Orin Kan: O Dájú Wipe Yio Gba Awọn Israeli ti Ẹmi Na Pẹlu
( “Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egypti ti ko mọ Josẹfu” (Eks. 1:8)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ko tọ k’ awọn mimọ bẹru Ki nwọn sọ ‘reti nu ‘Gba wọn ko reti ‘ranwọ rẹ Olugbala y’ o de ” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. O si se lopin ọjọ wọnni Lẹhin ‘ku Josẹfu Ọba miran jẹ ni Egypti Ti ko mọ Josẹfu 2. Awọn ọmọ ‘Sraeli bi si Wọn si rẹ nilẹ na Wọn di alagbara nla gan Ilẹ na kun fun wọn 3. Ọba titun ni Egypti P’ awon oloye rẹ jọ Wọn gbimọ pọ wipe ki wọn F’ ọgbọn ba ‘Sraeli lo 4. Wọn yan awon ‘konisisẹ Bẹni wọn npọn wọn loju Wọn f’ awon enia Rẹ s’abẹ Isinru to le gan 5. Sugbọn aw...