Orin Kan: Bi Ẹnyin Ba Bere Ohunkohun Ni Orukọ Mi, Emi O Se E
 
( “Bi ẹnyin ba bere ohunkohun ni orukọ mi, emi o se e.”  (Joh. 14:14))    Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:    N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi   “’Gbati ipe Oluwa ba dun, t’aye y’o si fo lọ   Ti imọlẹ ọjọ titun y’o si de   Nigbati awọn ọmọ igbala ba pejọ l’oke   T’a ba si p’orukọ nibẹ, un o wa m’bẹ       Ègbè   ‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun/3x   ‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun, un o wa mbẹ   Ẹniti o Kọrin Yi:        Orin Titun na Nìyí   1. Lotọ ati lododo ni ohun temi nwi fun nyin   Isẹ tie mi nse lawọn to gbami yo se   Ani ‘sẹ to tobi juyilọ nisẹ ti wọn yo se   ‘Tori Emi npada lọ s’ọdọ Baba   Ègbè   Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere/3x   Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere lorukọ mi lem’o se       2. Ki a ba le yin baba logo ani ninu...
 
 
 
 
 
 
