Orin Kan: Afunrugbin Na
( “Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.. ” (Matt. 13:3)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mase foiya ohunkohun Ọlọrun yio tọ Ọ Ma gbe ibi ikọkọ rẹ Ọlọrun yio tọ Ọ Ègbè Ọlọrun yio tọ Ọ Lojojumọ lọna gbogbo Oun yio ma tọju rẹ Ọlọrun yio tọ Ọ” Orin Titun na Nìyí 1. Ni akoko ifunrugbin Afunrugbin kan jade ‘Tor’ asiko wa f’ohun gbogbo Afunrugbin kan jade Ègbè Afunrugbin na jade Lati lọ fun irugbin rẹ Ọrọ ‘jọba ọrun Ohun ni irugbin na 2. Afunrugbin na jade lọ Lati lọ funrugbin Orisi ilẹ mẹrin ni ‘Rugbin to fọn bọsi Ègbè 3. Ilẹ akọkọ l’ẹba ọna Mbi tawọn kan bọsi...