Orin Kan: Mã Se Ìtọ ati Amọna Mi
( “Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: Nitorina nitori orukọ Rẹ mã se ìtọ mi, ki o si ma se amọna mi” (Psa. 31:3)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ Gbẹkẹle l’arin ‘danwo Bi ‘gbagbọ tilẹ kere Gbẹkẹle Jesu nikan Ègbè Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo Gbẹkẹle lojojumọ Gbẹkẹle lọnakọna Gbẹkẹle Jesu nikan” Ẹniti o Kọwe: Olùpilẹsẹ Ìwe: Olùtumọ: Orin Titun na Nìyí 1. Dẹti rẹ silẹ simi Gba mi ni isinsinyi Iwọ li mo gbẹkẹle Iwọ Ọlọrun ‘gbala Ègbè Iwọ l’apata at’odi mi Nitori orukọ rẹ Jọwọ ma se itọ mi Ki o si s’amọna mi 2. Okunkun b’aye mọlẹ O sofo o ri juju Sugbọn Iwọ n’ Imọlẹ ...