Orin Kan: Ìfẹ To Gaju
( “Ni ij ọ keji Johannu ri Jesu mbọ wa sọdọ rẹ; o si wipe, wo o ọdọ agutan Ọlọrun, ẹniti o ko ẹsẹ aiye lọ! ” (Jhn 1:29)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Boruk ọ Jesu ti dun to Ogo ni fun orukọ rẹ O tan banujẹ at’ọgbẹ Ogo ni fun orukọ rẹ Ègbè Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ Ogo f’orukọ Oluwa Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ Ogo f’orukọ Oluwa Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ìfẹ to ga julọ laiye lọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ọmọ bibi kansoso t’Ọlọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ègbè Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun 2. Ẹbun ọfẹ to ga ju laiye lọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ọmọ kan...