Orin Kan: Ohun To Sowọn Lati Se
( “Nitori o s ọwọn ki ẹnikan ki o to ku fun Olododo: sugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le daba ati ku” (Romu 5:7)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mura ẹbẹ ọkan mi Jesu nfẹ gb’ adura rẹ O ti pe k’o gbadura Nitorina yio gbọ Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ọlọrun fifẹ rẹ han ‘Fẹ to ga ju lo fihan ‘Gbato ran ‘mọ re waiye Lati wa ku f’ẹsẹ wa 2. O sọwọn ki a to ri Ẹnit’ yo gba lati ku Fun olododo enia Ti o mbẹ ni awujọ 3. Sugbọn fun ẹni rere Boya a le r’ẹnikan Ti yo daba lati fi Ẹmi rẹ lele f’oun 4. ‘Gbata ko le rẹnikan Lati ku f’olododo Tab’ ẹni rere aiye Melomelo awa ẹlẹsẹ ...