kan to wipe "a jẹ ègbodò nwá ẹni-kunra" ohun lohun ti Esu nse, Esu ti mọ wipe oun ko lọ ijọba rere na mọ, nitorina gbogbo ọna lo ngbà lati ri daju wipe ko si ẹniti yio de ọrun rere na pẹlu. Ere idi niyi to se nwá lati mu ọrọ na kuro lọkan awọn eniyan wọnyi. O ma njẹ iyalẹnu nigbamiran fun eniyan ani awọn afurungbin na lẹhin igbati wọn bá fi ọpọlọpọ apẹrẹ ati suru sọ ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan sugbọn sibẹ ti nwọn nwipe ọrọ na ko ye awọn.... Lẹhin o rẹhin, Satani yio wa lati mu ọrọ na kuro lọkan wọn patapata ti ilẹkun ijọba ọrun yio si ti mọ awọn eniyan na. Gbogbo ọrọ Ọlọrun ti iwọ na ngbọ pẹlu oniruru akawe ati apẹrẹ lati ẹnu awọn oniwasu, sugbọn sibẹ ti o nsọ wipe kò ye ẹ, njẹ ki ise wipe kòtò iparun ti Satani ti gbẹ́ kalẹ ni o fẹ lọ jìn si bayi? Ọrọ̀ tó hàn gbangba, wà á sọ wipe ko ye ẹ sibẹ, ki o sa le fi idi ara rẹ mulẹ ni, awọn miran pẹlu yio ma sọ wipe ọrọ ti awọn ngbọ kò yé wọn ki nwọn o ba le pọ́ ifun oniwasu na, sugbọn lẹhin gbogbo pípọ́ oniwasu na nifun sibẹ wọn yio tun sọ wipe ko ye awọn na ni. Lẹhin igbati wọn ba tẹsiwaju ninu ikorita yi ni Satani yio wa lati mu gbogbo ọrọ na kuro, ti nwọn yio si wá wà nipo òpè titi, nipasẹ eleyi ti nwọn yio si fi pari irin ajo wọn si ọrun apadi. Se ki ise iru ipò ti iwọ na wà ni eleyi? (H) IBERE: Olusoagutan Spurgeon ninu ọrọ rẹ lori iru awọn eniyan ti nwọn niru ọkàn to dabi ti ẹba ọna yi wipe, nigbati o jẹ wipe iru awọn eniyan wọnyi ma nwa sile ijọsin, iru wọn lo ma npọ nibi isẹ ìsìn ijọ ati oniruru ipade gbogbo, sugbọn sibẹ ti ọrọ Ọlọrun na kuna lati ri aye ninu aiye wọn. O wa joko lati bere lọwọ ara rẹ wipe, kinidi ti awọn eniyan wọnyi se ntẹsiwaju lati ma wá sinu ijọ gãn? Wọn ti nwa tipẹ sugbọn sibẹ aiye wọn ko yipada. Wọn le sebi igbati aiye wọn yipada larọ sugbọn to ba fi ma to isẹju kan si asiko na wọn yio tun ti padà si ikorita ti nwọn wà tẹlẹ. Kini ohun ti wọn wa nwa wa gãn? Idahun ti olusọagutan na ni fun ọrọ na ni wipe wọn ntẹsiwaju lati ma wá ki awọn eniyan bàá le mọ wọn gẹgẹbi ẹlẹ̀sìn. "Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, sugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu" (2 Tim. 3:5) "Nitoripe igba yio de, ti nwọn ki yio le gba ẹkọ ti o ye koro; sugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrin nwọn o lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn" (2 Tim. 4:3) Wọn nwa lati fihan wipe awọn ni ìwà bi Ọlọrun, ti o tilẹ jẹ wipe nse ni wọn nsẹ agbara rẹ. Wọn nwa lati fihan wipe awọn ni iwa mimọ bi o tilẹ jẹ wipe aiye wọn kún fun ẹ̀gbin gbogbo. Wọn nwa lati fi ara wọn han gẹgẹbi ẹnito sunmọ Ọlọrun bi o tilẹ jẹ wipe lọdọ̀ Satani ni nwọn wà. Wọn nwa lati le ri awọn ti nwọn yio bawọn se isọmọlorukọ, awọn ti nwọn yio ba wọn lọ sibi igbeyawo wọn tabi igbeyawo awọn ọmọ wọn, wọn nwa lati le ri awọn ti yio ma gbadura fun wọn nigbati wọn ba gbe àpótí ìbò, nigbati wọn ba di olóselu, wọn nwa ki nwọn o ba le ma ri awọn ti nwọn yio jijọ ma kàwé; nwọn nwa ki nwọn o ba à le ri awọn ọmọ Ọlọrun ti yio ma sanu wọn nigbati wọn ba nfẹ iranlọwọ kan tabi omiran.... A o ri wipe awọn eredi ti nwọn se nwa wọnyi ko nise pẹlu dide ọrun, eredi ti nwọn se nwa wọnyi ko nise pẹlu didi ẹda titun, eredi ti nwọn se nwa wọnyi ko nise pẹlu didi eniyan mimọ, eredi ti nwọn se nwa wọnyi ko nise pẹlu gbigba Ẹmi Mimọ sinu aiye wọn.... Eredi niyi ti ijọ se nri bose nri loni, ere idi niyi ti a se nri awọn eniyan ìkà ati awọn aseku pani eniyan ninu ijọ ati ninu ìgbàgbọ́ gbogbo. "Nitori larin enia mi ni a ri enia ika, nwọn wo kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okun nwọn mu enia" (Jer. 5:26) Njẹ nitori kini awa na se nwa sinu ijọ loni? Nitori kini awa na se darapọ mọ ijọ Ọlọrun? Nitori kini awa na se nfi ara wa han gẹgẹbi onigbagbọ? Nitori kini a se nse awọn nkan ti a nse ninu ijọ? O Kan Ìwọ Náà Apá Kẹta mbọ̀ lọ́nà….

Comments

Popular posts from this blog

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah