Orin Kan: Dá Mi Lohun Lọgan

 

(“Mase pa oju rẹ mọ kuro lara mi li ọjọ tie mi wa ninu ipọnju: dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pe, da mi lohun lọgan” (O. Daf. 102:2))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“Wọ Jesu t’a ti nreti

Lati gba wa lọw’ ẹsẹ

‘Gbawo ni ‘gbala yo de

Ti ao da ide ẹsẹ

Ẹniti o Kọrin Yi:



 Orin Titun na Nìyí

1. Gbọ adura mi Oluwa

Nigbati mo kepe Ọ

Tẹti s’ohun ẹbẹ mi

Ko dami lohun lọgan

 

2. Jẹki ‘gbe w’ọdọ rẹ

‘Gba mo wa ninu ‘pọnju

Fi anu rẹ han fun mi

Ko dami lohun lọgan

 

3. L’owurọ, l’ọsan, l’alẹ

Lemi o ma gbadura

Gba mob a mba Ọ sọrọ

Ko dami lohun lọgan

 

4. ‘Gba ‘we ẹbẹ adura mi

Ti mo kọ nin’ ọkan mi

Si wọ Oludande mi

Ko dami lohun lọgan

 

5. ‘Wọ f’eti si ẹkun mi

Ma dakẹ somije mi

Nitor’ oju mi nwo Ọ

Ko dami lohun lọgan



Comments

Popular posts from this blog

Displacing Yourself to Please Others, It Does Not Mean They Would Pay You Back

ÒWE YORÙBÁ (YORÙBÁ PROVERB)

Think of the Future