Orin Kan: Ọkan Ọba Wa lọwọ Oluwa
( “Aiya Ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odo omi: on a si dari rẹ si ibikibi ti o wu u ” (Owe 21:1)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ọna ara l’Ọl ọrun wa Ngba sisẹ rẹ l’aiye A nri ‘pasẹ rẹ lor’ okun O ngun igbi l’ẹsin Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ọkan Ọba wa ni ọwọ Oluwa b’od’ omi Oluwa lo si ndari rẹ Sibikibi to fẹ 2. Gẹgẹ b’ọkan ọba ti mbẹ Ni ọwọ Oluwa Bẹna l’ọkan enia gbogbo To ngbe ninu aiye 3. Ọga ogo nis’ olori Ni ‘jọba enia Oun a si fi ijọba fun Ẹnikẹni to wu 4. Gbogb’ ẹnyin to nse akoso Awọn enia ‘nu aiye Ẹ m’aisedede jinna si Ibugbe yin laiye 5. Ẹ f’ododo j’ẹsẹ kuro Leto isejọba yin...