Orin Kan: Tọ Ọmọde

(“Tọ ọmọde li ọna ti yio tọ: nigbati o si dagba tan, ki yio kuro ninu rẹ.” (Owe 22:6))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“O ti dara to lati ri

Awọn ara ni irẹpọ

T’ero at’ ọrọ wọn j’ọkan

Ti nwọn nfi ‘gbagbọ at’ ifẹ

Ègbè

Jumọ nwa ohun ti ọrun

Wọn nkede okiki Jesu

Jumọ nwa ohun ti ọrun

Wọn nkede okiki Jesu

Ẹniti o Kọrin Yi:



 Orin Titun na Nìyí

1. Ẹ jẹ ka tọ ‘wọn ọmọ wa

Lati igba ewe wọn wa

Nitor’ ọmọ ti a ba tọ

Ni yo f’obi rẹ nisinmi

Ègbè

Tọ ọmọde lọna ti yio tọ

Nigbato ba si dagba tan

Ki yo le kuro ninu rẹ

T’ọmọ rẹ ngba to wa lewe

 

2. Were lo di s’aya ọmọde

Pasan ‘tọni ni yio le jade

Kuro ni okan aiya rẹ

Nibito fi ikalẹ si

Ègbè

 

3. B’oba f’ọwọ pasan sẹhin

Kuro lara ọmọ t’o bi

Iwọ korira ọmọ rẹ

‘Torina ma f’ọwọ bawi sẹhin

Ègbè

 

4. Ẹnito fẹran ọmọ rẹ

A ma bawi ‘gbati reti wa

Nitori oun mọ eyi pe

Ibawi ki I p’ọmọde

Ègbè

 

5. Gbogbo ọmọ ti baba fẹ

‘Wọn na ni baba ma mbawi

‘Gbọn ọmọ ti a ko bawi

Ọmọ ale niru ọmọ na

Ègbè

 

6. Ọmọ t’aba jọwọ funra rẹ

Iru wọn lo ndojut’ obi wọn

Ọmọ t’aba nfẹ ki o gbọn

A o ni jọwọ rẹ fun ra rẹ

Ègbè

 

7. ‘Gbati aba mb’ ẹyin ọmọ i

Ẹ mase jẹ k’ọkan yin rẹwẹsi

Mu suru labẹ ibawi

Ko le k’ẹkọ to ye koro

Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Displacing Yourself to Please Others, It Does Not Mean They Would Pay You Back

ÒWE YORÙBÁ (YORÙBÁ PROVERB)

Think of the Future