Orin Kan: Ọrọ Rẹ Nitunu Mi

(“Eyi ni ìtunu mi ninu ipọnju mi: Nitori ọrọ rẹ li o sọ mi di ãye.” (Orin Daf. 119:50))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“Ẹ jẹ k’a f’inu didun

Yin Oluwa Olore

Ègbè

Anu Rẹ o wa titi

Lododo dajudaju

Ẹniti o Kọrin Yi:



 Orin Titun na Nìyí

1. Mase gbagbe ọrọ Rẹ

Si emi ọmọ-ọdọ rẹ

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

2. Ọrọ Rẹ na lo fun mi

Nireti ngba ‘reti pin

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

3. Nipa ọrọ rẹ lemi

Tun wa fi di alaye

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

4. Nipa ọrọ Ọlọrun

Lemi d’alabukun fun

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

5. Nin’ ọrọ ni mo fi mọ

Ẹni na to ngbeni ga

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

6. Ọrọ rẹ lo sọ fun mi

Nipa onidajọ aiye

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

7. Ọr’ Ọlọrun ye o lagbara

O mu ju ‘da lojumeji lọ

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

8. Ọrọ rẹ nfasiri ‘kọkọ han

‘Tori ohun l’awojiji

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju

 

9. Mo gbin ọrọ ẹ sọkan mi

K’ emi ma ba sẹ si ọ

Ègbè

‘Tor’ ọrọ rẹ n’tunnu mi

Gba mo wa ninu ‘pọnju



Comments

Popular posts from this blog

Displacing Yourself to Please Others, It Does Not Mean They Would Pay You Back

ÒWE YORÙBÁ (YORÙBÁ PROVERB)

Think of the Future