Orin Kan: O Rọrun Fun Ibakasiẹ Lati Wọ Oju Abẹrẹ
( “O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ oju abẹrẹ ju fun ọlọrọ lati wọ ijọba Ọlọrun lọ” (Mar. 10:25)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ ’Wọ Jesu t’a ti nreti Lati gba wa lọw’ ẹsẹ ‘Gbawo ni ‘gbala yo de Ti ao da ide ẹsẹ ” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. ‘Gba Jesu wa ni aiye P’ẹlawọn ‘mọ-ẹhin rẹ Ọmọkunrin kan tọ wa Lati ber’ ohunkan lọwọ rẹ 2. ‘Gba to de ọdọ Jesu O sọ p’ol’kọni rere Ohun rere ki lem’ o se Kinle niye ainipẹkun 3. Jesu si fun l’esi pe Ẹni rere kan ko si Bikos’ ẹnikan soso Ẹni na si l’ Ọlọrun 4. ‘Gbọn bi ‘wọ ba fẹ niye ‘Wọ nilati p’ofin mọ Base kọ sinu ‘we ofin Gẹgẹ bi ‘wọ tise ka ...