Kì Íse Tẹni ti Nfẹ
(“Njẹ bẹni ki ise ti ẹniti o fẹ, ki si ise
ti ẹniti nsare, bikose ti Ọlọrun ti nsanu” (Rom 9:16))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati
mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ
orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin
yi si Oluwa.
Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle larin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan”
Orin Titun na Nìyí
1. Gba Kaini oun Abeli
Wọn ru ẹbọ s’Ọlọrun
Ọlọrun gb’ẹbọ Abeli
Ti Kaini ni ko tẹwọgba
Ègbè
Ki ise tàwọn ti wọn fẹ
Tabi tẹni ti nsare
Bikoba se t’Oluwa
Oun l’Ọlọrun to nsanu
2. Gbat’Esau oun Jakọbu
Si wa ninu iya wọn
Gbana l’Ọlọrun ti sọ
P’ẹgbọn ni yo sin aburo
Ègbè
3. Ọmọ ọkọnrin mejila
Ni a bí fun Jakọbu
Sugbọn Josẹf’ l’Ọlọrun
Yan lati s’olori wọn
Ègbè
4. Adẹtẹ pọ nlẹ Israel
Lasiko woli Elisa
Ko s’ẹ ni to ri ‘wosan
Bikose Naaman ti Syria
Ègbè
5. Ọdun mejidinlogoji
Ni abirun kan ti lo
Leti odo Bẹtsaida
Oun nikan n-Jesu wosan
Ègbè
6. Kise latila tabi
Iwọ ohun gusu orun
Ni igbeleke ti nwa
Bikose lat’ọdọ Ọlọrun
Ègbè
7. Oluwa ni o le pa
Oun lo le sọ di ãye
O le sọ di talaka
O tun le sọ d’ọlọrọ
Ègbè
8. Oun na lo ngbe talaka
Soke latinu erupẹ
Oun lo ngb’alagbe soke
A mu wọn jogun ‘tẹ ògo
Ègbè
9. Nitorina lo wipe
Ngo sãnu f’ẹni mo nfẹ
Ngo se iyọnu fun awọn
Temi yio se yọnu fun
Ègbè
Comments
Post a Comment