Orin Kan: Sọtẹlẹ Ni Ìgbàgbọ
( “O tun wi fun mi pe, s ọtẹlẹsori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ ọrọ Oluwa” (Esek. 37:4)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ Ọrẹ bi Jesu ko si laye yi Oun nikan l’ọrẹ otitọ Ọrẹ aye yi y’o fiwa silẹ Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa Ègbè Ah! Ko jẹ gbagbe wa/2x Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa ” Orin Titun na Nìyí 1. Ọwọ Oluwa wa lara Esekiel’ O mu jade ninu ẹmi Rẹ Lọ s’arin afonifoji to kun Fun orisirisi egungung Ègbè ‘Gungun wọnyi yo ye/2x Bo ba s’ọtẹlẹ s’ wọn ni ‘gbagbọ 2. Oluwa mu ko sir in yi wọn ka Oun si ri pe wọn gbẹ pupọ Oluwa bi lere bi wọn le ye O dahun p’Oluwa lo le mọ Ègbè 3. Olu...